YorubaFact CheckMainstream

Òdodo ọ̀rọ̀! Àmujù omi le fa ikú eniyan

Ahesọ: Olumulo kan lori ikanni abeyefo @fact sọ wipe ti eniyan ba mu omi amuju, o le la ẹmi lọ. “Mimu omi l’àmujù le se iku pa ẹ,” olumulo naa lo sọ eyi.

Òdodo ọ̀rọ̀! Àmujù omi le fa ikú eniyan

Abajade iwadii: Òdodo ọ̀rọ̀. Ninu iwadii DUBAWA, a rii wipe lootọ mimu omi àmujù le fa amupara, eyi si le fa iku ojiji fun eniyan.

Ẹ̀kunrẹrẹ alaye

Atọmu òyì-omi (hydrogen) meji ati òyì ina (oxygen) ni o wa ninu omi, wọn si ṣe pataki si ilera ara eniyan. Omi lo pọ̀jù lara awon ọmọ ọwọ́ ni iwọn aarundinlọgọrin (75%) nigba ti iwọn omi lara agbalagba jẹ marundinlọgota (55%). Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iwulo ni omi n ṣe l’agọ ara, o maa bójútó iwọn igbona tabi otutu ara, ẹ̀yà dídà onjẹ, omi a maa mu ki eroja onjẹ sara loore, a ṣe iyokuro egbin ati bẹẹbẹẹlọ.

Ni ọjọ kẹẹdogun oṣù karun odun yii, olumulo kan lori ikanni X @fact sọ wipe mimu omi amuju le fa iku fun eniyan. ”Ti eniyan ba mu omi l’amuju, o le ku lojiji.”

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ eniyan lo ti ka atejade yii, ti wọn si ṣ’atunpin rẹ. A rii wipe bi awon olumulo kan ṣe gbagbọ ni àwọn miran ṣe alaigbagbọ.

Olumulo kan X Police (@sir_Nasmarr), sọ wipe iro ni ọrọ naa. Elomii Watcharat (@TonWatcharat), so wipe iwọn omi ti eniyan ba mu niise pelu irufe ere idaraya tabi iṣẹ́ ti eeyan ṣe. 

Awon olumulo miran RYAN (@10_tacotate) ati Ravi Elvin (@iravielvin) bere ibeere pe omi melo leniyan a mu ti a fa ipalara.

Biotilejepe omi se pataki si alafia ati ilera ara eniyan, aheso pe omi amuju le fa iku ṣe wa ni kayefi, DUBAWA si se iwadii lati fi idi ododo mule.

Ifidiododomule

Mimu omi ni amuju le mu ewu dani, o le fa hyponatremia, aisan ti o maa n waye nigba ti iyo afaralokun tinu ara ba sọ agbara rẹ nu.

Ile-ikawe ti àwọn onisegun oyinbo salaye pe iyọ ati minira ara maa n se ara loore. Sugbon ti eniyan ba mu omi amuju, iyọ afaralookun (sodium) a sọ agbara nu, sẹ́ẹ̀li ara a bere sii wu. Eyi a si fa ijamba fun ọpọlọ, o le fa iporuru ọkàn, giiri, tabi iku.

Ninu atejade kan, àjọ to n risi ọrọ ilera kindinrin ni ilẹ Amerika, sọ wipe ami apeere hyponatremia ni ki aya maa rin eniyan, ori fifọ, iporuru okan. Ti onitoun ko ba ri itoju, eyi le mu ki ori rẹ daru tabi ki ọpọlọ wu, ti o si le la ẹmi lọ.

Iwadii kan salaye pe opo ninu awon elere idaraya lo ti padanu emi won nitori amuju omi, kiise oungbe.

Iwọn omi ti omode nilo yato si ti agbalagba. Ọmọ ọwọ ti ojo ori re ko to oṣù mẹfa ò nilo omi rara, gbogbo omi ti won nilo n wa lati inu omi oyan, tabi iyefun wàrà, nitoripe omi le fa ijamba si kindinrin wọn. Leyin osu mefa, òbí le bẹrẹ sii fun ọmọ ni omi díẹ̀. Agbalagba okunrin le mu omi lita meji abo lojumo kan, obinrin le mu lita meji lojo kan.

