Getting your Trinity Audio player ready...
|
Ahesọ: Ojúlé wẹ́ẹ̀bù kan ni wọn ṣ’atunpin lórí ìkànnì WhatsApp, wọn ni a lè fi ṣe àtúnṣe orúkọ fún nọmba ìdánimọ̀, NIN.

Àbájáde ìwádìí: Irọ́ ni. Ìwádìí wa fi mu’lẹ pé ojúlé wẹ́ẹ̀bù yii kii ṣe ojúlówó. Ayédèrú linki ni wón fi sì orí atẹjade yìí.
Ẹkunrẹrẹ ìròyìn
Àwọn olumulo ikanni ibaraẹnisọrọ WhatsApp ṣ’atunpin ojúlé wẹ́ẹ̀bù kan láìpẹ́ yii, wọ́n ní ijọba àpapọ̀ ti paá ni ase fún ajọ to n rísí iforukọsilẹ fun idanimọ, eyi ti a mọ si NIMC lati ṣi ojúlé wẹ́ẹ̀bù kan ti yóò ràn àwọn ọmọ Naijiria l’ọ́wọ́ pẹlú àtúnṣe orúkọ.
Ifidiododomule
Akiyesi akọkọ ni wípé, kò sí àwọn leta pàtàkì tí o máà n gbeyin ojúlé wẹ́ẹ̀bù ijoba Nàìjíríà ‘gov.ng’, ojúlé wẹẹbu akalekako yii, ‘govspot.com’ lo gbẹyin rẹ.
Ni Ìgbà ti a tẹlẹ linki náà, ó gbé wa lọ ojúlé wẹẹbu miran. Linki tuntun ti a ri níbẹ̀ sì gbe wa lo ojúlé wẹẹbu kan ti àkòrí rẹ jẹ “Aaye Atunse/Iyatọ 2024”. Won ní ki a ṣe àtúnṣe ọjọ ìbí, orúkọ, nọmba ìpè, adirẹsi ati bẹẹbẹẹlọ.
Akiyesi wa ni wípé, ojúlé wẹẹbu tuntun yii bẹrẹ pẹlú “bet9ja” — tí ó jẹ́ ilé-isé tẹtẹ — èyí sì yato gedegbe sí oun tí wọn ni a le fi wẹẹbu náà ṣe.
Oniwadii wa ṣe bi ẹni ti o fẹ ṣe àtúnṣe orúkọ. Sugbon, linki náà gbe lọ ojúlé wẹẹbu miran ti àwọn eniyan ti n sọ ẹrí won pẹlú lilo ikanni náà fún atunṣe orúkọ. O ni kí a tè bọ́tìnnì kan láti ṣe ayewo bóyá o tọ sì wa láti ṣe àtúnṣe abi bẹẹkọ.
Ojúlé wẹẹbu ti o gbe wa lo yìí ní ki a f’orukọ sílẹ̀, o bere boya olumulo jẹ́ okunrin tabi obinrin, ọjọ́ ìbí, adirẹsi, nọmba ìpè ati ìpínlẹ̀. A sẹ àkíyèsí pé linki náà paradà di https://dffsfggdfjhffgjjhssf.blogspot.com/ eyi ti o ni kí a fì orukosile fún owó ọ̀fẹ́ ẹgbẹrun mẹẹdọgbọn N25, 000.
Leyin ti oniwadii wa tèsíwájú, o ri atẹjisẹ kan to kii ku oriire, o si ní ki o ṣ’atunpin linki náà pèlu èèyàn mẹẹdogun lórí ìkànnì ibaraẹnisọrọ Whatsapp ki o to le lọ ṣe àtúnṣe orúkọ fún nọmba idanimọ NIN. Eyi jẹ oun kan pàtàkì tí a máà n fi n ṣe ìdámọ̀ àwọn ayédèrú ojúlé wẹẹbu.
Siwaju sì, a lo aaye ayelujara Whois.com láti tọpinpin ẹni ti o ni ayédèrú ojúlé wẹẹbu náà, a ríi wípé, MarkMonitor Inc, ti o jẹ onisowo ni ìlu Amerika lo nii.
Wọn sì ojúlé wẹẹbu náà ni oṣu keje ọdún 2000, won sì ṣe àwọn àtúnṣe kọọkan sì ni oṣu kẹfa ọdún 2023, akoko iwe ẹri ojúlé wẹẹbu náà dopin ni oṣu kefa odun 2024.
A fì idi re mu’le pé àjò NIMC o gbani l’áyé láti ṣe àtúnṣe kọọkan l’ọ̀fẹ́ lori ojúlé wẹẹbu tàbí lórí ẹrọ alatagba.
A ríi wípé ninu ojulowo ojúlé wẹẹbu ti NIMC gbe kalẹ fún atunṣe nọmba idanimọ, ni àwọn lẹta wonyi gov.ng.
Akotan
Àwọn oni’tanjẹ mọọmọ lo linki yii https://tr.ee/Nimc-Portal-For-Correctioni/ lati gbe wa lo ayédèrú ojúlé wẹẹbu ki èniyàn ti kò ba fura le ro pé ojulowo ni, won a sì lo àwọn nọ́mbà idanimọ ọnítọ̀ún fún jibiti ni ọjọ́ iwaju. Nitori naa, ayédèrú ni ojúlé wẹẹbu akalekako náà.