Fact CheckHealthYoruba

Ǹjẹ́ jíjẹ ọ̀gẹ̀dẹ̀ alábàwọ́n le ṣokùnfa àrùn jẹjẹrẹ?

Getting your Trinity Audio player ready...

Àhesọ: Aṣàmúlò ìkànnì Facebook sọ wípé jíjẹ ọ̀gẹ̀dẹ̀ òmìnì tàbí àgbagbà èyí tí àwọ rẹ̀ ní àbàwọ́n dúdú le ṣokùnfa ààrùn jẹjẹrẹ. Bákannáà, ó sọ wípé ọ̀gẹ̀dẹ̀ tí a bá fi kẹ́míkà dẹ̀, ló ma ń ní àbàwọ́n dúdú lára.

Ǹjẹ́ jíjẹ ọ̀gẹ̀dẹ̀ alábàwọ́n le ṣokùnfa àrùn jẹjẹrẹ?

Àbájáde Ìwádìí: Dípò fífa àrun jẹjẹrẹ, ní ṣe ni àwọn èròjà aṣara lóore èyí tó wà nínú ọ̀gẹ̀dẹ̀ ma ń gbógun ti ààrùn náà. Ṣùgbọ́n, tí ènìyàn bá jẹ ọ̀gẹ̀dẹ̀ tí a bá fi kẹ́míkà làpọ́n fún ìgbà pípẹ́, ó lè dákún àwọn ǹkan tí ń fa àisàn náà. Nítorí èyí, àhesọ náà ṣini lọ́nà.

Ìròyìn Lẹ́kùńrẹ́rẹ́

Gẹ́gẹ́ bí àjọ elétò ìlera àgbáyé “WHO” ṣe sọ, ààrùn jẹjẹrẹ ló ń ṣokùnfa ikú ènìyàn kan nínú ènìyàn mẹ́fà lágbayé. Lẹyìn jẹjẹrẹ, àwọn ààrùn ọkàn ló tún máa n saba fa ikú ènìyàn kan nínú ènìyàn mẹ́rin lágbayé. Orílẹ̀-èdè Nàìjíría wà lára àwọn orílẹ̀-èdè Áfríkà èyí tí ààrùn jẹjẹrẹ ti wọpọ. Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí àti àkọsílẹ̀ àjọ National Cancer Control Plan, ènìyan 102,000 ló ma ń ní àìsàn yìí, tí 72,000 sì lugbadi ikú lọ́dọọdún.

Eastern Pride, aṣàmúlò ẹ̀rọ ibaraẹnisọrẹ Facebook ṣ’atunpín fọ́nrán kàn, èyí tí ẹni tó ń sọ̀rọ̀ nínú rẹ̀ wípé jíjẹ ọ̀gẹ̀dẹ̀ tí àbàwọ́n dúdú bá wà lára rẹ̀ le ṣokùnfa orísirísi jẹjẹrẹ.

Ó sọ wípé, “ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ló ní ààrùn jẹjẹrẹ. Jẹjẹrẹ ọyàn, jẹjẹrẹ egungun, jẹjẹrẹ ẹdọfóró àti bẹẹbẹẹlọ nítorí ǹkan tí à ń jẹ. Tí ẹ̀ bá rí irú àwọn ọ̀gẹ̀dẹ̀ wọ̀nyí lọ́jà, ẹ má ṣe ràá torí ó lè fa àìsàn lọ́jọ́ iwájú.”

Ó tẹ̀síwájú, ó kìlọ̀ fún àwọn olùwòrán rẹ̀ lati dẹkùn rírà ọ̀gẹ̀dẹ̀ t’óbá ti ní àbàwọ́n dúdú lára nítorí wípẹ́ kẹ́míkà olóró ni wọ́n fi jẹ́ kó pọ́n. Ni ojo kokanlelogun oṣù kiní ọdún 2024, àwọn 251 ti wo fọ́nrán ọ̀ún, bẹ́ẹ̀sìni àwọn méjìlélógún ti sọ̀rọ̀ lórí rẹ̀.

Títóbi àhesọ yìí àti pàtàkì ètò ìlera l’órílẹ̀dè Naijiria ló mú DUBAWA ṣe ìwádìí yìí.

Oun tí ìwádìí sọ nípa ààrùn jẹjẹrẹ 

Onímọ̀ ìlera lórí oúnjẹ, Alyssa Tatum ṣ’àwárí pé àwọn oúnjẹ tàbí oun mímu tí a fi kẹ́míkà múdùn wà lára oun tó lè ṣokùnfa àìsan jẹjẹrẹ. Àmọ́, ó túnbọ̀ sàlàyé síwájú si pé wọn kò lè jẹ́ àṣokùnfà àyàfi tí ènìyàn kò bá jẹ tàbí mu wọ́n ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì.

“Kò túmọ̀ sí pé tí ó bá jẹ ẹran sísun lọ́sẹ̀ tó kọjá, o ó wàá ní ààrùn jẹjẹrẹ lóní o. Kò kí ma ń ṣẹlẹ̀ lẹ́ẹ̀kan àyàfi tí a bá ń ṣe èyí fún ìgbà pípẹ́ ni. Nítorí náà, máa jẹ wọ́n ní’wọ̀ntúnwọ̀nsì,” onimọ náà ló sọ èyí.

