Ahesọ: Arábìnrin kan, ọmọ ìlú South Africa bí ọmọ mẹwa lẹẹkan náà láti gba àmì ẹyẹ àjọ Guiness World Record.
Àbájáde ìwádìí: Irọ́ ni. Obìnrín kan tí orukọ rẹ̀ ń jẹ́ Halima Cisse, ará ìlú Málì ni Àjọ Guiness World Record damọ gẹgẹbi ẹni ti óbí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ lẹẹkan náà l’agbaye. Cisse bímọ mẹsan ní ọdún 2021 ni ilu Cassablanca ní Morrocco. Àwọn Ileeṣẹ ìròyìn ṣ’agbeyewo àríyànjiyàn ọrọ ibẹẹwa arábìnrin Sithole, wọ́n sì tako ọrọ rẹ̀.
Ìròyìn lẹkunrẹrẹ
Ní ọjọ́ ajé, ọjọ́ keje oṣù kẹjọ ọdún 2023, olumulo ojú òpó Facebook kan, Babies First ṣ’atunpin ìròyìn kan pé ọmọ ìlú South Africa kan tí ó jẹ́ ọmọ ọdún metadinlogoji bí ibẹẹwa lẹẹkan náà.
“Àrà meeriri: Arábìnrin South Africa kan, ẹni tí ó jẹ́ omo ọdún metadinlogoji ti bi ọmọ mewaa lẹẹkan naa”.
Kódà, olumulo ìkànnì ibaraẹnisọrẹ náà tún ṣ’atunpin àwòrán arábìnrin náà, ọkọ rẹ̀ àti àwọn ọmọ náà. Kódà, olumulo náà ṣ’atunpin àkọsílẹ Ileeṣẹ Beautiful Life ti Media Guide Internet Database (MGID) gbejade.
Àkọsílẹ náà ṣàpèjúwe arábìnrin náà gẹgẹbi Gosiame Sithole, omo odun metadinlogoji tí ó ṣẹṣẹ bí ọmọ mewaa, o sì ṣeéṣe kí ọ gba àmì ẹyẹ àjọ Guiness World Record fún ẹni tí o bímọ jù l’ágbayé laarin ọjọ kan. Àkọsílẹ naa ṣàlàyé pé ọmọkunrin meje ati ọmọbinrin mẹta ni awọn ibeewa náà, o sì bí wọn ni ilé-iwosan kan ni ilu Pretoria ní orilẹ-ède South Africa.
Ìròyìn náà ṣàlàyé pé ọkọ arabinrin Sithole ti a mọ sí Tebogo Tsotetsi ti ríi lójú ìran tẹlẹ ri pé ìyàwó rẹ̀ bí Ìbejì ṣugbọn “inú rẹ̀ dùn gidigan lati ni ọmọ púpọ̀”.
Ìròyìn náà fi kun wípé ọpọlọpọ ènìyàn lo bú ẹnu atẹ lu tọkọtaya náà, kódà àwọn ènìyàn ò gbàgbọ́ ninu iroyin náà. Nítorí èyí, arabinrin Sithole àti ọkọ rẹ ṣàfihàn àwòrán ilẹ ọmọ (scan) ti wọ́n yà ní ilé ìwòsàn kí awọn ènìyàn le gbàgbọ́. Ìròyìn náà fi kun wípé ile ìwòsàn ti wọ́n ti bimo naa jẹrisii ọrọ náà.
Àwọn olumulo ìkànnì ibaraẹnisọrẹ bèrè síí ki tọkọtaya pẹlú àwọn ọrọ bíi “eku orire” ati bẹẹbẹẹlọ.
“Iyanu, a f’ope fún ọlọrun,” Fidelis Oguaka lo sọ èyí. “Iyanu Olodumare. Eku oríire,” Afusat Atinuke Braimoh lo kọ èyí.
Ọpọlọpọ ènìyàn lo bú ọwọ ìfẹ́ lu atẹjade náà, ọpọlọpọ ènìyàn sì sọrọ nípa rẹ̀, kódà àwọn olumulo míràn ṣ’atunpin ìròyìn yii. Èyí ló fàá tí a fi ṣe itọpinpin ọrọ náà ki a le fi ìdí òdodo múlẹ̀.
