|
Getting your Trinity Audio player ready...
|
Láípẹ̀ yii, olumulo ikanni Facebook, From Quarks to Quasars, sọ wipe ara eniyan ni ọkàn keji, isalẹ ẹsẹ̀ lo si wà.
“O ni ọkàn keji, o wa ninu iṣan ẹsẹ̀ rẹ,” olumulo ikanni ibaraenisọrọ yii lo sọ eyi.
Olumulo naa f’ikun wípé ọkàn keji yii ni iṣan soleus ti o maa n gbe ẹ̀jẹ̀ lati ẹyin ẹsẹ lọ sí aya.
“Ọkàn keji” ti olumulo naa fi ṣ’apejuwe iṣan ẹsẹ̀ lo fa iruju ti àwọn eeyan si n bere boya ootọ ni ọrọ naa tabi irọ.
“Ko si bi mo ṣe le gba ọrọ yii gbọ. Kò si ọkàn kejì ninu iṣan ẹsẹ wa,” Maria Bautistae, olumulo Facebook lo sọ bayi.
“Boya o wa lara oun ti wọn fi ma n sọ wipe awon ti iṣan ẹsẹ wọn tobi julọ, lo maa n pẹ laye,” Sue Zie, lo sọ eyi.
Okan lara iṣe DUBAWA ni lati tako ìròyìn ofege nipase gbigbe ojulowo iroyin, ati lati rii wipe awon eeyan mọ ododo oro nipa ilera ara won, nitori eyi a ṣe iwadii lori “ọkàn keji”, ati pataki ọkàn keji lori ilera ara.
Ọkàn keji ninu ara
Iṣan ẹṣẹ̀ ni wọn pe ni “ọkàn keji”. Wọn kọ maa fi oruko naa pe ni, o wa ni ọwọ isalẹ ẹyin ẹsẹ̀, lati orúkún.
Orisi iṣan lo ko jọ, paapaa iṣan soleus, iṣan t’o l’agbara ni, o si wa ninu iṣu ẹsẹ̀, oun lo maa n ran eniyan lọwọ lati rin ati lati s’are. Ìṣọ̀n ẹ̀jẹ̀ abọ naa wa lara eya yii, o si maa n gbe ẹjẹ lati ẹsẹ si ọkàn.
Àwọn iṣan wọnyi maa n ran eya isọn ẹ̀jẹ̀ l’ọ́wọ́, o maa n gbe ẹjẹ lo s’oke ni.
Ti iṣan ẹyin ẹsẹ̀ ba kórajọ, a fun iṣọn opo ẹjẹ pọ s’oju kan, a si mu ki ẹjẹ wọ inu ọkàn botiye.
Iwadii kan ti won gbejade ni National Library of Medicine, àwọn onimo nipa bi ọkàn ti n ṣ’iṣẹ fidirẹmulẹ pe iṣan eyin ese, maa n gbe ẹ̀jẹ̀ lati isale ara lọ sinu ọkàn.
Iṣan soleus gangan lo lagbara ju ti o si maa n gbe ẹjẹ julọ lọ sibi ọkàn, eyi safihan pataki iṣan yi ninu ayika ẹjẹ laago ara eniyan.
Bawo gaan ni iṣan soleus ṣe n ṣiṣe gẹgẹbi ọkàn keji?
Iṣan ẹsẹ̀ n sise bi oofa leyin ẹsẹ̀. Ti eniyan ba n rin, s’are tabi duro lori ìka ẹsẹ̀, iṣan ese a korajọ, a si fa ẹjẹ sinu ọkàn.
Iṣan ẹsẹ̀ ti a n pe ni ọkàn keji yii n ṣ’iṣẹ papọ pelu ọkàn lati mu ki ẹjẹ kaari ago ara eniyan.
O maa n gbe ẹjẹ̀ lati inu ẹsẹ̀ lọ inu aya. Ti iṣan ẹsẹ̀ yii o ba ṣ’iṣẹ daadaa, ẹjẹ le korajo sibi orúkún lo si isale ese, eyi si le fa wahala fun opo ẹjẹ.
Pataki iṣan ese
O maa n ran ni lowo lati rin, naro ati duro: iṣan ese wulo fun irin, ki eeyan sare ati fifo. O maa n fu ni lokun lati rin si waju si. Akosile kan lori Cleveland Clinic ṣ’agbekalẹ rẹ pe iṣan ẹsẹ̀ a je ki eeyan rin, sare, fo, ati rin s’iwaju.
