African LanguagesFact CheckHealthYoruba

Kòsí àrídájú pé ewúro pẹ̀lú omi àgbọn le wo àrun ẹ̀dọ̀

Getting your Trinity Audio player ready...

Àhesọ: Aṣàmúlò ìtàkùn ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ Facebook kan wípé mímu àpòpọ̀ ewúro àti omi àgbọn yóò pa àrun ẹ̀dọ̀ àti kídìnrín.. Tí iye àtọ̀ ọmọkùnrin bá kéré,. yóò sì tún ṣiṣẹ́ fun.

Àbájáde Ìwádìí: Kò sí àrídájú tó múnádóko lórí àhesọ yìí. Lótìítọ́ ni pé omi àgbọn àti ewúro ní àǹfàní tí wọ́n ń ṣe fún ìlera. Sùgbọ́n, kò sí ẹ̀rí tó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ láti lò wọ́n fún àwọn àrùn wọ̀nyí.

Ìròyìn Lẹ́kùńrẹ́rẹ́

Kídìnrín jẹ́ ẹ̀yà ara méjì tó ní ìrísí ẹ̀wà. Ẹ̀yìn tàbí ẹ̀gbẹ́ ọ̀pá ẹ̀yiǹ ló ma ń wà. Àwọn kídìnrín yìí ló ma ń báni fọ ẹ̀gbin inú ẹ̀jẹ̀ tí yóò sì sọ wọ́n di ìtọ̀. Àwọn ni wọ́n ma ń mú ìwọ̀ntúnwọ̀nsì bá àwọn èròjà ara bíi pòtásíọ́mù, sódíọ̀mù àti kásíọ́mù, tó ń ṣàkóso rírú ẹ̀jẹ̀ àti sẹ́ẹ́lì ẹ̀jẹ̀ pupa. Bí ẹ̀yà ara yìí ṣe lágbára tó, àwọn àìsàn kan ma ń kọlùú tí yóò sì sọ ọ́ di aláìlágbára láìpẹ́ ọjọ́. Bákannáà, ẹ̀dọ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀yà tó wà nínú ara. Òhun náà sì ní àwọn àrùn tó ma ń mú denukọlẹ̀. 

Láìpẹ́ yìí ni aṣàmúlò ìtàkùn ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ Facebook kan, Lady Chicoupes pín fọ́nrán kan nínú èyí tó ti sọ pé mímu omi àgbọn tí a gbo pọ̀ mọ́ ewúro le pa àwọn àrùn tó n’ísẹ pẹ̀lú ẹ̀dọ̀. Ó tún tèsíwájú wípé tí ọkùnrin bá ní ìṣòro òǹkà àtọ̀ kékeré tí àwọn olóyìnbo mọ̀ sí “low spam count,” àpòpọ̀ yìí yóò wòó sàn.

Tí iye àtọ̀ ọmọkùnrin bá kéré ju bí ó ṣe yẹ lọ, wọn yóò wípé ó ní “low sperm count.” Ìṣòro yìí sì wà lára ǹkan tí ma ń fa àìlèfó’bìnrin lóyún.

Fọ́nrán tí aṣàmúlò yìí pín ti lọ káàkiri. Àwọn ènìyàn 692 ló ti wòó tí ènìyàn 73 sì ti fèsì lórí rẹ̀. Kódà, àwọn míràn tún dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún “àṣírí” yìí. Nítorí bí àwọn ènìyàn ṣe gbàá àti ìtumò rẹ̀ lorí ètò ìlera gbogboògbò, DUBAWA gbìyànjú láti gbé àhesọ yìí yẹ̀wò.

