| 
                          Getting your Trinity Audio player ready...
                       | 
Ẹkunrẹrẹ alaye
Ni oṣù kẹsan ọdún 2025 ni a gbọ iroyin pe aarun Ebola tun ṣ’ẹyọ ni orilẹede Congo ti awon eeyan mejilelogoji si ti jade laye lataari aarun naa.
Igba kerindinlogun ti aarun yii ti bẹ si’lẹ́ lorileede naa re leyin ti won kọkọ sawari aarun naa ni odun 1976.
Nitori ewu to rọmọ aarun Ebola yii, ijoba Naijiria ti gbe awon igbese kan lati daabobo ara ilu ki won ma baa f’ori lugbadi aarun buruku yii. Awon igbese naa a dekun alaisan ti o ba fe wo orileede Naijiria lati awon ilu ti aarun yii ti tankale.
O se pataki ki a ranti pe ni ọdún 2014, arakunrin kan Patrick Sawyer omo ilu Liberia gbe aarun yi wo orileede Naijiria ni papako ofurufu ilu Eko ti eeyan mejo si jade laye.
Laipe yii, àwọn kan bẹrẹ sii gbe ìròyìn pe aarun Ebola ti wọ orileede Naijiria, sugbon ijoba fi araalu l’ọkan balẹ pe aririnajo meji ti won furasi ti se idanwo ni ile iwosan, esi idanwo si fi han pe awon eeyan wonyi ò ni aarun Ebola rara.
Sibẹ o se pataki ki onikaluku mọ nipa aarun Ebola yii, apeere aisan naa ati oun ti o ni lati ṣe ki o le wa ni ailewu aisan yii.
Kini aarun Ebola?
Kòkòrò aarun Ebola lo maa n ṣ’eda aarun Ebola. Ẹ̀yà meta lo ma n saba be sile ni ile adulawo, akọkọ ni Sudan ti ekeji rẹ si n jẹ Zaire, eketa ni Bundibugyo.
Aarun Ebola ko saba wọpọ lawujo eeyan ṣ’ugbọn o maa n tete ṣ’eku pani. Eniyan le f’ori lugbadi aarun yii t’o ba fara kan itọ́, ẹjẹ, omi ara tabi ara eranko bii àdán, inaki tabi ẹgbin ti o ni aisan naa lara. Koda, adan ti wọn pe ni ‘fruit bat’ ni o maa n saba ni aisan yii lara.
Ṣugbon o seese ki eeyan ko aarun naa lara alaisan ti o ba fara kan ẹjẹ, igbonse, ìtọ̀, eebi ati oru ara eni ti o ṣ’aisan. Koda, ti eniyan ba f’arakan eni ti o ku lataati aarun Ebola, o le f’ori lugbadi aarun Ebola.
Aami aisan Ebola
Aarun Ebola maa n saba farajọ ofinki, ni opolopo igba, o maa n mu awon apeere wonyi dani:
- Otutu
- Ki o maa re eniyan laise ise asekara
- Iba
- Eniyan a padanu ife ounje
- Ara riro
- Ori fifo
- Ofun a bere sii dun onitoun
Leyin igba díẹ̀, àwọn ami apeere wonyi a bere sii lagbara sii, onitoun a bere sii:
- Ya igbe gbuuru
- A bere sii padanu eje
- O le bere sii bi
- Omi ara alaisan a bere sii gbe.
Ti aarun naa ba ti wọ eniyan lara gaan, o seese ki o ni giri, àwọn eya ara kookan le bere sii daṣẹlẹ, o si le yori si iku.
Ami apeere aarun Ebola maa n farahàn laarin ojo meji si ose meta lara alaisan
Nitori naa, o ṣe pataki ki a daabo bo ara wa ki a si dena aarun Ebola nipa sise awon nkan wonyi:
Fọ ọwọ rẹ pẹlu omi ati ọṣẹ loorekoore.
Yago fun oku eniyan tabi eranko, ma se fi owo kan won paapaa ti o kò ba mọ oun to seku pawon.
Sọra fun eran igbẹ lasiko yii.
Ti o ba ṣẹṣẹ de lati irinajo ti o si ṣ’aisan, tete lọ ile iwosan lọ ri dọkita.
 
				 
					 
						


