Facebook ChecksFact CheckPoliticsYoruba

Iro ni o! Ààrẹ orilẹ-ede Nàìjíríà tẹlẹ ri, Obasanjo ò kú o

AHESỌ: Ààrẹ orilẹ-ede Nàìjíríà nigba kan ri, Olusegun Obasanjo ti di olóògbé.

ÀBÁJÁDE ÌWÁDÌÍ: Iro ni! Ìwádìí wà àti ìfòròwánilénuwò wa pẹ̀lú agbẹnusọ Obasanjo fi ìdí rè múlẹ pe irọ ni ọrọ náà. 

Ìròyìn lẹkunrẹrẹ

Ogbeni Olusegun Obasanjo ti darí orilẹ-ede Nàìjíríà lẹẹmeji ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ni ìgbà àkọ́kọ́, ọgbẹni Obasanjo jẹ oludari ìjọba ológun láti odún 1976 sí 1979, o sì padà wa gẹgẹbi ààrẹ ìjọba alágbádá ni ọdún 1999 si 2007. 

Laipe yii, ọgbẹni Obasanjo bù ẹnu atẹ lù ìṣèjọba ààrẹ àná, Muhammadu Buhari. Botilejepe o ti se díẹ̀ ti Obasanjo ti kúrò lórí oyè, kò ṣai mẹnuba ihuwasi àwọn aṣejọba ni orilẹ-ede Nàìjíríà. 

Ni ọjọ isẹgun, ọjọ karún osù kẹsan ọdún 2023, fónrán fídíò kán káàkiri orí ìkànnì ibaraẹnisọrọ WhatsApp pẹlu aheso pé, Ogbeni Obasanjo ti papoda. Ṣugbọn, èdè faransé ni won fi kọ àkòrí ọ̀rọ̀ náà. 

“DÉCÈS DE L’ANCIEN PRÉSIDENT DU NIGERIA OLUSHEGUN OBASANJO”, àwọn ọrọ wọnyi ni wọn kọ sí orí fónrán náà. 

Kódà, wọ́n kọ ‘sùn re o’ sì ori fónrán náà, èyí tí o ṣàfihàn àwòrán ọgbẹni Obasanjo.

A ṣe àkíyèsí pé fónrán náà ti gbòde kan, àti wípé àwọn ènìyàn ń bẹrẹ bóyá otitọ ni ọrọ naa tabi irọ, èyí lo fàá tí a fi ṣe ìwádìí wà. Ìdí míràn ni wípé, ènìyàn pàtàkì ni Obasanjo jẹ láwùjọ wa. 

Ifidiododomule

L’akọkọ a ṣe akiyesi àṣìṣe nínú akọtọ orúkọ ààrẹ tẹlẹ ri náà. 

Síwájú sí, a fi ọrọ ti wọn kọ lédè faransé sí orí ohun èlò ìtumò ìgbàlódé, Google Translate. O túmọ ọrọ náa sí ‘Iku ààrẹ tẹlẹ ri orilẹ-ede Nàìjíríà Olusegun Obasanjo”.

Olumulo kan lórí ìkànnì TikTok (Wazobia.fm) lo kọkọ ṣ’atunpin fọ́nrán náà. A ríi wípé ọpọlọpọ ènìyàn ló ti wo fónrán náà, wọn sì bú ọwọ ifẹ lùú.  

A tún rii wípé, olumulo náà kọ jẹ kí àwọn ènìyàn sọrọ tabi bere ìbéèrè nípa fónrán ọ̀ún. 

Fónrán náà lórí ìkànnì TikTok.

Ni ìgbà tí a ṣ’abewo sí ojú òpó náà dáadáa, a ríi wípé olumulo yìí, máa n ṣ’atunpin fidio ‘sunre o’ fún àwọn tó jẹ́ olókìkí, yálà àwọn àlùfáà, tàbí òṣèré tíátà, tàbí àwọn olorin ni orilẹ-ede Nàìjíríà.

A lo itọpinpin kókó ọ̀rọ̀ lati ṣe ìwádìí bóyá ojúlówó iwe ìròyìn kankan gbé ìròyìn nipa iku Obasanjọ, a ríi wípé kò sí oun tó jọ bẹ́ẹ̀.

Lẹyìn eyi, a kàn sí agbẹnusọ ààrẹ teleri náà, Kehinde Akinyemi, èsì rẹ ni wípé ààrẹ teleri náà wà ní alaafia kódà, o rin ìrìn àjò lọ òkè òkun laipẹ yìí. 

“O rìn ìrìn àjò lo sí orílẹ-èdè míràn. Kódà owurọ oni lo kúrò ní orilẹ-ede Nàìjíríà”, esi rẹ sí ìbéèrè wa leyi. 

Àkótán 

Ìwádìí wà ati èsì agbẹnusọ ààrẹ tẹlẹ ri orilẹ-ede Nàìjíríà, Olusegun Obasanjo fihàn pé ìró ponbele ni ìròyìn pé ọgbẹni Obasanjo jáde láyé. 

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Back to top button