Facebook ChecksFact CheckHealthYoruba

Òdodo ọ̀rọ̀, ọtí afunnilokun lè ṣe ijamba fún ìlera ara ènìyàn

Getting your Trinity Audio player ready...

AHESỌ: Ọtí afunnilokun le ṣe ijamba fún ikùn, ó lè mú ki ẹ̀dọ̀kí wú, o lè dín ọpọlọ, o sì lè kọlù ọjẹ-ara ọmọkùnrin (testosterone).

Òdodo ọ̀rọ̀, ọtí afunnilokun lè ṣe ijamba fún ìlera ara ènìyàn

Àbájáde ìwádìí: Òtítọ ni. Àkọsílẹ àwọn onímọ̀ àti ìwádìí fihàn pé otí afunnilokun le ṣe ìjàmbá fún àwọn ẹyà ara kọọkan bíi ikùn, ẹ̀dọ̀kí, ọpọlọ, àti ọjẹ-ara ọmọkùnrin.

Ìròyìn lẹkunrẹrẹ

Ki eniyan le ni okun, agbara, àti kí a lè ji pépé, ọpọlọpọ ènìyàn, ni idi iṣẹ oojọ wọn, pàápàá àwọn iṣẹ tó nilo agbára, bíi eré ìdárayá, ilé ẹ̀kọ́, ilé iṣé àti àwọn oun míràn, máa n sábà mú ọtí afunnilokun kí wọn lè parí iṣẹ́ wọn lasiko. 

Olumulo ìkànnì ibaraẹnisọrẹ, Facebook, Olubukola Oyenike Akeju fí atẹjade kan sí ojú òpó rẹ̀ pé mímú ọtí afunnilokun lè ṣe ìjàmbá fún àwọn ẹyà ara kọọkan, bíi ẹ̀dọ̀ ara. 

“Eyin okunrin, e bọ sí bí o. E f’opin sí mímu ọtí afunnilokun. Ọtí afunnilokun máa n ṣe ijamba fún ikùn, a mu ẹ̀dọ̀kí wù, din ọpọlọ, yóò si ṣe ipanilara fún ọjẹ-ara ọmọkùnrin.”  

Ọpọlọpọ olumulo ìkànnì Facebook ti bú ọwọ ìfẹ lu atẹjade náà, awọn eniyan sì n sọrọ nípa rẹ. 

Ọpọlọpọ ènìyàn lo dupe l’ọ́wọ́ olumulo náà fún ìtọ́nisọ́nà náà. Ṣugbọn àwọn ẹlòmíràn béèrè ohun ti o le fàá ti ọtí afunnilokun ṣe lè ṣe ìjàmbá fún ìlera àrà àwọn ènìyàn. 

“Kinni anfààní ọtí afunnilokun? Tí kò bá ní ànfààní kánkan, kilode ti àjọ to n mojuto ọrọ oúnjẹ ati oogun lorilẹede Naijiria, NAFDAC ṣe ń fi owo sí àwọn ọtí wọnyí? Boya o le se ijamba ti ènìyàn bá mú lamuju,” olumulo kan, Regina Mekeme Nelson ló sọ èyí. 

Àwọn ẹlòmíràn bere oun tó lè fàá to jẹ́ pé àwọn ọkùnrin nìkan ni ọtí náà ń ṣe ìjàmbá fún. 

“Se àwọn ọkùnrin nìkan lo ń mu ọtí afunnilokun ni?” olumulo míràn Symbolicman Obinna bèèrè. 

Botilẹjẹpe ọrọ naa fúnni ní òye àti ìmọ, ọpọlọpọ àríyànjiyàn lo tẹlẹ e, eyi lo fàá tí a fi ṣe ìwádìí wà.

Ifidiododomule

Ilé-isé ìròyìn ilu Amerika, Cable News Network (CNN) ṣàlàyé nínú àkọsílẹ re kan pé àwọn èròjà kọọkan wa inu oti afunnilokun ti o le se ijamba fún àgọ ara ènìyàn .

Kódà, ọpọlọpọ èlò imu kanilara (caffeine), àádùn, èròjà ajira (Vitamin B), eso guarana; taurin; amino acid ti a ri latara ẹran ati ẹja; ati L-Carnitine, ohun ti o máa ń so ọra inú ara di okun; lo wa nínú ọti afunnilokun.

