|
Getting your Trinity Audio player ready...
|
Àhesọ: Àwọn aṣàmúlò WhatsApp àti Facebook sọ pé Donald Trump ti pàṣẹ fún ìjọba orílẹ̀ èdè Nàíjíríà láti dá Nnamdi Kanu sílẹ̀.

Àbájáde Ìwádìí: Irọ́! Àtúpalẹ̀ DUBAWA fi hàn pé fídíò náà jẹ́ ìṣẹ̀dá AI àti pé ó ní àkóónú ìṣìnà.
Ìròyìn Lẹ́kùńrẹ́rẹ́
Fọ́nran tí aṣàmúlò WhatsApp kan fi ránṣẹ́ ní ẹ̀sùn kan pé Ààrẹ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà (US) tuntunz Donald Trump ti pàṣẹ fún ìjọba orílẹ̀ èdè Nàíjíríà láti gbé Nnamdi Kanu jáde kúrò látìmọ́lé. Fídíò ìṣẹ́jú méjì àti ìṣẹ́jú àáyá mọ́kàndínlógójì fi hàn pé Ọ̀gbẹ́ni Trump wí pé:
“Lónìí, mò ń ké sí ìjọba orílẹ̀ èdè Nàíjíríà láti dá Ọ̀gbẹ́ni Nnamdi Kanu sílẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ẹni tí wọ́n ti tì mọ́lé lábẹ́ àwọn ipò tó gbé ìbéèrè nípa ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn àti ìdájọ́ òdodo. Àtìmọ́lé Nnamdi Kanu ti pẹ́ gan-an, àsìkò sì ti tó fún ìjọba orílẹ̀ èdè Nàíjíríà láti bọ̀wọ̀ fún ìlànà òmìnira àti ìṣàkóso òfin.”
Ọ̀gbẹ́ni Trump, ẹni tí ó ní òun ti wo bí ipò Ọ̀gbẹ́ni Kanu ṣe ń lọ lọ́wọ́ dáadáa, sọ pé ó ti fa ìrora, ìbínú àti ìjákulẹ̀ tó jinlẹ̀ láàárín ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàíjíríà tí wọ́n rò pé ẹ̀tọ́ àti ohùn wọn ti ń di dídènà.
Bákan náà ló ṣ’èdánilóju ìtúsílẹ̀ fún Ọgbẹ́ni Kanu. Lẹyìn náà ló halẹ̀ pé gbogbo ìrànlọ́wọ́ sí ọmọnìyàn Nàìjíríà yóò dẹ́kun.
“Ní báyìí, jẹ́ kí n sọ kedere. Tí ọgbẹ́ni Kanu kò bá di títú sílẹ̀ ní 31, Oṣù kọkànlá, ọdún 2024, ìjọ̀ba mí yóò bẹ̀rẹ̀ ìlànà làti yọ owó, àti ìrànlọ́wọ́ ènìyàn tí à ń pèsè fún Nàìjíríà. Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà dúró fún ìdájọ́ òdodo àti ìjọba tiwa, a sì retí pé àwọn alájọṣepọ̀ wa yóò tẹ̀lé àwọn ìwà kan náà wọ̀nyí.
“Ní àfikún, tí Nàìjíríà kò bá gbé ìgbésẹ yìí, èmi yóò pàdé pẹlú àwọn olùdarí àgbáyé mìíràn láti jíròrò síwájú síi, pẹlú àwọn ìjìyà sí Nàìjíríà. Ayé ò gbọdọ̀ dúró láìṣe nǹkankan nígbà tí wọ́n tẹ ẹ̀tọ́ àwọn ènìyàn mọ́lẹ̀. Èyí kì í ṣe àtẹ̀jíṣẹ́ ìkórìíra. Ó jẹ́ àtẹ̀jíṣẹ́ ìrètí, ìdájọ́ òdodo, àti ìṣírò. A fẹ́ kí orílẹ̀ èdè Nàíjíríà gbilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè, mo sì gbàgbọ́ pé kíbọ̀wọ̀ fún ìdájọ́ òdodo àti ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn jẹ́ kọ́kọ́rọ́ sí ìdàgbàsókè ọ̀la fún gbogbo ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ẹ ṣeun, Ọlọrun ó sì bùkún Amẹrika.”
Wọ́n ti pín fídíò náà lórí Facebook. Ó ti farahàn lórí àwọn ojúewé bíi Biafra Iconic Warriors, níbi tí ó ti gba àwọn ìwòye tó lé ní 46,000, àti èsì 382.
