ElectionsFact CheckYoruba

Ìdìbò 2023: Ǹjẹ́ lóòótọ́ ni pé àjọ INEC Kì yóò kà àwọn ìbò wọ̀nyí?

Àhésọ: Àwòrán kan tí ó fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ipò òǹtẹ̀ ìka hàn, tí ó ṣàfihàn èyí tí àjọ INEC yóò kà àti èyí tí kì yóò kà lọ́jọ́ ìdìbò.

Àbájáde ìwádìí: Irọ́ ni èyí. Ìwádìí fihàn pé gbogbo ipò òǹtẹ̀ ìka tí ó hàn nínú àwòrán yìí ní àjọ INEC yóò kà mọ́ ìbò.

Ìròyìn Ní Kíkún 

Ìdìbò gbogbogbò orílẹ̀-èdè Nàìjíríà yóò wáyé ni ọjọ́ kẹẹ̀dọ́gbọ̀n, oṣù kejì ọdún yìí. Bí èyí ṣe ń súnmọ́lé ni oríṣiríṣi àlàyé yóò ma wáyé láti ṣe ìgbáradì fún àwọn olùdìbò. Ṣùgbọ́n, gbogbo àlàyé yìí kọ́ ló ma ń jẹ́ òtítọ́.

Láìpẹ́ yìí, àwòrán oríṣiríṣi òǹtẹ̀ ìka tí àwọn ènìyàn ń pín kiri lórí ìtàkùn ìbáraẹnidọ́rẹ̀ẹ́ Facebook, WhatsApp àti Twitter, pẹ̀lú àlàyé nípa ìpò tí o tọ́ fún ìbò àti èyí tí kò tọ́.

Gẹ́gẹ́ bí àwòrán yìí, ìka ti ènìyàn bá tẹ̀ sí iwájú lógò ẹgbẹ́ òṣèlú nìkan ni ó tọ́. Èyí túmọ̀ sí wípé, tí ìka rẹ bá kọjá tàbí tí o kàn ilà orí pépà ìbò rẹ, wọn kò ní káà mọ́ ìbò.

             Àhesọ tí à n sọ̀rọ̀ rẹ̀.

Nígbà tí àwọn tí ó gba àtẹ̀jáde yìí gbọ ti ń pin káàkiri, àwọn kan lórí ‘Twitter’ ṣàìgbà, wọ́n wípé ìdìbò kò lè já sí asán àyàfi tí o bá ṣòro lati mọ ibi ti ènìyàn tẹ ìka rẹ sí.

Pàtàkì àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí àti ìdí láti tanná sí ìpòruru tí wọ́n lè fa, ló jẹ́ kí a ṣe ìwádìí yìí.

Ìṣàmúdájú

Kí ni pàtàkì òǹtẹ̀ ìká 

Òǹtẹ̀ ìká jẹ́ àmì tí a ṣe sórí ǹkàn pẹlú abẹ́ ìka. Ó jẹ́ ohùn tí tí  ènìyàn méjì kò leè bára mu.

Ní orí kẹ́rin, ẹsẹ kéjìléláàádọ́ta, ìwé òfin ìdìbò títún 2022 tí àjọ elétò ìdìbò INEC fi le’lẹ, àjọ ọ̀hún fihàn pé àwọn yíò lo íńkì tí a kò lè parẹ́ fún itẹ̀ka àwọn olùdìbò.

Abala kan lábẹ́ ẹsẹ yìí kannáà fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé: “Níbikíbi tí olùdìbò bá fi ohunkóhun tó yàtọ̀ sí íńkì tí a kò lè parẹ́ tẹ ìbò, tàbí tí a fi òǹtẹ̀ ìka ṣe àbàwọ́n sí ara pépà ìdìbò, àjọ INEC kì yóò káà eléyìí mọ ìbò.

Ìka wo ni mo le lò láti fi dìbò?

Àjọ INEC ti ṣàrídájú pé olùdìbò leè lo ìka tíó wù wọ́n fi dìbò.

Gẹ́gẹ́ bí ìwé àfọwọ́ṣe tí INEC ṣe fún àwọn òṣìṣẹ́ ìdìbò, dandan ni kí a fi íńkì tí a kò lè parẹ́ s’ábẹ́ ìka tí a ó fi dìbò, pẹlú ipasẹ̀ irú ìdìbò tí a fẹ́ dì.