Àjọ American Beverage Association (ABA ṣàlàyé pé àwọn èròjà inu ọtí afunnilokun yìí wa ninu oúnjẹ ti a n jẹ, onimọ nípa ìlera ara, Katherine Zeratsky, osise ile iwosan Mayo Clinic ni ilu Rochester, Minnesota ṣàlàyé pé ìwọn awon èròjà naa máa n koja gbedeke ti o yẹ nínú ọtí afunnilokun ti a ba fi wẹ iye ìwọn awon èròjà náà ninu ounje ti a n jẹ, won sì sàlàyé pé ti a ba fi awon èròjà wọnyi kun ti elo imu kanilara (caffeine), o le se ijamba to po. 

Onimọ nípa iṣegun ọkan, Dokita John Higgins ti ilé-ìwé McGovern Medical School ni Yunifásítì Texas Health Centre, ilu Houston sọ wípé ọtí afunnilokun máa n ṣe ìjàmbá fún ìlera ọkàn, o ṣàlàyé pé elo imu kanilara (caffeine), amino acid (taurine) ati ajira (B vitamins) lo máa n ṣokunfa. 

Nínú ọrọ rẹ, dọ́kítà náà ṣàlàyé pé otí afunnilokun máa n fikun àníyàn, iporuru ọkan, ifunpa gíga, o sì lè mú ki ẹjẹ eniyan ki ju botiyẹ. Ṣugbọn, èròjà taurine lo n ṣokunfa eyi, èròjà naa máa n ṣe ikọlu fún omi ara, ati ẹjẹ.

Ṣugbọn, ṣe ọtí afunnilokun lè ṣe ikọlu to burú sí ikùn, ẹ̀dọ̀kí, ọpọlọ àti ọjẹ-ara ọmọkùnrin?

Àkọsílẹ Health line ṣ’àlàyé pé elo imu kanilara (caffeine) ti o wa ni inu tíì, kọfi, àti ọtí afunnilokun le ṣe ìjàmbá bíi iporuru ọkàn, aibalẹ okan, iwarìri, ailesun.

Kódà, ó lè fa orí fífọ́, ẹfọri tulu ati ẹjẹ rírú.

Atẹjade ile-eko gíga ti ìlú Amerika, University of Michigan ṣ’àlàyé pé èlò imu kanilara ti o wa nínú ọtí afunnilokun lè mu ki ènìyàn ya igbẹ gbuuru, o sì lè mu ki ènìyàn gbẹ. 

Atejade náà ṣ’alaye bi elo imú kanilara náà lè fa ki eniyan máa tọ s’ára. Kódà, o le gba oorun l’oju ènìyàn, fa ijaya àti àwọn oun míràn to léwu sí ìlera ara. 

LiveStrong ṣ’àlàyé pé àwọn oluṣeda ọtí afunnilokun máa ń fi ọtí líle sínú rẹ̀, èyí sì lè ṣe ìjàmbá fún ẹ̀dọ̀kí, paapaajulo tí ènìyàn bá mu ọtí afunnilokun lọpọlọpọ, ẹdọki ló máa jìyà rẹ̀. 

O ṣ’àlàyé síwájú síi pé ọtí líle tí ó wà ní inú ọtí afunnilokun máa n ṣe ìjàmbá fún ẹjẹ ara àti ẹdọki. Ṣugbọn ọtí amupara lo le fa àìsàn burúkú bíi ààrùn ẹdọ (Cirrhosis).  

Nínú Ìròyìn rẹ̀, ilé-isé ìròyìn Canadian Broadcasting Corporation (CBC NEWS), sọrọ nípa okunrin oṣiṣẹ kan ti o mu ọtí afunnilokun merin sí márùún ni ọjọ kan, okuntin náà ni àìsàn jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀, nítorí o ti koja gbedeke niacin ti o yẹ kò mú ni ọjọ kan. 

Ìròyìn CNN ṣàlàyé pé mímú èló imu kanilara lọpọlọpọ lè fa ìjàmbá fún ọpọlọ. Àìlera bíi rudurudu ọkàn, ailesun, Ijaya, ati bẹẹbẹẹlọ ló lè sẹyọ latarii mímu ọtí afunnilokun.

