Fact CheckEconomyFacebook ChecksYoruba

Orilẹ-ède ẹ́gíptì ni ọrọ ajé rẹ̀ tobi julọ ni ilẹ̀ Áfríkà, kìíse Nàìjíríà

Getting your Trinity Audio player ready...

Aheso: Àwọn olumulo ìkànnì ibaraẹnisọrẹ Facebook sọ wípé ọrọ ajé orilẹ-ède Nàìjíríà lo tóbi jùlọ ni ilẹ̀ Áfríkà.

Orilẹ-ède ẹ́gíptì ni ọrọ ajé rẹ̀ tobi julọ ni ilẹ̀ Áfríkà, kìíse Nàìjíríà

Àbájáde ìwádìí: Irọ ni. Iroyin orí ẹrọ alatagba ṣ’àfihàn pé ìlú ẹ́gíptì ni ọrọ ajé re tóbi jùlọ laarin odún 2023 sì 2024, orilẹ-ède Nàìjíríà sì jẹ ipò kẹta ní ilẹ̀ Áfríkà. 

Ẹkunrẹrẹ àlàyé 

Àwọn àtúnṣe kọọkan láti ọwó ìjọba Tinubu ti mú ki ọrọ ajé orilẹ-ède Nàìjíríà denukọlẹ, àwọn àtúnṣe bíi ìyọkúrò owó ìrànwọ́ epo, ati ìgbìyànjú lati jẹ ki owó Náírà le dúró, kó sì niyi laaarin awọn owo lagbaaye. Ilé-isé aṣeṣiro lorilẹede Naijiria, National Bureau of Statistics ṣàlàyé pé ni oṣu kẹjọ ọdún 2024 oúnjẹ àti àwọn ǹkan míràn ti gbe owó lórí.

Nítorí irọra ti o n koju àwọn ọmọ orilẹ-ède Nàìjíríà, orísirísi aheso ni wọn gbeka ori ayelujara, pàápàá eyi ti o ṣàpèjúwe orílẹ-èdè Nàìjíríà gegebi ìlu ti ọrọ ajé rẹ̀ tobijulọ ni ilé Áfríkà. Arákùnrin kan lóri ẹ̀rọ alatagba Edward Wonder sọ wípé, “Oro ajé orilẹ-ède Nàìjíríà ló tóbi jùlọ ni ilẹ̀ Áfríkà, pẹlú iye ènìyàn ìgbà mílíọ̀nù.” Òpòlopo àwọn aṣàmúlò ikanni naa lo ka, bù owo ife luu, ti wọn sì ṣ’atunpin ahesọ naa.

Wọn ṣ’atunpin ọrọ náà àwọn linki wọnyi. Ilu le, àwọn eniyan kerora owongogo ounje, koda ojoojumọ ni iroyin gbe Alaye nipa ọrọ ajé orilẹ-ède Nàìjíríà, eyi lo fá ti a fì ṣe ìwádìí lórí aheso náà. 

Àsàmúdájú 

A lò ero afunilesi ti DUBAWA gbekalẹ (ChatBot), a ríi wípé irọ lásán ni ọrọ náà, ó fi yé wa pé awọn orílè-èdè míràn wà ti ọrọ ajé wọn ju ti orilẹ-ède Nàìjíríà lọ.

Nínú àlàyé ti bánkì àgbáyé gbé jáde ni ọdún 2023, ọrọ ajé Nàìjíríà jẹ ìkẹta tó tobijulọ. Ìlú Egipti jẹ akọkọ, South Africa si jẹ orilẹ-ède kejì.

Bi ọdún yii ṣe n pari lọ, kò sí èri to dájú pé ọrọ ajé orilẹ-ède Nàìjíríà yòò wa ni ipo kinni sì iketa, awon ayewo ati ìwádìí gbèrò pé orilẹ-ède Nàìjíríà á bọ́ sí ipò kẹrin. South Africa a bo sí ipo kinni, o si ṣeéṣe kì Algeria bo si ipò kẹta nítorí ìwọn ọrọ ajé orílè èdè náà ju ti Nàìjíríà lọ.

Ọrọ ajé orilẹ-ède Nàìjíríà tobijulọ ni ilẹ̀ Áfríkà ni ọdún 2016, ṣugbọn ìyípadà dé baa ni ọdún 2017. Ni àsìkò ti ọrọ ajé orilẹ-ède Nàìjíríà dínkù, ni ti South Africa lekun si.

Àkótán

Biotilẹjẹpe ọrọ ajé orilẹ-ède Nàìjíríà jẹ ọkan lára àwọn to tobijulọ ni Áfríkà, kìíse òun gan-an lo tobi jù. Ọrọ ajé àwọn orílè-èdè miran jú ti Nàìjíríà lọ.

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Back to top button
Translate »