Facebook ChecksFact CheckHealthYoruba

Ṣé èepo ògèdè wẹ́wẹ́ lè mú kí eyín ènìyàn funfun lesekese?

Ahesọ: Inú eepo ògèdè lè fọ eyín ènìyàn mọ, kódà yòó funfun balau.

Àbájáde ìwádìí: Kò sí ẹrí tó dájú. Ìwádìí àwọn onímọ̀ ati ìfòròwánilénuwò pẹlu onimọ kan fi ìdí rè múlẹ pé èpo ògèdè wẹ́wẹ́ ò ṣeé fi fọ eyín mọ́, ki o sì funfun balau. 

Ìròyìn lẹkunrẹrẹ 

Àwọn Yorùbá a máa sọ wípé, ìmọ́tótó lo lè ṣ’ẹgun ààrùn gbogbo, nítorí èyí, a máa gba àwọn ènìyàn l’amọ̀ràn pé kí wọ́n gbé ìgbé ayé ìmọ́tótó. Àjọ to n risi ọrọ ọmọde ni agbaye UNICEF ṣàlàyé pé ìmọ́tótó lè fún ni ní àlàáfíà topeye, ìdàgbàsókè ati ìgboyà. Nítorí èyí, ọpọlọpọ ènìyàn ló ń ṣawari imọ nípa bí wọn ṣe lè wà ní ìmọ́tótó. 

Ni ìgbà míràn, àwọn ènìyàn a máa lọ orí ẹrọ alatagba láti kọ bi wọn ṣe lè ṣe ìmọ́tótó àgbègbè wọn ati ti awọn tikara wọn. 

Láìpẹ́ yii, olumulo ìkànnì abẹ́yẹfò X @Nig_farmer daba ọ̀nà abayọ fún àwọn tí eyín wọn ti dudu, kódà, o ṣàlàyé pé ọnà abayọ yìí máa mu ki eyín wọn funfun balau. 

“Kò sí oun tó burú tí eyín bà dudu, ko ṣaa ti ma rùn. Ṣugbọn, awa ènìyàn ṣafẹri eyín to funfun, to sí rẹwa lójú. Ti o ba fẹ ki eyín re ko funfun, họ àwọn oun funfun to wa ninu epo ògèdè wẹwẹ, ki ò sì fi fọ eyín rẹ. O máa n mu ki eyín funfun kíákíá.”

Ọpọlọpọ olumulodúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, ṣugbọn àwọn ẹlòmíràn ni àwọn gbàgbö. 

Bakan náà, ọpọlọpọ ènìyàn bèèrè bi wọn ṣe lè lòó, wọn sì fẹ mo boya epo ògèdè àgbagbà lè ṣe ìse kanna, sugbon olumulo yìí @Nig_farmer kò f’esi sí gbogbo ìbéèrè náà. 

Kódà, a ríi wípé wọn fi aheso naa sí orí ẹrọ ibaraẹnisọrẹ Facebook ni awọn ojú òpó wọnyii.

DUBAWA kíyèsi pé àwọn ènìyàn fẹ mọ síi nípa lílo eepo ògèdè fún fifọ eyín mọ́, èyí ló fàá tí a fi ṣe ìwádìí yìí. 

Kini o n ṣokunfa èyìn dúdú?

Nínú àkọsílẹ kan, ilé ìwòsàn Cleveland Clinic ṣàlàyé pé eyín dúdú ni ìyípadà àwọ̀ eyín ènìyàn. Eyín ènìyàn lè pupa, dúdú tabi ni àwọn amí kekeeke lórí. 

O ṣàlàyé pé ìyípadà àwọ̀ eyín le ṣẹyọ l’ọna meji: ìyípadà ti ita ati ìyípadà ti inú. Ìyípadà ìta máa n se àkóbá fun ìta eyín ènìyàn, ìyípadà inú máa n se àkóbá fún eyin láti inú wa. 

