Fact CheckEconomyYoruba

Òdodo ọ̀rọ̀! Orílẹ́èdè Nàíjírìà ló ní ọkọ̀ ojú irin ayára bí àṣá tó sáré jùlọ ní ilẹ̀ Áfríkà

Getting your Trinity Audio player ready...

Ahesọ: Olumulo ikanni ibaraenisore Facebook sọ laipẹ yi pe orileede Nàíjírìà ló ní ọkọ̀ ojú irin ayára bí àṣá tó sáré jùlọ ní ilẹ̀ Áfríkà.

Òdodo ọ̀rọ̀! Orílẹ́èdè Nàíjírìà ló ní ọkọ̀ ojú irin ayára bí àṣá tó sáré jùlọ ní ilẹ̀ Áfríkà

Abajade ìwádìí: Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà. Ètò ọkọ̀ rélùweè ti ìjọba ìpínlẹ̀ èkó gbé kalẹ̀ lè sáré ọkẹ mítà ọgbọn le lọọdunrun laarin wákàtí kan.

Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyẹ́

Ní àwọn orileede àgbáyé, àwọn oun amáyéderùn ti ìjọba gbe kale fun ìdàgbàsókè ìlú la ma fii se idiwon ìtẹ̀síwájú. Nitori naa ni àwọn aṣejọba maa ṣe n ya ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó s’ọ́tọ̀ fun àwọn oun èlò ìgbàlódé ti yoo mu ayédẹrùn fún ará ìlú.

Yíya ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó sọ́tọ̀ fun ètò igboke-gbodo ọkọ̀ paapaa ni àwọn ìlú nla, maa n mu idagbasoke ba ọ̀rọ̀ ajé orileede.

Ní ilẹ̀ Afrika, àwọn ètò amáyéderùn je kókó ọ̀rọ̀ tó ṣe pataki lawujọ eniyan. 

Láìpẹ́ yíì, olumulo ikanni ibaraenisore, Africa View Facts, sọ wípé orile ede Naijiria lo ni ọkọ̀ rélùweè ayára bí àṣá to sare julọ ni Afrika.

“Ọkọ̀ ojú irin ayára bí àṣá to sare jùlọ ní ilẹ̀ Afrika, Nàìjíríà ló wà. Ọkọ̀ naa maa rin lemaarun ni àárọ̀, eemerin ni ìrọ̀lẹ́. Ọkọ̀ ayára bí àṣá naa maa sáré ọkẹmítà ọgbọn le lọọdunrun laarin wákàtí kan.”

Ṣùgbọ́n a rii wipe awon olumulo miran ṣ’alaigbagbọ ọ̀rọ̀ náà. Enikan, Atunde Akanbi Wasiu sọ wípé, “Lọ South Africa, Kenya, Ethiopia ati awon ìlú míràn. Wàá rí ọkọ̀ ojú irin ayára bí àṣá to dara ju ti Èkó lọ.”

Olumulo miran, Zaidu Aliyu sọ wípé, “Íbo ni ọkọ̀ ojú irin náà wà? Kò sí ọkọ̀ ojú irin kankan ni orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.”

Àwọn elomiran gboriyin fun ìjọba ipinle Èkó, pelu ireti pe idagbasoke náà ma de àwọn ipinle miran.

A ṣ’àkíyèsí ariyanjiyan naa laarin awon olumulo naa, a si se iwadii.

Ifidiododomulẹ̀

ọjọ́ kọkandilogbọn oṣù kejì ọdún 2024, ààrẹ Bọlá Tinubu ṣe ìfilọ́lẹ̀ ọkọ̀ ojú irin Red Line, leyin bii ọdún mẹ́ta ti iṣẹ́ bẹ̀rẹ̀.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó, Babajide Sanwoolu ṣ’àlàyé pé ẹẹdẹgbẹta ẹgbẹrun eeyan ni ọkọ̀ náà ma gbe lójúmọ́ kan, pelu ibudokọ ni Agbado, nipinlẹ Ogun to fi de ipinlẹ Eko bii Iju, Agege, ikẹja, Oṣodi, Muṣin, Yaba sí Oyingbo.

Fun ètò rélùweè Red Line náà, ìjọba ra ọkọ̀ oju irin méjì to wa lara Talgo Series 8. Ọkọ̀ kookan le sare ọkẹmítà ọgbọn le lọọdunrun laarin wákàtí kan.

Wọ́n ṣ’ẹ̀dá àwọn ọkọ̀ náà fún eto rélùweè ilu nla Madison ati Milwaukee ni orileede Amerika, ṣùgbọ́n ipinle Eko lo pada ra.

Ìmọ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé ni won fi ṣ’ẹ̀dá ọkọ̀ ojú irin náà, ó sì wa ní ibamu pẹ̀lú eto ọkọ̀ rélùweè l’agbaye. Kódà, ààyè wa fún àwọn ènìyàn to n lo kẹ̀kẹ́ agbénirìn lori ọkọ̀ rélùweè naa.

Ọkọ̀ naa tun ni ẹ̀rọ amunawa tí wọ́n sopọ̀ mọ́ ijoko ti eeyan le fi muna sori erọ telefoonu wọn; ààyè tí wọ́n n kó ìwé ìròyìn si; ati ilé igbọnsẹ igbalode.

Ṣáájú àsìkò náà, Al-Boraq ni ilu Morocco lo ni ọkọ̀ ojú irin to sáré jùlọ ni Afrika, ọkọ̀ naa lè sáré ọkẹ mità ogún le lọọdunrun laarin wákàtí kan. Wọ́n bẹrẹ iṣẹ́ lori rélùweè naa ní ọdún 2018, ọkọ̀ náà sii rin irin ajo laarin ìlú Tangier àti Casablanca.

Àmọ́, ilé-iṣẹ́ Alstom ma pese ọkọ oju irin mejila to le sare ni iwon oke mita aadota le loodunrun laarin wakati kan, si ilu Morocco. Àwọn ipese wonyi je fun ìdíje ife agbaye ti ọdún 2030.

Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó se ifilọlẹ́ eto rélùweè Blue Line ni ọdún 2023 ti o sáré ni iwọn okemita ọgọ́rin laarin wákàtí kan. 

Bakan naa, ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó tọwọ́bọ̀wé pelu ìjọba àpapọ̀ lati bẹrẹ iṣẹ́ lori ètò rélùweè ọgọta okemita, ti yoo ran eto igbokegbodo ọkọ̀ ninu ilu naa.

Ṣùgbọ́n, àwọn ọkọ ojú irin tó yára bí àṣá wa ni orileede China, ti o si sáré ju ti ipinle Èkó lọ. Koda, ọkọ̀ rélùweè ilu China le sa okemita ota le nirinwo laarin wakati kan.

Akotan

Otitọ́ ni ọ̀rọ̀ pé orileede Nàìjíríà lo ni ọkọ̀ rélùweè to sare julo ni ilẹ̀ Afrika. Àwọn ọkọ̀ oju irin Red Line ti ìpínlẹ̀ Èkó le sare oke mita ọgbọn le lọọdunrun laarin wakati kan.

Show More

Related Articles

2 Comments

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Back to top button
Translate »