Fact CheckHealthYoruba

Njé ó ṣeéṣe ki Obìnrín rí nkan oṣù rẹ̀ láti atẹlẹwọ àti ẹsẹ̀?

Getting your Trinity Audio player ready...

Aheso: Awọn Olumulo ikanni ibaraẹnisọrẹ Facebook gbe ahesọ pé awọn obinrin le ṣẹ nkan osu wọn láti atẹlẹwọ pẹlu ẹsẹ̀. Ṣugbọn, ṣe otitọ ni ọrọ náà?

Njé ó ṣeéṣe ki Obìnrín rí nkan oṣù rẹ̀ láti atẹlẹwọ àti ẹsẹ̀?

Ìròyìn lẹkunrẹrẹ 

Laipẹ yii, Olumulo ikanni ibaraẹnisọrẹ, Faith Awudu Achonmakai bere ìbéèrè lórí bi àwọn obinrin ṣe lè ṣe nkan oṣù láti atẹlẹwọ tàbí ẹsẹ. “Nje o mo pé awọn obinrin le ṣẹ nkan osu láti atẹlẹwọ pẹlu ẹsẹ?”

Bákan náà, olumulo míràn ti orúkọ rẹ̀ jẹ́ Adefioye Ibukun Feranmi ṣ’atunpin ahesọ náà.

“Mo gbọ pé àwọn obìnrín míràn máà n ṣe ǹkan oṣù láti atẹlẹwọ pẹlu ẹsẹ wọn. Ṣe otitọ ni ọrọ naa? Mi ò gbagbọ.”

Olumulo míràn, Nwabunwanne Gloria Yahdinma kọ eyi sori ojú òpó rẹ l’ori ikanni náà, “Nje e mọ pé awọn obinrin miran máà n ṣe nkan oṣù láti atẹlewo pẹlu ẹsẹ wọn? Ejowo, ṣe otitọ ni ọrọ yii?”

Latarii bi ọ̀rọ̀ náà ṣe jẹ àti pàtàkì rẹ̀ sí ìlera àwọn obìnrín lágbayé, DUBAWA ṣe ìwádìí ọrọ náà, láti fi idi òdodo múlẹ̀.

Isamudaju

Ṣíṣe nkan oṣù jẹ ara ìlera àwọn obinrin, koda òòkàdẹrí ṣàfihàn pé ìdáméjì ìyè obirin to wa lágbayé lo ti balaga. 

Àwọn obinrin maa n ṣe nkan osu láàrin ọjọ́ meji sì meje nínu osù kan. Ajo àgbáyé to n risi oro àwọn ọmọdé UNICEF ṣàlàyé pé obìnrín kán a fì nkan bíi ọdún méje ṣe nkan oṣù. 

Ile-ise Cleveland ṣàlàyé ti nkan oṣù ṣe máà n wáyé nínú àgọ ara obinrin. Ẹ̀jẹ̀ pẹlú àwọn ọra kọọkan láti ile ọmọ, máà sàn láti ile ọmọ si ọrùn ile ọmọ, asi gba ojú ara jade si’ta. 

Ṣugbọn, nje o ṣeéṣe kì obinrin ṣe nkan osu láti atẹlewo pẹlu ẹsẹ?

Itopinpin kókó orò lórí ayélujára fihan pe kò sí èri to dájú nínú ìmọ sayensi to satileyin aheso náà. Ki a le ṣẹ amudaju ọrọ naa, DUBAWA ṣe ìfòròwánilénuwò pẹlú àwọn onímọ̀.

Ìfòròwánilénuwò pẹlú àwọn onimo 

Emmanuel Olowookeere, dokita onimọ nipa ẹya ara obinrin ati bi wọn ṣe n loyun, bimọ so pé aheso lásán ni ọrọ naa. Kò sí èri to dájú nínú ìmọ sayensi to satileyin ọrọ náà. 

“Ko ṣeéṣe kì obinrin ṣe nkan osu láti atẹlẹwọ tàbi ese. Ti ara obinrin ba pon tàbí to n laagùn, eyi o túmọ sí pe obinrin naa n ṣe nkan oṣù,” dókítà naa sọ ninu àlàyé rẹ.

Dókítà naa salaye pe àwọn àìsàn kan wa to le fa àwọn àpẹẹrẹ kọọkan ti kò wọ́pọ́, bíi ààrùn to dojukọ ile ọmọ, endometriosis.

“Endometriosis maa n wáyé ni ìgbà ti wón ba ṣe àwárí awọ ilè ọmọ ni eya àrà miran bíi inu ifun, ìwọ́ tàbí ẹdọfóró. Ṣugbọn, kò ṣeeṣe ki ẹjẹ nkán oṣù gbá atẹlẹwọ tàbi ẹsẹ̀ jade,” dókítà naa lo ṣàlàyé eyi. 

