ExplainersMedia LiteracyYoruba

Ọ̀nà mẹ́rin tí o lè gbà ṣe ìdámọ̀ ayédèrú owó náírà

Ni ọjọ́ kerindilogbon oṣù kẹwa ọdún 2022, bánkì àpapọ̀ orílè-èdè Nàìjíríà (CBN) kéde pé wọn yóò ṣe àtúntẹ̀ owo pẹpa igba náírà (N200), ẹẹdẹgbẹta náírà (N500) ati ẹgbẹrun kan naira (N1000). 

Godwin Emefiele, ọ̀gá àgbà bánkì náà ṣàlàyé pé ìgbésẹ̀ náà yoo ran wọn lọwọ láti ṣe igbawole iye owó tó tó trilionu meji náírà o le ni ẹẹdẹgbẹrin mílíọ̀nù (N2.72 trillion), owó ti ko sí ní sàkání awọn ilé ifowopamọ. Ìgbésẹ̀ náà yoo ran CBN lọwọ, lati gba “ìṣàkóso iye owó náírà ti ówà ni ita”.

Leyin ti ààrẹ Muhammadu Buhari ṣe àfihàn owó náírà tuntun naa, ọpọlọpọ ènìyàn ló fi ehonu wọn hàn pé yóò rọrùn fún àwọn onijibiti lati ṣe ayederu owó náà.

Kódà, ṣaaju ìgbà tí ijoba se àfihàn owó náírà tuntun, ọpọlọpọ ìròyìn ofege ni awọn eniyan n pinka lórí bí owó náà ti ri. Leyin eyi, aheso tànká orí ayélujára pé aró n jade lara owó náà ti omi bá ṣèṣì kan lára. Àwọn eloriman sọ wípé àwọn olóṣèlú n ṣe atejade ayédèrú owó náà ti wọn yoo fi ra ìbò, kódà àhesọ orisirisi ni won gbe ka pe awọn ènìyàn kan ti bere síi na ayederu owo naira tuntun yii.

Pelu gbogbo àhesọ to rọ mọ owó naira yìí, awọn eniyan bẹrẹ sí ní bẹrù nitori wọn kò fẹ pàdánù owó wọn. Nítorí náà, akọsilẹ yìí má ṣàfihàn bi ọ ṣe lè ṣe ìdámò ayédèrú owó náírà tuntun.

Ifọwọkan: Ti o ba fi ọwọ kan ojúlówó naira tuntun, pepa náà lè ní ọwọ, agaran sí ni. Koda, aro ti o wa lórí ojúlówó owó naira tuntun naa se rẹ́gí. Ayédèrú owó naira tuntun burẹwa gan, kò síi ṣe agaran. Koda, awọ re yatọ si ojúlówó náírà. 

Yẹ owó tí o gbà dáadáa, ti kii ba ṣe agaran ti o sì burewa, o ṣéeṣe kí o jẹ́ ayédèrú.

Nọ́mbà idanimọ onisisentele: Ti a ba fi ojúlówó ọwọ naira tuntun si abe èròjà ìmúná ultraviolet, nọ́mbà idanimọ onisisentele yìí yóò yí awo padà láti dúdú sí àwọ̀ ewé. Eyi jẹ ọ̀nà kan tí bánkì àpapọ náà gba lati dẹkùn ayédèrú owó náírà. 

Ọ̀nà mẹ́rin tí o lè gbà ṣe ìdámọ̀ ayédèrú owó náírà
Owó pepa ẹgbẹrun náírà (N1000) pẹlu nọmba idanimọ onisisentele 

Àti wipe fonti kan pato ni won fi tẹ nọmba idanimọ yìí sì ara ojúlówó owó náírà tuntun. Nọ́mbà idanimọ onisisentele yìí wà ní eyín owó pepa N1000 tuntun, sugbon iwájú ní ówà fún igba naira N200 ati eedegbeta naira N500.

Ontẹ Goolu: Ni ara ojúlówó owó Pepa N1000 tuntun, ontẹ goolu kan wà ní apá òtún lori owo náà ti a ko le fi ounkoun ṣikuro. Ninu ontẹ goolu yìí ni a tiri aami orile-ede Naijiria, ti won sì kọ egberun sí abé re. 

Ọ̀nà mẹ́rin tí o lè gbà ṣe ìdámọ̀ ayédèrú owó náírà
Ontẹ goolu lórí owó pepa ẹgbẹrun náírà (N1000)  

Ayédèrú ní owó ti ko ba ní ontẹ goolu tàbí ti a le yara họ ontẹ yi kuro. 

Òkun ìdáàbòbò: Ojúlówó owó náírà tuntun ni òkun ìdáàbòbò kan ti o fere da bi wipe o kan sugbon ti e ba fi eroja emuna wo fínífíní, òkun naa ko kan rara. Òkun yìí wà ní iwájú owó pepa N200 ati N500. O sí wà lẹyìn N1000. Ni afikun, o gbe onte ‘CBN’ ni apa méjèèjì owo naira yìí. 

Ọ̀nà mẹ́rin tí o lè gbà ṣe ìdámọ̀ ayédèrú owó náírà
Owó pepa ẹẹdẹgbẹta náírà pẹlu òkun ìdáàbòbò laarin rẹ

Àkótán

Awọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà gbọdọ le ṣe ìdámò ayédèrú owó náírà ki wọn lè dáàbòbo ara wọn, ki wọn sì ma pàdánù owó wọn. E le ṣe ìdámò owó ayédèrú ti ẹ ba farabalẹ ṣ’ayẹwo ìrísí, awọ, nọ́mbà idanimọ onisisentele ati bi owo náà ṣe ṣe agaran sí.

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Back to top button