ExplainersHealthYoruba

Àrùn onígbáméjì tó bẹ́ sílẹ̀ ní Nàìjíríà àti ọ̀nà márùn-ún tí a leè gbà dáàbò bo ara wa

Getting your Trinity Audio player ready...

Ẹnu ọjọ́ mẹ́ta yìí ni àrùn onígbáméjì (Cholera) tún bẹ́ sílẹ̀ ní orílè-èdè Nàìjíríà, tó sì ń jà bíi ìjì. Ìwádìí fi yé wa wípé, ó lé ní ẹgbẹ̀rún kan ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn onígbáméjì tí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ ní ọdún 2024 yìí nìkan, tí ènìyàn tí ó tó ọgbọ́n níye, ti t’ọwọ́ àrùn onígbáméjì yìí ṣe aláìsí. 

Gẹ́gẹ́ bí adarí àjọ tó ń dènà àrùn ní orílè-èdè Nàìjíríà (NCDC), Dókítà Jide Idris ti ṣe àlàyé, láàrín oṣù àkọ́kọ́ àti oṣù kẹfà ọdún 2024, ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn onígbáméjì yìí ni ó ti ṣẹlẹ̀ ní ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́rìnlélọgọ́rùn-ún ní ìpínlẹ̀ ọgbọ́n. Nínú àwọn ìpínlẹ̀ yìí ni a ti rí, ìpínlẹ̀ Abia, Bayelsa, Cross River, Delta, Imo, Katsina, Èkó àti Zamfara. Wàyí, ó di dandan fún wa láti ṣọ́ra, kí á sì ní ìmọ̀ nípa àrùn yìí láti leè mọ ọ̀nà àti dáàbò bo ara wa.

Kíni àrùn onígbáméjì (Cholera)? 

Gẹ́gẹ́ bí àjọ tó ń rí sí ìlera àgbáyé (WHO) ti ṣe àlàyé rẹ̀, àrùn onígbáméjì jẹ́ àìsàn tí kòkòrò àìfojúrí ti Vibro Cholerae, máa ń fà. Àrùn onígbáméjì jẹ́ àìsàn alákòóràn tí ó máa ń mú ènìyàn àti ẹranko abẹ́lé. Ó máa ń wáyé nípa oúnjẹ jíjẹ tàbí omi mímu tí kòkòrò àìfojúrí Vibro Cholerae yìí ti wọ̀. Àrùn yìí wọ́pọ̀ láàrín àwọn tí kìí sábà rí ànfàní omi tó mọ́ tàbí àyíká tó ní ìmọ́tótó. Rògbòdìyàn, àyípadà ojú ọjọ́, àti ìdàgbàsókè ìlú tí kò ní ètò, leè dá kún ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn onígbáméjì.

Àrùn onígbáméjì lágbára púpọ̀ tí ó sì yára pànìyàn. Àwọn olùwádìí ṣe àkọsílẹ̀ pé, ó tó mílíọ̀nù kan sí mẹ́rin ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn onígbáméjì tí ó máa ń ṣẹlẹ̀ láàárín ọdún kan ní àgbáyé, tí ó sì máa ń gb’ẹ̀mí ènìyàn tí ó tó ẹgbẹ̀rún mọ́kànlélógún sí ẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́tàlél’ógóje. Àrùn onígbáméjì leè ṣokùnfà ìgbẹ́ gbuuru tàbí èébì bíbì, ó sì lè tó wákàtí méjìlá sí ọjọ́ márùn-ún kí àmì àìsàn yìí tó fojú hàn.

T’ọmọdé-t’àgbà ni àrùn onígbáméjì leè ṣe o. Àrùn yìí leè ṣekú pani láàárín wákàtí péréte tí ó bá kọ lu ènìyàn nípa jíjẹ́ oúnjẹ tàbí mímú omi tí kòkòrò àìfojúrí Vibro Cholerae yìí ti wọ̀. Àrùn onígbáméjì leè ràn láti ara ẹnìkan sí òmíràn.  Nípa ìgbẹ́ gbuuru àti èébì bíbì yìí, omi ara leè ṣe àìtó kí ó sì jásí sísọ ẹ̀mí ẹni nù láàárín wákàtí péréte. Ìdá mẹ́ẹ̀dógún dí ìdá ogún ni kìí ye àrùn yìí nígbà tí ó bá ṣe wọ́n.

