Getting your Trinity Audio player ready...
|
Ahesọ: Àwọn olumulo èrọ alatagba gbé ahesọ kan pé abẹ́rẹ́ àjẹsára ti a fi n gbogun ti kòkòrò human papillomavirus (HPV), lè fa ikú àìtọ́jọ́ àti airọmọbi l’ọjọ́ iwájú.

Àbájáde ìwádìí: Irọ́ ni! Àtẹ̀jade ìwádìí àti àwọn onímọ̀ ṣàlàyé pé kò sí ẹrí tó dájú nínú ìmọ̀ sáyẹ́nsì to ṣ’atileyin ọrọ naa. Kàkà kí o fa ikú, abẹrẹ ajẹsara náà máa n gbogun ti kòkòrò afàìsàn àìlèfojúrí HPV àti jẹjẹrẹ ilé-ọmọ.
Ìròyìn lẹkunrẹrẹ
Ni oṣù kẹwa ọdún 2023, ijoba orilẹ-ede Nàìjíríà ṣe agbekalẹ abẹ́rẹ́ àjẹsára tí ó ń gbógun ti kòkòrò afàìsàn àìlèfojúrí HPV fún ọmọ obìnrin mílíọ̀nù méje. Wọn ṣe ìpèsè abẹ́rẹ́ àjẹsára náà fún àwọn ọmọ obìnrin ti ọjọ́ orí wọn kò ju ọdun mẹsan sí merinla lọ.
Ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, kòkòrò afàìsàn àìlèfojúrí HPV lo maa n ṣ’okùnfa jẹjẹrẹ ẹnu ọna ilé ọmọ lọpọlọpọ ìgbà, àjọ agbaye United Nations lọ sọ èyí, koda jẹjẹrẹ ẹnu ọna ilé ọmọ ni jẹjẹrẹ keta to máa n fa iku, oun sí ni ìkejì ti o máa n fa iku jùlọ fún àwọn obìnrin tí wọ́n jẹ́ ọmọ ọdún mẹẹdogun si mẹrinlelogoji.
Muhammad Ali Pate, mínísítà fún ọ̀rọ̀ ìlera àwujọ ni Nàìjíríà ṣàlàyé pé, “Kòkòrò HPV yìí lo máa n saba fa jẹjẹrẹ ẹnu ọna ilé ọmọ, o si ṣe pàtàkì ki àwọn òbí ọmọ obìnrin dáàbòbo àwọn ọmọ wọn, kí wọ́n jẹ́ kí wọn gba abẹ́rẹ́ ajẹsara yii.”
Koda, mínísítà náà ṣàlàyé pé àwọn ọmọ òun obìnrin mẹrin lo tí gba abẹrẹ ajẹsara náà.
Ìjọba Nàìjíríà f’ikun wípé àwọn a ṣe ìfitónilétí àti ẹ̀kọ́ ọjọ márùún ní àwọn ilé-ìwé ati àdúgbò káàkiri ni ipinle merindinlogoji àti olu ilu orilẹ-ede Nàìjíríà ni Abuja.
Ó sì ṣàlàyé pé, wọn yóò kọ́kọ́ ṣàgbékalẹ̀ abẹrẹ ajẹsara náà ni àwọn ilé ìwòsan kerejekereje. Apa keji àjẹsára náà yóò bẹrẹ ni oṣù kàrún ọdún 2024 ni ipinle mokanlelogun.
Kini kòkòrò afàìsàn àìlèfojúrí HPV?
Àjọ to n risi ọrọ ìlera lágbayé WHO ṣàlàyé pé kòkòrò náà lè wọ inú ara ènìyàn nípasẹ Ìbálòpọ̀, o sí le ṣe ìjàmbá fún àwọ̀, ojú abẹ́ àti ọ̀fun.
Àjọ náà ṣàlàyé pé gbogbo ènìyàn tó ti bẹrẹ síí ni Ìbálòpọ̀ lo le ṣ’agbako ààrùn náà, botilẹjẹpẹ o lè má farahàn; kódà, ẹ̀tò oki ará le fọ kòkòrò náà kúrò nínú ara.
