|
Getting your Trinity Audio player ready...
|
Ní ìgbà tí arabinrin Temitope Afolabi rii wípé ọkọ rẹ̀ le ṣ’ẹwọn lórí gbèsè miliọnu mejidinlaadọta náírà, ni o ba se iṣẹ́ alagbabi fún ìdílé kan, ki o le ran ọkọ rẹ̀ lọ́wọ̀. L’àkọ́kọ́, arabinrin yii fe ta kindinrin rẹ̀ kan sugbon kò ri ẹni to ma taa fun, lo fi gba iṣẹ́ alagbabi. Surrogacy jẹ ona kan ti eniyan le gba bimọ, sugbon ọ̀tọ̀ ni ẹni ti o ma ba gbe oyún. Ni ọpọ ìgbà, wọn a san owó fun alagbabi ni.
L’agbaye, iṣẹ́ alagbabi nlọ si iwọn bilionu metadinlogbon owo dola, biotilẹjẹpe àjọ àgbáyé (UN) ka ise alagbabi kun ìwà ipá lòdì si ẹ̀tọ́ obinrin. Ṣùgbọ́n, ní orileede Naijiria, ise alagbabi ti bẹrẹ sii lokiki, paapaa leyin ti awọn gbajúmọ̀ bíi Nancy Umeh, Ini Edo ati Chimamanda Adichie lo alagbabi fi bi awon omo won. Kódà, gbajumọ Ife Agoro sọ laipẹ yii pe oun yoo lo alagbabi biotilejepe oun ko ni ailera kankan.
Sugbon, kini iriri àwọn alagbabi ni orileede Naijiria, ati wipe bawo gaan ni iṣẹ́ alagbabi se lokiki bayi? Mo ba Temitope soro nigba ti o wa ninu ipo iloyun, titi ti o fi bimo lorí ikanni ibaraenisore Facebook, nibi ti o ti bami sọ iriri re leyin ti a si lade loju koju.
Temitope gba iṣẹ́ alagbabi ni osu karun odun 2024, wọn fun ni owo ni ilopo milionu meji o le ọ̀kẹ́ mẹwa fun owó ọkọ̀, ibugbe, ibimọ ati owó aṣọ.

Ṣugbọn, owo ti won san fun Temitope ko ka nkan nkan paapaa pelu ipo oro aje orileede yi. Egberun meta naira ni owo ti won yasoto fun owo oko lojumo sugbon owo naa ko to nitori ibugbe Temitope wa ni Sango Ota ni ipinle Ogun, ile iwosan ti o ti n gba itoju wa ni ilu Ikorodu ni ipinle Eko.
Leyin atotonu Temitope lori owó ọkọ̀, won ba fikun owo naa, si egberun naira, ati wipe ile iwosan ti o wa ni Ikeja ni won ni ki o ma lo. Pelu omije loju, Temitope ṣ’alaye pe oun a fi egberun kan kun owo naa ni gbogbo igba ti o ba n lo ile iwosan nitori owo oko kiito. Leyin o reyin, gbogbo owo ti won san fun Temitope ò to lati bọ awon omo tabi san owo ile tabi owo ẹ̀kọ́ awon omo to bi sile.
Temitope tunbo salaye pe aṣojú ile-ise alagbabi gba egberun lona irinwo lowo awon ti won ba gbe oyun, leyin to parọ pe ọkọ aladani Uber ni alaboyun gbe lọ ile iwosan ni gbogbo igba.
“Àwọn ọmọ Naijiria a maa lo ori eeyan,” Temitope lo sọ eyi pelu ibinu ninu ohun rẹ̀. “Wọn a ma rẹ eeyan jẹ nitori ajalu ati isoro ti eeyan n la kọja. Wọn o kin wo idamu oyun, eeyan a ma bi, ara riro ati beebeelo. Wọn kọ lo wa bii eru ni, nitori wọn mọ pe ti iwọ ba loo se, elomii a ṣe.”
