African LanguagesFact CheckYoruba

Ìdìbò ọdún 2023: Ko ṣeeṣe kí o fi onka nomba marun-un to gbeyin nọmba VIN, dìbò

Àhésọ: Olùdìbò ní ànfààní láti dìbò pẹ̀lú ònkà marun-un to gbẹyin nọmba idanimọ olùdìbò VIN nikan, láìsí kaadi idìbò alálòpé.

Àbájáde ìwádìí: Iro ni. Káádì ìdìbò alálòpé nìkan ni ó fún olùdìbò ní ànfààní láti dìbò, nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí o bá fẹ́ dìbò gbọ́dọ̀ gba káádì ìdìbò alálòpé rẹ̀. 

Ìròyìn lẹkunrẹrẹ 

Bi àsìkò ìdìbò ti ń sunmọle, pẹlu afikun iye ọjọ́ ti àwọn aráàlú lè gba káádì ìdìbò alálòpẹ́ wọn, orísirísi ìròyìn nípa gbígba káádì ìdìbò alálòpé ni àwọn ènìyàn ń gbé káàkiri, yálà lórí ibi tí wọn ti lè gba káádì náà tàbí lórí bí wọn ṣe lè lo káádì ìdìbò ní ọjọ́ ìdìbò. 

Àhésọ kan tí ó tàn ká orí ayélujára s’ọpẹ a lè lo ònkà nọmba marun-un to gbẹyin VIN láti dìbò. Àtẹ̀jade náà sọ pé olùdìbò lè ṣe àmúlò ònkà nọmba marun-un yìí láti dìbò, ọpẹ́lọpẹ́ ẹ̀rọ ìgbàlódé fún ètò ìdìbò, Bimodal Voter Accreditation System (BVAS).

Atẹjade náà f’ikun pé kí àwọn ènìyàn lọ ṣe àyẹ̀wò ọrúkọ wọn ni ojú òpó INEC lórí ayélujára tí ó niiṣe pẹlu ìforúkọsílẹ̀ olùdìbò. Olùdìbò tí orúkọ rẹ̀ bá wà ní orí ojú òpó INEC yìí lè ṣe àkíyèsí nọ́mbà marun-un ti o gbẹyin VIN yi, yóò sì fi dìbò.

Aworan atejade ná

Ọpọlọpọ ènìyàn ló gba atẹjade náà gbọ, tí wọn sì tún ṣ’atunpin rẹ l’órí WhatsApp.

Àwòrán atẹjade náà lórí ojú òpó ibaraẹnisọrọ ẹnìkan

Ni igba ti a ríi wípé, ọpọlọpọ ènìyàn ló n sọrọ nípa rẹ̀ àti wípé o lè mú àkóbá bá àwọn olùdìbò, DUBAWA ṣe itopinpin òtítọ́ ọ̀rọ̀ náà.  

Ifidiododomule

Ìpín kejì òfin àti ìlànà àjọ elétò ìdìbò INEC fún ìṣàkóso ìdìbò (2022), filélẹ̀ pé ìdìbò yóò wáyé nípasẹ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé Continuous Accreditation and Voting System (CAVS).

Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ dìbò gbọ́dọ̀ pèsè káádì ìdìbò alálòpé rẹ̀, lẹyìn èyí, òṣìṣẹ́ INEC á lo BVAS láti ṣ’aridaju bóyá ojúlówó ni káádì náà tàbí ayédèrú. 

Ìlànà náà fikun pé olùdìbò kò lè dìbò ní ibòmíràn yàtọ̀ sí ibùdó ìdìbò tí ó ti f’orúkọsílẹ̀. Orúkọ rẹ̀ si gbọ́dọ̀ wà ní inú ìwé ìforúkọsílẹ̀ àwọn olùdìbò. 

Bákan náà, kọmisọna àjọ elétò ìdìbò, Festus Okoye sọ pé ìrọ́ ni àtẹ̀jade náà, pẹlu àlàyé pé àgbékalẹ̀ rẹ lórí ètò ìdìbò kò yẹ̀.

“A ti pe àkíyèsí kọmisọna àjọ elétò idìbò sí atẹjade ayédèrú kàn ti àwọn ènìyàn ń pín ká orí ayélujára. Nínú atẹjade náà, wọn gbé àhesọ pé àwọn olùdìbò ò nilo káádì ìdìbò alálòpé wọn láti dìbò, yatọ sí ònkà nọmba marun-un to gbẹyin VIN wọn.

“Kaadi ìdìbò alálòpé nìkan ni a lè fi ṣe idanimọ olùdìbò lójó ìdìbò. Olùdìbò ti kò ní káádì ìdìbò alálòpé ò le dìbò. Ìlànà àjọ elétò ìdìbò níi wípé, ẹnikẹ́ni tí kò bá ní káádì ìdìbò alálòpé ò le dibo,” Okoye sọ èyí nínú atẹjade kan. 

Ìpín kinni, apá ketadinlaadota ti ètò ìdìbò tuntun ọdún 2022 fi lé lẹ̀ pé, “enikeni tí ó bá fẹ́ dìbò ní ọjọ́ ìbò gbọ́dọ̀ fi ara rẹ̀ hàn pẹ̀lú káádì ìdìbò alálòpé rẹ̀ fún alamojuto ètò ìdìbò fún isamudaju ni ibùdó ìdìbò ti ó ti fi orúkọ silẹ”.

Bákan náà, o ṣe pataki kí a mọ pé ẹ̀rọ ìgbàlódé ìdìbò BVAS f’aaye sílẹ fún idanimọ olùdìbò pẹlu ìmọ̀ ẹ̀rọ tó n ṣe àmúlò ontẹ ika, ati ojú, kiise ònkà nọmba tó wá lórí VIN.

Àkótán

Àbájáde ìwádìí wa fihàn pé bó ti lẹ̀ jẹ́ pé adiresi ojú òpó tí wọn fi sí orí àtẹ̀jáde akalekalo náà je ojúlówó, àhesọ pé olùdìbò lè lo ònkà nọmba marun-un to gbeyin VIN nìkan lati dìbò, kìí ṣe ootọ. Irọ́ nla àti aṣinilona ni ọ̀rọ̀ náà.

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Back to top button