Ifidiododomule
Lákọkọ́, a ṣ’ayẹwo ààyè ayélujára àjọ Guiness World Record. A ríi wípé, Halima Cisse, ọmọ orílẹ̀-èdè Mali tí ó bi ibẹẹsan ni ọdún 2021 ni àjọ náà damo gẹgẹbi ẹni ti o bi ọpọlọpọ ọmọ lẹẹkan naa.
A tún ṣe ìwádìí lórí àwọn ojúlówó iwe ìròyìn ti o niiṣe pẹlu ìtàn arabinrin Sithole, a rí ile-iṣẹ iroyin The Independent, British Broadcasting Corporation (BBC) tí ó wà ní ìlú London, iwe ìròyìn Guardian ni orile-ede Naijiria ati awọn miran, ninu iroyin ti won gbé jade ni oṣù kẹfà ọdún 2021, won ti ṣàlàyé pé kò sí ootọ ninu ọrọ naa.
Iwe ìròyìn the Independent sọrọ lórí gbogbo atotonu ọrọ náà, pẹlu agbekale kan lati ọdọ oṣiṣẹ ijoba agba kan ni ilu South Africa, Kholeka Gcaleka to ṣàlàyé pe irọ ni ọrọ náà.
Iwe ìròyìn naa mẹnuba akọsilẹ kan ti won gbé jáde ni oṣù kejìlá odun 2022 ti o ṣàlàyé pe ko sí enikéni ti ò dènà arabinrin Sithole lati ri àwọn ọmọ rẹ, koda ko sí ẹrí tó dájú pé o bímọ tabi loyun lásìkò náà. Kódà, faili rẹ̀ ní ilé ìwòsan Steve Biko Hospital fihan pe kò tíì ṣ’abewo sí ilé ìwòsàn náà láti ìgbà tí o ti bí ìbejì ni ọdún 2014.
Iwe ìròyìn The Independent tunbo ṣàlàyé pé wọn tètè paná ìròyìn èké náà nítorí kò sí àpẹẹrẹ omo kankan ni ibi kankan.
Kódà, ọgá àgbà ile-ise iroyin Pretoria News, Piet Rampedi ati ti Independent Media, Iqbal Suave ṣ’atileyin arabinrin Sithole ninu ahesọ rẹ pé won kò gba laaye lati ri awọn ọmọ rẹ.
Ìwádìí wà fihàn pé iwe ìròyìn Pretoria News ti ṣe ìfòròwánilénuwò pẹlu tọkọtaya náà, latarii èyí, wọ́n tako oun tí wọ́n sọ sẹyìn. Ìròyìn ateyinwa Pretoria News royin pé ọmọ mẹwaa ni wọ́n bí, ṣùgbọ́n wọn ṣalaye bi wọn ti gbebi ọmọ méjọ nikan.
Kìíse àwọn ọgá àgbà ile-ise iroyin yìí nikan lo ṣ’atileyin arábìnrin Sithole, kódà ayederu dọkita kan Dr Mpho Pooe, náà jẹrisi ahesọ pé wọn kò jẹ kí arabinrin Sithole ri awọn ọmọ rẹ. Ẹsun wọn ni wípé, lóòtọ́ ni arabinrin Sithole bi ibẹẹwa, ṣugbọn wọn ti jí àwọn ọmọ náà gbé.
Iwe ìròyìn The Citizen ti ìlú South Africa naa gbe ìròyìn náà, akosile wọn ṣàlàyé bi àwọn ọkunrin wonyi ṣe fi ẹsun kan dokita, ìjọba ati “ẹnikẹni ti o bere fun ẹrí pe arabinrin Sithole bi ibeewa” pe gbogbo won ni ajinigbe.
Iwe iroyin The Citizen tunbo ṣàlàyé pé àjọ Guinness World Record ti gbìyànjú láti ṣe ìwádìí oro náà, nitori won kò tii ri aridaju pe arabinrin naa bimo, kódà wọn kò rí awọn ọmọ náà.