Biotilejepe wọn menuba iye ti Temitope a gba leyin ti o ba bimo tan, won ko salaye oro naa fun daadaa. O buwo lu iwe ni ojo kerindinlogbon osu kejo odun 2024 leyin ti o ti loyun fun osu meta. Ninu iwe naa, wọn kọ sibẹ pe o le pakoda.
Iroyin BBC kan ṣ’alaye pe ẹmi alaboyun ati omo inu wa ni ewu julọ ni orileede Naijiria, koda iwadii fihan pe emi le bọ lara alaboyun lasiko ibimo ni Naijiria saaju awon orileede miran.
Surrogacy Agreement by Temitope AfolabiNi ipò ìlóyún gẹ́gẹ́ bi alagbabi, Temitope o le jade kuro nile, ko le je awon ounje kookan fun ose meji bii ọsàn, ọ̀pẹ-oyinbo, oti elerindodo, ati awon ounje miran. Koda, won palase fun pe o gbodo se ibewo si ile ise alagbabi loorekoore biotilejepe ko wuun, tabi ti omo re gan ba ṣ’aisan.
Leyin ti Temitope bimọ ni ojo kerinlelogun osu keji odun 2025, o bere sii ni awon ailera kan ti ko ni tele. O bere sii se nkan osu leemeta losu, o ni oyun iju, ati awon idojuko ile omo rẹ̀.
“Inu mi ko dun, wọn rẹ mi jẹ, mo da bi omugọ,” arabinrin Temitope ló sọ èyí, ó sì kabamọ pe òun gba iṣẹ́ alagbabi. “Leyin gbogbo ẹ, ọkọ mi pada ṣ’ẹwọn ni ọjọ kejidinlogun osu kejila ọdun 2024.”
Alagbabi miran ti mo ba s’ọrọ salaye pe oun naa ni isoro ati ailera leyin ti o bi ọmọ tan. Arabinrin yii, ọmọ ile Eko giga ti ilu Bini ko fi oruko re sile, o bi ìbejì fun idile kan. O so fun mi pe ilaji owo ti won san fun òun gege bi alagbabi ni oun naa lori aisan to kọlù òun leyin ibimọ.
Dokita Sunday Olanrewaju, eni ti o je alakoso Mother and Child Hospital salaye pe oyun ibeji mu ewu dani lopolopo.

Ó sọ wipe, bi ọmọ ṣe pọ ninu si, ni ewu ṣe pọ̀si fun alaboyun, obinrin naa wa ni ewu ifunpa giga, iku, ati ki o padanu ẹ̀jẹ̀. Awon oniwadii fidiremulẹ pe ti obinrin ba gbe ọlẹ inu ti kii se tirẹ̀, o wa ni ewu ailera bii ẹ̀jẹ̀ riru asiko iloyun ati beebeelo.
“Ọrọ yii kò ye awon omo Naijiria,” Temitope ṣ’alaye pe òun gbiyanju lati ta awon eeyan lolobo nipa iriri alagbabi lori ẹrọ alatagba. “Àwọn eeyan sọ wipe a f’ọwọ́si. Ti ki ba ṣe isoro ailowo lọwọ, eeyan wo lo ma fọwọsi iru nkan bẹ́ẹ̀? Ko si eeyan to le gbeja wa,” arabinrin Temitope lo sọ eyi.
Ipa ti Meta kó lati p’okiki iṣẹ́ alagbabi ni orileede Naijiria
Awon alagbabi ti mo ba s’ọrọ sọ wipe awon wa lori awon egbe kan ni ikanni ibaraenisore Facebook ti oruko re je: Egg donor and surrogate mother in Nigeria. Wọn ṣ’idasilẹ ẹgbẹ́ naa ni ojo karun osu kini odun 2023, pelu ọmọ egbe egberun marun o din ni igba.

Lojoojumọ ni wọn maa n fi ipolowo iṣẹ́ alagbabi si ori ikanni naa.