Wíwo ẹ̀yìn wá

Láti ìgbà tí àjàkalẹ̀ àrùn onígbáméjì ti kọ́kọ́ wáyé ní ọdún 1972, orílè-èdè Nàìjíríà tún ti ní àkọsílẹ̀ àjàkalẹ̀ àrùn yìí ní àìmọye ìgbà lẹ́yìn náà. Fún àpẹẹrẹ, ìparí ọdún 2010 ni orílè-èdè Nàìjíríà mọ̀ sí ìgbà kan tí àrùn yìí tún jà púpọ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ láti àríwá orílè-èdè yìí, ó sì tàn ká àwọn àgbègbè tó kù. Èyí yọrí sí bíi ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ènìyàn tí ó kó àrùn yìí tí ènìyàn tó dín díẹ̀ ní àádọ́jọ sì kú.

Orílè-èdè Nàìjíríà tún ti ní àkọsílẹ̀ àrùn onígbáméjì yìí ni ọdún 1992, 1995/1996, àti 1997. Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹwàá ọdún 2021, ó dín díẹ̀ ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún àkọsílẹ̀ àrùn onígbáméjì ní orílè-èdè Nàìjíríà ní, tí ènìyàn tí ó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta sì tipasẹ̀ àrùn yìí ṣaláìní. Ọwọ́jà àjàkalẹ̀ àrùn yìí dé ìpínlẹ̀ méjìlélọ́gbọ̀n nínú ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì pẹ̀lú olú ìlú, Abuja. Àwọn ọmọdé tí ọjọ́ orí wọn wà láàrin ọdún márùn-ún sí ọdún mẹ́rìnlá ni àrùn náà nípa lórí wọn jù. Apá àríwá orílè-èdè Nàìjíríà sì ni ọwọ́ àrùn náà sì ti dunlẹ̀ jù. Àwọn aṣèwádìí tilẹ̀ fì’dí rẹ̀ múlẹ̀ wípé, apá àríwá orílè-èdè Nàìjíríà ni àjàkalẹ̀ àrùn onígbáméjì wọ́pọ̀ sí jù lọ. Ní oṣù àkọ́kọ́ ọdún 2022, àkọsílẹ̀ àrùn onígbáméjì irínwó àti àádọ́rìn ni ó ṣẹlẹ̀ tí ó sì gba ẹ̀mí ènìyàn mẹ́ṣàán. Àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́ta ni àrùn náà ti jà jù. Àwọn ìpínlẹ̀ náà sì ni Taraba, Borno, àti Adamawa.

Àkọsílẹ̀ àrùn onígbáméjì látẹ̀yínwá ní orílè-èdè Nàìjíríà, nííṣe pẹ̀lú àwọn àjálù àdáyébá àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ rògbòdìyàn bíi ìgbésùmòmí Boko Haram. Àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ìlera àgbáyé (WHO), dábàá wípé, kí ibùdó ìtọ́jú àrùn onígbáméjì kí ó bọ̀ sì pàápàá jùlọ ní àwọn àgbègbè tí àrùn onígbáméjì yìí ti máa ń sábà sọṣẹ́.

Àwọn ọ̀nà tí a leè gbà dáàbò bo ara wa

Níwọ̀n ìgbà tí a ti mọ̀ nípa àrùn onígbáméjì àti bí àrùn yìí ti burú tó, ó di dandan fún wa láti mọ̀ àwọn ọ̀nà tí a leè gbà dènà àrùn yìí. Wọ̀nyí ni àwọn ọ̀nà márùn-ún tí a lè gbà dènà àrùn onígbáméjì: 

  • Fífọ ọwọ́ wa lóòrèkóòrè: Ọwọ́ fífọ ṣe pàtàkì púpọ̀ tí a bá fẹ́ dènà àrùn onígbáméjì. Ki a tó fi ọwọ́ sínú oúnjẹ tàbí omi, a ní láti fọ ọwọ́ wa mọ́. A ní láti fọ ọwọ́ wa kí á tó bẹ̀rẹ̀ iná oúnjẹ dídá, nígbà tí a bá ń se oúnjẹ náà àti nígbà tí a bá se oúnjẹ tán, kí á tó fún ọmọ ní oúnjẹ, lẹ́yìn tí a bá lọ sí ilé ìgbọ̀nsẹ́, lẹ́yìn tí a bá tọ́jú àwọn tó ní àrùn onígbáméjì àbí nígbà tí a bá ti ọwọ́ wa bọ ẹ̀gbin, a ní láti fọ ọwọ́ wa. 

