EconomyFact CheckYoruba

Iro àti aṣinilọna ni ìròyìn akálékáko pé ìjọba àpapọ̀ fẹ́ ṣ’àfikún owó oṣù Tinubu, Shettima

Ahesọ: Ìwé ìròyìn Daily Trust ṣe àgbéjáde ìròyìn kan pé ìjọba àpapọ̀, latarii àjọ tó ń rísí ìṣúná owó, Revenue Mobilisation, Allocation and Fiscal Commission (RMAFC) ti f’ọwọ́sí àfikún owó oṣù awọn aṣèjọba lọnà ẹ̀rin lé ní àádọ́fà (114%).

Àbájáde ìwádìí: Aṣinilọna ni ọrọ yìí. Botilẹjẹpe àjọ RMAFC daba fífi owó kún owó olóṣèlú ní ìgbà tí ìjọba Buhari wà lórí oyè, ìjọba tuntun yii ò tíì fi ọwọ́ sí àbá náà. 

Ìròyìn lẹkunrẹrẹ

Láti ọjọ iburawọle sí ipò ààrẹ, ààrẹ tuntun orile-ede Nàìjíríà, Bọla Tinubu ti bèrè síí gbé ìgbésẹ láti fi ìdí awọn ìlànà kọọkan múlẹ, èyí sì ti ni ipa lori awọn ara ìlú. Ìlànà kan tó ṣe pabambari ni ìyọkúrò owó ìrànwọ́ epo bentiroolu tí ó ti fa ọpọlọpọ ìyà àti ìṣẹ́ fún àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà; oúnjẹ ti wọ́n, bẹẹ si ni owó ọkọ̀ náà wọ́n.

Àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí gbà ajo RMAFC nímọ̀ràn láti yo kuro ninu owó awọn aṣèjọba, pàápàá ní àsìkò tí ààrẹ tẹlẹri Muhammadu Buhari ṣi wà lórí oyè. 

Ó jé iyalẹnu ní ọjọ́ kokanlelogun oṣù kẹfà ti ìwé ìròyìn Daily Trust gbé ìròyìn pé ìjọba àpapọ, nipasẹ àjọ RMAFC, ti f’ọwọ́sí àfikún owó awon aṣèjọba lọnà ẹ̀rin lé ní àádọ́fà. “Ijoba àpapọ ti ṣàfikún owo osu Tinubu Shettima pẹlu ipin ẹ̀rin lé ní àádọ́fà”, àkòrí iroyin náà ló sọ báyìí. Kódà, iwe ìròyìn Peoples Gazette gbé ìròyìn náà. 

Ìwé ìròyìn mejeeji lo tọkasi ìròyìn kan láti ile iṣẹ iroyin orile-ede Naijiria (News Agency of Nigeria). Wọ́n sọ wípé adarí àjọ RMAFC, ọgbẹni Muhammad Shehu sọ ọrọ yìí ní ibi ìpàdé kan ní ìpínlè Kebbi. Aṣojú adarí RMAFC, Rakiya Tanko-Ayuba ti o je komisona ìjọba àpapọ ṣàlàyé pé ọdún 2007 ni ìgbà kẹyin tí wọ́n ṣe àfikún owó àwọn aṣèjọba. 

Lẹ́yìn ti ìròyìn náà tànká, awọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí faraya lórí ọrọ náà. Ọpọlọpọ lo sọ wípé ó ṣe pàtàkì ki owó aṣèjọba orile-ede yii dínkù.  

Lẹ́yìn eyi, àjọ ti máa n já fún ètò ọmọ ènìyàn, Socio-Economic Rights and Accountability Projects (SERAP), se ipenija fún ìjọba lati dawọ irufẹ nkan bẹẹ dúró tàbí ki o gbaradi láti mojuba ilé ẹjọ́. 

“Iroyin pajawiri: Ìjọba Tinubu gbọdọ tako àbá ti àjọ RMAFC mu wa lati ṣe àfikún owó awọn aṣèjọba lọnà ẹ̀rin lé ní àádọ́fà, ati ìgbésẹ láti lo biliọnu merinlelogun náírà lórí àwọn osise ile igbimo aṣofin. Tí e kò bá fopin si awọn àbá yìí, a máa pàdé ní ilé ẹjọ,” atejade ti àjọ SERAP fi sí ojú òpó rè lorí ìkànnì abẹ́yẹfò ni eyi. 

