ExplainersMainstreamYoruba

Àyípadà ojú ọjọ́, ìjàmbá àti àwọn ohun t’o ní láti ṣe

Getting your Trinity Audio player ready...

Ó ṣeéṣe kí o ti ṣe àkíyèsí àwọn ǹkan bíi àìtètè rọ̀ òjò, ìṣẹ̀lẹ̀ ẹ̀kún omi, omíyalé, odò fífà tàbí gbígbẹ pátápátá, ooru àmújù, ìjì líle, àti àwọn àjàkálẹ̀ àrùn. Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ń tọ́ka sí àyípadà ojú ọjọ́ ji.

Àyípadà ojú ọjọ́, ìjàmbá àti àwọn ohun t'o ní láti ṣe

Kí ni àyípadà ojú ọjọ́?

Ní èdè kúkúrú, àyípadà ojú ọjọ́ níí ṣe pẹ‌lú àwọn ìyàtọ̀ tí ó ń bá oun gbogbo tí ó jẹ mọ́ afẹ́fẹ́, òfurufú, àti àyíká. Àyípadà ojú ọjọ́ máa ń hàn láti àkíyèsí ìwọ̀n òtútù tàbí ìwọ̀n ooru tí ó pẹ́ fún àkókò ìgbà kan ní agbègbè kan. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, àyípadà ojú ọjọ́ leè ṣokùnfà ooru àmújù, ó sì tún leè jásí òtútù àpọ̀jù.

Nígbàtí àwa ènìyàn bá ń dáná sun ilẹ̀, igbó, gé igi, tàbí tí à ń ṣe àwọn nǹkan tí ó leè mú afẹ́fẹ́ ‘carbon dioxide’ tú sínú òfurufú, ó ṣòro fún àwọn afẹ́fẹ́ tí kò wúlò wọ̀nyí, láti pòórá. Dípò bẹ́ẹ̀, àwọn afẹ́fẹ́ yìí yíò wà nínú òfurufú tí wọn yóò sì máa mú ooru. Èyí ni àwọn onímò ìjìnlẹ̀ ńpè ní “ipò ìmóhugbóná (greenhouse effect).”

Ohun tí a mọ̀ gẹ́gẹ́ bíi ipò ìmóhugbóná yìí kìí ṣe àjòjì sí àyè rárá. Ó jẹ́ ọ̀nà àdáyébá tí ojú ọjọ́ fi ń fi ìwọ̀n sí òtútù àpọ̀jù ni ayé. A leè ronú nípa aṣọ ìbora tí à ń lò láti dènà òtútù. Bí ẹnikẹ́ni bá tún wá dáná s’ábẹ́ aṣọ ìbora yìí, ó dájú wípé ooru yíò pọ̀ lápọ̀jù látàrí dídáná sábẹ́ẹ gbígbóná. Èyí sì tàsé ọpọlọ.

Gẹ́gẹ́ bí ipò ìmóhugbóná yìí ti ńṣe àkóbá fún òfurufú nípa yíyí ojú ọjọ́ padà, bẹ́ẹ̀ ni ó tún ńṣe àkóbá fún àyíká, ènìyàn, igi àti ewéko, ẹranko igbó, àti àwọn ẹ̀dá mìíràn tí wọ́n fi inú omi àti orí ilẹ̀ ṣe ibùgbé.

Ìṣokùnfà àyípadà ojú ọjọ́

Àyípadà ojú ọjọ́ tí à ń ní ìrírí rẹ̀ yìí, ń wáyé nípasẹ̀ ìṣe ọwọ́ ènìyàn bíi igi gígé, dídáná sun ilẹ̀ àbí igbó, lílo epo fósáílì, iṣẹ́-ṣíṣe àwọn ilé-iṣẹ́ tí a ti ń pèsè nkan, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. 

Látàrí àwọn ẹ̀rọ ilé-iṣẹ́ wọ̀nyí, afẹ́fẹ́ methane, carbon dioxide àti àwọn afẹ́fẹ́ mìíràn tí kò bá ojú ọjọ́ mu, yíò máa dà pọ̀ mọ́ òfurufú, tí yíò sì jásí ìdíbàjẹ́ ojú ọjọ́. Ìdí tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀ ni wípé, púpọ̀ àwọn ilé-isé tí a ti ń pèsè nkan ni ó nlọ epo fósáílì bíi, èédú, epo bẹntiróòlù, òróró àtùpà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àjókù àwọn èpò wọ̀nyí máa ń di afẹ́fẹ́ carbon tí a sì máa ṣe ọ̀pọ̀ ìbàjẹ́ sí òfurufú àti ìjàmbá fún ènìyàn. 

