ElectionsFact CheckMedia LiteracyYoruba

Ẹṣọ́ra o! Ẹ má ṣe tẹ àtẹ̀jísẹ́ sí ilà fóònù 8014, bí ẹ ṣe lè ṣe àrídájú ibùdó ìdìbò yin lóri ayélujára rèé

Àhésọ: Kí olùdìbò lè ṣ’awari ibùdó ìdìbò rẹ, tẹ àtẹ̀jísẹ́ pẹ̀lú nọ́mbà mẹsan orí káádì ìdìbò alálòpé rẹ ránṣẹ́ sí 8014. 

Ẹṣọ́ra o! Ẹ má ṣe tẹ àtẹ̀jísẹ́ sí ilà fóònù 8014, bí ẹ ṣe lè ṣe àrídájú ibùdó ìdìbò yin lóri ayélujára rèé

Àbájáde ìwádìí: Irọ́ ni. Ìwádìí wà ati alaye Ileeṣẹ àjọ tó ń risi ètò ìdìbò INEC fihàn pé ilá fóònù 8014 o ni ìbátan kankan pẹlu INEC tabi bi ènìyàn ṣe le ṣe awari ibùdó ìdìbò rẹ. 

Ìròyìn ni kikun

Idìbò gbogbogbò orílè-èdè Nàìjíríà yóò wáyé ni ọjọ́ keedogbon, oṣù kejì ọdún yìí. Bí èyí ṣe ń sunmọle ni àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà náà nlọ gba káádì ìdìbò alálòpé wọn. 

Àjọ elétò ìdìbò INEC ní olú ìlú orílè-èdè Nàìjíríà ti ṣe agbekalẹ ibùdó miran ti olùdìbò lè ti gba káádì ìdìbò alálòpé wọn, kí ó lè yá. 

Àjọ elétò ìdìbò náà tí kéde pé gbogbo ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó ti forukọsilẹ gbọdọ gba kaadi idibo naa saaju ojo keedogbon, oṣù kínní ọdún yii. Bi eyi ti n lọ lọwọ, àtẹ̀jáde akalekalo kan tàn ká orí ẹrọ ibaraẹnisọrọ WhatsApp. Àtẹ̀jade naa sọ pé ti ènìyàn bá tẹ àtẹ̀jísẹ́ pẹlu nọmba mesan ori kaadi ìdìbò sí ila foonu 8014, eyi yóò tọka adiresi ibùdó ìdìbò.

Atejade naa salaye pe àìní ìmòye ibùdó ìdìbò ko gbodo dènà olùdìbò láti má dibo. 

Ẹṣọ́ra o! Ẹ má ṣe tẹ àtẹ̀jísẹ́ sí ilà fóònù 8014, bí ẹ ṣe lè ṣe àrídájú ibùdó ìdìbò yin lóri ayélujára rèé
Aworan to ṣàfihàn atẹjade orí WhatsApp.

”Mi o mọ ibùdó ìdìbò mi kii se ìdáláre fún ẹnikẹni lati má dibo. Ẹ ṣe ifiranṣẹ nọmba mẹsan to wa lórí kaadi ìdìbò yin sí ila foonu 8014, leyin eyi, àtẹ̀jísẹ́ miran ti o gbe adiresi ibùdó ìdìbò yin yóò wọnu foonu yin,” atẹjade náà ló sọ bayii. 

Bi àsìkò ìdìbò ṣe ń sunmọle, àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà náà n ṣe ìtara láti mọ nípa bi wọn ṣe lè lo ẹtọ wọn gegebi olùdìbò ki wọn lè ṣe ìpinnu tó tọ. Nitori náà, a gbọdọ ṣ’aridaju pe àlàyé tabi ifilo tó munadoko wà ní arọwọto wọn. 

Isamudaju

Ibùdó ìdìbò ni ibi tí olùdìbò ti lè ṣe iforukọsilẹ ti yóò sì dìbò lọjọ ibo. Lati se awari ibùdó ìdìbò yin, ẹ le lo èrọ ìgbàlódé Polling Unit Locator Tool, ẹ o fi orúkọ ipinle yin, ijoba ibile ati ijoba agbegbe sí inú ẹrọ ìgbàlódé náà ti yóò ran yi lọwọ láti ṣàwarí ibùdó ìdìbò yin,

Ẹṣọ́ra o! Ẹ má ṣe tẹ àtẹ̀jísẹ́ sí ilà fóònù 8014, bí ẹ ṣe lè ṣe àrídájú ibùdó ìdìbò yin lóri ayélujára rèé
Aworan ẹrọ ìgbàlódé PU Locator Tool

Àjọ INEC ò mọ̀ nípa nọmba 8014 yìí

DUBAWA kan sí komisona fún àjọ ètò ìdìbò INEC Festus Okoye, o sì sàlàyé pé àjọ náà kọ ni o ṣẹda nọmba 8014 ọ̀ún. 