Sùgbón, tí ènìyàn bá kó kòkòrò náà lóòrèkóòrè, ó lè fa iṣaaju jẹjẹrẹ ilé ọmọ.
“Ki ènìyàn máa ni kòkòrò HPV lóòrèkóòrè ni ẹnu ona ilé ọmọ tabi ojú abẹ́ obìnrin, pàápàá ti wọn kò bá ṣe itọju rẹ, èyí lo n fa ipin ààrùn din logorun jẹjẹrẹ ile ọmọ,” àjọ náà lo ṣàlàyé èyí.
Cleveland Clinic ṣàlàyé pé ẹyà ọgọrun kòkòrò HPV ló wà, ṣùgbón ninu èyí, ọgbọn péré ló lè ṣe ikọlu fún ojú abẹ́ bíi ojú ara obìnrin, ilé ọmọ, nkan ọmọkunrin, ẹpọ̀n àti ihò idi.
Ilé ìwòsàn náà ṣàlàyé pé botilẹjẹpẹ ọpọlọpọ nínú àwọn kòkòrò HPV wọnyi ni kò lè ṣe ìpalára, àwọn eya kòkòrò HPV míràn lè fa iyatọ sí ẹnu ọna ilé ọmọ, ti wọn kò ba sí ṣe itọju èyí, o le fa jẹjẹrẹ ilé ọmọ.
“…Kòkòrò HPV le ṣe ijamba fún àwon obìnrin nítorí ó lè fa jẹjẹrẹ ile ọmọ ti wọn kò ba ṣe itọju rẹ. Àwọn ayewo kọọkan lè tètè ṣàwárí iyatọ wọnyi, láti dènà jẹjẹrẹ inú ilé ọmọ. Kódà, àwọn eya kòkòrò HPV ti kó le ṣe ìpalára le fa wọnwọn ní ojú ara obìnrin,” atejade ilé ìwòsan Cleveland ló ṣàlàyé èyí.
Botilẹjẹpẹ jẹjẹrẹ ilé ọmọ ló wọ́pọ̀ nínú jẹjẹrẹ ti kòkòrò HPV le fà, àwọn jẹjẹrẹ miran lè jẹyọ latarii kòkòrò HPV bíi jẹjẹrẹ inú iho-idi, jẹjẹrẹ nkan ọmọkunrin, jẹjẹrẹ ọ̀fun, jẹjẹrẹ ojú abẹ́ obìnrin àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀lọ.
Medical News Today ṣàlàyé pé kòkòrò HPV le wọnu ara ènìyàn nípasẹ ìbálòpọ̀ láàrin ọkùnrin àti obìnrin. O sí ṣeéṣe kí ènìyàn lugbadi kòkòrò náà lai sí ààmì àìsàn.
Botilẹjẹpẹ kiise gbogbo àkóràn kòkòrò HPV ló lè fa jẹjẹrẹ, ènìyàn lé ni jẹjẹrẹ ti o bá ni awọn ààrùn Ibalopọ míràn bíi chlamydia; ti eniyan bá tètè bimọ; eni ti o ti bí ọpọlọpọ ọmọ; ènìyàn to n fa sìgá tàbí tábà àti eni ti eya oki-ara rẹ̀ kò dápé.
Center for Disease Control gba imọran pé kí àwọn ọmọ okunrin àti obìnrin ti wọn je omo odún mọkanla sí méjìlá tabi ọmọ ọdún mẹsan, kí wọ́n gba abẹ́rẹ́ àjẹsára kí wọn ma ṣe ni àkóràn HPV.
Pẹlu akitiyan ìjọba àti ìfitónilétí lórí ọrọ abẹ́rẹ́ ajẹsara, DUBAWA ṣakiyesi wípé àwọn ènìyàn gbé ìròyìn ofege lórí ọrọ naa, wọn sì rò àwọn obi àti olutoju kí wọn ma gba abẹrẹ nàa fún àwon ọmọ wọn.
Lórí Facebook, ojú òpó kan ti o wà fún àwon màmá, Once A Mum Always A Mum Initiative (OMAM), olumulo kan bere ibere, pé ṣe kí oun gba abẹ́rẹ́ àjẹsára naa fún ọmọ òun obìnrin.