Yàtọ̀ sí ẹran, oúnjẹ ifunwara lè dákun pẹlú. Àwọn ọ̀nà tí à ń gbà pèse oúnjẹ wọ̀nyí lè fa kòkòrò ti awọn oloyinbo n pé ni “carcinogens” tó ma ń fa ààrùn jẹjẹrẹ sínú ara.

Bákanáà, ǹkan tí àwọn dọ́kítà mọ̀ sí “oxidative stress” (wàhálà) ọlọ́jọ́pípẹ́ wà lára àṣokùnfà ààrùn yìí. Àwọn èso tó kún fún “anti-oxidant” ni àwọn onímọ̀ ìlera sọ pé kí àwọn ènìyàn ma jẹ. Ọ̀gẹ̀dẹ̀ ọ̀mìnì àti àgbagbà wà lára eso tó ní èròjà “magnesium” àti ajira vitamin E, tó ń báni gbógun ti “oxidative stress.” Àbàwọ́n dúdú tí a rí lára ọ̀gẹ̀dẹ túmọ̀ sí wípé ó ti pọ́n jù. Tí ọ̀gẹ̀dẹ̀ bá sì ti pọ́n jù, ó ma ń ní àwọn “antioxidant” ati “trytophan” tí ń dènà àrun jẹjẹrẹ.

Ọ̀gẹ̀dẹ̀ afi-kẹ́míkà dẹ̀

Àríyànjiyàn nípa bí a ṣe le mọ ọ̀gẹ̀dẹ̀ tí a bá fi kẹ́míkà bíi kábádì dẹ̀, ti wà fún ọjọ́ pípẹ́. Bí ẹni tó ṣe àhesọ yìí ṣe wípé a lè dá ọ̀gẹ̀dẹ̀ wọ̀nyí mọ̀ nípa àbàwọ́n dúdú ara wọn, àwọn míràn wípé tí ìdí ọ̀gẹ̀dẹ̀ bá ní àwọ̀ ewé lẹyìn tó ti pọ́n, èyí túmò sí wípé kẹ́míkà ni wọ́n fi jẹ́ kó rọ̀.

Sùgbọ́n, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwádìí ti ṣe àrídájú wípé a kò lè dá ọ̀gẹ̀dẹ̀ tí wọ́n fi kẹ́míkà dẹ̀ mọ̀ nípa àwọ̀ ara rẹ̀. Àwọn olùwádìí bíi FullFact, USA Today, Reuters àti AFP Factcheck náà jẹrìí sí.

Èrò amòye 

DUBAWA kàn sí Temilade Omotosho, akàwégboyè lórí ìmọ oúnjẹ jíjẹ. A bá sọ̀rọ̀ lórí àhesọ tó wípé ọ̀gẹ̀dẹ̀ àpọ́njù lè fa àisàn jẹjẹrẹ. Arábìnrin Omotosho sọ pé yálà fífa ààrùn, ọ̀gẹ̀dẹ̀ tó bá pọ́njù ní àwọn èròjà aṣaralóore. Ó sọ pé “bí ọ̀gẹ̀dẹ̀ náà bá ṣe pọ́n tó ní ṣúgà ara rẹ̀ pọ̀ si. Síbẹ̀síbẹ̀, jẹjẹrẹ lè wáyé tí ènìyàn bá ti ni lára tẹ́lẹ̀.”

Bákannáà, amòye yìí wípé tí a bá lo fataláísà tàbí kẹ́míkà láti fi mú ọ̀gẹ̀dẹ̀ pọ́n, èyí lè yọrí sí àìsàn náà. 

Tessy Ahmadu, onímọ̀ ìṣègùn ààrùn jẹjẹrẹ ni ilé-ìwòsàn Federal Medical Centre ni Jabi, náà kó àhesọ yìí dànù. O wípé, “nítorí pé sẹẹlì jẹjẹrẹ ma ń jẹ gúlúkósì lára, àti wípé, gúlúkósì ara ọ̀gẹ̀dẹ̀ ma ń pọ̀ tó bá ti pọ́n, làwọn ènìyàn fi rò pé ọ̀gẹ̀dẹ̀ le ṣokùnfà àrun jẹjẹrẹ.”

Arábìnrin Ahmadu wípé irọ́ lèyí. Ó sàlàyé àwọn ànfààní jíjẹ ọ̀gẹ̀dẹ̀. “Wọ́n kún fún pòtásíọ́mù àti ohun aṣara lóore bíi maginésíọ́mù. Wọ́n kún fún gúlúkósì tí ó jé kí àwọn ènìyàn rò pe ó mú kí ọ̀gẹ̀dẹ̀ ma fa àrun jẹjẹrẹ. Amọ̀, èyí kìí ṣe òtítọ́ nígbà tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́nsì kò tíì fi ìdí rẹ̀ múlẹ.”

Àkótán

Ọ̀gẹ̀dẹ̀ àpọ́njù kò lè fa ààrùn jẹjẹrẹ. Tí ọ̀gẹ̀dẹ̀ bá ti ń jẹrà tàbí gbé òórùn burúkú jáde, ni ó le fa ìjàmbá fún ara. Nítorí náà, àhesọ wípé ọ̀gẹ̀dẹ̀ tó bá ní àbàwọ́n dúdú lára ma ń fa àìsàn jẹjẹrẹ ń ṣini lọ́nà.

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Back to top button