Ki eniyan máa jẹ àwọn oúnjẹ kan tabi mu ọtí kọọkan, taba, egbò eyin, ọjọ orí ènìyàn, jiini, àìsàn àti àwọn oogùn míràn lè fa ìyípadà àwọ̀ eyín. 

Kódà, ìwádìí kan fihàn pé àwọn ènìyàn tó féràn sìgá máa n ni ìyípadà àwọ̀ ẹyin ju awọn ẹlòmíràn lọ.

Àwọn oun wọnyi ati bẹẹbẹẹlọ ló maa n ṣokunfa ìyípadà àwọ̀ eyín ènìyàn, ọpọlọpọ ènìyàn máa n ṣ’àwarí ìmọ̀ nipa bí wọn ṣe lè ṣe ìyísódì, nipasẹ lílo oun àdáyébá. 

Njẹ eepo ògèdè wẹ́wẹ́ lè mu ki eyín ènìyàn funfun balau?

Èsì iwádìí kan ti won gbé jade lori PubMed Central ṣàlàyé pe ọpọlọpọ anfaani l’owa lára èpo ògèdè wẹ́wẹ́. Ìwádìí na fihàn pé awon oun èlò kọọkan bíi flavonoids, alkaloids, tannins, quinones, ati saponins, ti o ni èròjà antioxidant wà lara èpo ògèdè wẹ́wẹ́.

Bakan náà, “àwọn oun tí a gbá jade lataara èepo ògèdè wẹ́wẹ́ lè ṣe ikọlu ààrùn eyín.”

Ìwádìí náà ṣ’ayẹwo agbára àti iṣẹ tí èpo ògèdè wẹ́wẹ́ pẹlu àwọn oun àdáyébá míràn n se lati mu ki eyín ènìyàn funfun, bíi ata ilé pupa àti èédú. Èsì iwádìí na fihàn pé àwọn oun àdáyébá wọnyi ò le fa ìyípadà tó kún ojú oṣunwon, ṣùgbón wọn ṣe ìyísódì àwọ̀ eyín. 

Ìwádìí na ṣ’agbekale rẹ pé èédú tabi èpo ògèdè wẹwẹ ò ṣe ànfàní kan pàtó fún eyín, botilẹjẹpe wọn fi fọ ẹnu fún ìgbà pípẹ́, èyí fihàn pé àwọn oun wọnyi ò lè mú kí eyín funfun. 

Ṣugbọn, eyín màlúù ni wọn fi ṣe ìwádìí náà kìí ṣe eyin ọmọ ènìyàn. 

Ìwádìí míràn ti wọn gbé jade ni International Journal of Ayurvedic Medicine ṣ’ayẹwo agbara ti èpo ògèdè wẹ́wẹ́ ati èpo ọsàn ni lati mu ki ẹyìn awọn ọmọde funfun. 

O ṣàlàyé pé wọn ti n lo ògèdè wẹwẹ latayedaye fun ìwòsàn igbe gbuuru, ọgbẹ inú ati ẹjẹ riru. 

Ìwádìí náà filelẹ pe èpo ògèdè wẹwẹ ati ọsan lè sẹ ìyípadà sí àwọ̀ eyín ọmọdé. Ṣugbọn, awon oniwadii ṣàlàyé pé ìwádìí náà kò ṣéé gbẹ́kẹ̀lé, àyàfi ti a ba ṣe ìwádìí síwájú síi. 

Àkọsílẹ Montebello Dental Clinic ṣàlàyé pé kò sí ẹrí tó dájú nínú ìmọ̀ síáyẹ́nsì pé èpo ògèdè wẹwẹ lè mú kí eyín funfun. Àkọsílẹ náà ṣàlàyé pé botilẹjẹpe èròja potassium ati magnesium wa ninu ògèdè wẹwẹ, kò sí ẹrí tó dájú pé wọn a mu ki eyín funfun síi. 