Lẹyin wakati diẹ, àwọn olumulo miran gbàa nimọran pé kí o yẹra fún abẹ́rẹ́ àjẹsára nàa nítorí o le fa airọmọbi l’ọjọ iwaju fún ọmọ náà, koda àwọn ẹlòmíràn sọ pe o le fa ikú àìtọ́jọ́.
Olumulo miran sọ pé ìjọba ṣe agbekalẹ abẹ́rẹ́ àjẹsára náà láti fi ṣe idinku àwọn ọmọ orilẹ-ede Nàìjíríà àti pé kí àwọn ọmọ obìnrin má lè bímọ lọ́jọ́ iwájú.
Oludari ilé-ìwé kan ni ipinle Èkó bá DUBAWA sọrọ
DUBAWA ṣ’akiyesi wípé àwọn òbí o gba àwọn ọmọ wọn laaye láti gba abẹ́rẹ́ àjẹsára náà ní ilé-iwe nítorí ẹ̀rù.
Àjọ ti o n risi ọrọ ìlera ni ipinle eko Lagos State Primary Health Care Board fi ìwé ranṣẹ sí oludari ile-eko kan. Ìwé náà fi to ni leti pé oṣiṣẹ ìlera ìjọba ma bẹrẹ síi se àbẹ̀wò sí àwọn ilé ìwé láti fún àwon omo obìnrin ni abẹrẹ ajẹsara ti HPV.
Ìwé ifiranṣẹ náà gba àwọn obi ati alagbatọ nimọran pé kí wọn gba àwọn ọmọ obìnrin wọn ti ọjọ orí wọn kò ju eésan sí eerinla lò, láàyè láti gba abẹ́rẹ́ ajẹsara.
Oludari Ile ẹkọ náà sọ fún DUBAWA wípé ọ̀pọ̀lọpọ̀ obi ni ko tẹwọgba ètò àjẹsára ọfẹ náà.
“A tin gbọ pé ìjọba fẹ bẹrẹ síi fún àwon ọmọ l’abere àjẹsára, àwọn obi kọọkan sí ti kìlọ fún wa pé kí a ma ṣe abẹ́rẹ́ nàa fún àwon ọmọ won, wọn ni ‘abere ikú ni’. Koda, mo gbiyanju agbara mi láti sàlàyé anfaani ti o wà nínú gbígba abẹrẹ náà sugbon wọn kò gbọ. Koda, mọ sọ fún ikan lara wọn pè ti mo bá ni anfaani, mọ ma gba abẹrẹ náà fún ara mi, ọmọ mi obìnrin ṣì kéré sí òjò orí to lè gbà abẹrẹ náà,” oludari ile-eko náà lo sọ èyí fún DUBAWA.
Lórí ìgbìyànjú rẹ̀ láti jẹ kí àwọn obi kọọkan f’orukọ àwọn ọmọ wọn sílẹ, o ṣàlàyé pé:
“A fi ìwé ranṣẹ sí gbogbo òbí ti ọmọ wọn jẹ ọmọ ọdún mesan sí merinla sùgbón ọmọ mẹta péré ni àwọn obi wọn f’ọwọsii. Koda, a túnbọ̀ pé àwọn òbí wọnyi lórí foonu, kí a lè mọ bóyá wọn fọwọsi lóòtọ́. Àwọn ọmọ obìrin toku s’ope àwọn obi àwọn o f’ọwọsii nítorí ẹ̀rù. Mọ ṣ’abapade àwọn òbí míràn láti sàlàyé fún wọn, wọn ni kò lè yé mi, nítorí náà, mọ fi wọn lọrun silẹ
O f’ikun wípé, botilejepe ọmọ obìnrin ogun ninu ilé ìwé náà, ni o le gba abẹrẹ náà, àwọn ọmọ obìnrin mẹrin pere lo gba abẹ́rẹ́ ajẹsara náà. Àwọn ọmọ mẹta péré lo gba abẹ́rẹ́ náà ní ilé ìwé wa, ọmọ kẹrin, iya re mu lọ sí ìlé iwosan fún ra rẹ.