Ọwọ́ fífọ̀ kìí ṣe bíbu omi sí ọwọ́ lásán bíkò ṣe kí á fi ọṣẹ fọ ọwọ́ wa lábẹ́ omi tó ń dà kí ọṣẹ náà le pa àwọn kòkòrò àìfojúrí. Nígbà tí a kò bá ní ànfàní sí omi tó mọ́ àti ọṣẹ láti fọ ọwọ́ wa, a leè lo òògùn apakòkòrò (hand sanitizer), irú eléyìí tí a fi èròjà ọtí líle pèsè. A kò tilẹ̀ ní láti kọ́kọ́ tí ọwọ́ wa bọ ẹ̀gbin kí á tó fọ ọwọ́ wa. Nítorí pé ó yára fún ọwọ́ wa láti lọ sí ojú, imú àbí ẹnu wa nígbà tí a kò tilẹ̀ lérò. Èyí sì leè ṣokùnfà àwọn àrùn míràn tí ó tún yàtò sí onígbáméjì. Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ máa fọ ọwọ́ wa mọ́ ní ìgbà gbogbo. 

  • Ṣíṣọ́ oúnjẹ jẹ: A ní láti máa kíyèsí irú oúnjẹ tí à ń jẹ. Àwọn oúnjẹ bíi ẹja àti ẹ̀fọ́ sábà máa ń ní kòkòrò àìfojúrí tó ń ṣokùnfà àrùn onígbáméjì. Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ se àwọn oúnjẹ wá pẹ́ lórí iná kí a leè ri dájú wípé àwọn kòkòrò àìfojúrí inú oúnjẹ náà kú pátápátá. 

Kò tilẹ̀ dára láti máa jẹ oúnjẹ tí a kò sè, àyàfi bí ó bá jẹ́ oúnjẹ tó ní èèpo tí a leè bó kúrò kí á tó jẹ. Bí ó bá jẹ́ èso ni a fẹ́ jẹ, ó di dandan fún wa láti fi omi tó mó gaara ṣan èso náà dáradára, tàbí kí á bó èpo ẹ̀yìn èso náà kúrò kí á tó máa jẹẹ́. Àti wípé, a gbọdọ dẹ́kun jíjẹ́ àwọn oúnjẹ tí a pèsè ní àwọn ibùsọ̀ ẹ̀bá ọ̀nà.

  • Mímú omi tó mọ́: A gbọdọ se àkíyèsí irú omi tí à ń mu kí a má baà mu omi tí kòkòrò àìfojúrí tó ń fa àrùn onígbáméjì ti sába sí.  Oríṣiríṣi ọ̀nà ni a lè fi ṣe àrídájú omi tí à bá fẹ́ mu. A lè lo èròjà kiloráínì tí a fi ń tọ́jú omi kí ó lé ṣeé mu fún wa. Kiloráínì yìí jẹ́ ògùn tí ó ń pa kòkòrò inú omi kí omi náà leè ṣeé mu. 

Yàtọ̀ sí lílo èròjà kiloráínì fún omi mímu wa, a tún leè se omi tí à bá fẹ́ mu kí á tó muú. Omi sísè máa ń pa àwọn kòkòrò àìfojúrí inú omi. Ní síse omi yìí, a gbọ́dọ̀ ri dájú wípé omi yìí hó. Lẹ́yìn ìgbà tí a bá se omi mímu wa tán, kí a sì ṣe omi náà lọ́jọ̀ sínú ike tó mọ́ kí kòkòrò àìfojúrí má baà tún wọ̀ọ́. A tún leè sẹ́ omi mímu wa kí a sì fi èròjà kiloráínì sínú rẹ̀ láti pa àwọn kòkòrò àìfojúrí. Asẹ́ tí ojú rẹ̀ dí dáradára ni a gbọ́dọ̀ fi sẹ́ omi náà kí á lè baà ríi dájú wípé gbogbo ìdọ̀tí ni a ti sẹ́ kúrò. Lẹ́yìn èyí, omi náà ti di mímu fún wa.

