Fact CheckMainstreamYoruba

Aṣinílọ́nà! Ẹka ìjọba NOA kọ́ ló ṣẹda atẹjade akalekako tó gbani nímọ̀ràn nípa àìléwu lásìkò òjò

Aheso: Atẹjade akalekalo kan lori ìkànnì ibaraẹnisọrọ WhatsApp ni àwọn ènìyàn sọpẹ ó wá láti ọdọ ẹka ìjọba National Orientation Agency.

Aṣinílọ́nà! Ẹka ìjọba NOA kọ́ ló ṣẹda atẹjade akalekako tó gbani nímọ̀ràn nípa àìléwu lásìkò òjò

Abajade iwadii: Aṣinílọ́nà. Àkànpọ̀ ìròyìn òfegè ati aṣinilọna ni atẹjade náà, kìí sì ṣe ẹka ìjọba NOA lo ṣẹda rẹ.

Ìròyìn lẹkunrẹrẹ

Ni orilẹ-ede Naijiria, ojo arọrọda máa n saba rọ̀ laarin oṣù kẹrin sí oṣù kẹwa botilẹjẹpe owara òjò le rọ ni àwọn agbègbè kọọkan ni ìgbà míràn.

Laipe yìí, atẹjade akalekako kan ni a ṣ’abapade lori ìkànnì ibaraẹnisọrọ WhatsApp. Àwọn to n ṣ’atunpin rẹ ṣàlàyé pé ẹka ijoba NOA lo ṣẹda atejade náà kí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà le wa ni àìléwu lásìkò òjò.

Àtẹ̀jáde náà gbà awọn eniyan nímọ̀ràn pe kí wọ́n yàgò fún àwọn oun èlò bíi ẹrọ ibaraẹnisọrọ tabi fóònù alágbèéká, ẹrọ amohunmaworan, ati beebeelo ti òjò arọrọda ba n rọ̀.

Aṣinílọ́nà! Ẹka ìjọba NOA kọ́ ló ṣẹda atẹjade akalekako tó gbani nímọ̀ràn nípa àìléwu lásìkò òjò
Àwòrán atẹjade akalekako náà.

Nítorí ìtànkálẹ̀ atejade náà àti wípé ọpọlọpọ ènìyàn ló fẹ mọ boya òtítọ ni ọrọ náà, eyi lo je ka ṣ’ewadii ọ̀rọ̀ yìí.

Ifidiododomule

A kàn sí David Akoji, olùdarí ẹka ìjọba NOA, o sì ṣ’àlàyé pé atẹjade yìí kò ti ọdọ wọn wá. Ẹka ìjọba náà sọ pé àwọn ènìyàn máa n ṣ’atunpin atẹjade akalekako yìí lorekoore pàápàá lásìkò òjò.

”Ni àsìkò òjò bayii ni atejade naa máa n tànká. Àwa kọ́ la ṣẹda rẹ,” ìdáhùn NOA si ìbéèrè wa nìyí.

Àtẹ̀jáde tó gbani nímọ̀ràn yìí, mẹnuba ọpọlọpọ oun ti a ni láti yàgò fún lásìkò òjò, èyí ló fàá tí a fí ṣe ìwádìí wà lórí ìsòrí kọọkan.

Ọ̀rọ̀ kinni: Máṣe lo ẹ̀rọ fóònù alágbèéká ti òjò arọrọda ba n rọ̀.

Aṣinílọ́nà! Ẹka ìjọba NOA kọ́ ló ṣẹda atẹjade akalekako tó gbani nímọ̀ràn nípa àìléwu lásìkò òjò

Àbájáde ìwádìí: Aṣinilona ni ọrọ yìí.

Èsì itopinpin kókó ọ̀rọ̀ lórí ayélujára fihàn pé ìwé ìròyìn India Today ti ṣ’ayẹwo ọrọ náà, wọn sì sàlàyé pé ẹ̀rọ fóònù alágbèéká ko ni ounkoun láti ṣe pẹ̀lú mọnamọna tàbí àrá, àti wípé a lè lo fóònù wa ni ìgbà ti òjò baa n rọ̀.

