African LanguagesEconomyFact CheckYoruba

Òdodo ọ̀rọ̀! Orílè-èdè Nàìjíríà ni ó ń ṣe iṣẹ́-ọ̀gbìn ìrẹsì jùlọ ní ilẹ̀ Adúláwọ̀

Àhesọ

Olùrànlọwọ pataki fún ààrẹ Muhammadu Buhari l’órí ètò ọ̀rọ̀ awujo, tí ó sì tún jẹ́ igbákejì agbẹnusọ fún ikọ̀ ìpolongo ìdìbò f’ẹgbẹ òṣèlú APC, Ajuri Ngelale sọ, nínú ìfòròwánilénuwò kan pé orílè-èdè Nàìjíríà ni ó ń ṣe ògbìn ìrẹsì jùlọ ní ilẹ̀ Adúláwọ̀, pàápàá labẹ ìṣàkóso ìjọba Buhari. 

Èsì ìwádìí 

Òdodo ọ̀rọ̀! Orílè-èdè Nàìjíríà ni ó ń ṣe iṣẹ́-ọ̀gbìn ìrẹsì jùlọ ní ilẹ̀ Adúláwọ̀

Ìwádìí DUBAWA fihàn pé òtítọ ni ọ̀rọ̀ naa. Orílè-èdè Nàìjíríà ni ìlú tí ó ń ṣe iṣẹ́-ògbìn ìrẹsì jùlọ ní ilẹ̀ Adúláwọ̀. Bákan náà, ipò kẹrinla ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà wa nínú àwọn orile-ede tí ó ń ṣe iṣẹ ọgbin ìrẹsì kaakiri àgbáyé. 

Iroyin lẹkunrẹrẹ

Ọpọlọpọ itakurọsọ ló máa ń saba wáyé l’ásìkò ìdìbò. Ìbéèrè onírúurú ni àwọn olùdìbò a máa bèrè lọwọ ẹgbẹ òṣèlú ti ń ṣe ìjọba lọwọlọwọ, pàápàá lórí àwọn ètò àti ìlànà tí wọ́n ṣ’agbekalẹ rẹ̀ nípasẹ̀ ànfààní tí wọn ní láti ṣàkóso ijoba.

Ṣáájú eto idibo sí ipò ààrẹ tí ọdún 2023,  Olùrànlọwọ pataki fún ààrẹ Buhari l’órí eto ọrọ awujo, ti o sì tún jẹ igbákejì agbẹnusọ fún ikọ̀ ìpolongo ìdìbò ti ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Ajuri Ngelale bá ilé-isé ìròyìn Channels TV sọ̀rọ̀ laipe yìí.

Nínú àlàyé rẹ̀ lórí ìpinnu ẹgbẹ́ òṣèlú náà láti yan Bola Tinubu gẹgẹbi olùdíje ẹgbẹ, Ajuri – ninu ìfòròwánilénuwò náà pèlú Ṣeun Okinbaloye – sọ pé orílè-èdè Nàìjíríà ni ó ń ṣe iṣẹ́ ògbìn ìrẹsì jùlọ ní ilẹ̀ Adúláwọ̀ nisinsinyi, ju bó ti wà ní ọdún 2015.

A rí èyí nínú atẹjade kan lórí ìkànnì abẹ́yẹfò Twitter, tí David Offor fi sí ojú òpó rè pẹlu ọ̀rọ̀ ifori yìí, “Dino Melaye, Daniel Bwala àti Delẹ Momodu lapapọ, wọn kò lè figa gbága pẹ̀lú òye Ajuri. Ìbùkún nla ni Baba jẹ́ fún ikọ̀ ìpolongo Bola Tinubu.”

Fónrán iṣẹju méjì àti ìṣẹ́jú àáyá kokandinlogun tí onítọ̀ún pín sí ojú òpó rè, ṣàfihàn Ajuri tí ó ń gboriyin fún ìjọba Buhari lórí eto àti òfin iṣẹ ọgbin l’orile ede Nàìjíríà. Ó sọ wípé, “Tí e bá wo ìwé ifilole ètò ìṣèjọba (manifesto) ti Bola Tinubu gbejade, a sọrọ nípa iṣẹ ogbin, Ni oju-iwe ketadinlogbon, Tinubu ṣàlàyé pe oun yóò tẹsiwaju nínú ìpìlẹ̀ ti ààrẹ Muhammadu Buhari ti filelẹ nípasẹ̀ ètò ọ̀gbìn ni orile-ede yìí. Ni ọdún 2015, orílè-èdè Nàìjíríà je òkan nínú àwọn ìlú adúláwọ̀ tí máa ń saba gbé ìrẹsì wọlé láti ilẹ̀ òkèèrè. Lọ́jọ́ tòní, àwa ni orílẹ̀-èdè tí ó ń ṣe ògbìn iresi julọ ní ile adulawọ.”

