YorubaEconomyFact Check

Ṣé lótìtọ́ ni pé 70% ọmọ Nàìjíríà ni kò le kà’wé?

Getting your Trinity Audio player ready...

Àhesọ: Aṣàmúlò X kan sọ pé ìdá àádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún (70 per cent) àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni kò le kà’wé.

Ṣé lótìtọ́ ni pé 70% ọmọ Nàìjíríà ni kò le kà’wé?

Àbájáde Ìwádìí: Irọ́! Dátà láti ẹ̀ka ètò ẹkọ àpapọ̀ (Ministry of Education) fi ìṣirò iye àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí kò le kà’wé sí ìdá-kànlélọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún (31 per cent).

Ìròyìn Lẹ́kùńrẹ́rẹ́

Nínú ìjà tó ń lọ lọ́wọ́ láàárín Aṣòfin Natasha Apoti àti Godswill Akpabio, Ààrẹ Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin, fídíò kan jáde lórí ẹ̀rọ ayélujára, tí ó ń fi hàn pé àwùjọ àwọn obìnrin ní ìpínlẹ̀ Kogi péjọ ní ìgbìyànjú láti yọ Aṣòfin Natasha nípò.

Nígbà tó ń fèrò rẹ̀ hàn nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà, Shehu Sadiq, aṣàmúlò X, sọ wípé àwọn obìnrin tó wà nínú fídíò náà kò lè kà tàbí kọ ìwé ló mú ìkùnà bá ìjọba tiwa-n-tiwa. Bákanáà ló wípé ó lé ní ìdá àádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún (70 per cent) àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí kò le kà’wé

Ṣé lótìtọ́ ni pé 70% ọmọ Nàìjíríà ni kò le kà’wé?

A screenshot of Sadiq’s X post. Photo Source: X.

Àtẹ̀jíṣẹ́ Sadiq ṣẹ̀dá àríyànjiyàn tó gbóná láàrin àwọn aṣàmúlò mìíràn. Nígbà tí àwọn kan ń jiyàn lọ́nà tó yàtọ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn mìíràn, bíi @UchennaObi36947, kọ̀wé pé:

“Mo gbà pẹ̀lú rẹ, ọ̀rẹ́ mi rere, ṣùgbọ́n o gbọ́dọ̀ mọ̀ pẹ̀lú pé ìfihàn jẹ́ ara ẹ̀kọ́, àti pé 90% àwọn ènìyàn àríwá kò ní ìmọ̀, àti pé 70% nínú 70% àwọn aláìmọ̀wé orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí o mẹ́nu bà jẹ́ ará àríwá náà.”

Aṣàmúlò mìíràn, @brenokwaraji, sọ pé nọ́mbà náà ga ju bí Sadiq tí wí lọ: “90% lóòótọ́. Díẹ̀ nínú àwọn tó ní PhD tún wà nínú ẹ̀ka yìí, ” ó dahùn.

Ìgbìyànjú láti tàn’mọ́lẹ̀ sórí àhesọ yii ló jẹ́ kí DUBAWA ṣe ìwádìí yìí. 

Ìfìdíòdodomúlẹ̀

Àìmọ̀wé kì í ṣe nípa kíkà àti kíkọ nìkan. Ó sábà máa ń jẹ́ àbájáde àwọn ọ̀rọ̀ tó jinlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àìní àfààní tó dára sí ẹ̀kọ́ àti àwọn ipò ìgbé ayé tó le. Òṣì máa ń jẹ́ kí ó burú sí i, àti pé àwọn ohun àwùjọ bíi ọkùnrin àti obìnrin, ẹ̀yà, àti kíláàsì náà tún jẹ́ kí nkan le sí i.

Ìṣirò ọdún 2022 tí ẹ̀ka ètò ẹkọ àpapọ̀ (Ministry of Education) gbé jáde pe ìpele àìmọ̀wé orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lọ́wọ́lọ́wọ́ ní ìdá 31 (31 per cent). Lọ́dún 2025, àwọn oníròyìn àti ìjọba àpapọ̀ ṣì ń lo dátà yìí nítorí pé kò sí àkójọfáyẹ̀wò tuntun lẹyìn èyí. 

 Ní ìdá kejì, ìṣirò ìyè ènìyàn tó lè kàwé ní Nàìjíríà je ìdá òòkàndíláàdọ́rin (69%). Gẹ́gẹ́ bí ààjọ development aid ṣe wí, èyí jẹ́ èlé ìdá 17 (17%) láàrin ọdún karùndínlógún.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àkójọfáyẹ̀wò wọ̀nyí lè ti pẹ́ jù láti fi òtítọ́ hàn ní àwùjọ Nàìjíríà lónìí, wọ́n jẹ́ ohun tí ó wà nílẹ̀.

Ṣé lótìtọ́ ni pé 70% ọmọ Nàìjíríà ni kò le kà’wé?Àfihàn ìwọ̀n ìmọ̀-kọ̀wé àti àìmọ̀wé ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Oríṣun àwòrán: Dataphyte.

Àkótán

Ẹ̀sùn pé ó lé ní 70% àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí kò mọ̀wé jẹ́ èké. Àwọn àkójọfáyẹ̀wò àìpẹ́ láti ọ̀dọ̀ ẹ̀ka ètò ẹkọ àpapọ̀ fi ìṣirò iye náà sí 31%.

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Back to top button
Translate »