Getting your Trinity Audio player ready...
|
Àhesọ: Nàìjíríà jẹ́ orílẹ̀-èdè kejì tó ní iye ènìyàn tó pọ̀ jùlọ, tí ń gbé pẹ̀lú HIV.

Àbájáde Ìwádìí: Ìṣìnà. Ìjábọ̀ ọdún 2018 láti ọwọ́ UNICEF tí ó dá lórí àkójọfáyẹ̀wò ọdún 2015 ní eni náa tọ́ka sí. Èyí kì í ṣe aṣojú tí ó dára jùlọ fún ipò HIV lọ́wọ́lọ́wọ́ ní Nàìjíríà.
Ìròyìn náà tún sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ẹrù HIV, kì í ṣe iye àwọn ènìyàn tí wọ́n ń gbé pẹ̀lú HIV, gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ṣe àhesọ yìí ṣe wí.
Dátà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde l’ọ́dún 2023 fihàn pé ní Àfíríkà, Nàìjíríà ni nọ́mbà kẹta tó ga jù lọ, níye àwọn ènìyàn tí ń gbé pẹlú HIV.
Ìròyìn Lẹ́kùńrẹ́rẹ́
Ààrùn agbógunti kòkòrò àjẹsára ènìyàn (HIV) ń tẹ̀síwájú láti jẹ́ ọ̀rọ̀ ìlera tó ṣe pàtàkì kárí ayé, lẹ́yìn tí ó ti gba ẹ̀mí mílíọ̀nù 42.3 títí di àsìkò yìí.
Láti ọdún 2003, ìjọba orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà (US) ti ṣe ìdókòwò tó lé ní ọgọ́rùn-ún bílíọ́nù dọ́là nínú ìdáhùn HIV/AIDS àgbáyé, tí ó ń gba ẹ̀mí tó lé ní mílíọ̀nù 25 là nípasẹ̀ ètò pàjáwìrì Ààrẹ rẹ̀ fún Ìrànwọ́ Àrùn Éèdì (PEPFAR).
Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, Jan. 28, 2025, Donald Trump dá ìsanwó owó dúró nípasẹ̀ PEPFAR, ó kéré tán, fún àádọ́rn ọjọ́. Ìgbésẹ̀ yìí kan Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, tí wọ́n ti jẹ àǹfààní ètò ìrànwọ́ yìí.
Ní ìdáhùn sí iṣẹ̀lẹ̀ yìí, Dókítà orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Chinonso Egemba, tí wọ́n mọ̀ sí Dókítà Aproko, sọ pé orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní iye àwọn ènìyàn kejì tí wọ́n ń gbé pẹ̀lú HIV àti pé a gbára lé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀bùn.
“…Nàìjíríà jẹ́ orílẹ̀-èdè kejì lágbayé tó ní iye ènìyàn tó pọ̀ jùlọ, tí ń gbé pẹ̀lú HIV,“ àtẹ̀jíṣẹ́ to kà báyìí lórí X.
Díẹ̀ nínú àwọn aṣàmúlò X taàpa sí ìṣirò rẹ̀. Samuel Nika (@BikaSamuel) wí pé, “Tábìlì tí ò ń fi hàn jẹ́ fún títànkálẹ̀. Nàìjíríà je ìkẹta lórí nọ́mbà àwọn ènìyàn tí ń ngbé pẹ̀lú HIV. Ọ wà lẹyìn South Afrika àti Mozambique.”
Aṣàmúlò mìíràn (@swagbito) kọ̀wé pé, “Nàìjíríà kí ló ní iye kejì láwọn tí wọ́n ń gbé pẹ̀lú HIV. Jọ̀wọ́, dẹ́kun ṣíṣi àwọn ènìyàn lọ́nà.
Ní ìdáhùn sí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, Ọ̀gbẹ́ni Egemba pín àwòrán orísun rẹ̀, èyí tí ó fi ìjábọ̀ UNICEF hàn.
Apá kan àwòrán náà kà pé, “Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní àkóràn HIV/AIDS 190,950 lọ́dọọdún, ìwọ̀n kejì tó ga jùlọ ní àgbáyé.”
