Aheso: Olumulo ikanni ibaraẹnisọrẹ Facebook sọ wípé eniyan lé ni ààrùn rọpárọsẹ̀ lẹ́yìn tí ó bá tẹ̀lé àwọn ìlànà kan ninu baluwe/ wẹ̀ ní ọ̀nà àìtọ́.

Ifidiododomule: Irọ ni! Kó sí ẹrí to saju wipe kí eniyan wẹ bakan lè fa ààrùn rọpárọsẹ̀. Àwọn dokita ṣàlàyé pé òún tó le fa ààrùn rọpárọsẹ̀ ni ifunpa gíga, ọ̀rá àti kí ènìyàn sanra jù
Ìròyìn lẹkunrẹrẹ
Ààrùn rọpárọsẹ̀, tí a mọ̀ sí ikọlu ọpọlọ, máa n saba ṣẹlẹ̀ tí ẹ̀jẹ̀ kó ri ọ̀nà gbà lọ syi ọpọlọ, tàbí tí òpó ẹ̀jẹ̀ inú ọpọlọ bá já.
Nípasẹ èyí, ikolu le ṣẹlẹ sí awọn eya ara ọpọlọ tabi ki wọn doku. Ààrùn rọpárọsẹ̀ le fa ijamba fún ọpọlọ, aleebu ara tàbí ikú òjijì.
Ojú òpó kan lori ikanni ibaraẹnisọrẹ Facebook, Natural and nutrition medical remedies, ṣàlàyé pé ààrùn rọpárọsẹ̀ máa n saba bẹrẹ láti baluwe nítorí ti awọn ènìyàn bá fé wẹ, niseni wọn máa n kọ́kọ́ dá omi sori àti ọwọ́ wọn, èyí kó sí t’ọna. Olumulo náà ṣàlàyé pé èyí kó dara.
Ojú òpó náà fi kun pe orísirísi atejade àti ìwádìí lo fi idi ọrọ naa múlẹ àti wípé ààrùn rọpárọsẹ̀ wọpọ láwùjọ nitori bí awọn ènìyàn ṣe n wẹ̀. Ni akotan, ojú òpó náà filelẹ pe o ṣe pàtàkì ki ènìyàn kọ́kọ́ fọ ẹsẹ wọn náà, kí wọ́n tó fọ àwọn ẹ̀yà ara yòókù lọ sí ibi èjìká àti beebeelo.
Olumulo kan, Sila Nana sọ èyí: “Kayefi ni èyí, kódà o ti s’ọ̀rọ̀ dáadáa, ọna àìtó ni a ti n lo lateyinwa.”
Olumulo miran, Daniel Minyo ti kó ni igbagbo ninu ọrọ naa sọpẹ kiise òdodo ọrọ.
Ni igba ti a ṣakiyesi akọsilẹ náà, àwọn kókò ọrọ kọọkan ṣe wa ni kayefi. Kódà, awọn àríyànjiyàn to tele ọrọ naa lo fàá ti DUBAWA ṣe ìwádìí lórí ọrọ naa.
Ifidiododomule
Ninu atejade orí ikanni ibaraẹnisọrẹ náà, olumulo náà menuba awọn orisun ìròyìn kọọkan. Nítorí èyi, a ṣe ìwádìí lórí Journal of Canada’s Medical Association láti fi idi re mu’le boya awọn gbólóhùn kan láti atejade náà, sugbon a kó ri oun tó jọ bẹẹ. Eyí jé aṣinilọna.
Àjọ eto ìlera àgbáyé WHO ṣàlàyé pé àwọn ènìyàn ti wọn ti ni ààrùn rọpárọsẹ̀ teleri lé ni ààrùn rọpárọsẹ̀ ni igba miran. Ewu iku si sopọ mọ iru ààrùn rọpárọsẹ̀ ti eniyan bá ni.
