Facebook ChecksFact CheckPoliticsYoruba

Se lóòtọ́ ni ààrẹ Tinubu fẹ́ fi owó dọ́là rọ́pò Náírà? 

Getting your Trinity Audio player ready...

Ahesọ: Olumulo ikanni ibaraẹnisọrẹ Facebook ṣ’atunpin fọ́nrán kan to ṣafihan ibi ti ààrẹ Tinubu ti kede ìgbésẹ̀ lati fi owó dọ́là rọ́pò Náírà. 

Se lóòtọ́ ni ààrẹ Tinubu fẹ́ fi owó dọ́là rọ́pò Náírà? 

Àbájáde ìwádìí: Ayédèrú ní fónrán ọ̀ún, a ṣ’abapade ojúlówó fónrán náà lórí ile-ise amóhùnmáwòrán Arise News. 

Ìròyìn lẹkunrẹrẹ

Ní ọjọ kọkandinlọgbọn oṣù kàrún ọdún 2023, ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ọgbẹni Bola Tinubu sọ, nibi ayẹyẹ iburawole sí ipò aare pe, ètò ọ̀rọ̀ ajé orilẹ-ede yìí nilo àtúnṣe. 

Lẹyìn èyí, ni ọjọ kẹrinla oṣu kefa ọdún 2023, banki apapo orilẹ-ede Nàìjíríà kéde pe wọn yóò sọ oniruuru ọjà pasipaarọ owo dọ́là si náírà di ọkan ṣoṣo. 

Ni ọjọ́ kerindinlogbon oṣù kẹjọ ọdún 2023, Folami Adeyinka, olumulo ikanni ibaraẹnisọrẹ Facebook, ṣ’atunpin fónrán kan to ṣafihan oníròyìn Oji Okpe níbi ti o ti kéde pé ọgbẹni Tinubu ti fagile lilo owó náírà, o sí ti fi owó dọ́là rọ́pò. 

Fónrán náà ṣàfihàn oníròyìn náà nì ibi ti o ti n ṣàlàyé pé ààrẹ fẹ parọ owó náírà pẹ̀lú dọ́là. Síwájú si, fónrán náà ṣafihan ogbeni Tinubu tó ń ṣàlàyé pé, “A fẹ dènà lilo owó náírà, a ó si bẹ̀rẹ̀ síí lo owó dọ́là.”

Se lóòtọ́ ni ààrẹ Tinubu fẹ́ fi owó dọ́là rọ́pò Náírà? 
Àwòrán fónrán náà 

Ọpọlọpọ ènìyàn lórí ẹrọ alatagba Facebook àti Instagram ló ṣ’atunpin fónrán ọ̀ún.  

Bí àwọn olumulo kan ṣe tako fónrán náà, àwọn miran gbagbọ pe otitọ ọrọ ni. Olumulo kan @ootconsult sọ wípé, “Ko sí oun rere kan tí yóó ti ara Arise TV jade wa”. Elomiran @23_24_beautybar, kọ eyi, “Ayederu ní fónrán yìí, ìmọ ẹrọ Artificial Intelligence ni wọn fi ṣeé, e sakiyesi enu oniroyin àti ẹni aare Tinubu, ko bojumu.”

Nítorí pàtàkì ọrọ naa si ọrọ ajé orilẹ-ede Nàìjíríà àti oun ti ó lè dasilẹ, DUBAWA ṣe ìwádìí ọrọ naa.

Ifidiododomule 

Lakọkọ, DUBAWA ṣakiyesi awọn aiṣedeede kọọkan ninu fónrán ọ̀ún. A tún ríi wípé wọ́n ṣi àwọn ọ̀rọ̀ kan pè, èyí fihàn pé ìmọ ẹ̀rọ Artificial Intelligence ni wọn fi ṣe. 

A ló ẹ̀rọ INVID láti fi ṣe itọpinpin fọ́nrán náà. Ìwádìí wa fihàn pe lóòtọ́, ayédèrú ní fọ́nrán ọ̀ún, wọn kọ̀ gbé ohùn sórí fónrán náà ni, láti fi tan àwọn ènìyàn jẹ, kí wọn le rò bóyá ààrẹ Tinubu lo sọ ọrọ naa. 

Itọpinpin àwòrán lateyinwa ṣafihan ojúlówó fónrán to ṣafihan ibi ti ààrẹ Tinubu tí ń sọrọ ni àpéjọ kan ní ọdún 2022 ti o ti kéde èròngbà rè lati dije fún ipò ààrẹ orilẹ-ede Nàìjíríà. 

Koda, a ṣe ayẹwo ẹrọ alatagba ile-ise ìròyìn Arise News àti ti ààrẹ Tinubu. A ṣ’abapade atẹjade kan láti Arise News lori ìkànnì abeyefo X tó fihàn pé ayédèrú ní fónrán ọ̀ún. 

“Kere o! Arise News ò ni ibasepọ kankan pẹ̀lú fọ́nrán ayédèrú ti àwọn ènìyàn ń pín ká orí ayélujára. Ayédèrú ní fónrán to ṣafihan ibi ti ààrẹ Bola Tinubu ti n kede pe yóó fi owó dọ́là parọ owó Náírà, iṣẹ́ awọn ènìyàn buruku ni,” atejade náà lo sọ èyí. 

Se lóòtọ́ ni ààrẹ Tinubu fẹ́ fi owó dọ́là rọ́pò Náírà? 
Àwòrán atẹjade ilé-isé Arise News lori ìkànnì abeyefo 

A ṣe ìwádìí síwájú sí láti mọ̀ bóyá àwọn ìwé ìròyìn míràn gbé ìròyìn yìí, sùgbọ́n kó sí oun tó jọ bẹẹ. 

Àkótan

Irọ́ àti aṣinilọna ni ọrọ náà. A ṣ’awari ojúlówó fónrán ọ̀ún nipasẹ INVID, a ṣí ríi wípé ile-ise ìròyìn Arise News ti tako ayédèrú fónrán náà. 

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Back to top button
Translate »