Àwọn alaisan ti aisan won ni nkan se pelu oungbe tabi aini iwonba omi to tọ lago ara, irufe eniyan bee nilo lati mu omi pupọ, wọn si le lo ORS (omi ati iyọ̀) lati mu ki ara pada bọ sipo. Eniyan ti ko ṣ’aisan nilo lati mu omi to ba n p’oungbẹ, irufe iṣẹ́ tabi ere idaraya ti o n se ati iru agbegbe ti o n gbe naa ni nkan ṣe pelu iwọn omi ti o maa mu.

Imọran àwọn onimọ̀

Awon onisegun so wipe biotilẹjẹpe omi se pataki laago ara, mimu omi l’amuju le se ijamba fun kindinrin, sọ iyọ afaralookun di alailagbara, yoo si mu ọpọlọ wu. 

Onimo nipa anfaani ti ounje n se laago ara, Oluwatobi Bankole, ni ilu Ondo so pe looto mimu omi lamuju le fa aisan hyponatremia.

“Ti eniyan ba mu omi ju botiyelọ, onitoun wa ninu ewu aisan hyponatremia. Ki eeyan mu omi lita meta si merin laarin wakati kan le se ijamba si kindinrin.” Onimọ naa f’ikun wipe ti iyo afaralokun ba ja wale laago ara, omi a ri aye wọ inu awon sẹẹli kan bii ọpọlọ, o si le fa iku ojiji.

Ọjọgbọn Ignatius Onimawo, eni ti o je oludari ile ekọ agba, Yunifasiti Ambrose Alli, gbani nimoran pe omi lita mefa lojumo kan ti to. “Ti eniyan ba mu omi to koja lita mefa, ipalara le waye, o si le la ẹmi lọ.”

Ọjọgbon Ayodeji Akinbodewa, ẹni ti o jẹ onimọ nipa ilera kindinrin sọ wipe awọn ọmọde o nilo omi ti o poju. “Ko si aye pupo fun omi ninu ara omode nitori naa, omi díẹ̀ ti tó. Amuju omi le fa ipalara ati iku. Koda omi wa ninu ounje ti a n jẹ, iwọnba omi ti eniyan nilo ni ojo kan wa lati inu ounjẹ, omi ati awon nkan miran ti o wọ inu ara wa ni ọjọ kan.”

Onimo naa salaye pe agbalagba le mu lita meta omi ni ojumọ kan. O fikun wipe ti eniyan ba mu ju eyi lọ, o le bere sii bì gbogbo ounje ti o ti je. “Lapapo kindinrin, àpòòtọ  ati ọkàn eniyan le farada omi lita meta si marun lojo kan.”

O salaye pe ti eniyan ba poungbẹ bii enu gbigbe tabi itọ dudu, o ṣeeṣe ki onitoun mu omi koja lita meta ṣugbọn dokita nilati se akiyesi iru eniyan bẹẹ. O tunbọ sọ wipe ti kindinrin tabi àpòòtọ ba da’ṣẹ silẹ, omi a bere sii dagun sinu ara, eyi si le fa iku ojiji.

Awon onimo naa lapapọ sọ wipe o se pataki ki a se idanileko awon eniyan nipa iwonba omi ti won nilo lago ara, paapaa ni igba oru tabi ni asiko ise asekara tabi ere idaraya, ki won ma baa fori lugbadi iku ojiji.

Akotan

Otito ni ọrọ pe omi amuju le fa iku ojiji. Abajade iwadii ati imoran awon onimo ṣ’agbekalẹ rẹ pe mimu omi l’amuju laarin wakati tabi iseju díẹ̀ le fa amupara. Eyi si le la ẹmi lọ.

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Back to top button
Translate »