YorubaMainstream

Iléẹjọ́ kan ni ki arabinrin yii san owó ìtanràn leyin ti o kọ̀ lati ṣ’abewo si okunrin to fun ni owó ọkọ̀. Kini òfin sọ?

Getting your Trinity Audio player ready...

Tita omonikeji lọọre jẹ oun kan pataki ninu ìbáṣepọ̀ ọmọ eniyan, paapaa laarin awon ti wọn jẹ́ ololufẹ. Biotilejepe itaniloore ati owo iranwọ́ laarin ololufe wọpọ, o le fa aawọ tabi arinyanjiyan laarin wọn.

Laipe yii, àwọn olumulo ikanni X ṣ’atunpin fonran kan ti o ṣ’afihan obinrin kan ti orúkọ rẹ n jẹ Jennifer ti o f’ojú ba iléẹjọ́, leyin ti o gba owó ọkọ̀ l’ọwọ okunrin kan ti ko si mu adehun rẹ ṣẹ.

Ninu fonran ti o gbode kan yii, adájọ́ naa n s’ọ̀rọ̀ ni èdè Igbo, pe o ku si Jennifer l’ọwọ́ ki o san owó itanran egberun irinwo o le aadota tabi ki o fi ẹwọn ọdun meje finra.

DUBAWA ṣ’akiyesi orisirisi esi ti awon eniyan n fọ si fonran naa. Awon kan gbagbo, awon kan ṣ’alaigbagbo.

Olumulo kan, Dr Izu sọ pe “iwa odaran ni, idajo yii dara pupọ.” Elomiran @OmoEkoAwori sọ́ pe iru idajo bee ru oun loju, “Se ileejo wa fun iru ejo bayii?”

Iru ejo bayii kọ lo ma kọkọ gbode lori ayelujara. Ni ibẹrẹ ọdun yii, ileejo kan ni ipinle Ọṣun dájọ́ pe ki arabinrin kan san egberun lona aadojo leyin ti orekunrin re fun ni egberun meta naira fun ibewo ti ko si mu adehun re se.

Nitori bi oro naa se gbode kan ati irufe esi ti awon olumulo ikanni naa n fọ, DUBAWA kọ akọsilẹ yii lati ṣ’alaye boya ile-ẹjọ́ májísíréètì le joko gbọ iru esun bẹẹ.

Ilé ẹjọ́ májísíréètì

A ṣ’akiyesi pe àwọn olumulo ikanni yii n bere boya o ṣeeṣe ki iléẹjọ́ májísíréètì da iru ejọ bee fun eeyan ati pe se o ba ofin mu ki ileejo naa dajo ni ede ibile.

Ileejo májísíréètì je iléẹjọ́ àkọ́kọ́ ti opolopo eeyan maa n gbe oro lo lati fi esun kan elomiran. Ileejo májísíréètì ni won ti maa n gbo ejo ti ese naa ko ba jọmọ ti iwa odaran. Awon ileejo kekeeke yii lo maa n gbo ejo kekeeke ti won a si dajo bo ti ye.

Lori esun odaran, ti o ba se ẹ̀ṣẹ̀ kekere, ileejo májísíréètì a dajo ese ti ijiya re ko ju odun meji lo, sugbon iwa odaran bii agbebon, ipaniyan, tabi jibiti olowo gobio, iléẹjọ́ giga ni won a ti gbo ejo yii.

Ofin ipinle kookan ni ileejo májísíréètì maa n fi n d’ajọ. Sibesibe, àṣẹ ileejọ májísíréètì wa lataara ofin orileede paapaa ofin to niise pelu iwa odanran ni guusu orileede Naijiria (Criminal Code Act) ati ofin ihuwasi eniyan (Penal Code) ti ariwa orileede Naijiria. Bakan naa, ipinle kookan a maa ni ofin ti ileejo májísíréètì le lo lati dajo.

Kini ofin so nipa gbigba owo l’ona eburu?

Abala 419 ofin orileede Naijiria nipa iwa odaran menuba ese gbigba owo tabi oun miran lowo elomii l’ọna eburu. Ofin naa ko gba enikeni laaye lati gba owo pelu itanje tabi ki eeyan hu iwa jibiti lati gba dukia tabi ki eeyan so fun enikan ki o fun elomiran ni dukia rẹ̀.

Ofin naa ri gege bi iwa odanran, pelu ijiya odun meta l’ọgba ẹwọn tabi odun meje ti owo naa ba to egberun kan abi jube lo.

Ti eniyan ba fi iwa etan gba owo lowo elomiran, o jebi esun itanje. 

Ki a le ni oye boya iwa Jennifer je iwa odaran, DUBAWA ba awon amofin sọrọ, won si la wa looye.