Nitori bí ọrọ naa ṣe ri, oludari ilé ìwé náà gba ijọba ni imọran láti máà se ìfitónilétí tó yẹ fún àwon òbí ní èdè abínibí lórí pàtàkì abẹ́rẹ́ ajẹsara náà.
Kini awọn ìwé imo sọ nipa abẹrẹ ajẹsara HPV?
Atẹjade ọdún 2022 kan ṣàlàyé pé botilẹjẹpẹ abẹrẹ àjẹsára náà kò lè ṣe ìtọ́jú àkóràn, abẹrẹ náà lè se idiwọ fún àkóràn HPV. Atejade naa ṣàgbékalẹ̀ rẹ pé orísirísi àròsọ ni àwọn ènìyàn gbé ká lórí abẹ́rẹ́ ajẹsara náà, o sí gbaninímọ̀ràn pé kí a máa soro nipa abẹrẹ ajẹsara yíi àti ipa ti o lè kó nínú ìdènà ààrùn jẹjẹrẹ. Atejade náà sọ pé ìgbésẹ̀ yii le jẹ kí àwọn òbí gba abẹrẹ ajẹsara yíi fún àwon ọmọ wọn.
Ìwádìí kan ti wọn gbé jade ni ilú Gambella ni orilẹ-ede Ethiopia tẹnumọ pàtàkì ẹkọ ìlera nipa àkóràn HPV àti abẹrẹ ajẹsara HPV, èyí ti o le mu ki àwọn ènìyàn yí okan wọn pada.
Atẹjade míràn lórí PubMed ṣ’ayẹwo ipa ti abẹrẹ ajẹsara HPV kó nínú àwọn ti wọn gba. Ìwádìí náà fihan pe lóòtọ́ abẹ́rẹ́ ajẹsara HPV ti dènà ààrùn jẹjẹrẹ nínú àwọn ọmọ obìnrin àti okùnrin; ṣùgbón, o ṣe pàtàkì kí wọn ṣe abojuto àwọn ènìyàn wònyí titi di asiko ti wọn bá bẹrẹ síi ni ibalopọ l’ọ́jọ́ iwájú.
Kini awọn onimọ sọ?
DUBAWA bá àwọn onímọ̀ nípa ètò-ara obìnrin sọrọ lórí ẹ̀rù tabi ìpáyà àwọn òbí wọnyi àti pàtàkì abẹ́rẹ́ àjẹsára HPV.
Dokita Nathaniel Adewole, ẹni ti o jẹ ọjọgbọn ninu imọ ètò-ara obinrin ní Yunifasiti ti Abuja sọ fún DUBAWA wípé abẹ́rẹ́ àjẹsára HPV ò lè fa ikú tàbí airọmọbi bí awọn ènìyàn kan ti sọ.
Dokita náà ṣàlàyé pé wọn máa n fun àwon èniyàn ni abẹrẹ náà latarii pé wọn fẹ dènà jẹjẹrẹ ẹnu ona ilé ọmọ, gegebi wọn ti n fun àwon èniyàn ni abẹrẹ ajẹsara àìsàn polio kí wọn ma baa ni polio. O fi kun wípé jẹjẹrẹ ẹnu ona ilé ọmọ jé òkan lára àwọn jẹjẹrẹ ti o máa n saba fa ikú fún àwọn obìnrin ni orilẹ-ede Nàìjíríà.
“Abere àjẹsára HPV o ni nkankan ṣe pelu airọmọbi tàbí ikú. Ti o bà jẹ lóòtọ́ ni o ti fa ikú fún àwon ènìyàn kan, àwọn ènìyàn á ti pariwo síta. O ṣe pàtàkì kí àwọn òbí jẹ kí àwọn ọmọ wọn gba abẹrẹ yii lasiko. Jẹjẹrẹ ẹnu ona ilé ọmọ le sọ olowo di ẹdun arinlẹ. Kí àwọn ènìyàn ma ṣe fi owo yepere mu kòkòrò yii; ẹnikẹ́ni ti o bá ni anfaani láti gba abẹ́rẹ́ ajẹsara yíi, kó yàrá tete gbaa. Kódà, mo gboriyin fún ìjọba fún igbese yii, o fihan wípe wọn ronú eto ìlera ọjọ iwaju wa àti ti àwọn ọmọ wa,” dokita naa lo sọ èyí.
