Fact CheckMainstreamYoruba

Ǹjẹ́ òtítọ́ ni wípé ìjọba Dubai ń fún àwọn ènìyàn ní owó ìrànwọ́ fún ààwẹ̀ Ramadan?

Aheso: Atẹjade kan ti àwọn ènìyàn ń pin káàkiri lori WhatsApp sọ wípé ìjọba Dubai ń fún àwọn ènìyàn ní àádọfa dọ́là ($110) gẹ́gẹ́ bí owó ìrànwọ́ fún oṣù mímọ́ Ramadan.

Ǹjẹ́ òtítọ́ ni wípé ìjọba Dubai ń fún àwọn ènìyàn ní owó ìrànwọ́ fún ààwẹ̀ Ramadan?

Àbájáde ìwádìí: Irọ́ ni. Ìwádìí wà fihàn pé ìjọba Dubai ò fún ẹnikẹni ní owó ìrànwọ́ fún Ramadan àti wípé aṣinilona ni ìròyìn náà. 

Ìròyìn lẹkunrẹrẹ

Awọn Musulumi lágbayé ti bẹrẹ ààwẹ̀ gbígbà nínú oṣù àpọ́nlé Ramadan, eyi ti wọn máa n ṣe lọdọọdun. Ni asiko ààwẹ̀ yi, oríṣiríṣi ìròyìn ni a máa n ṣábà pade ni ori ayelujara.

Ninu oṣù mímọ́ yi, o ṣe dandan fún àwọn Musulumi òdodo lati ra oúnjẹ sí ilé, ki wọn lè jẹ oúnjẹ to ba agọ ara wọn mu, kí okun le wà fún ààwẹ̀ gbígbà, won a sì nilo owó fun eyi.

Bi ààwẹ̀ ti n lọ, atẹjade kan ti tan ka ori ayelujara pẹlu aheso pe ìjọba Dubai ń pín àádọfa dọ́là fún àwọn ènìyàn káàkiri àgbáyé gẹgẹbi owó ìrànwọ́ lásìkò ààwẹ̀ Ramadan, àti wípé gbogbo ènìyàn káàkiri àgbáyé ló lè forukọsilẹ fún ètò náà. 

Ǹjẹ́ òtítọ́ ni wípé ìjọba Dubai ń fún àwọn ènìyàn ní owó ìrànwọ́ fún ààwẹ̀ Ramadan?
Àwòrán atẹjade akalekako náà 

DUBAWA ṣe ìwádìí atejade yìí nítorí ó tí tànká orí ayélujára, àti wipeu ọpọlọpọ ènìyàn ló fẹ mọ̀ bóyá ootọ ni tàbí irọ́.

Ifidiododomule

DUBAWA ṣe itopinpin kókó ọrọ lóri owó ìrànwọ́ Ramadan lati ọdọ ìjọba Dubai, sùgbọ́n a kò rí oun kankan. Àmọ́ṣá, ìwádìí wà fihàn pé ọpọlọpọ ilẹ́eṣẹ́ àti àwọn olójú àánú lo ti bẹrẹ sí ní pín oúnjẹ fún àwọn ènìyàn l’asiko Ramadan. 

Ìròyìn kan láti ìwé ìròyìn Arab News je ko di mímọ̀ pé olórí ìlú Dubai, Sheikh Mohammed bin Rashid Al-Maktoum, ṣ’agbekalẹ ètò kan tí yóò pèsè oúnjẹ lọnà ọgọrun mílíọ̀nù fún àwọn aláìní ni àsìkò ààwẹ̀ Ramadan. 

Àwọn oún tó mú ìfura lọwọ 

A fi linki tí ó wà nínú atẹjade yii sí ori ẹrọ ìgbàlódé ti a máa n lo lati ṣe ìwádìí ààyè ayélujára, Whois.com, èsi ìwádìí wà fihàn pé ìpínlè Ọ̀yọ́ ní orilẹ-ède Nàìjíríà ni wọ̀n ti ṣ’èdá ààyè ayélujára yìí, kìíse ìlú Dubai gẹgẹbi atẹjade náà ti wí.

Ǹjẹ́ òtítọ́ ni wípé ìjọba Dubai ń fún àwọn ènìyàn ní owó ìrànwọ́ fún ààwẹ̀ Ramadan?
Àwòrán èsì ìwádìí wa l’ori ààyè ayélujára náà 

Oun míràn ni wípé, o ṣeéṣe ki èèyàn ṣ’àbẹ̀wò sí ààyè ayélujára yìí láì fi orúkọ sílẹ̀ lóri fọọmu iforukọsilẹ yìí, eyi mu ifura dani.

Ǹjẹ́ òtítọ́ ni wípé ìjọba Dubai ń fún àwọn ènìyàn ní owó ìrànwọ́ fún ààwẹ̀ Ramadan?
Àwòrán fọọmu iforukọsilẹ

Òun miran ni awọn ẹri eke ti o wa lori aaye ayelujara yìí. Eyi jẹ òun kan pataki ti a máa fi n ṣe idanimọ awọn onijibiti lori ayélujára. Awọn linki ẹrí èké yìí jé òkan lára oun tí àwọn onitanjẹ àti onijibiti máa n lò láti ṣ’ẹ̀tàn.

Ǹjẹ́ òtítọ́ ni wípé ìjọba Dubai ń fún àwọn ènìyàn ní owó ìrànwọ́ fún ààwẹ̀ Ramadan?
Àwòrán ẹ̀rí èké 

Leyin ti a díbọ́ bi eni ti o forukọsilẹ lori ààyè ayélujára yìí, a ri atejade kan to sọ pé àwọn ènìyàn àádọta lọnà egberun nikan ló lè fi orúkọ silẹ.

Leyin èyí, ààyè ayelujara náà bèrè fún àfikún alààyè nipa ènìyàn kí a tó lè ráàyè gba owó náà; ẹ lè rí èyí ninu àwòrán tó kàn; eyi jẹ ọnà kan ti awọn olutanjẹ ati onijibiti máa n lò lati mú kí ènìyàn ṣ’àbẹ̀wò sí ààyè ayelujara wọn. 

Ǹjẹ́ òtítọ́ ni wípé ìjọba Dubai ń fún àwọn ènìyàn ní owó ìrànwọ́ fún ààwẹ̀ Ramadan?
Ìdí tí atẹjade náà fi tànká 

Ọ̀kan lára àwọn àfikún àlàyé naa ni ki olumulo ṣ’atunpin fọọmu naa pelu ẹbí àti ọ̀ré wọn, èyí fún wa ni ofiri oun tí o jẹ kí iroyin naa tànká orí ẹrọ ibaraẹnisọrọ WhatsApp.

Akotan

Ìwádìí wà fihàn pé ijoba Dubai ò ṣe àgbékalẹ̀ ètò kankan lati fún àwọn ènìyàn ní owó ìrànwọ́ Ramadan, ati wípé àwọn tó ṣ’ẹ̀dá fọọmu akalekako náà ni èròngbà buburu. Nitori náà, irọ̀ nla ati asinilona ni aheso yii. Ẹ ṣọ́ra.

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Back to top button