Fact CheckHealthYoruba

Ǹjẹ́ ọpọlọ aláboyún ma ń súnkì kí ó tó bímọ?

Getting your Trinity Audio player ready...

Àhesọ: Aṣàmúlò ìkànnì X kan wípé ọpọlọ obìrin má ń súnkì nígbà tí ó bá wà nínú oyún. Ó sì nílo oṣù mẹ́fà láti padà sí bí ó ṣe yẹ kó wà.

Ǹjẹ́ ọpọlọ aláboyún ma ń súnkì kí ó tó bímọ?

Àbájáde Ìwádìí: Kò sí àrídájú tí ó múnádóko láti fi ìdí àhesọ yìí múlẹ̀. 

Ìròyìn Lẹ́kùńrẹ́rẹ́

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìyípadà ló ma ń ṣẹlẹ̀ sí ara obìnrin nígbà tí ó bá wà nínú oyún. Lára èyí tí a le ṣe àkíyèsí rẹ̀ ni ikùn gíga, sísanra síi, títóbi ilé ọmọ, àìsàn àràárọ̀ àti ẹ̀yuǹ ríro. Àwọn òmìrán ní: itọ̀ gbogbo ìgbà, orí fífúyẹ́, àìrí’gbẹ́ yà, ìyàtọ̀ àwọ̀ ara, ọyàn, àti ojú ara. 

Yàtọ̀ sí èyí, àhesọ kan tí UberFacts tẹ̀ sórí ìkànnì X ti gbalẹ̀ lórí ẹ̀rọ WhatsApp. Wọ́n wípé ọpọlọ obìrin ma ń kéré si nígbà tó bá lóyún. Yíò sí nílò oṣù mẹ́fà lẹyìn ọmọ bíbí kí ó tó padà sí bí ó ṣe wà tẹ́lẹ̀.

Ìfìdíòdodomúlẹ̀

Oyún ma ń bẹ̀rẹ̀ nígbà tí ọlẹ̀ inú bá sọ sínú ilé ọmọ tí a mọ̀ sí utérọ́sì. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ aláboyún kìí rí àmì kan pàtó lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tí èyí bá wáyé. Àmọ́ lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ díẹ̀, wọn yóò bẹ̀rẹ̀ sí rí àwọn àmì kan èyí tí kìí rí bákànnáà fún gbogbo wọn àyàfi tí wọ́n bá lọ ṣe àyẹ̀wò. Síbẹ̀síbẹ̀, a kò tíì rí àmì tó wípé ọpọlọ aláboyún yóò súnkì.

Ọpọlọ sísúnkì

Ọjọ́ orí wà lára ǹkan tó ma ń jẹ́ kí ìwọ̀n ọpọlọ o yípadà. Bí ènìyàn ṣe ń dàgbà sí ma ń n’ípá lórí àwọn mólẹ́kù àti mọfọ́lọ́gì, sẹ́ẹ́lì àti òye. Bí ọpọlọ bá ṣe n kéré sí, pàtàkì jùlọ ní kọ́tẹ́sì iwájú tí ìfunpá gíga sì ń ṣẹlẹ̀, óṣeése kí àrùn rọpárọsẹ̀ tàbí kí ẹ̀jẹ̀ má dé àwọn ẹ̀yà ara kànkan (ischemia). Bákannáà ni àwọn sẹ́ẹ́lì ẹ̀jẹ̀ funfun lè ní ègbò.

Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde kan ṣe wí, kìí ṣe ohun tí o jẹ́’yàlẹ́nu fún ọpọlọ láti ní àyípadà bí ènìyàn bá se ń dàgbà sí. Awọ rírún tó bo ọpọlọ ma ń tínrín sí, asì lè ṣe àkíyèsí rẹ̀ ní lóòbù iwájú tó ń ṣàkóso ìrántí. Ẹ̀yà tí a mọ̀ sí “temporal lobe” tò ma ń jẹ́ kí ohun t’énìyàn ń gbọ́ yé ènìyàn náà ma ń tínrín si. 

Àwọn ẹ̀yà tó ma ń súnkì dàbí túùbù. Wọ́n sì ma ń gbé àlàyé láti ọpọlọ lọ sí gbogbo arayókùn àti láti ara lọ sí ọ̀pá ẹ̀yiǹ. Nígbà tí ọpọlọ bá súnkì, àsopọ̀ láàrin àwọn níúrónì yóò díkùn. Èyí yóò mú kí ìlọ́lù wà láàrin àwọn atagba níúrónì.

Ǹjẹ́ ọpọlọ aláboyún ma ń kéré sí?

DUBAWA kàn sí Dọ́kítà Ayodele Adewole, Olùdarí ẹ̀ka tó ń ṣe ìtọjú fún aláboyún àti ọmọ kékeré (Obstetrics and Gynaecology) Mother and Child Hospital, nílù Ondo. Ó wípé kò sí òtítọ kankan nínú àhesọ tó wípé ọpọlọ aláboyún ma ń súnkì. 

Ó wípé, “irọ́ pátápátá ni èyí. Ọpọlọ kìí kéré si ní ìwọ̀n. Àmọ́, iṣẹ́ tí ọpọlọ ń ṣe lè díkùn nípasẹ ọjọ́ orí. Oyún kò sì ni ǹkankan ṣe pẹ̀lú èyí.”

Bákanáà, Olórí Dọ́kítà pátápátá n’ílé ẹ̀kọ́ ìwòsàn University of Medical Sciences (UNIMED) ní’lú Ondo, Adesina Akintan sàlàyé pé sáyẹnsì kò tí fi ìdí irú àhesọ báyìí múlẹ.

Ó wípé “èmi ò tí gbọ́ irú àhesọ tó wípé ọpọlọ aláboyún máa ń kéré sí tí yóò sì nílo oṣù mẹ́fà láti fi hù padà lẹyìn oyún. Nítorínáà, èmi ò gbà wípé òtítọ ní nítorí pé sáyẹnsì kò ì tí fi ìdí rẹ̀ múlẹ.

Yàtọ̀ sí ohun tí àwọn dọ́kítà wọ̀nyí sọ, àtẹ̀jáde Nature Neuroscience kan fi dáni lójú pé àwọn àyípadà kan ma ń wáyé nínú ọpọlọ aláboyún èyí tí yóò jẹ́ kí ọpọlọ rẹ̀ ó kéré si. Àtẹ̀jáde yìí wípé ayípadà náà ló ma ń ṣe ìgbáradì fún ìyá ọmọ kí ó tó bí’mọ.

Bákannáà, a tún rí ìwádìí òmíràn tó fí ara pẹ́ẹ.. Àmọ́, fún eléyìí, nígbà tí wọ́n bá ní oyún àkọ́kọ́ ní àyípadà náà má ń wáyé nínú ọpọlọ aláboyún fún àpẹrẹ, láti lè tọjú ọmọ rẹ̀ bí ó ṣe yẹ. 

Àkótán

Àwọn ẹ̀rí tí a kójọ tako ara wọn. Kò sì tí sí ìwádìí sáyẹnsì tó múnádóko lórí àhesọ tó wípé ọpọlọ aláboyún ma ń súnkì. 

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Back to top button