YorubaFact Check

Irọ́ ni! Ìwé ìrìnnà orílẹ̀-èdè Yorùbá kò ní ìdánimọ̀ òfin, wọn kò gbẹ́sẹ̀lé ìwé ìrìnnà Nàìjíríà 

Getting your Trinity Audio player ready...

Àhesọ: Koiki Media tẹ àtẹ̀jáde kan wípé àwọn orílẹ̀-èdè l’ágbàáyé ti ń gbẹ́sẹ̀lé ìwé ìrìnnà orílẹ-èdè Nàìjíríà. Bákannáà, ó wípé ìwé ìrìnnà ilẹ̀ Yorùbá ti ń fún àwọn ènìyàn láánfàní láti rìnrìn àjò jákèjádò Iwọ̀-oòrun Áfíríkà, Yúróópù, àti Àríwá Amẹ́ríkà.

Irọ́ ni! Ìwé ìrìnnà orílẹ̀-èdè Yorùbá kò ní ìdánimọ̀ òfin, wọn kò gbẹ́sẹ̀lé ìwé ìrìnnà Nàìjíríà 

Àbájáde Ìwádìí: Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àhesọ nípa ìdíwọ́ ìwé ìrìnà orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ṣini lọ́nà, inú fọ́nrán aṣàmúlò Facebook kan ni wọ́n ti yọ àwòrán ìwé ìrìnàjò orílẹ-èdè Yorùbá (Yorùbá Nation) yìí, tí wọ́n sì pààrọ rẹ láti tan àwọn ènìyàn jẹ.

Ìròyìn Lẹ́kùńrẹ́rẹ́

Bí àwọn ọmọ’lẹ́yìn bìáfúrà, tí a mọ̀ sí IPOB ṣe ń jìjàgbaara fún òmìnira ni Gúúsù-Ìlàoòrùn, l’àwọn ọmọ’lẹ́yìn Orílẹ-ède Yorùbá (Yorùbá Nation) ò dáwọ́ ẹkún ìpínyà dúró ní Gúúsù Ìwọ̀-oòrùn Nàìjíríà.

Láìpẹ́ yìí, Koiki Media, aṣàmúlò Facebook kan, èyí tó máa ń sábàá tẹ àtẹ̀jáde nípa Yorùbá Nation, fi àtẹ̀ránṣẹ́ kan sóri Facebook àti X pé, àwọn orílẹ̀-èdè l’ágbàáyé ti ń gbẹ́sẹ̀ lé ìwé ìrìnnà orílẹ-èdè Nàìjíríà. Sùgbọ́n, ìwé ìrìnnà ilẹ̀ Yorùbá ti ń fún àwọn ènìyàn láánfàní láti rìnrìn àjò jákèjádò Iwọ̀-oòrun Áfíríkà, Yúróópù, àti Àríwá Amẹ́ríkà.

Irọ́ ni! Ìwé ìrìnnà orílẹ̀-èdè Yorùbá kò ní ìdánimọ̀ òfin, wọn kò gbẹ́sẹ̀lé ìwé ìrìnnà Nàìjíríà 
Àwòrán àtẹ̀jáde ọ̀hún rèé lórí X.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èniyàn bíi Senaike Opeoluwa ló ti ṣiyè méjì lórí àfihàn yìí. 

“Ìwé ìrìnnà orílẹ-èdè Yorùbá? Ìgbà àkọkọ tí n ó gbọ́ èyí rèé,” o kọ s’ábala àríwísí.

Nì’dà kejì, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èniyàn náà lótún fara mọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, tí aṣàmúlò @Smile39526600 wípé, “Èyí ni ohun tí gbogbo wa tí ń retí.” Bákannáà ló bèèrè bí òhun yóò ṣe rí tirẹ̀ gbà.

Èyí kò yàtọ̀ lórí Facebook tí ookandínlẹ́gbẹ̀rin ènìyàn tí buwọ́lùú tí mẹ́rìnlélọ́gọ́rin sì ti pín àhesọ yìí káàkiri.