Àkọsílẹ Sutter Health fikun wípé ọtí afunnilokun máa n fa ẹfọri, Ijaya, iwarìri, ki eniyan máa bínú sódì àti bẹẹbẹẹlọ.

Àbájáde àjọ Advantageja fi ìdí rè múlẹ pe ti ọkùnrin ba mu imu elo kanilara, o ṣeéṣe ki o ni ilopo ọjẹ-ara ọmọkùnrin, sugbon fún ìgbà díẹ̀ ni. 

O mẹnuba ìwádìí àjọ International Journal of Sports Nutrition and Exercise Metabolism ti o fi ìdí rè múlẹ pe, elo imu kanilara máa n ṣe ilopọ ọjẹ-ara ọmọkùnrin sugbon, nígbà kanna, o máa n fikun wahala ati iporuru ọkàn, èyí tí o le mu ki ọjẹ-ara ọmọkùnrin dawọ iṣẹ́. 

Njẹ awọn ọkunrin nikan ni ọtí afunnilokun le ṣe ní ìjàmbá?

Ìwádìí yunifásítì ìlú Boston ni Amerika, Boston University School of Public Health fihàn pé tí ọkùnrin ba mú oti afunnilokun, o le fa airọmọbi fún tọkọtaya.

Ìwádìí na filelẹ pé ti obìnrin bá lo elo imu kanilara, kii saba dènà oyun. Sugbon, tí ọkùnrin ba muu, o le mu ki atọ ọmọkùnrin ma kun oju osunwon to. Ìwádìí náà ṣe ìmúlò ẹgbẹta okùnrin ti wọn kò lè fún obìnrin loyun, ìwádìí sí fihàn pé mímú oti afunnilokun ni o ṣokunfa.

Sugbon, mímu oti afunnilokun le se ijamba fún okunrin ati obinrin bákan náà, gẹgẹbi àkọsílẹ Women Health Editors. 

Kini àwọn onimọ sọ?

Abdulsalami Olayinka, onimọ nipa fifi ounjẹ wo aisan, ni Yunifasiti isegun ti ìlú Ìbàdàn, University College Hospital (UCH, ṣàlàyé pé àwọn èròja ọtí afunnilokun ò ní ànfààní ti wọn sọ pé o ni. O fikun wípé ajira (Vitamin B12) ti o wa ninu ọtí afunnilokun o le ṣiṣẹ ajira ati wípé elo imu kanilara ti o wa ninu oti afunnilokun le fa ẹjẹ riru. 

Ó ṣàlàyé pé èlò imu kanilara lè fa ìjàmbá fún ìlera ọkàn, o sì lè fa ọtí amuju. 

Kódà, o ṣàlàyé pé àwọn oluṣẹda ọtí afunnilokun máa n fi ṣuga sí lòpòlopò, èyí sì lè mu ki inú máa run ènìyàn. O mẹnuba ijamba ti ọtí náà n se fún edo. 

Onimọ náà ṣàlàyé pé otí afunnilokun le fa airọmọbi, pàápàá lára àwọn ọkunrin. Nítorí, àwọn ọkunrin lo máa sábà mú ọtí afunnilokun ju awọn obinrin lọ, ṣugbọn eyi ko tumọ sì wípé kò le se ijamba fún àwọn obinrin, arákùnrin Olayinka ló sọ bẹẹ. 

Onimọ nípa ọrọ oúnjẹ, Temiloluwa Omotoso, ṣàlàyé pé mímú oti afunnilokun dalẹ ọjọ orí ènìyàn. O ṣàlàyé pé ewú to wa ninu mímu oti náà ju anfaani ibẹ̀ lọ. Kódà o lè ṣe ìjàmbá fún ètò èso ara ati ọkan ènìyàn. 

Onimọ náà fikun wípé elo imu kanilara lè fa wahala ati iporuru okan, kódà o máa n fa ifunpa gíga fún àwọn ẹlòmíràn. Oun náà sọ wípé kìíse ọrọ bóyá ènìyàn jẹ ọkùnrin tabi obinrin, sugbon bi ara onikaluku ṣe rí. 

Akotan

Òtítọ ni ọrọ náà. Àkọsílẹ awon onimọ, ati iforowanilenuwo jerisi ọrọ pe oti afunnilokun le se ijamba fun ikùn, ẹdọki àti ọjẹ-ara ọmọkùnrin.  

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Back to top button