Aheso: Òwú lórí tàbí l’àwùjẹ̀ ọmọdé lè dekun èsúkè.
Àbájáde ìwádìí: Irọ́ ni ọ̀rọ̀ yíí.
Botilẹjẹ pé ọrisisiri ọ̀nà ni a lè gbà dẹ́kun èsúkè, fifi òwú sí orí ọmọdé tàbí orí ẹnikẹni kìí dẹkun èsúkè.
Ìròyìn ni kikun
Èsúkè, tí ó jẹ́ sisunki iṣan-agbede eniyan (diaphragm) lè ṣẹlẹ̀ lẹyìn tí ènìyàn bá ti jẹ oúnjẹ púpọ̀, mu ọtí elerindodo tàbí tí eniyan bá dunnú lójijì.
Gbogbo ènìyàn tó wà lorilẹ ayé yìí lo ti se èsúkè ni ìgbà kan tabi òmíràn; fún ọpọlọpọ ènìyàn, èsúkè kìí ju iṣẹju díẹ̀ lọ.
Laipẹ yii, olùmúlò kàn nì Facebook ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Esther Mark, dá àbá pé okùn òwú ni orí ènìyàn le f’opin sí èsúkè.
“Mo fi ọwọ́ sí orí mi, kíni mo bá níbẹ̀? Mo rí okùn òwú kàn ti yóò bá mi fi òpin sí èsúkè náà,” olumulo yìí kọ eyi sí ojú òpó rè.
Ọpọlọpọ ènìyàn ni Nàìjíríà àti ní ilẹ Áfríkà ló ní igbàgbó nínú ìṣe yìí. Ní ayé òde òni, ọpọlọpọ ènìyàn ṣi gbàgbọ́ nínú fífi òwú dẹkun èsúkè gẹgẹbi àbájáde ìwádìí kan ti a ṣe lori ìkànnì abẹ́yẹfò, Twitter.
Ìpín metalelogoji (43%) àwọn eniyan tó dahun sí ìwádìí náà ló gbàgbó pé òwu lé fi òpin sí èsúkè, mejidinlogoji (38%) ò gbagbọ, mokandinlogun ò ni nkan ti won fẹ sọ nípa rẹ.
O fẹẹ dàbí pé ìgbàgbọ yii lo jẹ ki ọkọ arabinrin olùmúlò ojú òpó Facebook yìí fi okùn òwu lee lori ni ìgbà ti o n ṣe èsúkè. Sugbon, se àrídájú n bẹ pe òwú ni nkan ṣe pẹlu èsúkè? A ríi wípé ìgbàgbọ yii wọpọ laarin ọpọlọpọ ènìyàn, eyi lo je ká ṣe ìwádìí wà láti fi ìdí òdodo múlẹ̀.
Itopinpin otito
Awọn onimọ nípa oògùn òyìnbó máa n pé èsúkè ni ‘singultus’ ati wípé ìhùwàsí wa bi ki ènìyàn má jẹun púpọ̀ lójú kanna tàbí kí ènìyàn jẹun kiakia, ki ènìyàn máa mu ọtí elerindodo, ounjẹ alata, ki ènìyàn máa ṣe wahala lọpọlọpọ, tabi ki ènìyàn máa dunu lojiji, mímú oti lile, tàbí ki iyatọ dé bá ojú ọjọ ati awọn oun míràn lè fa èsúkè.
A lè dẹkun èsúkè tí a ba ṣe ìyípadà si àwọn ihuwasi ati igbe ayé wa, bíi ki a dẹkun ounjẹ àjẹjù, lọ́ra jẹun, ki a yẹra fún oúnjẹ tó lata púpọ̀, yẹra fún ọtí líle, oti elerindodo, kí a ṣe eré idaraya bíi ki ènìyàn mí kanle ati ki ènìyàn ṣe iṣaro, lati dẹkun wahala.
Ti èsúkè ba bẹrẹ síi mu ìrora wa ti eniyan ò lè jẹun, sùn tàbí mí dáadáa, ó dára ki irufẹ ènìyàn bẹ́ẹ̀ lọ rí dọ́kítà, eyi le jẹ aami àpẹẹrẹ àwọn ààrùn kan bíi ààrùn rọpárọsẹ̀, acid reflux (ki acid ikun ṣàn lati inu pada sinu oesophagus (itọpa ti o so ẹnu pọ mọ ikun), o sì lè fa multiple sclerosis (eyi ni ki òkí ara máa bá ẹ̀ṣọ́ ara jà).
Apileko kan ti Health Line gbejade fihàn pé awọn ọna kan wà ti a le gbà mú ki iṣan-agbede eniyan sinmi. Awọn ọna náà ni kí: a ṣe ìmí; mí sí inú àpò, fa orukun eni móra ati awọn ìgbésẹ míràn. Apileko ti United Kingdom National Health Service fi idi rẹ múlẹ̀.
Àyẹwò fihan pé kí ènìyàn da omi ara (orgasm) ati ki wọn fi ọwọ ra awon eya ara to sunmo nkan ọmọbirin/ọmọkùnrin (rectal massage) lè fi òpin si èsúkè. Ti o ba buru ju, dókítà iru eniyan bẹẹ lè ni kí ó lo ogun (Gablofen), chlorpromazine (Thorazine) ati metoclopramide (Reglan).
Ajọ ti n bojuto ààrùn tí kò wọ́pọ̀ l’awujọ National Organisation for Rare Diseases (NORD), fi ìdí re mu’lẹ̀ pé wọn máa n saba fi oògùn se ìtọjú èsúkè, awọn ògùn wonyi ni chlorpromazine (Thorazine), haloperidol, ati metoclopramide.
Ti èsúkè ba se eniyan l’asiko ti won ṣe iṣẹ abẹ fún onítọ̀ún, awọn dokita máa lo oògùn ephedrine tabi ketamine fún itọju iru eniyan bẹẹ.
Ni igba míràn, dokita le fi alaisan sí ipò aimọkan (hypnosis), lati ṣe itọju tó péye, ni ìgbà míràn, wọn máa fi abẹrẹ sí inú ara eniyan bẹẹ.
Ajọ náà fikun pé ti àwọn ìtọjú wọnyi ba kùnà láti mú ènìyàn lára dà, awọn oniṣẹ òògùn le ṣe isẹ abẹ fún irufẹ eniyan bẹẹ, bíi ki won gún-un ni abẹ́rẹ́ ni inú ẹṣọ ọrùn (phrenic nerve).
Àkótán
Botilẹjẹpe ọpọlọpọ ọna ni a lè gbà dẹkun èsúkè, fífi òwú sí àwùjẹ̀ ọmọde tabi ori ẹnikẹni kii ṣe ikan lara rẹ.
Ni àfikún, àyẹwò àwọn oun tó ń ṣokunfa èsúkè fihàn pé kò sí ìbátan kankan nínú kí ènìyàn fi òwú sí orí ènìyàn ati èsúkè.