Lọ́pọ̀ ìgbà lati ká IPOB àti Yorùbá Nation m’ọ́dìí títẹ àtẹ̀jíṣẹ́ èké. DUBAWA pínú láti ṣe ìwádìí yìí nítorí bí àhesọ náà ṣe wúwo tó.

Ìfìdíòdodomúlẹ̀

Ní oṣù kẹjọ, ọdún 2025, Amẹ́ríkà àti orílẹ̀-èdè Árábù (United Arab Emirates), nìkan ló tí gbé àwọn ìlànà ìwé ìwọlú tó le ju t’àtẹyìnwá sóri àwọn aṣàmúlò ìwé ìrìnnà Nàìjíríà. Yàtọ̀ s’àwon èyí, kò tíì sí orílẹ̀-èdè kan tó gbẹ́sẹ̀ lé ìwé ìrìnnà Nàìjíríà pátápátá.

Kódà, dátà láti àbájáde ìwádìí atọka iwe irinna Henley ti Oṣù keje, ọdún 2025, fihàn pé ìwé ìrìnnà Nàìjíríà ti wà ní ìpò  eéjìdínlọ́gọ́rin (88) nínú àwọn orílẹ-èdè mọ́kàndínnígba (199). 

Ìjábọ̀ láti inú ìtọ́kasí yìí, èyítí wọ́n tẹ̀ sí’ta lọ́jọ́ kejìdínlógún, oṣù keje, kò mẹ́nuba ìwé ìrìnnà Yorùbá Nation kankan.

A ṣe ìwádìí àwòrán ìwé ìrìnnà Yorùbá Nation tí wọ́n fi kún àhesọ yìí. Àbọ rẹ̀ gbé wá lọ sí fọ́nrán Facebook kan tó ti wà lórí ẹ̀rọ ayélujára láti ọjọ́ kejìlélógún, oṣù kẹfà, ọdún 2025. A ṣe àfiwé àwọn méjèèjì. A rí àwọn òhun tí ó jọra, bákannáà, la rí àwọn òhun tó yàtọ̀ gédégbé.

Àkọ́kọ́, fọ́nrán ọ̀hún ṣàfihan ọwọ́ obìnrin kan tí ó mú ìwé ìrìnnà Nàìjíríà dání. Lókè rẹ̀, wọn kọ ọ̀rọ̀ tó kà lédè gẹ̀ẹ́sì pé “Economic Community of West African States.” Wọ́n sì kọ “Republic of Nigeria” sọ́wọ́ ìsàlẹ̀. 

Nínú fọ́tò tínu àhesọ yìí, a rí ọwọ́ obìnrin yìí kannáà. Sùgbọ́n, wọ́n yìí àwọn ọ̀rọ̀ t’ówà lókè àti ìsàlẹ̀ ìwé ìrìnnà yìí sí “DIPLOMATIC PASSPORT”, “YORUBA NATION, ORÍLẸ-ÈDÈ YORÙBÁ.”

Irọ́ ni! Ìwé ìrìnnà orílẹ̀-èdè Yorùbá kò ní ìdánimọ̀ òfin, wọn kò gbẹ́sẹ̀lé ìwé ìrìnnà Nàìjíríà 
Àfiwé ìwé ìrìnnà inú àhesọ (apá ọ̀tún), àti torí fọ́nrán Facebook 

Láfikún, a ṣe àwárí àmì àjèjì kàn tí ó hàn gbangba lọ́wọ́ òkè apá ọ̀tún, lẹ́gbẹ̀ẹ́ ibi tí wọ́n ti rọ́po ààmì ECOWAS pẹlú ti ààmì Yorùbá Nation. Kódà, wọ́n tún yí àwọ ìwé ìrìnnà yìí padà díẹ̀ láti lè jẹ́ kí ó dàbí òtítọ.

Àkótán

Àhesọ tó wípé àwọn orílẹ̀-èdè ágbàáyé ti ń gbẹ́sẹ̀lé ìwé ìrìnnà Nàìjíríà ṣini lọ́nà, ayédèrú sì ni àwòrán ìwé ìrìnnà Yorùbá Nation tí wón fi kún àtẹ̀jáde náà.

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Back to top button
Translate »