Fact CheckPoliticsYoruba

Kìí ṣe Emefiele ló fi obitibiti owó pamọ́ lọnà àìtó, ààrẹ orílẹ̀-èdè Sudan tẹlẹ rí lo ṣee

Ahesọ: Àjọ otelemuye Nàìjíríà ṣe àwárí obitibiti owó tí Emefiele gbé pamọ́ sí ilé.

Kìí ṣe Emefiele ló fi obitibiti owó pamọ́ lọnà àìtó, ààrẹ orílẹ̀-èdè Sudan tẹlẹ rí lo ṣee

Àbájáde ìwádìí: Iró ni. Àyẹ̀wò fínífíní àti ojúlówó ìròyìn fihàn pé fónrán fídíò náà kò tilè ni nkankan ṣe pẹlu àjọ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ àti ọgbẹni Emefiele. Kódà fónrán náà ṣàfihàn àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba Sudan ní ibi tí wọ́n ti ń kó owó tí ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí orílè-èdè Sudan al-Bashir, jí kó.

Ìròyìn lẹkunrẹrẹ

Fónrán fídíò kan tí wọ́n pín kàn wá ṣàlàyé pé Ileeṣe agbofinro orile-ede Naijiria (State Security Service) ṣe imokunpada obitibiti owó ti adari banki àpapọ Godwin Emefiele, ko pamọ́ sí ilé lọ́nà àìtọ́.

Lati ọjọ kẹsan oṣù kẹfà ọdún yii ni ìjọba àpapọ tí pàṣẹ pé kí Ọgbẹni Emefiele dáwọ́ dúró lẹ́nu iṣẹ́ latarii ẹsun ti wọ́n fi kàn-án. Kódà, Ileeṣẹ agbofinro DSS ṣe ìfòròwánilénuwò pẹlu adari agba banki àpapọ fún ìwádìí wọn. 

Olumulo ìkànnì abẹ́yẹfò tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Your Chemistry Tutor (@simplyTEEWHY) lo fi fónrán yìí sì ori ẹrọ alatagba, ọpọlọpọ olumulo ìkànnì náà ló sì satunpin fónrán náà, ti won sì lérò pé otito ni.

Laipe, a rí orísun fónrán náà, a sì ríi wípé olumulo míràn tí orúkọ rẹ̀ ńjẹ́ Fatimah Abdullahi4860 (@FAbdullahi4860) ti ṣ’atunpin fónrán náà. O so wipe:

”Ẹ ni lati ri èyí…oun tí àjọ otelemuye rí ní ilé Emefiele ni èyí.”

Kìí ṣe Emefiele ló fi obitibiti owó pamọ́ lọnà àìtó, ààrẹ orílẹ̀-èdè Sudan tẹlẹ rí lo ṣee
Atẹjade orí ikanni abẹ́yẹfò Twitter

Fónrán iṣẹju aaya merindinlogbon náà ṣàfihàn ọkùnrin méjì ni yàrá nla kan ti o kún fún owó dọ́là. Bi ẹnìkan nínú wọn ṣe bèrè síí ko owó kuro ninu àpò kan, ẹnikeji bèrè síí ko owó náà sí orí pẹpẹ ti wọ́n ti ń ka owó.

Ọpọlọpọ olumulo lo wo fídíò náà, won sọrọ nípa rẹ, won sì ṣ’atunpin rẹ. Oníkálukú ló rí oun kan tàbí méjì sọ nípa fónrán náà. 

Olumulo kan, Abbåh Jåmø (@realhajjibaba) gbàgbọ́ nínú ahesọ náà, kódà ó ní òun ò lè ronú ìdí tí ọ̀gá àgbà bánkì àpapọ náà ṣe kó owó tabua náà pamọ́.

“Nibo lo ń gbé owó yii lọ, nitorí Olorun?” olumulo náà lo bèèrè èyí.

Ṣùgbọ́n olumulo míràn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Usman ss (@usman_sulayman_), kò fi tara tara gbàgbọ́ nínú ahesọ náà, ó ní;

“Ṣé ó dáwa lójú pé èyí ṣẹlẹ ní ilé Emefiele?”

Ẹ̀wẹ̀, nítorí pàtàkì ọrọ yìí àti gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ laipẹ yìí tí ó fa ìdádúró lẹnu iṣẹ fún ọ̀gá àgbà CBN náà, DUBAWA ṣe ìwádìí yìí láti fi ìdí òdodo múlẹ̀.

Isamudaju ọrọ

Ìgbésẹ̀ kinni tí a gbé ni àyẹ̀wò fónrán náà fínífíní, kí a le mọ̀ bóyá a rí oun kan tàbí méjì tí ó ma ṣ’atọ́nnà bóyá yàrá náà jẹ́ òkan nínú àwọn yàrá ilé ọ̀gá àgbà CBN ọgbẹni Emefiele tàbí yàrá àjọ otelemuye, DSS.