Fún ìdìbò gbogbogbò, a ó fi íńkì sí èyíkéyìí nínú ìka marun. Ṣùgbọ́n bí kìí bá ṣe tí gbogbogbò, abẹ́ àtànpàkò ọwọ́ òsì ní íńkì yíò wà.

Ọ̀nà tí o tọ́ láti fi íńkì sí ìka àtànpàkò.

Bá wo ni kí aṣe tẹ ìka?

DUBAWA kàn sí kọmísọnà fún àjọ ètò ìdìbò INEC Festus Okoye, o sì pèsè ẹ̀dà ìwé àkànṣe (manual) tí àjọ náà pilẹ̀ fún àwọn òṣìṣẹ́ ìdìbò lọ́dún 2022.

Ìwé yìí sàlàyé pé òǹtẹ̀ ìká tó bá gun orí ààyè ẹgbẹ́ òṣèlú míràn, lọ́gbọọgba tàbí tíó gun ọ̀pọ̀lọpọ̀ ààyè tí a pèsè fún àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú ni awọn kì yóò kà mọ́ ìbò. Bákanáà, INEC kì yóò kà ìwé ìdìbò tí kò ní òǹtẹ̀ ìká kankan mọ ìbò.

Àpẹẹrẹ òǹtẹ̀ ìká lórí ìwé ìdìbò.

Lódìkejì, tí a bá tẹ ìka sórí lógò ẹgbẹ́ òṣèlú tàbí sí àárín ìlà iwájú lógò ẹgbẹ́ òṣèlú kan, INEC yóò kà èyí mọ́ ìbò.

Àpẹẹrẹ ìbò tí INEC yóò kà.

Àlàyé ìlànà tí wọn yóò gbà dìbò lọ́jọ́ ìdìbò

Bí wọn yóò ṣe dìbò ní yúnítì rẹ lọ́jọ́ ìdìbò rèé:

Ìgbésẹ Kiní – Ní pólí yunìtì rẹ, tò sórí ìlà èyí tí òṣìṣẹ́ INEC yóò fi jẹ́rìí sí bóyá o wà níbi tí o yẹ kí o ti dìbò.

Ìgbésẹ Kejì –  Òṣìṣẹ́ INEC yíò yẹ káàdì ìdìbò rẹ wò pẹlú ẹ̀rọ BVAS tí àjọ náà ti pèsè. Bákanáà wọn yóò s’kánì ìka rẹ pẹlu ẹ̀rọ yìí.

Ìgbésẹ Kẹta – Lẹ́yìn tí òṣìṣẹ́ INEC bá ti rí òrúkọ rẹ nínú rẹ́gísítà olùdìbò, yíò fí íńkì tí a kò lè parẹ́ sórí ìka kékeré rẹ.

Ìgbésẹ Kẹrin – Aṣojú àwọn òṣìṣẹ́ ní pólí yunìtì yìí ma wá fún ọ ní pépà ìdìbò tí ó ti buwọ́lù. Yíò wá dárí rẹ sínú àyè kólóbó tí wàá tí tẹ ìka rẹ.

Ìgbésẹ Kàrún – Tí o bá ti wọ inú rẹ̀, ìgbà yìí ni wàá wá tẹ ìka rẹ sí iwájú ẹgbẹ́ òṣèlú tí o yàn láàyò. Lẹ́yìn náà, rọra ká pépà yìí padà bí wọn ṣe fún ọ.

Ìgbésẹ Kẹfà – Kúrò nínú ayé kólóbó yìí, fí pépà ìdìbò rẹ sínú àpótí ìbò ní’wájú gbogbo ènìyàn.

Ìgbésẹ Keje – Báyìí, o wá le kúrò ní agbègbè yìí pátápátá tàbí, tó bá wù ọ́, dúró di ìgbà tí wọn yóò kà ìbò.

Àkótán

Ìwádìí wa ṣàfihàn pé gbogbo òǹtẹ̀ ìká tó wà nínú àwòrán tí àwọn ènìyàn ń pín kiri yìí ní INEC yóò kà lọ́jọ́ ìdìbò, èyí tí o lòdì sí àhesọ tí o tẹ̀le.

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Back to top button