ElectionsExplainersFeaturedMedia LiteracyYoruba

Ìdìbò ọdún 2023: ìbéèrè mẹwàá nípa àyẹ̀wò orúkọ ati ìdìbò ni ọjọ ibo

Ti a ba gbe iwa ìbàjẹ́ sapa kan, ailemuilerise ati awọn oun míràn, àìní ìmòye nípa ètò ìdìbò jẹ ọkan lára àwọn oun tí ó maa n fa aibikita olùdìbò ni orílè-èdè Nàìjíríà.

Ìdìbò gbogbogbò ọdún 2023 yóò wáyé láàrin aadọrin ọjọ, o sì ṣe dandan kí olùdìbò ni oòyè awọn oun kọọkan nipa ètò ìdìbò. 

Nítorí eyi, akọsilẹ yìí yóò dáhùn ìbéèrè mẹwàá tí ẹ lè ni lorii àyẹ̀wò orúkọ l’ojo ìdìbò àti bí ènìyàn ṣe le dìbò yan oludije ti o fẹ ni ojo idibo. 

  1. Asiko wo ni wọn yóò bèrè ayẹwo orukọ, ati pé ìgbà wo gaan ni ìdìbò yóò bẹ̀rẹ̀? 

Gẹgẹbi agbekalẹ àjọ elétò Ìdìbò lorile-ede Naijiria, INEC, gbogbo ibùdó ìdìbò gbọdọ ṣí fún àyẹ̀wò orúkọ ati ètò ìdìbò ni ago mẹjọ owurọ. Ti o ba sì di aago meji osan, won gbodo fi òpin síi. 

Àmọ́ṣá, tí àwọn ènìyàn bá ṣì wà lórí ila ṣaaju aago meji ọ̀sán, alamojuto ètò ìbò yóò sọfún agbofinro kí o dúró sí ẹyin ènìyàn tó gbẹyin lórí ìlà, ki ààyè má wà fún ẹlòmíràn láti darapọ mọ wọn. 

  1. Tani ó lè dìbò?

Oludibo gbọdọ jẹ ọmọ orile-èdè Nàìjíríà ti ọjọ orí rẹ sì ti to ọmọ ọdún méjìdínlógún, olùdìbò gbọ́dọ̀ ti fi orúkọ silẹ, o sì gbọ́dọ̀ ni kaadi ìdìbò alálòpé (PVC), iru eniyan bẹẹ ni ẹtọ lati dibo. 

Amosa ti onítọ̀ún bá ni gbogbo oun ti a ka silẹ yìí sùgbón tí ó gba ibùdó ìdìbò ti ko ti fi orúkọ silẹ lọ, àjọ ètò ìdìbò Nàìjíríà (INEC) ti sọ pé irufẹ eniyan bẹẹ kọ ní le dibo. Sugbon, awọn oṣiṣẹ INEC le tọka iru eniyan bẹẹ si ibùdó ìdìbò to yẹ.

  1. Bawo ni wọn ṣe n ṣe ayẹwo orukọ?

Àyẹwò oruko jẹ ọnà kan ti a maá n gba ṣe idanimọ olùdìbò ti o kun oju osunwon lati dìbò. A tún lè sọ pé ayewo oruko je ona kan ti INEC le gba lati se àrídájú pé ènìyàn ní ẹtọ lati dìbò kí wọn to lè fún onitoun ni ààyè lati tẹsiwaju lọ dìbò. 

Òfin ètò idibo tuntun se ìfilọ́lẹ̀ pe oṣiṣẹ INEC gbọdọ ṣe ayẹwo fínífíní lori kaadi ìdìbò, olùdìbò sí gbódò ṣe ontẹ ika nipasẹ Bimodal Voter Accreditation System (BVAS). Leyin eyi, awọn oṣiṣẹ INEC a ṣe àwárí orúkọ oludibo lori ìwé ìforúkọsílẹ̀ awọn olùdìbò. Ti won ba ti ri oruko onítọ̀ún, won a fi àmì síi, wọn a tun fi inki ti a kò lè parẹ́ sí eekan-ọwọ olùdìbò. Eyi je ẹrí pé a ti ṣe ayẹwo orúkọ fún onítọ̀ún. 

  1. Bawo ni won se n dibo?

Ti won ba ti parii àyẹwò oruko, àwọn oṣiṣẹ INEC máa fún olùdìbò ni iwe pélébé ìdìbò ti alamojuto ètò ibo ti fọwọsi, fi ontẹ luu, ti won sì ti kọ deeti sí. Leyin eyi, won a dari olùdìbò sí àgọ ìdìbò ti yóò ti dibo.

Ni ipele yii, INEC fi ààyè sílẹ fún àwọn àkàndá ẹda láti ní oluranlowo (ti akanda eda yan funrararẹ). Ti awọn ohun elo iranlọwọ ba wa ni ibùdó ìdìbò, oṣiṣẹ INEC a fún ènìyàn ti ko riran.