Ìtumọ̀ àkòrí náà, oríṣiríṣi èrò tí wọ́n gbé kalẹ̀ àti ìdí láti tàn’mọ́lẹ̀ sórí ọ̀rọ̀ náà ló jẹ́ kí DUBAWA ṣe ìwádìí yìí.
Ìfìdíòdodomúlẹ̀
Nítorí pé Dókítà Aproko tí fí orísun àhesọ rẹ̀ hàn, a kọ́kọ́ wo ìròyìn UNICEF. Ìròyìn yìí sọ pé Nàìjíríà ní ẹrù HIV/AIDS tó kẹta jùlọ ní ayé, pẹ̀lú àfihàn pé àwọn ènìyàn mílíọ̀nù mẹ́ta ni ń gbé pẹ̀lú HIV àti àkọ́sílẹ̀ titun 190,950, l’ọ́dún 2015.
“Nàìjíríà ní ẹrù HIV/AIDS tó kẹta jùlọ ní ayé, pẹ̀lú àfihàn pé àwọn ènìyàn mílíọ̀nù mẹ́ta ni ń gbé pẹ̀lú HIV (PLHIV) àti àkọ́sílẹ̀ titun 190,950 ní 2015,” apá kan ìròyìn náà kà.
A ṣe àkíyèsí pé ìjábọ̀ UNICEF yìí sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ẹrù HIV, kì í ṣe iye àwọn ènìyàn tí ó ga jùlọ tí wọ́n ń gbé pẹ̀lú HIV, ó sì wá láti inú àkójọfáyẹ̀wò 2015. Nítorí náà, a tẹ̀síwáj láti wá àkójọfáyẹ̀wò UNICEF lọ́wọ́lọ́wọ́ lórí iye àwọn ènìyàn tí wọ́n ń gbé pẹ̀lú HIV ṣùgbọ́n a kò rí àwọn ìjábọ̀ pàtó tàbí àkójọfáyẹ̀wò tí ó bá èyí mu. Àwọn ìròyìn tí ó wà láti ọ̀dọ̀ UNICEF ni “HIV Statistics-Global àti Regional Trends,” ìṣirò HIV fún ẹ̀rọ ìgbàlódé àwọn ọmọdé, àti ìdènà HIV ọ̀dọ́.
Gẹ́gẹ́ bí Àjọ Ìlera Àgbáyé (WHO) ṣe sọ, láti ọdún 2023, àpapọ̀ àwọn ènìyàn mílíọ̀nù 39.9 ló ń gbé pẹ̀lú HIV kárí ayé, pẹ̀lú mílíọ̀nù 38.6 nínú iye yìí tí ó jẹ́ àgbàlagbà (ọdún kẹ́ẹdógún lọ sókè). Nínú àwọn àgbàlagbà mílíọ̀nù 38.6 wọ̀nyí, mílíọ̀nù 20.5 jẹ́ obìnrin, nígbà tí mílíọ̀nù 18.1 jẹ́ ọkùnrin. Àkójọfáyẹ̀wò yìí tí WHO gbé kalẹ̀ kò fọ́ àwọn nọ́mbà náà sí orílẹ̀-èdè.
Àkójọfáyẹ̀wò láti Development Aid gbà pẹ̀lú àwọn nọ́mbà àgbáyé WHO. Ṣùgbọ́n ó tẹ̀síwájú láti fọ́ wọ́n sí àwọn agbègbè. Fún ilẹ̀ Adúláwọ̀, àwọn ènìyàn mílíọ̀nù 20.8 ní Ìlà Oòrùn àti Gúúsù Áfíríkà ń gbé pẹ̀lú HIV, àwọn ènìyàn 210,000 ní Àárín Ìlà Oòrùn àti Àríwá Áfíríkà ń gbé pẹ̀lú HIV, àwọn ènìyàn mílíọ̀nù 5.1 sì ń gbé pẹ̀lú HIV ní Ìwọ̀ Oòrùn àti Àárín Áfíríkà.
