Facebook ChecksFact CheckPoliticsYoruba

Iro ni! Olori ijọba ologun tẹ́lẹ̀rí, Gowon ò kú o

Getting your Trinity Audio player ready...

Ahesọ: ìròyìn akalekako kan lo gbe aheso kan pé olori ijọba ologun nigba kan ri lorilẹede Naijiria, Ọgagun fẹyinti, Yakubu Gowon ti dagbere f’aye. 

<strong>Iro ni! Olori ijọba ologun tẹ́lẹ̀rí, Gowon ò kú o</strong>

Àbájáde ìwádìí: Irọ ni. Ọgbẹni Gowon Edoumiekumor, ẹni tí o jẹ alaga teleri fun igbimọ àwọn ọgá àgbà Yunifasiti, ni o di olóògbé. Kódà, ojúlówó ilé-isé ìròyìn kankan ò gbé ìròyìn náà. 

Ìròyìn lẹkunrẹrẹ

Wọn bí ọgbẹni Yakubu Gowon ni ọjọ́ kọkandilogun oṣù kẹwa ọdún 1934 ni ilu Pankshin, orilẹ-ede Nàìjíríà. Ó jẹ́ olórí ìjọba ológun láti ọdún 1966 sí 1975. Ogbeni Gowon jẹ onígbàgbọ nínú isokan àti ìgbéga orilẹ-ede Nàìjíríà. 

Ni ọjọ kẹsán, oṣù kewa ọdún 2023, ìròyìn tànká orí ẹrọ alatagba àti àwọn ilé-isé ìròyìn kọọkan pé ọgbẹni Gowon ti jade láyé. Àwọn ilé-isé ìròyìn wònyí lo àwòrán ogagun feyinti náà, wọn sì kọ àkòrí yìí síi, “olori ijọba ológun tẹ́lẹ̀rí, ọgagun Yakubu Gowon, ọmọ ọdún mokandinl’àádọ́rùn, ti di olóògbé.”

Ọpọlọpọ olumulo ẹrọ alatagba lo gba ìròyìn náà gbọ, ti wọn sì bá ẹbi rẹ̀ kédùn. Olumulo kan lórí ìkànnì ibaraẹnisọrẹ Paul Adelaja so wipe, “Ki èmi rẹ sinmi ní alaafia, o je ènìyàn kan pàtàkì sí orílẹ-èdè Naijiria.”

Nítorí irufẹ ènìyàn ti ìròyìn náà dálé lórí ati bi o ti tanka, DUBAWA ṣe ìwádìí oro náà.  

Ifidiododomule

A ṣe itọpinpin kókó ọrọ lori ayélujára lati ṣawari ìròyìn naa ni ojúlówó ilé-isé ìròyìn sugbon kò sí oun tó jọ bẹẹ. Oun tí a rí ní ìròyìn kan lati iwe ìròyìn Tribune nípa ikú alaga teleri igbimọ àwọn ọgá àgbà Yunifasiti, Gowon Edoumiekumor, ẹni ti o dagbere f’aye ni ọjọ keje, oṣù kewa, ọdún 2023.

A ríi wípé ìròyìn ofege náà bẹrẹ síí tanka orí ẹrọ alatagba nítorí orúkọ to dawọn pọ̀, ‘Gowon’, èyí tí o je kí àwọn ènìyàn gbàgbọ́ pé ogagun feyinti ni won sọ. 

Bakan náà, Adeyeye Ajayi, ẹni tí o je agbenuso ọgbẹni Gowon, nínú atejade kan to fi sita ṣàlàyé pé kìíse ogagun feyinti ló di olóògbé . 

“Gowon sí wá láyè óo, o sì wà ní alaafia ara. Ogagun feyinti, Gowon ò kánjú lo ibi kankan,” ọgbẹni Àjàyí kò èyí sinu atẹjade rẹ. 

Ogbeni Orusi Kenneth, agbẹnusọ mínísítà teleri fún ètò ẹkọ, sọ wípé ogagun feyinti Gowon sí wá láyè ati l’alafia, o sì wà ní ìlú London. 

A ṣí ti ṣ’abapade ọpọlọpọ àwòrán to ṣàfihàn ibi ti ogagun fẹyinti Gowon ati àwọn ọmọ-ọmọ rẹ l’ọkunrin ti n wo èrè bọọlu alafẹsẹgba ni ìlú London. 

Àkótán 

Ọgagun fẹyinti Gowon ṣi wá laye. Ọgbẹni Gowon Edoumiekumor, ẹni tí o jẹ alaga teleri igbimọ àwọn ọgá àgbà Yunifasiti, ni o di olóògbé. Agbenuso ogagun feyinti náà ti fi atẹjade kan síta, nibi ti o ti takò ìròyìn ofege náà. 

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Back to top button
Translate »