  • Òfin tótó àti ìjábọ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó f’ara jọ àrùn onígbáméjì:  Ọ̀kan nínú àwọn ọ̀nà tí a fi lè dáàbò bo ara wa lọ́wọ́ àrùn onígbáméjì ni ṣíṣe òfin tótó àti ìjábọ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó jọ mọ́ àrùn onígbáméjì yìí, fún àwọn àjọ elétò ìlera. Bí a bá ṣe àkíyèsí ìṣẹ̀lẹ̀ ìgbẹ́ gbuuru, èébì bíbì, àìtó omi lára, àti àwọn ohun tí ó fi ará jọ àwọn nǹkan wọ̀nyí lára àwọn ẹni tí ọjọ́ orí wọn bẹ̀rẹ̀ láti ọdún méjì sókè, a ní ojúṣe láti fi tó àwọn elétò ìlera létí. 

Ṣíṣe òfin tótó yìí ni ẹ̀sẹ̀ kùkú, ìgbèríko àti àwọn ìjọba ìbílẹ̀ kọ̀ọ̀kan yíò ran àwọn àjọ elétò ìlera lọ́wọ́ láti mọ ìgbésẹ̀ tó yẹ láti gbé. Ọ̀kan nínú àwọn ìgbésẹ̀ tí wọ́n lè gbé nígbà tí a bá fi àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí tó àwọn àjọ yìí létí ni, ṣíṣe ìkéde tó rinlẹ̀ kí àwọn àgbègbè tí àrùn náà kò tíì tàn dé leè múra sí ọ̀rọ̀ ìlera wọn. Bákan náà, nípa ṣíṣe òfin tótó àti ìjábọ̀ lórí àrùn yìí, àwọn àjọ elétò ìlera yíò le mọ irú àsìkò tí àrùn yìí máa ń ṣẹlẹ̀ láti lè dènà dèé ní ọjọ́ iwájú.

  • Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí àrùn onígbáméjì: Ṣíṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí àrùn onígbáméjì leè ràn àwọn tí kò ní ìmọ́ lórí àrùn yìí lọ́wọ́ láti mọ̀ nípa rẹ̀ àti láti borí rẹ̀. Ìmọ́ nípa àrùn yìí leè ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti lè dáàbò bo ara wọn nígbà tí àrùn náà bá bẹ́ sílẹ̀ ní agbègbè wọn. 

A leè ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tàbí ìkéde lórí ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán, ẹ̀rọ rédíò, nípa títẹ ìwé pélébé, ìwé àwòrán alálàyé, ìwé àlẹ̀m’ógiri, kíkó àwọn ènìyàn jọ ní agbolé láti jíròrò lórí àrùn onígbáméjì, àti àwọn ọ̀nà míràn bẹ́ẹ̀. Nípa èyí, ọ̀gọ̀rọ̀ ènìyàn ni yíò ní ìmọ́ tí ó yẹ lórí àrùn yìí. Àgbègbè kọ̀ọ̀kan leè ṣe ètò lórí àwọn ọ̀nà láti dènà àrùn onígbáméjì. Nípa ìkópa àwọn ènìyàn nínú ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àti ìlanilọ́yẹ̀, àrùn onígbáméjì yíò rọrùn láti borí.

Àkọtán

Àrùn onígbáméjì jẹ́ àrùn tó burú púpọ̀ tí ó sì yára ṣekú pani. A gbọdọ dáàbò bo ara wa lọ́wọ́ àrùn yìí. O sì tún jẹ́ ojúṣe wa láti dáàbò bo àwọn ẹbí àti ará wa gbogbo nípa ìlanilọ́yẹ̀.

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Back to top button