Àkọsílẹ náà sọ wípé ọna meji ni a lè gbà ṣe ìyípadà àwọ̀ eyín: àkọ́kọ́ ni lílo kẹ́míkà láti fi bo eyín; ìkejì ni ki a fi tipatipa mu ìyípadà bá àwọ̀ eyín. 

O ṣàlàyé pé tí a bá lo èpo ògèdè wẹ́wẹ́, kò ní ṣe ìse to yẹ kò ṣe nítorí èpo náà kò le mu ìdòtí kúrò. Bakan náà, kò sí kemika kankan nínú èpo ògèdè wẹwẹ ti a lè fi bó eyín. 

Ṣugbọn, o ṣàlàyé pé, ògèdè dára fún jijẹ, èròjà potassium inu ògèdè wẹ́wẹ́ máa n fún eyín ni agbara. 

Koda, àwọn onimọ ti se ìwádìí lórí lílò èpo ògèdè wẹwẹ fún itọju aisan iba, eewo, ati awọn àìsàn míràn.

Ìwádìí kan ti won gbé jade laipe yii ṣ’ayẹwo ipa ti èpo ògèdè wẹ́wẹ́ kò ninu ikọlu kòkòrò P. gingivalis ati A. actinomycetemcomitans. Ìwádìí naa fihàn pé ọtí líle àti oun tí a gbá sílẹ lataara èpo ògèdè wẹ́wẹ́ lè ṣe ìwòsàn àwọn kòkòrò afàìsàn wọnyi. Ṣugbọn, kò mẹnuba lílo èpo ògèdè wẹ́wẹ́ lásán láti fi fọ eyín ènìyàn.

Àwọn onimọ sọrọ

DUBAWA ṣe ìfòròwánilénuwò pẹlu Chioma Agu, ẹnití o jẹ onimọ iṣẹgun oyinbo ti o n tọju eyín, ni ile-eko àgba ti ìlú Enugu. Ó sọ wipé kò sí ẹ̀rí tó dájú nínú ìmọ̀ sáyẹ́nsì pé èpo ògèdè wẹ́wẹ́ lè mú kí eyín funfun. 

“Ko sí òtítọ nínú ọrọ náà, kò sí ẹrí tó dájú nínú imo sáyẹ́nsì. O ni awon oun kọọkan ti ìmọ̀ sáyẹ́nsì gbekalẹ ki a fi se itọju ẹyin,” onimọ náà ló sọ èyí.  

O fikun wipe awon èròjà àdáyébá kọọkan wà tí ènìyàn lè fi ṣe itọju eyín, ṣugbọn o ṣàlàyé pé wọn lè ṣe ijamba fún eyín ènìyàn. 

“Awon èròjà wọnyi lè bó ìta eyín ènìyàn, yóò sí mu ki ẹyìn funfun dé òdiwọn kan. Ṣugbọn, wọn le se ijamba fún eyin,”

Arábìnrin Agu ṣàlàyé pé ìyípadà àwọ̀ eyín lè ṣẹyọ láìsí okunfa kankan, nítorí ati inú ló ti wa.  

O gba imoran pé tí ẹnikẹni be fẹ mu ki ẹyìn wọn funfun, ki wọn kọ́kọ́ lọ ṣ’abẹwo sí ọ̀dọ̀ dókítà olutọju èyín. O tun sọ wípé, ti ènìyàn bá fẹ ni eyín tó funfun balau, wọn lè lo veneer, oun ti won fi n ṣe èyín lpoge.

“Àwo èwà eyin lasan ni, wọn máa fi ń bo eyín ènìyàn, kò kíì gba idoti sara,” arabinrin Agu ló sọ èyí. 

Àkótán 

Ko sí ẹrí tó dájú nínú imo sayensi pé a lè fi èpo ògèdè wẹ́wẹ́ fọ eyín ènìyàn kí o sì funfun balau. 

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Back to top button