Getting your Trinity Audio player ready...
|
Ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́: Nínu igbohunsafẹfẹ kan tí àwọn èèyàn ṣ’atunpin lórí ìkànnì WhatsApp, arákùnrin kan kilọ fun àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà pé ki wọ́n yàgò fún lílo òògùn Septrin nítorí ó lè mú kí awọ ara ṣí dànù.
Àbájáde ìwádìí: Òdodo ni ọ̀rọ̀ náà. Ọkan lára àwọn àpẹẹrẹ tàbí ìpalára lílo oògùn Septrin ni àwọn oloyinbo n pè ní Stevens-Johnson Syndrome. Ṣugbọn, èyí kò wọ́pọ̀.
Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé
Laipẹ yii, igbohunsafẹfẹ kan gbòde kan. A gbọ́ ohùn arákùnrin kan to n kìlọ̀ fún àwọn èèyàn pé kí wọ́n ma lo òògùn Septrin nítorí ó lè ṣe ìjàmbá fún wọn.
Arákùnrin náa ṣàlàyé pé alabaṣiṣẹpọ rẹ̀ kan lo òògùn náà fún ikọ́. Ṣugbọn lẹhin ti o lo òògùn yíì ni ara bẹrẹ síí yun, kódà ara rẹ̀ bẹrẹ síí ṣi mọ́ aṣọ.
Wọn sáré gbé arábìnrin náà lọ ilé ìwòsàn, ní ìgbà tí dókítà fí ojú ba arábìnrin náà, ó béèrè pé, ṣe wọn lo òògùn Septrin.
Arákùnrin náa sọ wípé, “Leyin wákàtí díẹ̀ tí wọn lo òògùn náà ni ara bẹrẹ síí yun wọn. Bí wọ́n ṣeé n yun ni àwọ̀ ara bẹrẹ síí bó. Kódà, awọ ara won bò mọ orí ibùsùn. Wọn ko lè mura dada, ìró ati iborùn ni won fi bo’ra lọ ilé ìwòsàn. Dókítà ṣì béèrè pé ṣe wọn lo òògùn Septrin.”
Nitori pàtàkì ọ̀rọ̀ naa ni Dubawa ṣe ifidiododomule yíì.
Kini Septrin?
Òògùn Septrin, ti a mọ̀ sì co-trimoxazole, jẹ egbòogi apa-kòkòrò àrùn ti wọ́n fi n ṣe ìtọ́jú àkóràn. Egbòogi apa-kòkòrò àrùn méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ trimethoprim ati sulfamethoxazole ni o wa nínú co-trimoxazole.
Aidsmap ṣàlàyé pé wọ́n máà n fi òògùn Septrin dènà òtútù àyà pàápàá fún àwọn eniyan ti o ni ààrùn Ibalopọ HIV. O fi’kun wípé òògùn naa máà n dena toxoplasmosis, tí ó jẹ́ ààrùn ọpọlọ.
Medlineplus ṣàlàyé pé òògùn Septrin kò ni pa kòkòrò-àrùn àìlèfojúrí ti o máà n fà òtútù, ọsin tàbi àwọn àkóràn míràn. Ṣugbọn, o gbani nímọ̀ràn pé kí àwón èèyàn lo òògùn ni ìbámu pẹ̀lú ìlànà dókítà wọn.
Ṣé lootọ ni òògùn Septrin lè mú kí àwọ̀ ara ènìyàn bó dànù?
Ọkan lára oun tí o le ṣẹlẹ ṣí eniyan to ba lo Septrin ni kí àwọ̀ ara bó dànù.
Cleveland Clinic salaye pé òògùn náà lè ṣokunfa ki awọ ara dúdú si, ki ó bó, tàbí ṣí kúrò.
Ní ọdún 2020, àwọn oniwadii ṣe ìwádìí lórí ipa ti òògùn Septrin lè ko lára aláìsàn. Wọn ríi wípé ki àwọ̀ ara ènìyàn bó tàbí ṣí dànù kò wọ́pọ̀, èyí sì lè ṣẹlẹ̀ sí ènìyàn kàn nínú ènìyàn mílíọ̀nù kan to lo òògùn yíì l’ọdun kan.
Ìwádìí na fi mu’le pé aláìsàn kan, ọmọ ọdun àádọta bẹrẹ síí padanu awọ̀ ara rẹ̀ lẹhin tí ó lo òògùn yíì fún ọsẹ méjì, ṣugbọn arábìnrin náà ṣẹṣẹ ṣe iṣẹ abẹ ni àsìkò naa ni, eyi si le faa.
Kódà wọn ṣàlàyé pé aláìsàn náà n lo òògùn fún ifunpa gíga ati aiṣan ito suga.
Iwadi náà salaye pé, botilejepe àwọn èèyàn máà n pàdánù awọ ara lẹyìn ti wón ba lo òògùn Septrin, òògùn yì o si lara àwọn oògún to maa n saba n fa ìpàdánù awọ ara eniyan bayii.
Ìwádìí miran fihàn pe lootọ, àwọn eniyan le bẹrẹ síí padanu awọ ara won leyin ti wón ba lo òògùn Septrin pàápàá laarin awon eniyan ti won ni ààrùn Ibalopọ HIV/AIDS.
DUBAWA ba oníṣègùn òyìnbó, Dókítà Francis Agbaraolorunpo sọrọ. Arákùnrin Agbaraolorunpo ṣàlàyé pé lootọ ni ènìyàn le pàdánù awọ ara lẹyìn ti o ba lo òògùn Septrin sugbọn èyí kò wọpọ.