Oun kan pàtàkì ni wípé kò sí nkankan nínú àwọn arákùnrin náà tó wọ asọ idanimọ àjọ otelemuye náà, tabi kaadi idanimo ti a le fi mọ boya awọn agbofinro orilẹ-ède Nàìjíríà ni wọ́n jẹ́.

Oun míràn tó mú ìfura dání, ní wípé a kò gbọ́ ohùn kankan. Awọn arákùnrin tí wọ́n yà sínú fónrán náà, wọn kò f’ọhun, bẹẹ kò sí ounkóun tó tọka sí bóyá wọ́n jẹ́ òṣìṣẹ́ àjọ otelemuye Nàìjíríà.

Bákan náà, yàrá ibi tí àwọn arákùnrin náà wà kò dàbí pé wọ́n wà ní ilé ẹnikẹni. Yàrá náà farajọ gbọ̀gán bíi èyí ti wọ́n lò ní ilé iṣẹ́ tí ó ni ọpọlọpọ tábìlì àti àwọn àpótí. 

A ṣe àyẹ̀wò ìròyìn lórí bíi àjọ otelemuye ṣe ṣ’abewo sí ilé Emefiele láti ṣe ìwádìí. A ríi wípé iṣẹlẹ náà ti pẹ́ díẹ̀, torí ó ṣẹlẹ ní oṣù kinni ọdún yìí, ní ìgbà tí wọ́n ṣ’abewo sí ofiisi gomina banki agba náà ni olú ileese banki àpapọ Nàìjíríà.

Botilẹjẹpe nínú gbogbo rògbòdìyàn àtìmọ́lé Emefiele, àjọ otelemuye s’ọrọ nípa èròngbà wọn láti ṣe ìwádìí nínú ilé àti ofiisi Emefiele, wọ́n kò tíì ṣeé.

Ṣugbọn, ki a le mọ orísun fónrán náà, a ṣe itọpinpin rẹ̀ lórí ayélujára, a ríi wípé ìwé ìròhìn The Spy ti lo fónrán náà ní ọjọ́ kokandinlogun oṣù kẹrin ọdún 2019.

Iwe ìròyìn The Spy ṣàlàyé bí wọ́n se rí “mílíọ̀nù mẹwa owó òkè òkun (dola)” nínú àpò owó nínú ilé ààrẹ teleri ìlú Sudan, Omar al-Bashir tí àwọn ológun yọọ́ nípò, ni ọdún 2019.

Ìwé ìròyìn naa mẹnuba fónrán akalekalo kan tí wọ́n ṣ’atunpin sórí ìkànnì amohunmaworan orí ayélujára, YouTube, tí o ṣ’afihan bí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba Sudan ṣe ń gbé owó kúrò ní inú àpò owó kan. Àwọn owó náà wà ní ìlé ọgọrun àti ọgọta dola.

Fónrán yìí kànnà ni olumulo ìkànnì abẹ́yẹfò Fatimah Abdullahi4860 (@FAbdullahi4860) ṣ’atunpin sí ojú òpó rẹ̀. Ṣùgbọ́n, a ríi wípé nínú fónrán ti wọ́n pín sí orí ìkànnì YouTube, a gbọ́ ohùn ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń ka owó, àti ohùn ẹnikan tí ó n sọ èdè àwọn ará Sudan.

Lati fi ìdí òdodo múlẹ̀, a ṣe àbẹ̀wò àwọn ìwé ìròyìn to munadoko bóyá wọ́n gbé ìròyìn náà ní àsìkò tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé.

A ríi wípé ni ogunjo, osu kẹrin, odun 2019, iwe ìròyìn the Independent ṣ’àlàyé pé ìwádìí ń lọ lórí bí Omar al-Bashir ṣe kó owó pamọ́ lọnà àìtọ́, lẹ́yìn tí wọ́n ṣe àwárí “ọpọlọpọ owó òkè òkun bíi dola, pound ati awọn owó ile won” ni ile rẹ.

Kódà, ilé-isé ìròyìn British Broadcasting Corporation (BBC) gbé ìròyìn yi kan naà, wọ́n sọ wípé, “Won se awari obitibiti owó ní ilé al-Bashir”, àti wípé wọ́n ti fi ṣikun òfin mú ààrẹ tẹlẹ ri orilẹ-ede Sudan náà. 

Àkótán ọrọ 

Iro nla ni aheso naa. Kò sí oun kankan tó fìdí rẹ múlẹ pe fónrán náà ni òun kankan ṣe pẹ̀lú Ọgbẹni Emefiele tabi àjọ otelemuye Nàìjíríà DSS. Bakan náà, àwọn àlàyé tí a gbà sílẹ̀ láti àwọn ojúlówó ìwé ìròyìn fi ìdí rè múlẹ̀ pe wọ́n gba fónrán náà sílẹ̀ ni ilé ààrẹ tẹlẹri orile-ede Sudan, al-Bashir, leyin ti àṣírí tú pé ó kó owó pamọ́ lọnà àìtọ́

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Back to top button