Ileeṣe Meta jẹ alakoso ikanni Facebook, Instagram pelu WhatsApp. Ileese naa ni oun ni ojuṣe lati daabobo awon eniyan ki won wa nj ailewu. Ilana rẹ̀ kan to n bojuto ipolongo lori ikanni Facebook gbegi dina awon ìṣe to n rẹ’yan jẹ bii ki won maa ta omode ati iyanjẹ lenu iṣẹ́.
Mo kọwe ranṣẹ si Meta, ibeere mi si ni lati fidiremule boya ileese naa ka iṣẹ alagbabi si irenijẹ, ti o ba si ri bẹ, kilode ti awon egbe kookan wa lori ikanni Facebook ti won polowo ise alagbabi si awon obinrin bii Temitope. Lẹyin ti ileese Meta yọ awon ẹgbẹ naa kúrò, o fesi pe,
“Awon ipolongo ati egbe ti o n se iyanje eniyan boya nipa tita ọmọ tabi alagbatọ ọmọ l’ona aitọ, wọn ru òfin ati ilana wa, o si se pataki si wa ki a yọ won kuro bi a ti ṣe bayi.”

Ṣugbọn, Olivia Maurel, ẹni ti o jẹ agbẹnusọ Casablanca Declaration, ajọ to n ja fun opin ise alagbabi lagbaye, gba imoran pe dipo ki ikanni Facebook se iyokuro awon egbe alagbabi ni Naijiria, ise si po lati se, ki won gbegidina ipolongo ise alagbabi ni gbogbo agbegbe ni Naijiria.
Iroyin ofege gbode kan
Yatọ si iha ti Meta kọ si iyanjẹ, ileese naa ko faye gba iroyin ofege lori awon ikanni rẹ̀. Sibẹ̀, irọ́ lo poju ninu oun ti àwọn aṣojú ileese alagbabi maa n sọ fun awon obinrin ti o ma n ba eeyan gbe oyún, paapaa ninu itakuroso won lori ikanni Whatsapp. Won a ma fi itanje mu ki awon obinrin naa se adehun pelu ileese won.
Mo ni iriri pelu Omobolanle Oguntolu, eni ti o je asoju ileese alagbabi kan. Mo ṣ’abapade ipolongo ise alagbabi re ninu egbe kan lori ikanni ibaraenisore, Surrogate Mothers Nigeria. Arabinrin Omobolanle fi nọmba ipe re sòrí ipolongo naa, mo si ba sọrọ.

Nigba ti mo ba Omobolanle s’ọ̀rọ̀ lori WhatsApp, o salaye fun mi pe oun ti ran obinrin marundilogoji lọwọ lati se iṣẹ́ alagbabi. O si f’ikun wipe wọn a san milionu meji naira ó lé díẹ̀ fun mi.

Mo gbiyanju lati ba s’ọrọ ki o fikun owo naa, sugbon ko gbọ tẹ̀mi. Aṣoju ileese alagbabi kan, arabinrin Sophia kilọ fun mi pe kò si iyipada kankan ti mo le ṣe leyin ti mo ba tọwọ bọ’we.
Mo sọ fun Omobolanle pe igba àkọ́kọ́ ti mo ma gba iṣẹ́ alagbabi re, pe ki o sọ gbogbo oun ti mo ni lati mọ̀ fun mi. O ṣ’alaye pe lẹyin owó ti wọn ma fun mi, kò si anfaani pupọ nibẹ fun mi.
“Ìgbà àkọ́kọ̀ ti o ma ṣe re, o da ki o mọ oun ti o fe kese bọ,” arabinrin yii lo sọ bayi.
Ṣugbọn nigba ti mo bere ile iwosan ti mo ma lo fun itọju, arabinrin yii sọ fun mi pe oun kò ni sọ afi ti mo ba fẹ lọ bẹ̀. Ó ṣe mi ni kayefi, mo tunbọ bere bi mo se le ṣ’iwadii nipa ile iwosan naa, ṣugbọn o ni kò ṣ’eeṣe. Mo bere pe ti nkan ba ṣ’ẹlẹ si mi ninu oyun tabi ti mo ba ku ninu oyun, iyaẹnu lo jẹ fun mi nigba ti o so fun mi pe kò si nkan to ma ṣe mi.”
