Fact CheckHealthYoruba

Ǹjẹ́ ìhu-ehín ọmọdé le ṣ’ekú pa ọmọ ọwọ́?

Getting your Trinity Audio player ready...

Ahesọ: Olumulo ikanni TikTok kan, Ajoke (@harjohkeh001) sọ wípé ìhu-ehín lo ṣ’e ikú pa ọmọ òun.

Ǹjẹ́ ìhu-ehín ọmọdé le ṣ’ekú pa ọmọ ọwọ́?

Abajade iwadii: Irọ ni. Àwọn dokita to n ṣe ìtọ́jú ọmọdé ṣ’alaye pe ìhu-ehín wa l’ara idagbasoke ọmọ, kii fa iku. Bakan naa, iwadii filelẹ pe ìhu-ehín ò le ṣ’eku pa ọmọ, ṣugbọn ààmì apeere ìhu-ehín le yọri si iku ti wọn kò ba ṣe ìtọ́ju omo naa daadaa.

Ekunrere alaye

Ehín wa lara ẹ̀yà ẹ̀da onje ara ti o maa n ran eeyan lọwọ lati ge ounje si keekeekee tabi ki ounje kunna ni ona ti o ma see gbemi. Ọmọde a maa hu ehín ni igba ti ehín ba bere sii jade lati èrìgì. Ni ọpọ ìgbà, a maa bere sii ri apeere ehín lati ọmọ oṣù maruun siwaju.

Ní ọjọ́ ketadinlogun oṣù karun, olumulo ikanni TikTok Ajoke @harjohkeh001 sọ wipe ìhu-ehín lo ṣ’eku pa ọmọ òun. O ṣ’atunpin fọnran kan to ṣ’afihan ibi ti o ti n jo pelu ọmọ naa, leyin iṣeju aaya díẹ̀, a ri ibi ti o ti gbe omo naa si ẹsẹ, ti ọmọ naa n gba itọju.

O kọ eyi si ori fonran naa, “Bi enikeni ba wa mi wa, ẹ sọ fun wọn pe mo padanu Mudashir mi si ìhu-ehín. Ọpọlọpọ olumulo lo wo fonran ọ̀ún, ti wọn ṣ’atunpin rẹ̀.

Àwọn kan ba k’ẹdun, wọn si f’ikun pe lootọ, ìhu-ehín le la ẹ̀mí lọ. DUBAWA ṣ’akiyesi pe ariyanjiyan wa lori ahesọ naa.

Olumulo ikanni ibaraẹniṣọrẹ, Facebook, Priscilla Nwogu Onyi beere, “Ṣe o ṣeeṣe ki ìhu-ehín pa ọmọde. Ǹjẹ́ ó da ọ l’ójú pe ìhu-ehín ni tabi aisan sepsis. Aarun sepsis maa n se iku pa omode lopo igba, o se pataki fun obi lati kiyesara. Ki Ọlọrun tẹ ọmọ naa s’afẹfẹ ire.”

Olumulo TikTok kan @Khadija sọ wipe ni ọdun 2013, òun padanu ọmọ òun ọkunrin si ìhu-ehín. “Ní ọdún mẹsan ṣ’ẹyin, ọmọ mi okunrin bẹrẹ sii hu ehín ni ọmọ oṣù mẹrin, eyi si la ẹ̀mí lọ.”

Arakunrin kan lori ikanni TikTok @Daddygold01 sọ pe òun ni iru iriri yii, “Ọmọ mi obinrin ku ni igba to n ṣe ehín.”

Ṣugbon arabinrin kan bere ibeere pataki pe ṣe lootọ ni ìhu-ehín le fa iku fun ọmọde. “Ku ọrọ ọmọ, ṣugbọn ṣe dọkita lo sọ pe ìhu-ehín lo ṣ’eku pa ọmọ rẹ? Ma binu fun ibeere mi, ṣugbọn mo fe mọ̀.”

Gẹgẹbi ojuṣe wa ni DUBAWA lati fi ojulowo iroyin àti alaye s’ita, a ṣe iwadii lori ọrọ naa.

