Getting your Trinity Audio player ready...
|
Àsíá jẹ́ oun pàtàkì, kìí ṣe aṣọ lásán; àsíá jẹ́ àmì ìdámọ̀, ó ṣàfihàn ìtàn àti ìṣe àwọn ènìyàn ní orílẹ-èdè, ilé iṣé tàbí agbègbè. Yàtọ̀sí orisirisi àwọ̀ ti o máà n wa lara àsíà, àwọn ààmì àti ìtumò wọn, àsíá jẹ́ oun kan pàtàkì tí a fií ń p’itan iṣọkan, akíkanjú ati àṣà.
Èyí n’iìdí tí àwọn olumulo ẹ̀rọ alatagba ni orilẹ-ède Nàìjíríà fi ń ṣ’ariyanjiyan lórí àsíá kan. Ní ọjọ́ kìíní oṣù kẹjọ ọdun yìí, ti àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà bẹrẹ iwọde láti fi ẹhọnu wọn hàn l’ori “aisedeede ijọba Bola Tinubu.” Ni asiko iwọde yìí ní ìpínlẹ̀ Kano, àwọn olufẹhonuhan gbè àsíá kan tí ó farajọ ti orílè-èdè Russia.
Èròngbà awon ènìyàn ní pe boya ààrẹ orílè-èdè Russia fé da si ọ̀rọ̀ Nàìjíríà, gegebi ó ṣé da si ti orílè-èdè Niger tí o súmọ́ wa nibi. Àsíá kan náà tàbí èyí tó farajọ ni a ri l’egbe ààrẹ Tinubu ni ìgbà ti o ba àwọn ọmọ orílè-èdè Nàìjíríà sọrọ ni ọjọ́ kẹrin, osù kẹjọ. Àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà n béèrè pé, “irú àsíá wo rèé?”
Ọpọlọpọ ènìyàn, bíi arakunrin Kayode Ogundamisi ni ìdánilójú pé àsíá ti àwọn oluwọde gbé sókè ní ìpínlẹ̀ Kano náà ni o wá l’egbe ààrẹ.
Arákùnrin Ogundamisi kò àkọsílẹ yìi si ojú òpó re lórí ìkànnì abeyefo, “Awon ọgẹdẹ dudu ti a n bà sòrò lórí ẹrọ alatagba. Won ni àsíá ti o wá l’egbe ààrẹ ni áṣíà ti idanimọ orílè-èdè Russia.”
Àwòrán to ṣafihan àsíá naa l’egbe ààrẹ
Ìròyìn ofege le mu aleebu ba àwọn eniyan lawujọ ati ile-ise, o le mu kí awon eniyan s’alaigbagbo oun kan ati ki wọn mẹ́nu kúrò lorí àwọn ọ̀rọ̀ to ṣe kókó, pàápàá ẹhọnu àwọn oniwọde. Akọsilẹ yii fi ìdí òdodo múlẹ̀ lórí àsíá ti a ri l’egbe ààrẹ Tinubu.
Àsíá wo ni àwọn olufehonuhan gbe sókè ni ipinle Kano?
Wahala ati idamu ni a le fi ṣàpèjúwe iwode ti o lòdì aiṣedede ijọba ti wón ṣe ni ipinle Kano. Gege bi irohin ti a gbọ́, àwọn onijagidijagan bèrè síí ṣe ibajẹ si oun ini ti ijoba ati ará ìlú, rògbòdìyàn yii lo faa ti ijoba ìpínlè naa fi kede òfin kónlé-ó-gbélé fún wákàtí merinlelogun.
Oniroyin kan Instablog9ja ṣ’atunpin àwọn àwòrán tó ṣàfihàn àwọn onifehonuhan ti wón gbè àsíá alawọ funfun, àwọ̀ aró ati àwọ pupa àwọn ẹlòmíràn sì gbe àworan Putin, ààrẹ orílè-èdè Russia. Biotilẹjẹpe wọn yá okàn nínù àwọn àwòrán yii ni oṣu kẹta ọdún 2023 ni orilẹ-ède Congo.
Àwọn olumulo kan tilẹ gbè aheso pé awon oniwode ọ̀ún gbé àsíá ìlú Kano. Dubawa ni àrídájú pé ìrọ́ ni ọ̀rọ̀ naa nítorí áṣíá ìlú Kano ni àwọ òféèfè, pupa, buluu pẹlú aworan irawo funfun. Lootọ, àsíá ti àwọn oniwọde yíí gbe dani jẹ ti idanimo orílè-èdè Russia.
Asíá ti àwọn oniwọde gbe dani (òkè) ti ìlú Kano (àárín) ati ti ilu Russia (isalẹ).
Biotilẹjẹpe àsíá ti a ri l’egbe ààrẹ Tinubu farajọ ti ìlú Russia, o yatọ sí ra. Àsíá ti o wá l’egbe ààrẹ Tinubu ni àwọ pupa, buluu, funfun ati àwọ ewé. Ṣugbọn àwọ̀ ewé yii ò hàn gbangba nígbàtí wón ṣe igbasilẹ fónrán ààrẹ.
Aare Tinubu, gégébí ọgagun ikọ ogun ati ààbò orílè-èdè Nàìjíríà
Ọjọ́ ti ogbeni Tinubu bọ́ sí ipò ààrẹ orílè-èdè Nàìjíríà ni ọjọ́ ti wón fi jẹ ọgagun iko ogun orílè-èdè Nàìjíríà. Oun tí àsíá yìí dúró fún niyi.
Àsíá ààrẹ orílè-èdè Nàìjíríà gẹgẹbi ọgagun iko oogun orílè-èdè Nàìjíríà
Wọn máà n ṣe àpèjúwe àsíá yii pé o jẹ àsíá ààrẹ orílè-èdè Nàìjíríà gẹgẹbi balógun ikọ̀ ogun orílè-èdè wa, o ṣe pàtàkì ki àsíá yií wa pẹlú asíá idanimọ orílè-èdè Nàìjíríà pẹlú ààrẹ. Kódà, àsíá yii máà n wa l’ẹgbẹ àwọn ààrẹ ti o ti je sẹyìn ti won si di ipo ọgagun iko oogun orílè-èdè wa. Àwọn àwòrán wọnyí ṣàfihàn àwọn ààrẹ teleri pẹlu ásíá yií.
Aworan to ṣafihan àsíá ọgagun l’egbe ààrẹ teleri Muhammadu Buhari
Ọgbẹni Goodluck Jonathan ni ìgbà ti o n sọrọ ni ayajọ ọjọ isejọba alagbada ni odún 2010
Dubawa fi idi re mu’le pé àsíá ti o wá pẹlú ààrẹ Tinubu yàtọ̀ gedegbe sí èyí ti àwọn olufẹhọnuhan gbé dání ni ipinlẹ Kano.