YorubaFact CheckMainstream

Irọ́ ni! Àgbà olorin Juju, Ebenezer Obey ò kú o

Getting your Trinity Audio player ready...

Aheso: Olumulo ikanni ibaraẹniṣọrẹ Facebook sọ wipe ilumọọnka olorin Ebenezer Obey-Fabiyi ti pakoda.

Irọ́ ni! Àgbà olorin Juju, Ebenezer Obey ò kú o

Abajade iwadii: Iro nla! Gbajúgbajà olórin naa funrare lo fohun pe oun ò kú, koda awon ojulowo iwe iroyin fi idi re mule pe olorin naa wa laaye.

Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé

Alagba Ebenezer Obey je agba olorin ti o se aseyori ni idi ise orin kikọ. Awon eniyan mọ si Baba Commander. Ni ọjọ kẹta osu kerin odun yii ni gbajugbaja olorin naa pe ọmọ odun mẹtalelọgọrin.

Tunde Sobowale, olumulo ikanni Facebook gbe ahesọ pe akorin agba, Ebenezer Obey ti di oloogbe.

“Sun re ni aya olugbala re, alagba Ebenezer Obey, commander ti ku,” Tunde lo kọ eyi si oju opo rẹ.

Nitori ẹni ti ọrọ kan, iroyin naa bere sii tan kaakiri ori ayelujara, wọn si ṣ’atunpin rẹ lopolopo igba. Oro naa se wa ni kayefi, DUBAWA si se iwadii lati fi idi ododo mule.

Ifidiododomule

A se itopinpin koko oro lori ayelujara, lati se iwadii oun ti àwọn ojulowo iwe iroyin n sọ nipa gbajugbaja olorin naa ṣugbọn a ko ri oun kankan. Ṣugbọn, a ṣ’abapade fọnran kan ni oju opo olorin naa lori ikanni Instagram ti o kọ ọ̀rọ̀ yii si, “MO WA LAAYE!!!!” ti o si fi opin si atotonu nipa iku re.

Koda, olorin naa kọ orin ni ede Yoruba ati ede Geesi lati sọ wipe oun o ku o. “Iroyin eleje bere sii gbode kan ni awon wakati kan seyin pe emi ajihinrere Ebenezer Obey ti pakoda. Irọ́ ni. Mo wa laaye.”

Tope Olukole, agbenuso olorin naa, ba ile-ise TVC sọ̀rọ̀. O ni, “Ẹ jẹ́ ka mo eyi to je ododo. Alagba Ebenezer Obey Fabiyi wa laye, won wa laaye! Laipe yii, won ba idile ọmọ wọn kan ṣ’ajọyọ. Iroyin ofege to n tan ka ori ayelujara wonyi jẹ iro ati asinilona. Inu wa dun pe Alagba wa laaye.”

Àwọn ojulowo iwe iroyin miran bii Punchng, Tribune Online ati iwe iroyin The Nation naa gbe iroyin pe alagba naa ṣi wa laaye.

Akotan 

Irọ ni ọ̀rọ̀ pe Ebenezer Obey ti di oloogbe. Olorin agba naa ati agbenuso re ti fi idi re mule pe alagba Obey wa laye ati laaye.

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Back to top button
Translate »