Igi gígé yálà fún èédú ṣíṣe, ilé kíkó àbí ohunkóhun, láì gbin òmíràn rọ́pò, pẹ̀lú àwọn ohun tí ó ń ṣokùnfà àyípadà ojú ọjọ́. Igi ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ànfàní tí ó ń ṣe fún àyíká àti àwa ènìyàn. Fún àpẹẹrẹ, igi máa ń ṣe àfọ̀mọ́ afẹ́fẹ́, a sì tún máa pèsè àtẹ̀gùn “oxygene,” èyí tí ó ṣe pàtàkì fún ènìyàn, ẹranko àti ohun ẹlẹ́mìí gbogbo láti wà láàyè. Igi máa ń dènà ọ̀gbàrá, ìjì líle tí ó leè bi ilé wó, àti àwọn ànfàní àìníye mìíràn. Nígbàtí a bá gé igi láì gbin òmíràn rọ́pò, à ń gé gbogbo àwọn ànfàní wọ̀nyí dànù ni.

Dídáná sun igbó àbí ààtàn a máa ṣokùnfà àyípadà ojú ọjọ́ pẹ̀lú. Gẹ́gẹ́ bí àwọn àlàyé tí a ti ṣe tẹ́lẹ̀, àbáyọrí dídáná sun igbó, kó ewu títú afẹ́fẹ́ carbon s’ojú òfurufú àti ewu ọ̀gbàrá, papọ̀ ni. Ó tilẹ̀ tún leè ṣé ọ̀pọ̀ ìjàmbá tó tún jù bẹ́ẹ̀ lọ.

Àyípadà ojú ọjọ́, ìjàmbá àti àwọn ohun t'o ní láti ṣe

Kí ni àwọn onímọ̀ sọ nípa àyípadà ojú ọjọ́?

Ewu ń bẹ lóko longẹ́ o! Àwọn onímò ìjìnlẹ̀ sọ wípé, níṣe ni ayé ń gbóná síi ju ti àtẹ̀yìnwá lọ. Ó sì ṣeéṣe kí ó tún gbóná jù báyìí lo. Èyí sì mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ewu dání, bíi iná àjóràn, ooru àmújù, ẹ̀kún omi, pípàdánù àwọn ẹranko igbó àti àwọn ohun abẹ́mí mìíràn, àti àwọn ìjàmbá mìíràn. 

Gẹ́gẹ́ bí àjọ ìfọwọ́sowọ́pọ̀ láàárín àwon ìjọba orílè-èdè àgbáyé tó ń rí sí àwọn ọ̀rọ̀ tó níṣe pẹ̀lú àyípadà ojú ọjọ́ (Intergovernmental Panel on Climate Change (IPCC)), àyípadà ojú ọjọ́ ti ń nípa lórí gbogbo agbègbè tó wà ní àgbáyé, tí èyí sì ń farahàn nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bíi àyípadà ìṣọwọ́rọ òjò, ẹ̀kún omi, yíyọ́ọ yìnyín, ìgbóná omi òkun, àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ abanilẹ́rù mìíràn tí ó ti ń ṣẹlẹ̀ sí ọ̀pọ̀ ènìyàn káàkiri. Àwọn àyípadà ojú ọjọ́ wọ̀nyí ń gbilẹ̀ tí wọ́n sì ń ràn bíi iná inú ọyẹ́ ni.

Àjọ United Nations kín ọ̀rọ̀ yìí lẹ́yìn. Wọ́n ṣàlàyé wípé, àyípadà ojú ọjọ́ leè nípa lórí ìlera wa, bí a ṣe leè ṣ’ọ̀gbìn oúnjẹ wá, ilé’gbèé, ààbò àti iṣẹ́. Àti wípé, àyípadà ojú ọjọ́ ń nípa lórí ẹgbẹ́ àwọn ènìyàn kan ju àwọn ẹgbẹ́ ènìyàn mìíràn. Fún àpẹẹrẹ, àwọn tó ń gbé ní orílè-èdè tí ó jẹ́ erékùṣù kékeré. Ìpayà ewu ẹ̀kún omi ti mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn sá àsálà kúrò ní ìlú wọn. Pabambarì ọ̀rọ̀ náà ni wípé, iye àwọn tí ó ṣeéṣe kí ó tún fi tipátipá kúrò ní agbègbè wọn, leè tún pọ̀ síi ní ọjọ́ọ’wájú.

Àwọn ewu tó rọ̀ mọ́ àyípadà ojú ọjọ́

Àbájáde ìwádìí sọ wípé, yíò tó bílíọ̀nù méjì sí mẹ́rin owó dọ́là ilẹ̀ Amẹ́ríkà, tí yíò máa bá ọ̀rọ̀ ìlera lọ látàrí àyípadà ojú ọjọ́. Èyí túmọ̀ sí pé, àyípadà ojú ọjọ́ ní ewu fún ìlera ènìyàn.