Àjọ to n rísí ọrọ ìyípadà ojú ọjọ ni orile-ede Amerika National Weather Service, ṣ’àlàyé ninu ìtọ́nisọ́nà rẹ̀, pé a le lo ẹrọ fóònù alágbèéká ti àrá ba sán. ìtọ́nisọ́nà náà ni ki a ma ṣe lo ẹrọ kọmputa ati tẹlifóònù olókùn.

“Àrá tabi mọnamọna le gba awọn ila kọọkan koja, pàápàá ní ìgbèríko. E yàgò fún àwọn ohun èlò tó n lo iná, bíi tẹlifóònù olókùn, àyàfi tí o ba ṣe dandan (ẹrọ fóònù alágbèéká ṣee lo). Ewú n bẹ ti o ba lo ẹrọ kọmputa, ti okun ina ba wa lara rẹ.”

Ìwádìí awọn omowe lori ààyè ayélujára ResearchGate jẹrisi ọrọ àjọ náà.

Ọ̀rọ̀ keji: Má ṣe lo ẹrọ amohunmaworan ti òjò arọrọda ba n rọ̀.

Aṣinílọ́nà! Ẹka ìjọba NOA kọ́ ló ṣẹda atẹjade akalekako tó gbani nímọ̀ràn nípa àìléwu lásìkò òjò

Àbájáde ìwádìí: Òtítọ́ ọ̀rọ̀ ni.

Àkọsílẹ TheCable ṣàlàyé pé ìyípadà ojú ọjọ sódì, tabi òjò arọrọda le mú kí ẹ̀rọ amohunmaworan má ṣiṣẹ daada. Eyi ni won n pe ni ‘rain fade’

Ẹka ijoba Amerika to n rísí ọrọ ààbò, US Department of Homeland Security, ṣe ikilọ pé kí àwọn ènìyàn má ṣe lo oun èlò tí wọn fi sí inú iná ti àrá ba n san tàbí ti mọnamọna ba bo oju ọ̀run.

Ẹka náà gbani nímọ̀ràn pé kí a lo àwọn oun èlò idaabobo sí ilé wa ki a ma se ri ikọlu. 

Ọ̀rọ̀ kẹta: Máṣe lo digi tabi oun èlò gilasi ni ìgbà ti òjò arọrọda ba n rọ.

Aṣinílọ́nà! Ẹka ìjọba NOA kọ́ ló ṣẹda atẹjade akalekako tó gbani nímọ̀ràn nípa àìléwu lásìkò òjò

Ìwádìí: Ko sí ẹrí tó daju

Ni igba tí a ṣe ìwádìí wà, a ko ri ìròyìn tàbí àkọsílẹ kankan tó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pe lílo digi tàbí gilasi ni àsìkò òjò mu ewu dani.

Ọ̀rọ̀ kẹrin: Ma se wẹ̀ ní ìgbà ti òjò ba n rọ.

Aṣinílọ́nà! Ẹka ìjọba NOA kọ́ ló ṣẹda atẹjade akalekako tó gbani nímọ̀ràn nípa àìléwu lásìkò òjò

Àbájáde ìwádìí: Aṣinilọna ni oro yi.

Àjọ to n rísí ọrọ ìyípadà ojú ọjọ náà gbani nímọ̀ràn pé kí awọn ènìyàn yàgò fún wiwẹ ni igba ti àrá ba n san, kìíse ti òjò ba n rọ.

Àkótán

Àtẹ̀jáde akalekako tó n gbani nímọ̀ràn lórí àìléwu lásìkò òjò jẹ àkànpọ̀ iró àti ọrọ aṣinilọna, ko sí wa láti ọdọ àjọ NOA.

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Back to top button
Translate »