“O ṣeéṣe kì ara obinrin pọn, eyi o túmọ sí pe o n ṣe nkan oṣù láti ẹyà àrá nàá. Kódà atẹlẹwọ le máà laagun, sùgbón kìíse nkan oṣù, o le jẹ aarun ìlé ọmọ, endometriosis.” 

Dókítà naa sọ wípé biotilẹjẹpe ààrùn endometriosis le fa egbò si inú ọpọlọ obinrin, kò ṣeeṣe ki nkan oṣù wa láti atẹlẹwọ tàbí ẹsẹ̀.

O gbá awujo eniyan niyanju láti gbojule ojulowo ìròyìn tó niiṣe pẹlu ilera won, ki wọn sì yàgò fún àníàní.

Onisegun oyinbo miran, Adekemi Odeyemi so wípé kò ṣeeṣe ki eje nkan osu gba ibòmíràn jade láti ara obinrin yatọ sí ojú ará, ṣugbọn o mẹnuba aarun ìlé ọmọ Endometriosis to le fa idiwọ.

Odeyemi ṣàlàyé pé a kò lé kò ọrọ naa danu, paapa ti obinrin naa ba ni ààrùn Endometriosis.

“Oun to le ṣokunfa ki ara obinrin sèjè ni ibòmíràn yatọ sí ile ọmọ lasiko nkan oṣù ni wọn pè nì Endometriosis. Eyi máà n saba waye leyin ti wón ba ri ora ile ọmọ ni àwọn èyà míràn nínú ara. Nítorí náà, lásìkò nkan oṣù, àwọn èyà arà miran yii a máà sèjè. Kò wópò ki obinrin ṣe nkan osu láti atẹlẹwọ tàbi ese, sugbọn a kò lé kò ọrọ naa danu.”

Ààrùn Endometriosis

Eyi jẹ aisan ti o kolu idamẹwa obinrin lágbayé pàápàá àwọn to ti balaga.

Ajo to n risi eto ìlera lágbayé WHO sọ wipe alaisan máà ni irọra lópòlopò ni àsìkò nkan oṣù, ìgbà ibalopọ tọkọtaya, ṣiṣe igbọnsẹ, yóò ma ni irira, ààrẹ, koda o le fa ibanuje ọkàn ati airọmọbi. Aiṣan yíi le bèrè ni ìgbà ti eniyan ba bẹrẹ síí ṣe nkan oṣù titi di ìgba ti yóò ṣe tán.

Ìwọ ilé-ọmọ ma nipọn ṣí, a sì bẹrẹ síí sèjè ni ìgbà ti obinrin ba n ṣe nkan oṣù. Ṣugbọn fun obinrin to ni ààrùn Endometriosis, àwọn èyà arà miran yatọ sí ile ọmọ a bẹrẹ síí sèjè, èyí sì ma fa ìrora nigba nkan osu. 

Ìwádìí kan ti oniwadii Fawole ati àwọn yòókù gbejade ni ọdún 2019 fihàn pé aiṣan yíi wọpọ láàrin àwọn obinrin ni orile-ede Nàìjíríà. Ṣugbọn onṣẹ ni lanu pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ obinrin o tètè fura, bẹ́ẹ̀ sini wọn o tètè wa itọju lọdọ àwọn dókítà.

Àwọn amí apeere àisàn Endometriosis yii ni irọra nígbà nkan oṣù, ki ikun máà dun obìnrín, ẹyin riro lasiko nkan oṣù, ki obinrin maa padanu èjè púpò nígba to n ri nkan osu, irọra lasiko ibaṣepọ, airọmọbi, igbe gbuuru, wahala ati idiwọ ti eeyan ba fẹ ṣe igbọnsẹ ati bẹẹbẹẹlọ.

Kayefi ni óún naa pato to ṣokunfa àìsán Endometriosis yii, bí ọ sí jépé kò tíì si iwosan, àwọn ona kan wa ti àwọn oníṣègùn ṣe n wo aisan náà, nipasẹ iṣẹ abẹ ati lilo oògùn. Iwadi DUBAWA ṣàgbékalẹ̀ àwọn ibì ti aiṣan Endometriosis yii ti le ṣẹ́yọ laago ara, bíi ààyè to wa lẹyìn ilé ọmọ, ibu ẹyìn, ati awon ibòmíràn.

Ọpọlọpọ ipenija lo dojukọ àwọn ti o ni ààrùn Endometriosis yii, ṣugbọn wiwa ojútùú sí aisan náà lásìkò ṣe pàtàkì.

Àkótán 

Ìwádìí wa fihàn pe, biotilẹjẹpe ààrùn Endometriosis le mu ki obinrin sèjè ni eya àrà miran yatọ sí inu ile ọmọ, eyi kò túmọ sí pe obinrin le sèjè láti atẹlẹwọ tàbi ẹsẹ̀. Ojú ara nìkan ni nkan oṣù le gba jade. Nítorí idi eyi, aheso lásán ni ọrọ náà.

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Back to top button
Translate »