Ní àfikún, aṣàmúlò Facebook Hichief Sunny Odogwu tún fídíò náà pẹ̀lú pẹ̀lú èsì rẹ̀, ó fi àkọlé rẹ̀ sọ pé: “Ìròyìn ayọ̀: Donald Trump pàṣẹ fún ìtúsílẹ̀ Mazi Nnamdi Kanu kí ó tó di ọjọ́ 31 oṣù kọkànlá. Kú oríire fún gbogbo #Biafrans.”
Pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí fídíò náà ti gbà lórí ẹ̀rọ ayélujára, DUBAWA pinu láti ṣàyẹ̀wò òtítọ́ rẹ̀.
Ìfìdíòdodomúlẹ̀
Olùdarí àwọn ará ìbílẹ̀ Biafra (IPOB), Nnamdi Kanu, ẹni tí wọ́n mú ní June 27, 2021, ní orílẹ̀-èdè Kenya tí wọ́n sì gbé e lọ sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lẹ́yìn náà, ń dojú kọ ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn àti ìwà ipá nípasẹ̀ Radio Biafra rẹ̀, láàrin àwọn mìíràn. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Punch ṣe sọ, Ọ̀gbẹ́ni Kanu ti lò jú ọjọ́ 1,133 lákámọ́ Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìpínlẹ̀ (DSS).
Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, àwọn ènìyàn àti àwọn àjọ ti pè fún ìtúsílẹ̀ Ọ̀gbẹ́ni Kanu. Fídíò tí ó ń tàn kiri lórí ẹ̀rọ ayélujára fi hàn pé Ọ̀gbẹ́ni Trump darapọ̀ mọ́ àwọn ìpè wọ̀nyí.
Síbẹ̀síbẹ̀, DUBAWA ṣe àmì àkóónú ìdààmú nínú fídíò náà, pẹ̀lú ìyàtọ̀ láàrin ọ̀rọ̀ Ààrẹ Trump àti àwọn ìgbésẹ̀ ètè rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe ń sọ̀rọ̀. Bákannáà ni DUBAWA ṣàkíyèsí ipò tí wọ́n gbé àwòrán Ọgbẹ́ni Kanu àti Ààrẹ Tinubu.
Nítorí èyí, a lo InVID WeVerify láti pín fídíò yìí sí abala. Ìwádìí lórí àwọn abala wọ̀nyí tọpinpin àwòrán náà sí ọ̀rọ̀ ìṣẹ́gun Ààrẹ Trump níbi ayẹyẹ ìṣọ́ ìpolongo rẹ̀ tó wáyé ní West Palm Beach, Florida.
Nínú ọ̀rọ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, Ọ̀gbẹ́ni Trump sọ̀rọ̀ nípa àṣẹ ìdìbò ìtàn rẹ̀ àti àwọn ètò rẹ̀ láti “wò” Amẹ́ríkà sàn kí ó sì tún ààlà ṣe. Kò sí àkókò kankan tí ó mẹ́nuba Nàìjíríà tàbí Nnamdi Kanu.
Nínú fídíò tí wọ́n ṣe, wọ́n ṣe Ọ̀gbẹ́ni Trump láti sọ pé, “Tí wọn kò bá gbé Ọ̀gbẹ́ni Kanu jáde lójú kọkànlélọ́gbọ̀n, oṣù kọkànlá, ọdún 2024, ìjọba mi yóò bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ yíyọ ìrànlọ́wọ́ ìṣègùn, ìṣúná, àti ìrànlọ́wọ́ ọmọnìyàn kúrò ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.”
Lẹ́yìn tí a wo fọ́nrán yìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àìṣedéédé fihàn pé ayédèrú (deepfake) ní fídíò yìí. Fún àpẹẹrẹ, àṣìṣe ọjọ́. Ọgbọ̀n ọjọ́ ló wà nínú oṣù kọkànlá, kìí ṣe òkànlélọ́gbọ̀n bíi fọ́nrán ọ̀hún ṣe wí.
Bákan náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó borí nínú ìdìbò ààrẹ làìpẹ́ yìí, Ọ̀gbẹ́ni Trump ṣì nílò láti wà ní ipò ààrẹ rẹ̀ tó ṣì di Jan. 20, 2025, kí ó tó má a pàṣẹ.
Àkótán
Àwọn ìyàtọ̀ wọ̀nyí dábàá pé wọ́n yí fídíò náà padà lórí ẹ̀rọ ayárabíàṣá nípa lílo àwọn irinṣẹ́ ìjìnlẹ̀. Ayédèrú ní fọ́nrán ọ̀hún.
Juliet Buna ló kọ́kọ́ ṣ’àkọsílẹ ìwádìí yìí lé’dè gẹ̀ẹ́sì, tí Sunday Awóṣòro sì túmọ̀ rẹ̀ sí ède Yorùbá.