O tun maa n ran ni lọwọ lati na ika ẹsẹ̀ soke, ati lati na ẹsẹ̀. O n ṣiṣẹ fun inaro, iduro, fun ese l’okun, o si maa n ran eyan lọwọ ki o duro deede ki o ma baa ṣubu tabi ta’sẹ̀.
Ẹjẹ a kaari ara: Iṣan ẹsẹ̀ maa n gbe ẹjẹ̀ kaakiri ago ara. Bi eniyan ṣe n gbẹsẹ, ni iṣan yii a fun ìsọ̀n ẹjẹ, a si gbe ẹjẹ lo inu ọkàn. Nitori idi eyi ni wọn fi n pe iṣan ẹsẹ ni ọkàn keji.
Cleveland Clinic ṣ’alaye pe iṣan ese maa n sise bi oofa adayeba. Bi a se n rin tabi gbe ese ni ẹjẹ n lo lati ẹsẹ̀ si inu ọkàn.
Iwadii fihan pe ti iṣan ese ba sunki leekan soso, o le fa ida ogoji si ogota ẹjẹ si inu ìsọ̀n ẹjẹ. Ki eeyan gbe ese s’oke ti a ba n rin maa mu ẹjẹ yika gbogbo ara.
A dẹkun ipalara: Ise kan ti iṣan ese maa n se ni pe a maa dekun ki eeyan ma ni ipalara tabi egbo. iṣan yii kii se fun irin tabi ninaro nikan, o maa n dabobo ẹsẹ̀ ati ara kuro lowo aiṣan.
Iṣan ese yii tunbọ maa n dekun ara wiwu ati didi ẹjẹ. Ti iṣan ese yii o ba sise fun igba pipe, ayika ẹjẹ yii a dawọ duro, o si le fi eeyan sinu ewu. Iwadii kìlọ̀ pe aisedede isan ese le mu ki ẹjẹ di sinu isọn ẹjẹ.
Nitori eyi, awon onimọ iṣegun oyinbo maa n gba imoran pe ki a se ere idaraya, rin loorekoore, sare, gbera kuro loju kan ki isan ese le sise daadaa. Nigba ti iṣan ba kan ara wọn, awọn isan wonyi a ko ẹjẹ to korajọ si ẹsẹ kuro, wọn yoo da a pada sinu ọkàn wa, a si dekun wahala bi ẹjẹ didi.
Ọrọ lẹnu onimọ
DUBAWA ba Michael Ogirma sọrọ, eni ti o je ojogbon nipa ilera eegun ara ni yunufasiti Ahmadu Bello. O ṣ’alaye pe isan ese ni won pe ni ọkàn keji nitori awon opo ẹjẹ wa ninu isan wonyi.
O ni, “Bi o se n rin kaakiri si, bee ni isan ese a maa kan ara won. Isan ese maa n gbe ẹjẹ lati ese pada lọ si ọkàn.”
Dokita naa tun f’ikun wipe ti eniyan o ba maa rin kaakiri, opo ẹjẹ to wa ninu isan ese le kuro nibe ki o lo di opo ẹjẹ ti o n gbe ẹjẹ lo si inu ọkàn. O gbani niyanju lati ma lo isan ese daadaa ki eyan ma baa fori lugbadi aisan.
DUBAWA ba dokita Lateef Thanni sọrọ, ọjọgbọn nipa ilera egungun ni Ile Eko Giga Yunifasiti Olabisi Onabanjo. A se wadi lowo re pe bawo ni awon eniyan, paapaa awon ti o maa n joko tabi duro fun igba pipẹ, se le fi okun si isan ese won ki won ma baa ṣ’aisan. O gba imọran pe ki awon eniyan dekun jijoko fun wakati meji leekan.
“Bi o ba ti e ma joko fun igba pipe, maa fi ika ese re ta ilẹ̀, tabi maa fi ese re, ki ẹjẹ le pada sinu ọkàn,” dokita naa lo sọ eyi.
O f’ikun wipe sise ere idaraya le dekun ailera, o si gba imọran pe ki eniyan maa mu omi daadaa, rin loorekoore ati se ere idaraya leemeta l’ọsẹ.
Akotan
Kiiṣe irin nikan ni a maa n fi isan ese se, o sise gegebi ọkàn keji fun eniyan, a maa fa ẹjẹ pada si inu ọkàn, ko si ni je ki ọkàn wa ninu idamu. Sise ere idaraya ati ki eeyan ma joko sii s’ibi kan maa n ran ilera ara lọwọ.