Jumoke Falade, nọọsi to n ṣiṣẹ ni ile ìwòsan ikọni ti yunifasiti ìpínlè Eko sọ pe o ya oun lẹnu pe enikan le sọ pe iṣẹ́ alagbabi ò lewu, o f’ikun pe opolopo ewu lo mu dani bii iku.
Omobolanle sọ fun mi pe ti mo ba fe ṣe iṣẹ́ alagbabi, iṣẹ́ abẹ ni a fi bimọ nitori kò mu ewu dani. Ṣugbọn dọkita Olanrewaju ti o jẹ dọkita obinrin ni Mother and Child Hospital sọ pe bibi ọmọ lati ojú ara lo dara ju nitori o yára, ati wipe ara obinrin a tete da ṣáká l’asiko.
Oniṣegun naa f’ikun pe iṣẹ́ alagbabi kò niiṣe pelu ilé ọmọ lasan.
“Ẹ̀dọ̀fóró alaboyun ni ọmọ inu a ma fi mi. Ẹ̀jẹ̀ aláboyún ni a maa kaakiri ara ọmọ, eroja ti obinrin ba ri l’ara ounjẹ ni a maa ṣe ara ọmọ naa loore,” dokita lo sọ bẹ.
Omobolanle sọ fun mi wipe òfin Naijiria ṣ’atilẹyin iṣowo iṣẹ alagbabi, nitori naa ni àwọn obinrin ṣe n ṣe.
Ṣugbọn, amofin Marvellous Igbineweka tako ọrọ naa pe ofin to n risi ilera ti odun 2014 gbe ilana kalẹ pe iṣowo iṣẹ́ alagbabi ru ofin. Ofin naa ko fi aaye gba ki eeyan fi eya ara re tọrọ, tabi ki wọn ta fun elomiran. Amofin naa fikun pe òfin ẹ̀tọ́ àwọn èwe ti ọdún 2003, ipin ketala ti òfin to n gbogun ti kiko àwọn eniyan lọ s’oko ẹrú ati ofin to n ṣ’akoso ìṣe iṣegun oyinbo, ṣ’agbekale àìb’òfinmu iṣẹ́ alagbabi.
Agbejọro miran, Dogo Joy Njeb sọ pe oun ti wọn kò f’ofin de, ko tapa s’ofin. O f’ikun wipe orilede Naijiria maa n fi aaye gba ibasepọ ki wọn si tọwọ bọ’we, o si seese ki ise alagbabi wa lara eyi.
Nigba ti mo bere lowo Omobolanle idi ti nkò le ri alaye nipa ileese alagbabi lori ero ayelujara, Regal Surrogate Services, ó sọ fun mi pe oruko ti oun maa n pe ileese oun niyen.
Ìjọba Nàìjìríà faramọ
Ileese alagbabi ti Omobolanle ‘dasilẹ ko ni iforukosile l’ọdọ ijọba, biotilẹjẹpe ko si òfin kankan to fofin de lati ṣe iforukosilẹ. Òfin orileede Naijiria kò mẹ́nuba nkankan to niise pelu iṣẹ́ alagbabi, nitori naa, ariyanjiyan n lọ lori oro naa. Awon kan ninu ile igbimọ aṣofin gb’iyanju lati f’òfin de iṣẹ̀ alagbabi sugbon wọn kò ri ṣe. Igbiyanju ti wọn ṣe ni ọdún 2012 àti 2016 ja si pabo nítorí àwọn ọmọ ile igbimo aṣofin yooku kò fọwọsi.
Mo kàn si Christiana Eguma, ẹni ti o jẹ olori eka to n risi ọrọ akọ ati abo (Gender Technical Unit) ni ile igbimo asofin agba, nipa ikunna Naijiria lori ise alagbabi. Christiana tun jẹ alabojuto igbimọ kan to n risi ẹ̀tọ́ awon obinrin. Arabinrin Christiana ṣ’alaye pe eka naa a da si oro naa nipase gbigbe awon ilana kookan kale lori ewu ilera to wa ninu ise alagbabi.
