Getting your Trinity Audio player ready...
|
Àhesọ: Aṣàmúlò Instagram kan, Dókítà Daryl Gioffre, sọ pé àgbàdo ní àwọn májèlé (aflatoxins) tí ó ń fa àrùn jẹjẹrẹ.
Àbájáde Ìwádìí: Ọ̀rọ̀ pé àgbàdo lè ní àwọn aflatoxins tí ó ń fa àrùn jẹjẹrẹ jẹ́ òtítọ́. Awọ́n onímọ̀ sọ pé èyí máa ń ṣẹlẹ̀ lọ́nà àdánidá, ṣùgbọ́n ìṣàkóso tí kò dára lẹ́yìn ìkórè máa ń mu pọ̀ sí i.
Ìròyìn Lẹ́kùńrẹ́rẹ́
Àgbàdo jẹ́ ìpanu tí ó gbajúmọ̀ láàrin àwọn ọmọ Nàìjíríà. Bóyá wọ́n ṣe é, suún, tàbí yí padà sí ǹkan mìíràn, kò sí ẹ̀yà ọmọ Nàìjíríà tí kìí jẹ àgbàdo.
Ní ọjọ́ kaàrún, oṣù kẹsàn-án, ọdún 2024, aṣàmúlò Instagram kan, Dókítà Daryl Gioffre, gbé fídíò kan jáde, pẹ̀lú àkọlé tó wí’pé “Ọmọ ọdún mélòó ni ọ́ nígbà tí o mọ̀ pé àgbàdo ní àwọn aflatoxins mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n, èyí tí ó jẹ́ fọ́ngọ́sì, tí ó ń fa àrùn jẹjẹrẹ?”
Lọ́jọ́ kẹwàá, oṣù kẹwàá, ọdún 2024, àtẹ̀jíṣẹ́ náà ti gba ìfẹ́ tó lé ní 53,000.
Ọ̀rọ̀ Ọ̀gbẹ́ni Gioffre gbé àwọn àníyàn jáde nípa ewu ìlera tó ṣe é ṣe kí ó wáyé látàrí ohun tí à ń jẹ. DUBAWA pinnu láti ṣe ìwádìí èyí nítorí ààbò ìlera gbogbo ènìyàn.
Ìfìdíòdodomúlẹ̀
Gẹ́gẹ́ bí National Cancer Institute ṣe sọ, “Aflatoxins“ jẹ́ ẹgbẹ́ àwọn májèlé tí kòkòrò máa mú jáde, pàápàá jùlọ “Aspergillus flavus” àti “Aspergillus parasiticus,” tí wọ́n sábà máa ń rí lórí àwọn irúgbìn bíi àgbàdo, ẹ̀pà, irúgbìn òwú (cottonseed), àti èso igi (tree nuts). Gẹ́gẹ́ bí National Cancer Institute ṣe sọ, kòkòrò wọ̀nyí máa ń gbilẹ̀ nínú ojú ọjọ́ tó lọ́ wọ́ọ́rọ́ tí ó sì tutù, ó sì lè ba irúgbìn jẹ́ ní pápá àti nígbà ìkórè àti ìpamọ́.
Àwọn ènìyàn lè fi arawọn sí’jàmbá aflatoxins nípa jíjẹ àwọn oúnjẹ tí a mú lát’ara ohun ọ̀gbìn tàbí ẹranko bíi ẹran, wàrà, tó ní májèlé yìí. Àwọn òṣìṣẹ́ oko náà lè wà nínú ewu nípa mímí eruku tí wọ́n ṣẹ̀dá nígbà ìṣàkóso àti ṣíṣe àwọn irúgbìn wọ̀nyí.
Fífi ara hàn sí aflatoxins fún ìgbà pípẹ́ léwu púpọ̀ fún ìlera. Gẹ́gẹ́ bí Biomedcentral ṣe sọ, Aflatoxin B1 ló léwu jùlọ nínú àwọn aflatoxins. Ó jẹ́ àrùn jẹjẹrẹ tó ga àti pé wọ́n ti so mọ́ àrùn jẹjẹrẹ hepatocellular, irúfẹ́ àrùn jẹjẹrẹ ẹ̀dọ̀. Ipa àrùn jẹjẹrẹ ti aflatoxins, pàápàá jùlọ AFB1, túbọ̀ ń pọ̀ sí i nínú àwọn ènìyàn tí wọ́n ní àrùn jẹjẹrẹ B (HBV). Bákannáà, Aflatoxins náà ti ní ìbámu pẹ̀lú irúfẹ́ àrùn jẹjẹrẹ àti ìbàjẹ́ ẹ̀yà ara mìíràn, pàápàá jùlọ sí ẹ̀dọ̀ àti kídìnrín.
Ní àfikún sí àwọn ipa carcinogenic wọn, aflatoxins wà “mutagenic,” èyí tí ó túmọ̀ sí pé wọ́n lè yí DNA padà, wọ́n sì jẹ́ genotoxic, èyí tí ó lè fa àbùkù ìbí, gẹ́gẹ́ bí Ambiotec Solutions ṣe ṣàkíyèsí. Wọ́n tún ṣe ìdíwọ́ fún ètò àjẹsára, tí yóò jẹ́ kí àwọn ènìyàn túbọ̀ ní àrùn bíi HIV tàbí àrùn jẹjẹrẹ. Ó túlè yọrí sí ìdènà àjẹsára, tí ó ń bá’ra gbógun ti àrùn. Aflatoxins lè fa aflatoxicosis, èyí sì leè ba ẹ̀dọ̀ jẹ́.
