Fact CheckPoliticsYoruba

Irọ́ ni o! Ààrẹ Tinubu ò se ìdádúró àwọn ilé-ẹjọ́ gẹgẹbi ìròyìn yìí tí wi

AHESỌ: Tinubu gbegi dina àwọn ilé ẹjọ kọọkan ni Nàìjíríà kí wọn má bàá le kúrò ní ipò ààrẹ.

ÀBÁJÁDE ÌWÁDÌÍ: Irọ́ ni. Ilé-isé ìròyìn tó gbé ìròyìn yìí kò ṣéé gbẹ́kẹ̀lé. Bákan náà, kò sí ìwé ìròyìn ojúlówó kankan tó gbé ìròyìn náà. 

Ìròyìn lẹkunrẹrẹ

Olumulo ìkànnì ibaraẹnisọrẹ Facebook, Igbotimesmagazine ṣ’atunpin ìròyìn kan pé ààrẹ Bọla Tinubu ti gbégi dínà gbogbo ilé-ẹjọ́ tí ó ń mójútó igbẹjọ awuyewuye ẹjọ́ tó ṣuyọ lórí ètò ìdìbò aarẹ. Olumulo náà ṣàlàyé pé Tinubu gbé ìgbésẹ yìí nítorí ẹ̀rù n bàá pé wọn a yọ kúrò ní ipò ààrẹ.

“Aare Tinubu ti polongo ìdádúró gbogbo ilé-ẹjọ́ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, o ṣàlàyé pé ẹrú ìyọkúrò n ba oun,” àkòrí ìròyìn yìí lo kà báyìí.

Àkọsílẹ náà sọ wípé àwọn amofin ti tako iyansipo Tinubu, ó fikun wípé, “eyi ti da wahala ati idojukọ sílẹ̀ láàárín àwọn amofin ati àwùjọ eniyan.”

Wọn diboyan ààrẹ Tinubu ní ọjọ́ ketalelogun oṣù kejì ọdún yìí pẹlu mílíọ̀nù mẹjọ, ati ẹgbẹrun lọna ẹgberin o din diẹ; ìbò mílíọ̀nù méje ó dín díẹ̀ ni Atiku Abubakar tó jẹ oludije ẹgbẹ òṣèlú Peoples Democratic Party ni, Peter Obi tí ó jẹ́ oludije ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party si ní ìbò to le diẹ ni miliọnu mẹfa.

Leyin ti àjọ eleto idibo, INEC kéde Tinubu gegebi olubori ninu idije naa, ọgbẹni Atiku ati Obi faake kọ́rí pe awọn kò lè gbà èsì ìbò tí INEC kéde, kódà àwọn méjèèjì gba ile ẹjọ lọ pé kí ilé ẹjọ́ wọgile èsì ìbò naa.

Ìgbìmọ̀ ẹni marun-un ni o n gbọ ẹjọ lori awuyewuye ibo to gbe aarẹ Bola Tinubu wọle, nigbati Haruna Tsanmani jẹ olórí wọ́n, sugbon igbimo naa ò tíì ṣe idajọ lórí ehonu awọn oludije náà. 

Nítorí pàtàkì ọ̀rọ̀ náà, àti wípé àwọn ọmọ orile-èdè Nàìjíríà fojusona sí ìdájọ, DUBAWA ṣe ìwádìí àròsọ náà. 

Ifidiododomule

Òun kan to se pataki ni wípé, àkọsílẹ náà kò ní orúkọ kódà kò sí idanimo kankan fún-un, èyí mú wa ṣ’iyemeji orísun ìròyìn náà. 

A ṣe itọpinpin ìròyìn náà lórí àwọn ojúlówó ìwé ìròyìn, láti mọ̀ bóyá wọ́n gbé ìròyìn náà, sugbon ko sí oun tó jọ bẹẹ.

Kódà iwe iroyin Premium Times ti gbé ìròyìn kan jáde pé ilé ejo ò tíì ṣe idajọ lórí ẹ̀sùn tí Atiku àti Obi fi kan ààrẹ Tinubu àti àjọ INEC latari pe wọn kéde Tinubu gegebi aare ta diboyan. Ìròyìn Premium Times ṣàlàyé pé ilé-ẹjọ́ ò tíì pinnu lórí ẹjọ́ tí wọ́n fẹ dá lórí itako Obi ati Atiku, kódà wọn mẹnuba oṣù kẹsán, gegebi asiko ti ilé-ẹjọ́ máa joko gbẹyin lati gbọ ọrọ náà.   

Ó ṣe pàtàkì kí a mẹnuba awọn ti Atiku ati Òbí pèlẹ́jọ́, àwọn ni àjọ eleto ìdìbò INEC, ààrẹ Bọla Tinubu, ìgbákejì ààrẹ Kashim Shettima àti ẹgbẹ òṣèlú All Progressive Congress (APC). 

Ìwé ìròyìn Punch náà ṣ’agbejade ìròyìn náà. 

Ni ìgbà tí a wo àkọsílẹ náà fínífíní, a ríi wípé àwọn tí wọn kò, se àsìse — eyi ti o le sí àwọn eniyan lọna.

Nínú akosile naa, won ni “idibo to n bò lónà” botilẹjẹpe ìdìbò naa ti wáyé sẹyìn, lati oṣù kejì ọdún yìí.

A tún ṣe itọpinpin kókó ọrọ lati mọ bóyá lóòtọ́ ni àwọn amofin ní Nàìjíríà ń binu gidi lórí ọ̀rọ̀ náà, ṣugbọn kò sí oun tó jọ bẹ́ẹ̀.

A kàn sí agbẹnusọ ẹgbẹ òṣèlú APC, Felix Morka. Ọ̀gbẹ́ni Morka bu ẹnu atẹ lu àwọn tó ń pín ìròyìn ọ̀ún lórí ayélujára. Ó sọ wípé aṣinílọ́nà ni ìròyìn náà, kódà o ni, “radarada ni”. 

Àkótán 

Irọ́ ni ìròyìn náà. Kò sí ojúlówó ìwé ìròyìn kankan tó gbé ìròyìn náà. Ààyè ayélujára to ṣ’atunpin ìròyìn èké náà ko ṣéè gbẹkẹle. Kódà, ogbontarigi ni won ninu ka ṣ’atunpin ìròyìn ẹlẹjẹ, pàápàá jùlọ lasiko ìdìbò. Agbẹnusọ ẹgbẹ òṣèlú APC náà ti tako ahesọ naa, o ni ko sí òtítọ nínú rẹ̀.

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Back to top button