Asofin Olamijuwonlo Alao-Akala to n ṣ’oju ẹkun gusu Ogbomosho, ariwa ati Oriire gbiyanju lati ṣ’agbekalẹ òfin to bojuto iṣẹ́ alagbabi ni orileede Naijiria. Ofin naa a bojuto iforukosile ileese alagbabi. Ofin naa a tun gbegidina iṣowo iṣẹ alagbabi. Eyi tunmọ si pe wọn kò ni san owó fun alagbabi.
Honorebu Olamijuwonlo sọ pe òfin naa, “a bojuto ise alagbabi ni orileede Naijiria, a si rii wipe awon eniyan o ni ru ofin ilera.”
Bakan naa, Honorebu Uchenna Okonkwo, aṣoju ekun gusu ati ariwa Idemili ti ipinle Anambra naa ti gbiyanju lati fi ofin silẹ lati dabobo ẹ̀tọ́ àwọn obinrin paapaa nipa ọrọ alagbabi ati awon nkan miran. Yoo tun f’ofin de iṣowo iṣẹ́ alagbabi sugbon obinrin ti o ba fe ṣe alagbabi lati ṣe iranwọ fun idile miran le ṣe lai gba owó.
Ṣugbọn arabinrin Olivia, ti wọn bi nipasẹ alagbabi, sọ pe oun kò faramọ́ irufe ofin bẹ́ẹ̀.
“Ko si iyato kankan laarin fífi iṣẹ́ alagbabi se iṣowo ati awọn t’onṣe l’ọfẹ. Oun kanna ni mejeeji: wọn a lo ara obinrin lati fi bi ọmọ fun elomii lai naani oun ti yoo ṣẹlẹ si ilera, alaafia ati iyì obinrin naa.”
Àjọ agbaye gba àwọn orileede agbaye ni iyanju pe ki wọn f’opin si iṣẹ́ alagbabi ni gbogbo ọna, ki wọn f’ofin de àwọn ile-ise alagbabi ati aṣoju wọn, fa’gile iwe adehun alagbabi ati ile-ise alagbabi, ki alagbabi si jẹ iya ọmọ to gbe s’inú, ni ibamu pelu ofin.
Mo kan si honorebu Olamijuwonlo lori ikanni abeyefo (X), WhatsApp, mo si kọ’we ransi lori imeeli sugbon kò fesi. Bakan naa, mo gbiyanju lati ba honorebu Uchenna Okonkwo s’ọrọ sugbon ko ṣeeṣe.
Olivia kilọ pe, “Tí orileede Naijiria ò ba tete wa nkan ṣe si ọrọ naa, o seese ki ilu naa di ibi ti awon eniyan lagbaye a bere si wa obinrin fun ise alagbabi, won a ma lo ara obinrin bii oun elo ati bimo, ọmọ a si di oun katakara.”
Ipadasẹyin
Ailera n ba Temitope finra lọwọ bayi leyin to gba iṣẹ́ alagbabi, owó ti wọn san fun ni ilọpo milionu kan o le ẹgbẹrun oodunrun tan laarin oṣù mẹ́ta.
O fi owó naa jẹ’un, san owó ileewe ọmọ merin to bi sílẹ̀ ati pe o fi owo ranṣẹ si ọkọ rẹ̀ to wa l’ẹwọn, o si san gbèsè.

Ni bayi, owo ise alagbabi ti tan, Temitope si pada si kara kata ponmo, pelu ireti pe a le ri owó ti a fi tọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀.
Ọ̀rọ̀ olótùú: A ṣ’ẹda akosile yii ni èdè gẹẹsi, a si tunmo re si Hausa. DUBAWA túnbọ̀ ṣe igbasilẹ fonran yii.