Ìfìdíòdodomúlẹ̀

Ìwádìí sáyẹnsì kan fi ìdí rẹ̀ mú’lẹ̀ pé ewúro lè ṣiṣẹ́ fún àìsàn ìtọ̀ ṣúgà àti ẹjẹ ríru lára ẹranko. Bákannáà ni ẹgbẹ́ àwọn oníṣègùn ìbílẹ̀ ti Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà ma ń gba aláìsàn níyànjú láti lo ewúro fún ìwòsàn. Ṣùgbọ́n, àjọṣepọ̀ óníṣègùn òyìnbó orílẹ̀-èdè (National Library of Medicine) tàpa sí lílò àgbo ìbílẹ̀. Wọ́n ní, ọ̀nà tti wọ́n ń gbà pèsè ògùn ìbílẹ̀ kò ní òṣùwọ̀n. Àìní òṣwọ̀n yìí sì lè fa lílò wọ́n lápọ̀jù (overdosage) tó lè ṣ’àkóbá fún ara.

Gẹ́gẹ́ bí J.O Williams, onímọ̀ nípa oúnjẹ ṣe sọ nínú ìwádìí rẹ̀ kan tí ó ṣe lórí “Àǹfàní omi àgbọn,” ó wípé omi àgbọn ní èròjà bíi “antioxidants” tí a tún mọ̀ sí “phytonutrients.” Àwọn eléyìí ma ń ṣe ànfàní fún ẹ̀dọ̀ ẹranko. 

Ṣùgbón, arákùnrin Williams ṣe ìkìlọ pàtàkì. Ó wípé “tí o bá ní àrùn kídìnrín, o ní láti ṣe àkíyèsí sí iye pòtásíọ́mù to ń fi sínú ara rẹ.”

DUBAWA kàn sí Dọ́kítà Johnson Udodi, aláforúkọsílẹ̀ àgbà nílé ìwòsàn tó ga jùlọ, (National Hospital) Abùjá. Ó wípé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé  Ìwé Àkọsílẹ Òkèèrè Ìmọ Ìṣègùn Ẹranko (International Journal of Veterinary Science) gbà pé ewúro ati àwọn ohun tí a rí lára àgbọn ń ṣe anfààní fún ara, kò tíì sí ẹ̀rí ìbáṣepọ̀ gbangba tó péye, láti fi ìdí rẹ̀ mú’lẹ̀ pé àpapọ yìí yóò wo àrùn kídìnrín tàbí àrùn òmíràn. O tèsíwájú wípé “yóò dára tí wọ́n bá lè ṣe ìwádìí lórí èyí lọ́jọ́ iwájú, kí wọ́n sì dan wò lára ènìyàn.”

David Agbawan, tó jẹ́ dọ́kítà àgbà ní’lé ìwòsàn tó ga jùlọ ti ìlú Abùjá, fara mọ́ ohun tí Dókítà Udodi sọ.

Ó wípé, àwọn ènìyàn lè ma sọ wípé lílò àpòpọ̀ ewé àti àwọn ǹkan òmíràn lè ṣe ìwòsàn, ṣùgbón, àhesọ lásán ni gbogbo rẹ̀ àyàfi tí ìwádìí sáyẹ́nsì bá fi ìdí rẹ̀ mú’lẹ̀ pé wọn kò ní ìjàmbá.

Ó tèsíwájú pé, “kò tíì sí ìwádìí sáyẹnsì tó fi dáni lójú pé omi àgbọn àti ewúro le ṣe ìwòsàn fún àwọn àrùn tó jẹmọ́ kídìnrín, ẹ̀dọ̀ tàbí òǹkà àtọ̀. Mo rọ gbogbo ènìyàn láti kíyèsi ibi tí wọn yóò ti máa gba ìmọ̀ràn ìlera.”

Àkótán

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwádìí ti fi hàn pé omi àgbọn àti ewúro wo àrùn bíi ẹ̀jẹ̀ ríru àti ìtọ ṣúgà lára eranko, kò sí ẹ̀rí sáyẹ́nsì nípa agbára wọn nínú ènìyàn tàbí nínú mímú ìdàgbàsókè bá òǹkà àtọ̀ kékeré.

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Back to top button
Translate »