Ni àgọ ìdìbò, olùdìbò ni lati ṣe ontẹ ika (eyi ti a ti fi inki sí) sí ẹgbẹ orúkọ olùdíje to wuu. Leyin eyi, olùdìbò máa yìí ìwé ìdìbò yii sì inú, tee pẹrẹsẹ yóò sì fi sí inú àpótí ibo to yẹ. Won gbodo ṣe eyi ni “ìkọ̀kọ̀ ni gbangba” ni ibamu pẹlu abala àádọta (apa kinni) ti òfin ìdìbò tuntun.

Leyin eyi, olùdìbò “le kuro ní ibùdó ìdìbò tàbí dúró tí o ba wu won, àmọ́ wọn gbọdọ ṣe eyi ni ọna to ba ofin mu, lati sakiyesi bi wọn yóò ṣe ṣe ikede esi ibo.”

  1. Se mo le ṣ’aami sí ìwé pélébé ìbò pẹlu ohun tó wù mí? 

Yato si inki ti a ko le parẹ ti INEC máa n lo, ti olùdìbò ba fi ohun miran bíi gege ikowe, se aami sí ìwé pélébé ìdìbò, irufẹ ibo naa ko ni já sí nkankan. 

Sugbon ti oludibo ba se aṣiṣe pẹlu ìwé pélébé ìdìbò, ti won ko sí lè lo iru pẹpa bẹẹ lati ṣe idiboyan oludije to wù wọn, wọn le mu iwe pelebe ìbò náà lè alamojuto eto ibo lọwọ. Ti alamojuto ibo ba ríi wípé, iwe pelebe ìbò náà kò ní seelo tabi pe o ti di ibaje, alamojuto eto ibo máa fún olùdìbò ni òmíràn. Alamojuto ibo gbọdọ fagile iwe pelebe ìbò ti ko ṣeelo yìí, lesekese. 

  1. Njẹ mo le ba ọrẹ mi dibo?

Rara, ajo eleto idibo INEC o fi ààyè gba ẹnikẹni lati ba elomiran dibo. Eyi ni won pe ni ‘afarawe’ tabi itanje. Enikeni tó bá ru òfin ni ọna yii, yóò ko sí gbágà ọlọpa, irufẹ eniyan bẹẹ yóò sì fojú ba ile-ejo.

Òfin yii mu ẹnikẹni ti alamojuto eto ibo ba gbagbo pe ko le tii to ọmọ ọdún méjìdínlógún. Eyi wa ni ibamu pẹlu abala ketadinlogota, apa kinni òfin ìdìbò tuntun. 

  1. Njẹ mo le pariwo oríkì ẹgbẹ òṣèlú ti mo fẹràn ni ibùdó ìdìbò?

Apá kinni abala kerinlelaadorun òfin ètò idibo tuntun paa lase pe gbogbo eto ipolongo idibo gbọdọ bẹrẹ ni aadojo ọjọ ṣáájú ọjọ ibo, ati wípé a gbọdọ mu opin dé bá ipolongo idibo ni wakati merinlelogun ṣáájú ọjọ ibo. Ẹ̀wẹ̀, ki ènìyàn máa pariwo oriki ẹgbẹ òṣèlú rẹ ni ibùdó ìdìbò tumo sí pé onitoun n se ipolongo fún ẹgbẹ òṣèlú rẹ ni. Kò sí ààyè fún ẹnikẹni lati ṣe eyi tabi gba ona miran lati rà ibo ni ọjọ ibo. 

  1. Nje mo le dibo fún Oludije meji?

Rara o, o ko le dibo fún oludije meji. Apa kinni abala kokanlelaadota ti òfin ètò ìdìbò tuntun ṣe ifilole pé, “Oludije kan pere ni olùdìbò le dibo yan, olùdìbò o sì tún ní anfààní lati dibo ju ẹẹkan lọ fún ẹnikẹni ni àsìkò ìdìbò kanna.”

  1. Nje mo le lo ẹ̀rọ aláàgbéká ninu agọ ìdìbò?

Rara o. Èwọ̀ ni ki ènìyàn lo fóònù tàbí ẹrọ alágbèéká kankan ninu agọ ìdìbò, gege bi òfin ètò idibo tuntun. Eyi ni lati dena iwa ìbàjẹ́ ní àsìkò ìdìbò. 

  1. Kini yóò ṣẹlẹ ti esi ba pọ ju iye eniyan to dibo lọ?

Apa keji abala kokanlelaadota ti òfin ètò idibo tuntun ṣe ìpèsè pe ti esi ibo ba ju iye eniyan to lẹtọ lati dibo lọ, alamojuto ibo lè fagile esi ibo ni ibùdó ìdìbò náà. 

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Back to top button