Àyípadà ojú ọjọ́ leè sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ di aláìnílé lórí nípa Ìjì líle, ẹ̀kún omi, ìṣẹ̀lẹ̀ omíyalé tàbí ìtàn ìtànkálẹ̀ aṣálẹ̀. Ó leè fa ooru àmújù àbí iná àjóràn. Ó leè fa ìyàn àbí ààtò oúnjẹ, òṣì, pípàdánù àwọn ẹranko igbó àbí kí ó mú wọn sá kúrò ní agbègbè kan lọ sí òmíràn. Wọ̀nyí àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ewú ni ó rọ̀ mọ́ àyípadà ojú ọjọ́.

Àwọn ohun tí o ní láti ṣé láti dẹ́kun àyípadà ojú ọjọ́

Ọ̀run ń yaá bọ̀, kìí ṣe torí ẹnìkan o. Gbogbo ènìyàn pátá ló ní ìṣẹ́ láti ṣe kí á leè dẹkùn àyípadà ojú ọjọ́ àti ewú tó rọ̀ mọ́ọ.

A gbọ́dọ̀ dẹkùn igi gígé. Nígbàtí ó bá sì pọndandan fún ọ láti gé igi, o gbọ́dọ̀ ríi dájú wípé o gbin ọ̀pọ̀ igi mìíràn rọ́pò ọkàn tí o bá gé. Yàtọ̀ sí ẹwà tí igi ń mú bá àyíká wa, igi ní ànfàní tó pọ̀ púpọ̀. Igi a máa dá Ìjì àti àwọn Ìjì líle dúró dípò kí wọ́n bì lu ilé. Igi a sì máa dá ọ̀gbàrá dúró pẹ̀lú. Nígbàtí tí o bá gbin igi, yíò máa pèsè àtẹ̀gùn tí ó mọ́ tí ó ṣeé mí sí imú, yíò sì tún pèsè òjìji fún wa. Igi máa ń dènà ìtànká aṣálẹ̀ pàápàá, ó sì tún leè pèsè oúnjẹ jíjẹ fún ènìyàn àti ẹranko.

Àyípadà ojú ọjọ́, ìjàmbá àti àwọn ohun t'o ní láti ṣe

Ewu púpọ̀ ló rọ̀ mọ́ ayípadà ojú ọjọ́. Orísun Àwòrán: The Cable.

O gbọ́dọ̀ dẹkùn ilẹ̀ sísun, ààtàn sísun àbí dídáná sun igbó. Gẹ́gẹ́ bí o ti mọ ìjàmbá tí afẹ́fẹ́ carbon ń ṣe, nígbàtí o bá dẹkùn àwọn ìṣe wọ̀nyí (ilẹ̀ sísun, dídáná sun igbó, abbl), a leè ní ìrètí dídín afẹ́fẹ́ carbon kù ní ojú òfurufú.

Pípàrọ̀ ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ àti àwọn alùpùpù elépo rẹ sí àwọn tó ń fi agbára oòrùn àbí iná ẹ̀lẹ́tíríkì ṣiṣẹ́. O leè lo kẹ̀kẹ́-aláfẹsẹ̀wà bí ó bá ṣeéṣe. O ní láti máa ṣe àtúnlò àwọn ohun èlò rẹ dípò rírà òmíràn. Nípa ṣíṣe èyí, a óò dín fífi ohun ìní ṣòfò àti níní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ láti dànù. Dídín oúnjẹ tí o fi ń ṣòfò ṣe pàtàkì pẹ̀lú. Bí o bá ní láti da ohun jíjẹ nù, kí o ri dájú wípé o ri àwọn àjẹkù oúnjẹ náà mọ́ inú ilẹ̀.

Àwọn ìgbésẹ̀ wọ̀nyí àti àwọn òmíràn bíi, ṣíṣe ìtọ́jú àyíká rẹ, dídín iná mànàmáná tí ò ń lò kù, fífi òye àyípadà ojú ọjọ́ yìí yé àwọn ẹlòmíràn, yíò ràn wá lọ́wọ́ láti dẹ́kun àyípadà ojú ọjọ́. 

Àkọtán 

Àyípadà ojú ọjọ́ ń ṣẹlẹ̀ ní tòótọ́ ó. Kìí ṣe àròsọ lásán rárá. Ó ń ṣokùnfà ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìjàmbá fún ènìyàn àti àyíká wa, a sì gbọ́dọ̀ gbé ìgbésẹ̀ láti dẹ́kun rẹ̀. 

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Back to top button