Onimọ náà sọ wípé o ṣe pàtàkì ki àwọn ọmọbìnrin ti wọn wa ni gbedeke ọjọ orí mẹsan sí merinla naa gba abẹrẹ ajẹsara yíi kí wọn to bẹrẹ síi ni Ibalopọ pẹlu ọkùnrin kí wọn ma baa ni jẹjẹrẹ ẹnu ona ilé ọmọ. Koda, o gba àwọn òbí nimoran pé kí wọn tewogba ìpèsè ìjọba yii.
“Ìgbésẹ̀ nla ni ìjọba ti gbé yii. Abẹ́rẹ́ ajẹsara yíi gbowolori, o ṣe ni ni kayefi pé àwọn ènìyàn gbé ìròyìn èké lórí ré. O ṣe pàtàkì ki àwọn eniyan rántí pé ìjọba kanna lo gbé abẹrẹ ajẹsara rọpárọsẹ̀ (polio), igbona (measles), ikọ́ ife (whooping cough) àti awon àìsàn miran,” dokita naa lo sọ èyí.
Dokita Qudus Lawal, eni ti o jẹ ọjọgbọn nípa ètò-ara obinrin ti o sí jẹ oṣiṣẹ Irrua Specialist Teaching Hospital ni ipinle Edo sọ wípé abẹrẹ ajẹsara HPV “dara, ọpọlọpọ ìwádìí lo sí fi idi èyí múlẹ.”
O ṣàlàyé wipe wọn ti bere eto ajẹsara yíi láti ọdún 2006 ni àwọn orilẹ-ède agbaye, won sí ti lòó ni igba mílíọ̀nù aadọrinlerugba, kó sí sí enikéni ti o jẹwọ pé o fa ikú tabi airomobi.
Dokita Lawal ṣàlàyé pé ìròyìn ofege ti awọn ènìyàn n gbé káàkiri nipa abẹrẹ àjẹsára náà jeyo latari “pé ajẹsara náà ni nkan ṣe pelu àwọn ọmọ obìnrin keekeekee, àti wípé o niiṣe pẹlu ìbálòpọ̀ laarin ọkunrin àti obìnrin, oun ti a ríi gẹgẹ bí eewọ.”
Dokita naa sí ṣàlàyé pé oun ti o fàá ti orílẹ-èdè Nàìjíríà ṣe ṣe agbekalẹ abẹrẹ àjẹsára naa fún àwon ọmọ obìnrin nìkan ni nítorí wípé kò sí owo ti a lè fi ra ajẹsara náà. “Ni àwọn orilẹ-ède miran, bíi Austrialia, UK, wọn máa n fun àwon omokunrin àti ọmọbinrin ni abẹrẹ ajẹsara, sùgbón torí kò sí ọwọ ni ìjọba Nàìjíríà ṣe fẹ fún àwon ọmọ obìnrin nìkan,” dokita náà lo sọ bẹẹ.
Ọgbẹni Lawal f’ikun wípé irọ ni àwọn ahesọ pé abẹrẹ ajẹsara HPV le fa ikú àti airọmọbi. O ṣàlàyé wípé ninu imo sayensi, àwọn onimọ ni ọna ti wọn ṣe lè mọ boya oun kan lo ṣokunfa nkan míràn.”
“Fun àpẹẹrẹ, ti eniyan bá mu ọtí elerindodo, leyin iseju meji, o jade sita, o sí ni ìjàmbá ọkọ, o sí gba’be ku, ṣe oti elerindodo ti o mu, lo fa ikú fún? Kó sí ẹrí to daju ninu imo sayensi pé abẹrẹ ajẹsara HPV le fa airọmọbi tàbí ikú àìtọ́jọ́.”
Àkótán
Irọ ni aheso pé abẹ́rẹ́ ajẹsara HPV lè fa airọmọbi àti ikú àìtọ́jọ́. Kò sí ẹ̀rí tó dájú nínú ìmọ̀ sáyẹ́nsì tó ṣ’atileyin ọrọ náà.