Àjọ Ìlera Àgbáyé (WHO) ròyìn pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwọ̀n aflatoxins lè yọrí sí ikú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, nígbà tí ìfarahàn ọjọ́ pípẹ́ sí ìwọ̀n kékeré lè yọrí sí àìlera ètò àjẹsára tàbí àwọn àléébù oúnjẹ.
Ní ṣókí, àwọn aflatoxins jẹ́ májèlé tó lágbára tí ó ń fa oríṣi ewu ìlera, láti àrùn jẹjẹrẹ ẹ̀dọ̀ títí dé ìdènà àjẹsára. Májèlé yìí sì nílò ìṣàkóso ìṣọ́ra láti dín ìfihàn àwọn ènìyàn kù.
Àwọn Ọ̀jọ̀gbọ́n Sọ̀rọ
Onímọ̀ nípa oúnjẹ, Emmanuel Oyebamiji ti Yunifásítì Kwazulu-Natal, South Africa, fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn aflatoxins wà nínú àgbàdo. Ó tẹnumọ́ ewu ìlera tí ó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ìṣe tí kò dára lẹ́yìn ìkórè. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun kò lè fìdí ìpele aflatoxin gangan múlẹ̀ nínú àgbàdo, Ọ̀gbẹ́ni Oyebamiji ṣàkíyèsí pé àgbàdo sábà máa ń ní ẹ̀yà tí kò kéré sí ogún fún bílíọ́nù kan (ppb) májèlé ohun (20 parts per billion).
Ọ̀gbẹ́ni Oyebamiji sọ pé àwọn ìlànà ìmọ́tótó tí kò dára nígbà ìkórè àti lẹ́yìn ìkórè ló má ń sábà dákún aflatoxins.
Ọ̀gbẹ́ni Oyebamiji ṣàlàyé pé, ”O máa ń ṣẹlẹ̀ lọ́nà àdánidá, ṣùgbọ́n ìṣàkóso tí kò dára máa ń mú kí ìṣòro náà burú sí i.
Ó yẹ ká’wọn àgbẹ̀ o ríi dájú pé wọ́n kórè àgbàdo nígbà tó bá tútù ní ìpele 20% sí 30%. Èyí yóò dèna aflatoxin láti dàgbà.“
Ó tún kìlọ̀ pé tí ènìyàn bá fi omí gbígbóná se àgbàdo tàbí kí ènìyàn suún, èyí kò tó láti pa aflatoxins.
“Díẹ̀ nínú àwọn ènìyàn gbàgbọ́ pé sísè àgbàdo lè dí awọn ipele aflatoxin kù, ṣùgbọ́n kòrí bẹ́ẹ̀. Aflatoxin jẹ́ ohun ewu tí a mọ̀ fún àrùn jẹjẹrẹ.”
Láti dènà rẹ̀, ó wípé àwọn ènìyàn ní láti ṣe ìmọ́tótó fún àwọn fún àwọn irinṣẹ́ oko àti ilé ìkóóújẹpamọ́sí.
“Ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ ni ṣíṣe ìmọ́tótó awọn irinṣẹ́ ìkórè láti fọ eruku, ìdọ̀tí tàbí ohun àjèjì tó lé ṣe ìjàmbá kúrò. Àwọn àgbẹ̀ gbọ́dọ̀ rí i dájú pé wọ́n tún àwọn àpótí ìpamọ́ ṣe láti dènà ìjì ọ̀rinrin àti láti lo àwọn oògùn ìpakòkòrò sí láti tọ́jú àwọn agbègbè ìpamọ́.”
Dókítà ìṣègùn, Omobolanle Braihmoh, ṣe àfihàn ewu jíjẹ oúnjẹ pẹ̀lú ẹ̀yà mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n fún bílíọ̀nù kan àwọn májèlé tí ó léwu. Ó tẹnumọ́ pé jíjẹ oúnjẹ tí ó yẹ ká sè ní tútù le yọrí sí ìṣòro ìlera.
“Kò yẹ ká máa jẹ oúnjẹ tó yẹ fún sísè ní tútù. Díẹ̀ nínú àwọn àgbẹ̀ jiyàn pé jíjẹ oúnjẹ tí a kò sè máa ń ṣètọ́jú àwọn èròjà aṣara lóre sii. Ṣugbọn, ewu àkóràn fungal máa ń pe sí nígbàtí a kò bá se àwọn oúnjẹ tó yẹ fún sísè.”
Àkótán
Ọ̀rọ̀ pé àgbàdo lè ní àwọn aflatoxins tí ó ń fa àrùn Aflatoxins, èyí tí kòkòrò ń ṣe, ń fa ewu ìlera tó lágbára, pẹ̀lú àrùn jẹjẹrẹ ẹ̀dọ̀, ìdènà àjẹsára, àti ikú pàápàá. Ìṣàkóso tí kò dára lẹ́yìn ìkórè máa ń sábà mú ọ síi.
Juliet Buna ló kọ́kọ́ ṣ’àkọsílẹ ìwádìí yìí lé’dè gẹ̀ẹ́sì, tí Sunday Awóṣòro sì túmọ̀ rẹ̀ sí ède Yorùbá.