Facebook ChecksFact CheckHealthYoruba

Njẹ a lè fi tòmátì ati aáyù fọ asẹtọ ọmọkunrin mọ́?

Getting your Trinity Audio player ready...

AHESỌ: Ojú òpó kan lórí ìkànnì ibaraẹnisọrẹ Facebook gbe ahesọ kan pé tòmátì ati garlic/aáyù lè fọ asẹtọ ọmọkùnrin mọ́.

Njẹ a lè fi tòmátì ati aáyù fọ asẹtọ ọmọkunrin mọ́?

Àbájáde ìwádìí: Kò sí ẹrí tó dájú. Botilẹjẹpe àwọn atẹjade kan ṣ’agbekalẹ ìwúlò tòmátì ati garlic/aáyù nínú ìlera asẹtọ ọmọkùnrin, kò sí ìdánilójú pé méjèèjì lè “fọ asẹtọ ọmọkùnrin mọ́”.

Ìròyìn lẹkunrẹrẹ

Aṣẹtọ jẹ ẹṣẹ oje-ara kékeré kan ti o wa ni ara ọmọkùnrin. Aṣẹtọ tobi bíi awùsá, o sì ní àpẹẹrẹ awùsá. Kódà, ẹ̀gbẹ́ eegun ikoko-idi ni o wà, ó sì wà lábé àpòòtọ. Aṣẹtọ ni ó máa ran ọmọkùnrin lọwọ láti pèsè àtọ̀ ti o máa di ọmọ tí o ba obìnrin lajọsepọ.

Ìwádìí kan fihàn pé léyìn àìsàn jẹjẹrẹ ọ̀nà ọ̀fún, àìsàn jẹjẹrẹ aṣẹtọ jẹ aisan jẹjẹrẹ keji to n seku pa àwọn ọkùnrin. Èyí ló fàá ti awọn ènìyàn ṣe n daba onírúurú ọ̀nà tí ènìyàn lè gbà fọ aṣẹtọ ọmọkùnrin.

Olumulo ìkànnì ibaraẹnisọrẹ Facebook, Eerifeoluwasimi fi fónrán kan sí ojú òpó rẹ̀, ni ibi ti o ti ṣàlàyé pé tí a bá lọ tòmátì ati garlic/aáyù papọ, ti a sì gbé mu, ó lè fọ aṣẹtọ ọmọkùnrin.

Nínú fónrán náà, okunrin kan ṣàlàyé pé o se pàtàkì kí àwọn ọkùnrin ti o ti pé ogoji ọdun, ki wọn fọ aṣẹtọ wọn, nípa mímu apapọ tòmátì ati garlic/aáyù. O ṣàlàyé pé tí a bá lọ awe garlic/aáyù ati èso tòmátì kan papọ, èyí lè ṣe ìdáàbòbò ara kúrò l’ọwọ àìsàn. 

Fonran náà ti kalekako, kódà ọpọlọpọ ènìyàn ló wò fonran náà, wọn sì bú ọwọ ìfẹ luu. 

Ìtànkálẹ̀ fónrán náà àti pàtàkì ọrọ yí lo fàá tí DUBAWA fi ṣe ìwádìí lati fi ìdí òdodo múlẹ̀.

Ifidiododomule 

Ìwádìí kan ti àjọ Better Nutrition gbejade, ṣe agbekalẹ rẹ̀ wípé èso tòmátì dára púpọ fún ìlera aṣẹtọ ọmọkùnrin, nítorí tòmátì ní èròjà lycopene, èròjà ti o n ṣara lóore, ti o sì máa n daabobo ìlera aṣẹtọ ọmọkùnrin. Ìwádìí ti fihàn pé kí eniyan máa jẹ èso tòmátì lọpọlọpọ ti se idinku àìsàn jẹjẹrẹ aṣẹtọ, àwọn ìwádìí míràn daba pé èròjà lycopene ọ̀ún lè se ìdádúró ìdàgbàsókè àìsàn aṣẹtọ ti ó burú jai, èyí tí awon oloyinbo n pé ni Benign Prostatic Hyperplasia (BHP).

Ìwádìí Pubmed fihàn pé o ṣeéṣe kí àwọn ọkùnrin ti wọn máa n je àlúbọ́sà, garlic/aáyù, àlúbọ́sà eléwé, má ṣe ṣ’agbako aiṣan jẹjẹrẹ aṣẹtọ. 

Bakan náà, ìwádìí kan ti National Library of Medicine gbe jáde fihàn pé garlic/aáyù (Allium sativum) ni awọn anfaani kọọkan bíi kí o gbogun ti jẹjẹrẹ, iredodo, kódà o ni èròjà antioxidant. Nítorí èyí, latayeraye ni won ti n lo garlic/aáyù fi se itọju jẹjẹrẹ aṣẹtọ. Ṣugbọn, àwọn onimọ tunbọ ni lati ṣe ìwádìí lórí ọ̀nà ti wọn le fi lo garlic/aáyù fún ìlera ara ènìyàn.

Awon onimọ sọrọ

DUBAWA ba Abiola Ayanbukola sọrọ, ẹni tí o je dókítà ní ilé ìwòsan ti Yunifasiti Obafemi Awolowo, nínú ọrọ rẹ, dókítà náà sọ wípé òun máa ń gbọ́ nípa ibaṣepọ àìsàn jẹjẹrẹ aṣẹtọ pẹlu tòmátì ati garlic/aáyù. Ṣugbọn, kò sí ẹrí tó dájú wípé, wọn máa ń fi méjèèjì fọ aṣẹtọ ọmọkùnrin.

O ṣàlàyé wípé òun kò kì n gba awọn aláìsan ni imọran láti jẹ tabi mu tòmátì ati garlic/aáyù. Ní tóun o, n’isẹ ní òun máa n gba wọn niyanju láti jẹ oúnjẹ to dára, pàápàá jùlọ ki wọn jẹ èso ati ẹ̀fọ́. 

“Lootọ, èso tòmátì ati garlic/aáyù lè ṣe aṣẹtọ lóore ṣugbọn mi o mọ̀ nípa ki wọn fi fọ aṣẹtọ nítorí nko tii ri ẹnikẹni ti won loo fún,” dókítà náà ló sọ èyí. 

Dokita Busola Adebesin, ti o wa ni orilẹ-ede Gambia, ṣàlàyé pé ọpọlọpọ èròjà lycopene lo wa ninu èso tòmátì, o sì ṣeéṣe kí wọn ṣe iranlọwọ fún ẹni to ní ààrùn jẹjẹrẹ aṣẹtọ. O tunbọ ṣàlàyé pé ọnà kan ti a lè gbà dènà ààrùn jẹjẹrẹ aṣẹtọ ni ki eniyan máa jẹun to dara lásìkò.

Fún àwọn ènìyàn tí wọ́n fẹ́ràn láti ma mu ọtí líle ati láti jẹ ẹran lọpọlọpọ, ó ṣe pàtàkì fún wọn láti máa jẹ èso ati ẹ̀fọ́ ni gbogbo ìgbà. Èròjà aṣaraloore pọ nínú tòmátì, garlic/aáyù, ẹ̀wà/eèré. 

Akotan

Botilẹjẹpe èròjà lycopene wa nínú èso tòmátì, èyí sì lè ṣe ìdènà jẹjẹrẹ aṣẹtọ, àwọn onímọ̀ nilo lati ṣe ìwádìí síwájú síi lórí ìmúlò akanpọ garlic/aáyù ati tòmátì láti fi fọ aṣẹtọ ọmọkùnrin. 

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Back to top button
Translate »