“Kiise INEC lo fi atejade yii sita,” eyi ni esi ọgbẹni Okoye sí ìbéèrè wa. 

Ni igba ti a kan sí agbẹnusọ alága àjọ INEC, Rotimi Oyekanmi, ó fi atẹjade kan, lori ìkànnì abeyefo Twitter, ránṣẹ sí wa. Atejade naa to wa lóri ojú òpó INEC se ìfilọ́lẹ̀ bi olùdìbò ṣe lè ṣe awari ibi ti yóò ti gba kaadi idibo rẹ.

”Ajo to n risi eto idibo INEC ti ṣe ni irọrun fún olùdìbò láti gba kaadi idibo alálòpé wọn ni agbegbe wọn. Awọn olùdìbò to ti fi orúkọ silẹ le tẹ atejise awon alaye ti o tọ sí ọkan lára awon ila foonu meji yii ki won le ṣe awari ibi ti wọn yóò ti gba kaadi idibo won.”

Awọn nọmba náà ni 0906-283-0860 ati 0906-283-0861. Ki olùdìbò fi ipinle, ijoba ibile ati ijoba agbegbe wọn ránṣẹ sí awọn nomba yii. 

Ẹṣọ́ra o! Ẹ má ṣe tẹ àtẹ̀jísẹ́ sí ilà fóònù 8014, bí ẹ ṣe lè ṣe àrídájú ibùdó ìdìbò yin lóri ayélujára rèé
Aworan ti INEC fi sí ojú òpó rè lorí ìkànnì abeyefo Twitter pẹlu alaye lori bi olùdìbò se le gba kaadi idibo alalope won.

Kini nomba 8014 yìí wà fún àti pé báwo ni wọn ṣe n lo?

Oniwadi wa tele ilana tó wa nínú atẹjade akalekalo yii, o sì fi nọmba mesan ori kaadi idibo rẹ ransẹ sí ila foonu 8014 ṣùgbọ́n èsì tí ó gbà kò ni nkankan ṣe pẹlu ibùdó ìdìbò. 

Ẹṣọ́ra o! Ẹ má ṣe tẹ àtẹ̀jísẹ́ sí ilà fóònù 8014, bí ẹ ṣe lè ṣe àrídájú ibùdó ìdìbò yin lóri ayélujára rèé
Aworan esi àtẹ̀jísẹ́ náà 

Leyin ti o tẹ atejise sí 8014, atejise kan lati nọmba miran (9001) wọ ori foonu oniwadi, èyí si ṣàlàyé pé wọn a yọ aadota naira (N50) kúrò lórí foonu oniwadi wa. Atejise náà fayesile fún oniwadi lati ṣe itẹwọgbà tabi kọ̀ọ́

Leyin ti o ṣe itẹwọgbà tan, ifiranṣẹ miran wolé sí ori foonu oniwadii, ifiranṣẹ náà ṣàlàyé pé wọn ti se àgbàsílẹ̀ esi oniwadii wa, pelu ileri pe ifiranṣẹ miran yóò tẹlẹ.

Ẹṣọ́ra o! Ẹ má ṣe tẹ àtẹ̀jísẹ́ sí ilà fóònù 8014, bí ẹ ṣe lè ṣe àrídájú ibùdó ìdìbò yin lóri ayélujára rèé
Aworan èsì àtẹ̀jise keji

Amosa, wakati merinlelogun ti kọja, ko sí sí oun tó jọ bẹẹ. Botilejepe a ko le so nipato oun ti nomba 8014 yìí n se, ko ni nkan ṣe pẹlu bi é sele ṣ’awari ibùdó ìdìbò yin tabi ibi ti e o ti gba kaadi idibo alálòpé yin.  

Àkótán

Ìwádìí wà àti èsì àjọ elétò idibo INEC ṣàfihàn pe nomba yii o ni nkankan se pelu àjọ náà tàbí sise awari ibùdó ìdìbò. 

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Back to top button