Arákùnrin Rampedi ati Suave sọ wípé dipo ọmọ mẹwaa, ọmọ méjọ ni arábìnrin naa bi, meji sí kú síi ninu, gegebi iwe ìròyìn TheCitizen.
Amò, se arabinrin Sithole bi ọmọ mẹwaa bi?
Ìwádìí ilé-ise ìròyìn BBC ṣàlàyé pe arábìnrin Sithole tí ó jẹ́ alabagbe arákùnrin Tebogo Tsotesi, n lọ ìjò kanna pẹlu ọgá àgbà ìwé ìròyìn Pretoria News, ọgbẹni Rampedi.
Ogbeni Rampedi se ìfòròwánilénuwò pẹlu awọn tọkọtaya náà, wọn sì sọ fún wipe àwọn n reti ọmọ, leyin èyí, won ṣ’atunpin àwòrán arábìnrin Sithole ti o lóyún sinu.
BBC ṣàlàyé pé iwe iroyin Pretoria News gbé ìròyìn ni ọjọ kẹjọ oṣù kẹfà ọdún 2021 pe tọkọtaya náà ti bi ọmọ mewaa, botilẹjẹpe arábìnrin Sithole àti ọkọ rẹ, arakunrin Tsotesi nikan lo fi iroyin naa to wọn létí.
Arákùnrin Tsotesi salaye pé àyà rẹ sọ fún òun nipasẹ ifiranṣẹ kan ni, kódà ko ní anfààní lati lọ ilé ìwòsàn nítorí aarun COVID.
Kódà, ọgbẹni Rampedi ṣ’agbejade ìròyìn náà lẹyìn ti wọn sọ fún lat’ori ìkànnì WhatsApp, ko sì gba alaye kankan láti ile ìwòsàn náà.
Lẹyìn tí alabojuto ileeto náà jẹrisi ọrọ náà, awọn ile ìròyìn míràn bẹrẹ síí gbé ìròyìn náà. Ṣugbọn, o ṣeéṣe kí ọ jẹ iroyin ẹlẹjẹ nitori alabojuto náà gbọ ìròyìn yìí ní ẹnu ìdílé náà nìkan ni, kò fi ojú kan àwọn ọmọ náà.
Iwe-iroyin Pretoria News kọjale, kò sọ orúkọ ilé ìwòsan ti wọn ti bi àwọn ọmọ náà, kódà àwọn ilé iwosan ni agbegbe Gauteng tete f’ohun síta pé kò sí irú igbẹgbi bẹe lọdọ wọn.
BBC ṣàlàyé pé léyìn ọjọ́ mẹwa, ile iṣẹ Independent Media, tí o ni Pretoria News f’ẹsun kan Steve Biko Academic Hospital. Kódà, arákùnrin Tsotesi kede pe ki àwọn ènìyàn dẹkùn fífi owó ránṣẹ́ sí arábìnrin Sithole nítorí wọn kò mọ ibi tí ó wà. Bakan náà, arábìnrin Sithole sọ wipe ololufẹ rẹ̀ fẹ ná nínú owó náà.
Lẹyìn o rẹyin, wọn ṣ’awari arabinrin Sithole, wọn sì gbé lọ ilé ìwòsàn fún itọju, àwọn alabojuto ilu Guateng lo so èyí di mimo.
Awọn ọmọ wo ni o wa ninu àwòrán wọnyi?
A ṣe itọpinpin atẹyinwa lórí ẹrọ ayelujara Google, a sì ríi wípé àwọn ọmọ wọnyi ni wọn bí ni ọjọ́ kokonla, osu kokonla ọdún 2011 ni ìlú Surat ní India. Koda, ìròyìn naa wa ni inu linki yìí.
Àkótán
Irọ ni ọrọ náà. Àjọ Guiness World Record ò fun arabinrin Sithole ni àmì ẹyẹ fún ẹni tí o bímọ ju lẹẹkan náà l’agbaye. Ọpọlọpọ iroyin lo ṣ’agbeyewo àríyànjiyàn lori ibeewa arabinrin Sithole, won sì tako ọrọ rẹ.