|
Getting your Trinity Audio player ready...
|
Aheso: Atẹjade ikanni X gbe ahesọ pe ile-ise ọmọogun òfurufú ti orile ede Naijiria se ìkọlù si ilu kan ni ipinle Kwara ni àìmọye ìgbà.

Abajade iwadii: Asinilona! Iwadii DUBAWA f’ihan pe àwòrán akalekako ọ̀ún kò tọka si ìkọlù òfurufú ni ilu Oke-Ode ti Ipinle Kwara. A rii wipe ipinle Borno ni wọn ti ya àwòrán naa ni ọdún 2024.
Iroyin l’ẹkunrẹrẹ
Ni ojo meta yii, àwọn agbégbọn kọlu awon ilu kookan ni ipinle Kwara. ìkọlù buruku ti o la emi lọ si ni, awon elomiran si farapa. Eyi lo faa ti opolopo araalu sa kuro ni ilu naa nitori ewu iku ojiji.
Olumulo ikanni X @Milnewsng sọ wipe ile-ise omoogun òfurufú Naijiria se ìkọlù lati òfurufú lodi si awon agbégbọn naa.
O fi àwòrán kan ṣatileyin aheso rẹ̀, àwòrán naa ṣ’afihan awon agbegbe kookan ti samisi fun ìkọlù òfurufú naa. O ni awon ilu naa ni Kakihun, Oke-Ode, Babanla ati awon agbegbe to sunmo ipinle Kwara.
Awon olumulo ikanni ibaraenisore ati Ikanni Instagram ṣ’atunpin aheso naa.
Ni ojo kejo osu kewa ọdún yii, awon olumulo ikanni X ti bu owo ife lu atejade naa.
A se agbeyewo oun ti awon olumulo n so nipa atejade yii. Awon kan gbaagbo, awon kan si se alaigbagbo. Ewo nkan ti awon eeyan sọ.
Afonja Ojolowo 1 bere wipe, “Tani o n satileyin iru iro yii, nigba ti o je pe awon eniyan n sa asala fun emi won?”
Olumulo miran @Superdtech gba ọ̀rọ̀ naa gbo, o wi, “O dara bee. Mo ni igbekele ninu iko omoogun orilede yii, won ti ṣ’akojọ oun ija lati dokujo awon agbesumoni wonyi”.
Elomi @Rerevonschopfer sọ wipe, “Mi o gba oro yii gbo. Awon eeyan maa n ṣ’atunpin iru fonran yii ni gbogbo igba, ìkọlù si n peleke sii.”
@Effzee sọ wipe, “Aworan asnilona ni eyi.”
Ariyanjiyan to wa lori atejade naa lo faa ti DUBAWA se iwadii.
Ifidiododomule
A se itopinpin koko oro lori ayelujara ki a le s’amudaju lori ojulowo ile-ise iroyin. Sugbon, a ko ri nkankan.
DUBAWA lo itopinpin àwòrán lateyinwa. Esi iwadii ni pe won ti fi àwòrán oun si ori ayelujara lati osu kewa ọdún 2024. Zagazola Makama lo koko fi àwòrán naa s’ori ayelujara.
Bakan naa, a ṣe agbeyẹwo oju opo ile-ise omoogun òfurufú Naijiria lori Ikanni X, a si rii wipe won ko so oun kan nipa isele yii.
Akotan
Iwadii DUBAWA fidirẹmulẹ pe àwòrán akalekako yii ko ni ounkan sise pelu ìkọlù agbegbon si awon ilu kookan ni ipinle Kwara. Àwòrán naa niise pelu isele kan ni ọdún to k’ọja.