Atẹjade naà fihàn gbangba pé àbá lásán ni ọrọ náà, ìjọba tuntun naa ò tíì fi ontẹ lùú. DUBAWA gbé ìgbésè láti fi idi ododo múlẹ̀ kí a lè dẹkun iruju lori ọrọ náà. 

Ifidiododomule

Ipin eerinlelogorin ti ìwé òfin ọdún 1999 ṣàlàyé pé àjọ RMAFC lè ṣe ìpinnu lórí àfikún owó àwọn aṣèjọba, apá kẹrin ìpín náà ṣàlàyé àwọn aṣèjọba ti o le jẹ anfaani naa. Awon aṣèjọba ati oṣiṣẹ ijoba naa ni awon ti o n sise ni ẹka imunimofin, eka ti o n ṣe ofin, ati awon agbofinro. Kódà apa kerin ipin erinlelogofa se ìpèsè fún àwọn oṣiṣẹ ìjọba ni ipinle.

Ìpín aadọrin ṣàlàyé pé àwọn oṣiṣẹ ẹka ìjọba aṣòfin ti ijoba apapo lè jẹ ìgbádùn àfikún owó, kódà ìpèsè náà wà fún àwọn aṣòfin ti ìpínlè, gẹgẹbi ìpèsè ìpín ọ̀kan lé ní àádọ́fà.

Ṣùgbọ́n, o ṣe dandan ki ìjọba ṣe ìpèsè awọn ètò kọọkan kí àfikún owó tó wáyé. Ààrẹ orílẹ̀-èdè le fọwọsi àbá tàbí ìpinnu àjọ RMAFC leyin ti wọn ba ṣe àgbéyẹ̀wò rẹ̀ fínífíní gẹgẹ bi ipin merinlenigba òfin náà

Àmọ́ṣá, ààrẹ gbọ́dọ̀ ṣe ìpàdé pẹ̀lú àjọ àwọn mínísítà ṣaaju ifọwọsi àfikún owó naa, gẹgẹbi ìsòrí kefa ìwé òfin tí wi. Ni àsìkò ti a ṣ’agbejade ìròyìn yii, ní ọjọ kokanlelogun oṣù kẹfà ọdún yii, ààrẹ tuntun ò tíì yan awọn mínísítà tó lè gbàá nímọ̀ràn nipa ọrọ naa. 

Bákan naa, ààrẹ Tinubu rin irin àjò lọ sí orile-ede Parisi ni ibi ti o ti n ṣe ìpàdé lori ìṣúná owó pẹlu awọn lobaloba. Kódà aare orile-ede Faransé Emmanuel Macron lo pe ìpàdé yìí. 

Ìròyìn akalekako náà ṣàlàyé pé ìjọba ti fọwọsi àfikún owó láti asiko ijoba Buhari, ni ojo kinni odun 2023. Sugbon, ko sí ìpèsè fún àwọn oṣiṣẹ ijoba ti wọn jẹ aṣòfin àti agbofinro. Awon aṣèjọba eka ìjọba imunimofin àti oṣiṣẹ ìjọba miran nìkan ló ni anfaani yìí. 

Kódà agbẹnusọ àjọ RMAFC, ọgbẹni Christian Nwachukwu sọ̀rọ̀ pé ààrẹ Tinubu ò fọwọsi àbá náà.

Àkótán 

Botilẹjẹpe òtítọ ni ọrọ pe ajo RMAFC ń gbero láti ṣe àfikún owó àwọn oloselu lọnà ẹ̀rin lé ní àádọ́fà, ẹka ìjọba meji ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló ní lati fọwọsi. Ati wipe agbẹnusọ àjọ náà ṣàlàyé pé ààrẹ Tinubu ò tii fi ọwọ síi. Nitori náà, èké àti aṣinilọna ni ìròyìn náà. 

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Back to top button