Francis Oche, ẹni ti o jẹ amofin ni ile-eko giga Yunifasiti Veritas salaye pe abala ofin 419 ti orileede Naijiria niise pelu gbigba owo l’ona eburu.

“Ti o ba mọọmọ tan elomii jẹ, gba owo, ti o si kọ lati mu adehun rẹ ṣẹ, iwa odaran ni. Fun apeere, eniyan kan fun o ni owo ọkọ lo sibikan, sugbon o mu adehun naa ṣẹ tabi kọ lati da owo pada, iwa odaran nii.”

O f’ikun alaye re pe ti afuni ba bere owo re, ti o si ko lati da owo naa pada, iwa odaran nla ni.

Amofin naa sọ wipe, “awọn opo meta adehun lo wa: akọkọ ni pe awon eniyan naa gbodo ni adehun (fifuni ati gbigba), oun keji ni nkan ti o so wọn pọ bii owo, iketa si ni wipe, adehun naa wa labe ofin.”

Ti eniyan ba gba owo l’ọna aitọ, iwa jibiti nii, abala ofin 419 ti orileede Naijiria mu eniyan bee.

Iléẹjọ́ wo lo ni agbara lati joko gbọ iru esun yii?

DUBAWA bere lowo amofin Francis pe ileejo wo lo le joko gbo irufe oro yii, o si salaye fun wa pe, “ile-ejo májísíréètì le joko gbọ oro naa ti ese naa ko ba pọ, iyen ti ijiya esun ko ba koja odun meji ni ọgba ẹwọn. Ẹ̀ṣẹ̀ to ba buru ju bayi lọ, iléẹjọ́ giga ni won a gbe lọ.”

Amofin Peter salaye pe iye owo ti olùpẹ̀jọ́ ba na lo maa sọ irufe iléẹjọ́ to maa gbo ejo naa. Ti owo naa ba kere si milionu meje naira, iléẹjọ́ májísíréètì le joko gbo, sugbon ti owo naa ba ju bayi lo, igbejo le waye ni iléẹjọ́ giga ipinle tabi iléẹjọ́ giga ti orileede.

O tunbo f’ikun pe ile-ejo kotemilọrun maa n gbo ejo ti won gbe wa lati awon iléẹjọ́ mejeeji wonyi— iléẹjọ́ májísíréètì ati iléẹjọ́ giga, bee si ni a tun ni iléẹjọ́ to ga julo ni orileede Naijiria.

Se o seese ki adajo maa so ede abinibi l’asiko igbejo? 

Francis salaye pe o seese ki adajo iléẹjọ́ majisireeti lo ede abinibi ni awon igba kookan lasilo igbejo.

O sọ wipe, “iléẹjọ́ ibile ati iléẹjọ́ majisireeti le se igbejo ni ede abinibi paapaa ti olupejo ati olujejo o ba gbo ede geesi.”

Ṣugbọn ni iléẹjọ́ giga, ede gẹẹsi ni won maa lo. Ko ba ofin mu ki enikeni se igbejo ni ede abinibi ni iléẹjọ́ giga. Ti okan lara awon olujejo tabi olupejo o ba gbo ede geesi, won a pe ògbufọ̀ ki o tunmo oun ti won sọ.

O salaye lekunrere pe iléẹjọ́ gbodo ri pe ejo naa ye awon ti won wa ni iléẹjọ́ yekeyeke.

Ogbeni Peter fikun wipe ede geesi ni won maa n lo ni iléẹjọ́ l’orileede Naijiria, ko si bojumu ki adajo lo ede abinibi.

Sugbon o seese ki okan lara olupejo tabi olujejo ma gbo ede geesi, ogbufo a ran onitoun lowo lati tunmo oun ti iléẹjọ́ n so si ede abinibi.

O salaye pe iléẹjọ́ ibile ni anfaani lati lo yala ede geesi tabi ede abinibi nitori irufe awon eniyan ti won maa n saba lo ibe.

Sugbon eleyi o tunmo si pe ede abinibi nikan ni wọn a fi se igbejo ni gbogbo igba. 

Akotan

Biotilejepe gbigba owo l’ọna aitọ lọwọ elomiran je ese labe ofin Naijiria, ijiya to tọ́ si onitoun ati iléẹjọ́ ti yoo joko gbo oro naa dale iye owo ti olupejo fun olujejo ati iwa jibiti olujejo.

Iléẹjọ́ majisireeti le gbo ejo naa bi a ti salaye ninu akosile yii, sugbon ede geesi ni won gbodo fi se igbejo, biotilejepe adajo le lo ede abinibi lekookan. 

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Back to top button
Translate »