Awọn aṣàmúlò ìkànnì abẹ́yẹfò ti wo fónrán náà ní ìgbà ẹgbàárún dín ní eérinlá-dín-ní-ọ́ta lé ní irinwó (9,554). Won sì ti bù ọwọ ifẹ luu ni igba ojì lé ní ẹgbẹ́rin (840), won satunpin rẹ ni ọna àrún dín ní ọ́rin lélọ́ọ̀dúnrún (375), ó sì ní ọ̀rọ̀ ìwòye méjì lé l’ọgọrun (102).

Ìdíyelé iresi àpò kan (50kg) l’ásìkò tí a ko ìròyìn yìí jé egberun marun-le-logbon náírà (₦35,000), eyi ló mú kí a ṣe alaigbagbọ àhesọ náà. A sì ṣe ìwádìí ọ̀rọ̀ náà. 

Òdodo ọ̀rọ̀! Orílè-èdè Nàìjíríà ni ó ń ṣe iṣẹ́-ọ̀gbìn ìrẹsì jùlọ ní ilẹ̀ Adúláwọ̀
Aworan atẹjade náà láti orí ìkànnì abẹ́yẹfò Twitter. 

Ìwádìí

Kí ààrẹ Muhammadu Buhari tó gba ipò gẹgẹbi ààrẹ l’ọ́dún 2015, orílè-èdè Nàìjíríà ná owó tó tó bílíọ̀nù méjì dọ́là ($2.41 billion) láàrin ọdún mẹta fún ṣíṣe igbewọle ìrẹsì láti ilẹ̀ òkèèrè, Gómìnà bánkì àpapọ̀ orílẹ-èdè Nàìjíríà, Godwin Emefiele ló sọ ọ̀rọ̀ yìí. 

DUBAWA ríi wípé bánkì àpapọ̀ ilẹ̀ wa ṣ’agbekalẹ àwọn ẹtọ kan fún àwọn agbe bíi: Commercial Agriculture Credit Scheme àti N220bn Micro Small and Medium Enterprises Development fund. Àwọn ètò yìí jẹ́ ònà tí ìjọba ń gbà láti ṣe iranlọwọ fún àwọn àgbẹ alàdáni ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Bákan náà, ni ọjọ ketalelogun osu kefa odun 2015, ijoba àpapọ gbẹ́sẹ̀lé ṣíṣe agbewole ìrẹsì sí Nàìjíríà láti ilẹ̀ òkèèrè.

Ni osu keji, ọdún 2022, awọn Ileeṣẹ tí maá ń ṣe ògbìn ìrẹsì bẹrẹ síi ṣe ìpèsè ni ìlọ́po mejidinlaadorin lati mewa, gẹgẹbi oro gomina bánkì àpapọ.

Gomina náà f’ikun wípé àwon Ileeṣẹ ọ̀gbìn ìrẹsì wọnyi ti n ṣe ìpèsè to mílíọ̀nù mẹta ìwọn toonu ti a ba safiwe rẹ pẹlu ìpèsè ọ̀kẹ́ mẹ̀tàdínlógún àbọ̀ ti o n ṣe tẹ́lẹ̀.

Ìwádìí wà fihàn pé Nigeria gbe’gba oroke ni’nu àwọn orílẹ̀-èdè tí ń ṣe ògbìn ìrẹsì ní ilẹ̀ adúláwọ̀.

Òdodo ọ̀rọ̀! Orílè-èdè Nàìjíríà ni ó ń ṣe iṣẹ́-ọ̀gbìn ìrẹsì jùlọ ní ilẹ̀ Adúláwọ̀
Àwòrán tábìlì orilẹ-ede tó ń ṣe ògbìn ìrẹsì lágbayé. Orísun àwòrán: Wikipedia.

Data láti àjọ United Nations’ Food and Agriculture Organisation (FAO), fihàn pe Nàìjíríà wà ní ipò kẹrinla láàrin àwon orílè-èdè agbaye tí ń ṣe ògbìn ìrẹsì ní ọdún 2020, orílẹ-èdè China lọ gbé ipò kinní. 

Bákan náà, àjọ (United States Department of Agriculture’s Foreign Agricultural Services) ṣàfikún ọrọ naa pe orílè-èdè Nàìjíríà ni o n ṣe iṣẹ-ogbin iresi julọ ni Áfríkà.

Atejade àjọ náà ni osu kọkànlá ọdun 2021 fihàn pé Nàìjíríà ṣe àgbéjáde ìrẹsì iwọn toonu mílíọ̀nù merin o le ni ogójì ọ̀kẹ́ (4.89 million metric tonnes) ni ìgbà tí orílè-èdè Egypt tẹ̀lẹ pẹ̀lú mílíọ̀nù merin. 

Òdodo ọ̀rọ̀! Orílè-èdè Nàìjíríà ni ó ń ṣe iṣẹ́-ọ̀gbìn ìrẹsì jùlọ ní ilẹ̀ Adúláwọ̀
Aworan tabili náà. 

Àkótán 

Botilẹjẹ pé ìdíyelé ìrẹsì lọwọlọwọ ga jù ti ọdún 2015 lọ, òtítọ ni ọrọ ti Ajuri sọ pé Nàìjíríà n ṣe ògbìn iresi ju awọn orilẹ-ede miran ni ile Áfríkà. 

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Back to top button