“Stevens-Johnson Syndrome ni wọn pé ìpalára yíi, sùgbón kò sábà wọpọ. O ṣeéṣe ki aláìsàn náà ti lo òògùn Fansidar tẹlẹ. Báwo ni òògùn na ṣe ṣe onítòhún? Eyi lo fáa ti awa dókítà máà n saba bere ọpọlọpọ ìbéèrè ti àwọn ènìyàn ba wà sì ilé ìwòsan pé oogùn wo ni kò ba wọn lara mú. O léwu gan ki àwọn eniyan bẹrẹ síí fi eru sí àyà àwọn ènìyàn nipa ijamba lilo òògùn Septrin. Lóòótọ́ ìpalára kan ti lilo òògùn Septrin máà n fa niyen, sùgbón kò wọpọ rárá,” dokítà máà lo sọ eyi.
O ṣàlàyé pé ọpọlọpọ nkán ni awon dókítà máà n sakiyesi rẹ ki wọn to sọ pé kì àwón eniyan yàgò fún òògùn.
Arákùnrin Agbaraolorunpo sọ wípé àwọn aisan ti o ti ṣe aláìsàn seyin, òògùn ti won lò pèlú Septrin, ìpara, ibi ti alaisan ti ra òògùn ọ̀ún ati awon oun miran ni wọn máa rò papọ.
“O ṣeéṣe pé ara ẹni ti nkan yín ṣẹlẹ ṣí rí àìsàn nàá gẹgẹbi ajoji, ara si ní láti gbèjà ara rẹ. O le jẹ̀ nítorí àwọn iyato kọọkan, tabi onitoun ló òògùn yi papo pẹlú òògùn miran. Se arabinrin náà rà ipara miran ati beebeelo? O se pataki ki a ṣe iwadii sì oun tó lé ṣokunfa ìpàdánù awọ ara.
“Ti irufẹ nkan báyìí ba sẹlẹ, àwọn ẹgbẹ kan wa ti wón máà n ṣe iwadii sì iru nkan báyìí. Ilè ìwòsan ti nkan yii ti ṣẹlẹ ní láti ṣe ìfitónilétí, ègbé naa sì má wo òògùn naa, àwọn eniyan ti won lò oogun yíì, wón a sì ba ajo NAFDAC ṣiṣe.
Dókítà naa sọ wípé ìpàdánù awọ ara, leyin ti ènìyàn ba lo òògùn Septrin le ṣẹlẹ ṣí eniyan kan ninu ẹgbẹrun méjì.
O kilọ pé kì àwón eniyan máà sọra bi wón ṣe n lo èro alatagba, biotilẹjẹpe gbogbo eniyan lo ni anfaani ati lo èro náà, àwọn eniyan kan máà n ṣiilo.
Dókítà naa fi’kun wípé ki awon eniyan yàgò fún lílò òògùn lai ri dókítà won, ati wípé àwọn eniyan ti dókítà fún ni òògùn, ki wọn fito dókítà leti ti wón ba ri oun tí kò tẹ wọn lọrùn.
“Ti a ba so àwọn ìpalára òògùn fun yin, e o ni lo òògùn kankan ràrá. Ìpàdánù awọ ara yii ni a n pé ni Stevens-Johnson Syndrome, kò sì wọpọ. Ko daa ki èniyàn máà lo òògùn ti dókítà o kọ fun-un.”
Dókítà Qudus Lawal sọ fún DUBAWA pé ìpàdánù awọ ara le ṣẹlẹ ti ènìyàn ba lo òògùn Septrin sugbọn kìíṣe nínú gbogbo ènìyàn.
“O le ṣẹ ipalara fún àwọn èèyàn kan. Kódà, gbogbo àwọ̀ ara alaisan le ṣi danu, oun nì a n pé ni Stevens-Johnson Syndrome TEN.”
Ọrọ keji: Àwọn onisegun oyinbo pelu ẹgbẹ wọn, Nigerian Medical Association (NMA) kọ lẹta sí ijoba apapo kò fi ofin de lílò òògùn Septrin.
Àbájáde ìwádìí: Iró ni. NMA sọ fún DUBAWA pé àwòn ko gbe ìrù ìgbésẹ̀ naa.
Ninu igbohunsafẹfẹ naa, arákùnrin yii sọ wípé àwọn dókítà ati egbé oníṣègùn oyinbo Nigerian Medical Association tí kọ lẹta sí ijoba apapo ki o fopin si lilo oògùn Septrin.
“Dokita naa sọ pé wọn ti bẹrẹ síí kilọ fun àwọn ènìyàn ki wọn ma lo oogun Septrin mọ. Koda, ègbè àpapọ dókítà ni orile-ede Nàìjíríà ti kọ lẹta sí ijoba apapo pe ki wọn fòfin de òògùn yì..”
Sugbon ṣe òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ naa?
Ki a le fi idi ododo múlẹ, DUBAWA kan si Dókítà Bala Audu, eni ti o jẹ ààrẹ ègbé àwọn onisegun oyinbo ni orilẹ-ède Nàìjíríà. Ogbeni Audu so wípé iró to jina sì òtítọ ni. O ṣàlàyé pé kò sí ìgbà kankan tì ègbé náà kọ lẹta sí ijọba apapọ lórí ọ̀rọ̀ yii.
O so wipe, “Iro ni ọ̀rọ̀ yii. Àjọ NMA ò kọ lẹta kankan sí ijoba pé ki wọn fòfin de Septrin. Mi o mo ibi ti e ti gbọ oro yii.”
Akotan
Bíótilẹpe ìpàdánù awọ ara jẹ oun kan to le ṣẹlẹ ṣí èèyàn to ba lo òògùn Septrin, ìwádìí ati oro onimo fihan pe kò wọpọ. Bákan naa, àwọn dókítà ati ajọ NMA kò kọ lẹta kankan sí ijoba apapo kò fòfin de òògùn Septrin.