Ifidiododomulẹ

Ti ọmọde ba bẹrẹ sii hu ehín, awon aami apeere ihu-ehí a farahan laarin ojo si ọ̀sẹ̀ díẹ̀. Ọmọde a hu ehin laarin odun maarun akọkọ aye rẹ̀.

Akọsile kan lori WebMD ṣ’alaye pe ifarahan ami apeere ihu-ehín yatọ lara ọmọ si ọmọ. Erigi ọmọ le wu, omo mii a kanra, a sii ma ke, o le ẹ ki ara gbona díẹ̀ si niwọnba, ọmọ a fe ge nkan tabi eeyan jẹ, o le maa da itọ́, eyi le fa ki ara omo naa su, o le maa wúkọ́, o le fi bere sii f’ọwọ pa ẹkẹ tabi etí rẹ̀, a fi ọwọ s’ẹnu ni gbogbo igba, iyipada a tun de ba bi o ṣe n jẹun tabi sùn.

Atejade MedicineNet f’ikun wipe ìhu-ehín le mu ki erigi wu, o si le fa ikanra ṣugbọn kò le fa igbona, ìgbẹ́ gbuuru, ikọ tabi ooru ara. O ṣ’alaye pe biotilejepe awon iwadii kan menuba igbona ihu-ehin, kiise igbona to m’ewu dani.

Awon dokita t’o ń ṣe itọju ọmọde sọ fun DUBAWA pe ìhu-ehín le mu irora dani pelu igbonara díẹ̀, ṣugbọn kò le la ẹ̀mí lọ.

Amina Abubakar, dokita kan ni ile iwosan itoju ọmọ ati iya ni ipinle Niger, Jummai Babangida Maternal and Child Hospital sọ wipe, “Ọmọ miran le ni irora, irora yii si le mu ki ooru ara leke. Ti obi o ba foju to ọmọ naa, ati ti ọmọ naa o ba gba itọju to yẹ́, o le fa iku. Ṣugbọn, a ò le sọ pe ìhu-ehín ló fa ikú iru ọmọ bẹ́ẹ̀.”

Dokita agba ni ile iwosan olukọni ti ile-ẹkọ agba ilu Uyo, Frances Okpokowuruk faramọ oun ti Amina sọ siwaju, ó ṣ’alaye pe ìhu-ehín wa lara idagbasoke ọmọ, ti ara ọmọ ba si gbona díẹ̀, eyi ṣẹlẹ̀ nítorí erigi to wu ni. 

“Ọmọ ọ̀ún le bẹrẹ sii ke, erigi a maa yun, o si le maa da itọ́. Awon nkan wonyi le ṣẹlẹ̀.” Ṣugbọn, awọn ihuwasi ọmọ l’àsìkò yii le fi ọmọ naa s’inu ewu akoran, ti awon òbí le ro pe ìhu-ehín ni.

“Ní asiko yii, erigi a maa yun ọmọ, o le mu orisirisi nkan si ẹnu. O tun bọsi asiko ti ọmọ a bẹrẹ sii ra, o si seese ki omo mu nkan nilẹ k’o fi si enu. Ni igba miran, idọti le wa nilẹ, ọmọ a si mu s’enu.

“Ti agbegbe ọmọ ò ba wa ni ìmọ́tótó, ọmọ a ni akoran kokoro ailefojuri, àwọn eeyan a ni ìhu-ehín lo pa ọmọ naa. Rara, kiiṣe ìhu-ehín ṣugbọn awon akoran lataara idọti ti ọmọ fi si enu lo fa igbe gbuuru.”

Akotan

Ìhu-ehín ò le fa iku fun ọmọde. Awọn dokita ọmọde ati iwadii fihan pe ìhu-ehín wa l’ara idagbasoke omo, kii si fa iku. Ṣugbọn ti a ko ba kiyesara tabi ṣe itoju ami apeere ìhu-ehín, omi le teyin wọ igbin l’ẹnu.

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Back to top button
Translate »