YorubaFact CheckPolitics

Ǹjẹ́ olórí ile igbimọ aṣofin Eko paṣẹ fun ara ìlú ki won dìbò fun oludije biotileje ọ̀daràn?

Getting your Trinity Audio player ready...

Aheso: Olumulo ikanni X ṣ’atunpin fonran kan nibi ti Mudashiru Obasa, eni ti o je olori ile igbimọ asofin Eko ti n parowa fun ara ilu ki wọn dibo fun oludije labẹ asia egbe oselu APC biotilẹjẹpe onitoun ti daran ri. 

Ǹjẹ́ olórí ile igbimọ aṣofin Eko paṣẹ fun ara ìlú ki won dìbò fun oludije biotileje ọ̀daràn?

Abajade iwadii: Aṣinilọna ni aheso naa. Fọnran naa ṣ’afihan Obasa ti o n parọwa fun awon omo egbe oselu  APC ki won ṣe atileyin oludije ti egbe naa ba fakale lai naani oun ti won gbagbo.

Ẹkunrẹrẹ àlàyé

Olumulo ikanni X @Omoelerinjare ṣ’atunpin fonran kan laipe yii, pe Mudashiru Obasa, olórí ilé ìgbìmọ̀ aṣofin Èkó ti pàṣẹ pe ki àwọn ara ilu dìbò fún oludije ẹgbẹ́ oṣelu onigbale All Progressive Congress (APC), bi onitoun ba tile je ọ̀daràn.

Akori ti olumulo naa fi ṣ’atilẹyin fonran ka bayi, “Ẹnikẹni ti ẹgbẹ APC ba mu silẹ lati ṣe aṣojú rẹ̀ ninu ìbò, boya odaran ni tabi bẹẹkọ, ti ẹgbẹ́ ba ti yan onítọ̀ún, kò si iyemeji lori ọ̀rọ̀ naa, ayafi ti o ba fẹ fi egbe silẹ.”

DUBAWA ṣ’akiyesi pe awon olumulo miran bẹrẹ sii bu ẹnu àtẹ́ lu ẹgbẹ òṣelu APC lori ọrọ ti Obasa sọ, àwọn miran si sọ pe aṣigbọ ni.

“Ko sọ pe ti onitoun ba jẹ ọ̀daràn. Oun ti o sọ ni wipe, onitoun da tabi ko da. Nkan ti oro re tumo si niyen.” @Phemoragh lo dahun bayi.

Olumulo miran @Ashman_babane sọ wipe: “Naijiria ti bajẹ. Àwon eniyan wọnyi n jo, won si n ṣ’ajọyọ pelu awon ti o n ba aye wọn jẹ.”

DUBAWA woye pe o ṣe pataki ki a se iwadii lori ahesọ yii nitori iha ti o kọ si ọ̀rọ̀ òṣèlú ni orile-ede yii ati wipe, itumọ miran ni wọn fun ọ̀rọ̀ olori ile igbimo aṣofin.

Ifidiododomule

A ṣe itopinpin kókó ọ̀rọ̀ lori erọ igbalode Google ati awon ojulowo iwe iroyin ni Naijiria ki a le ṣ’amudaju boya looto ni Obasa fọ gbolohun ọ̀ún tabi bẹẹkọ. Ṣugbọn, a kò ri iroyin kankan.

DUBAWA ṣ’akiyesi pe fonran ti won ṣ’atunpin si ikanni X, lati ikanni TikTok ni wọn ti mu. Fonran ori TikTok ṣ’afihan ìgbà ti Obasa ṣile iṣé APC ni ijoba ibilẹ Alimosho.

Ọ̀rọ̀ ti Obasa sọ ni Yoruba lọ bayii, “A fa ọmọ ẹgbẹ lẹ, o ni ko da, ṣe o ma pà rẹ̀ ni? Tabi o fe lọ si ẹgbẹ miran? O da, ko da, ti ẹgbẹ ba ti mu eniyan le, o ti da nọọni.”

A rii wipe Obasa o menuba nkankan to niiṣe pelu boya onitọun jẹ odaran tabi eni ti o ṣe ẹ̀wọ̀n ri.

Akotan 

Iwadii DUBAWA fidirẹmulẹ pe aṣinilona ni atejade olumulo ikanni X lori oun ti ogbeni Obasa sọ, èyí wáyé nítorí kò ṣe ogbufọ naa botitọ ati botiyẹ.

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Back to top button
Translate »