Ààrùn rọpárọsẹ̀ ò wọpọ nínú àwọn ènìyàn ti ọjọ orí wọn kò tó ogójì ọdun; ti èyí bá ṣẹlẹ, oun tó le ṣokunfaa ni ifunpa gíga tabi aisan ẹjẹ riru. Sùgbón, ààrùn rọpárọsẹ̀ máa n wáyé ninu ipin mẹjọ awọn ọmọde ti o ni ààrùn sẹ̀jẹ̀dọ̀lẹ (sickle cell)
Ààrùn rọpárọsẹ̀ le waye ti ẹ̀jẹ̀ ò bá ṣàn lọ sí ọpọlo tabi ti apakan inú ọpọlọ bá n dede ṣẹ̀jẹ̀. Àwọn oún tó le ṣokunfa ààrùn rọpárọsẹ̀ ni ifunpa gíga, ara sisan lasan ju, siga mímú, jíjẹ oúnjẹ ti kó dara, kí ènìyàn kọ̀ láti ṣe ere idaraya àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀lọ.
A ṣ’abapade àkọsílẹ kan láti American Stroke Association ni ibi ti awọn onkọwe ti gbaninímọ̀ràn lórí bi awọn tí ó ní ààrùn rọpárọsẹ̀ ṣe le wẹ̀, sugbon wọn kò mẹnuba ilana kankan tabi ki wọn bẹrẹ láti apá kan ninu ara lọsí òmíràn. Akọsilẹ náà mẹnuba ọna ailewu lasan ni.
Thanh Phan, ẹni ti o jẹ olórí àwọn oniwadii nípa ilera ọpọlọ (Neuroscience Research) ni ile-ise Monash Health, so fún iwe iroyin AFP ni oṣù kẹwa ọdún 2020 pe idena ẹjẹ sí ọpọlo lo máa n fa ààrùn rọpárọsẹ̀. Idena wọnyi máa n ti ọkan tabi iṣọn ẹjẹ wa. Oun miran to le ṣokunfa ààrùn rọpárọsẹ̀ ni ti òpó ẹjẹ bá dede já.
DUBAWA kan sí Precious Newman, eni ti o jẹ onisegun oyinbo, o so wípé oun kó faramọ gbogbo oun tó wa ninu akosile akalekako náà.
“Ti eniyan bá kọkọ fọ ẹsẹ re ninu baluwe, bí o ṣe màá mí yato. Sùgbón ti o bà dà omi láti ori sí ese, wa ríi wípé ara re ma balẹ daada.
“Oun tó máa n fa ààrùn rọpárọsẹ̀ ni ẹjẹ riru, kí ènìyàn sanra lasan ju àti beebeelo. Ti eniyan bá ni ifunpa gíga tabi aisan ẹjẹ riru, ti wọn kó sí ṣe itọju àìsàn nàá, o le fa ààrùn rọpárọsẹ̀.
“Gbedeke ifunpa to dara mi 120/80mmhg – 125/85mmhg. Ounkoun to ba kọja 140/100mmhg – 160/120mmhg s’oke le fàá kí èeyan di ero Ile iwosan, ki wọn le ṣe ṣe itọju àìsàn.
“Sùgbón kí ènìyàn kọkọ dà omi sori ninu baluwe ò lè fa ààrùn rọpárọsẹ̀, àyàfi ti onitoun bá ni aisan ẹjẹ riru tabi ti onitoun bá ni awọn ààrùn kọọkan ti o niiṣe pẹlu ọkàn, pàápàá eni ti o baa n fa siga. Kó sí ẹrí to daju ninu imo sayensi pé kí ènìyàn máa kọkọ dà omi sori ninu baluwe lè fa ààrùn rọpárọsẹ̀,” dokita naa lo sọ èyí.
Àkótan
Kí ènìyàn máa kọkọ dà omi s’ọri ni baluwe ò lè fa ààrùn rọpárọsẹ̀; oun tó le ṣokunfa ààrùn rọpárọsẹ̀ ni ifunpa gíga, ati kí ènìyàn sanra jù.