A tún rí àkójọfáyẹ̀wò láti Central Intelligence Agency (CIA) lórí ìwọ̀n ìtànkálẹ̀ AIDS láàrin àwọn àgbàlagbà, èyí tí ó fi Eswatini sí ipò àkọ́kọ́ àti Lesotho ní ipò kejì láti ọdún 2021. CIA ṣe àkíyèsí pé àkójọfáyẹ̀wò wọn lórí ìwọ̀n ìtànkálẹ̀ àgbàlagbà ṣe àfiwé ìdá ọgọ́rùn-ún àwọn àgbàlagbà (ọmọ ọdún 15-49) tí wọ́n ń gbé pẹ̀lú HIV/AIDS.
Data Statista t’ọdùún 2023 lórí àwọn ènìyàn tí ń gbé pẹ̀lú HIV ní àwọn orílẹ̀-èdè Áfíríkà tí a gbà láti ọ̀dọ̀ Joint United Nations Programme on HIV/AIDS (UNAIDS) tí ṣe àkójọ South Africa gẹ́gẹ́ bíi orílẹ-èdè tí ó ní nọ́mbà tí ó ga jùlọ tí àwọn ènìyàn mílíọ̀nù 7.7 sì ń gbé pẹ̀lú HIV. Mozambique ló tẹ̀lé pẹ̀lú ènìyàn mílíọ̀nù 2.4 àti Nàìjíríà pẹ̀lú ènìyàn mílíọ̀nù 1.7.
Nítorí pé àwọn dátà tó wà lórí ìtànkálẹ̀ HIV, ẹrù HIV, àti ìye ènìyàn tí ń gbé pẹ̀lú rẹ̀ yàtọ síra, a gbìyànjú láti ṣàlàyé àwọn ìwọ̀n yìí.
Gẹ́gẹ́ bí Ilé-iṣẹ́ àtọ́jú àrùn Centre for Disease Control (CDC) se wí, ìtànkálẹ̀ jẹ́ ìyè àwọn tó kó àrùn, ìyè ìṣẹ̀lẹ̀, tàbí ìyè àwọn tó fi àmì àrùn nàá hàn ní àkókò kan.
Ilé-iṣẹ́ ìfọwọ́sowọ́pọ̀ orílẹ̀-èdè fún àrùn àkóràn (National Collaborating Centre for Infectious Diseases) ṣàlàyé ẹrù àrùn gẹ́gẹ́ bí ìṣòro àti àdánù tí ó ní í ṣe pẹ̀lú àrùn, àìlera, àti ikú. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwọ̀n ẹrù àrùn ló gbájú mọ́ àwọn ohun tí ó ń fa tàbí mú àìsàn burú sí. Àwọn nkan wọ̀nyí pẹ̀lú iye àwọn ìṣẹ̀lẹ̀, ikú, àìsàn, àìlera, iye owó ìṣúná owó àti ìyàsọ́tọ̀ ewu.
Báyìí, ẹrù HIV ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn nkán nínú. Kìí ṣe iye àwọn ènìyàn tí ń gbé pẹ̀lú àìsàn nìkan. Nítorí náà, lílo dátà ẹrù dípo nọ́mbà àwọn ènìyàn tí ń gbé pẹ̀lú àìsàn HIV kò ṣe deede.
Àkótán
Àwárí wa fihàn pé ní Áfíríkà, Nàìjíríà ní nọ́mbà kẹta tí ó ga jùlọ nínú àwọn ènìyàn tí ọ ń gbe pẹ̀lú HIV gẹgẹ bí í dátà ọdún 2023. Ìròyìn tí wọ́n gbé jáde lọ́dún 2018 tí ó ń tọ́ka sí àkójọfáyẹ̀wò ọdún 2015, kì í ṣe aṣojú tó dára jùlọ fún ipò HIV lọ́wọ́lọ́wọ́ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Lois Ugbede ló kọ́kọ́ ṣ’àkọsílẹ ìwádìí yìí lé’dè gẹ̀ẹ́sì, tí Sunday Awóṣòro sì túmọ̀ rẹ̀ sí ède Yorùbá.