Getting your Trinity Audio player ready...
|
Aheso: Atejade kan ti won tan ka ori ikanni Whatsapp salaye pe bébà ìgbọ̀nsẹ̀ le fa akoransi ẹ̀ya ìtọ̀ ara obinrin.

Abajade iwadii: Aṣinílọ́nà! Iwadii fihan pe ti obinrin ba lo bébà naa lati fi nu idi lati ẹ̀yìn lo si iwaju oju ara, o le ko akoran. Sugbon, ko si oun to tokasi pe bébà naa lo n fa akoran, éyí nilo iwadii.
Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ alaye
Awon olumulo ikanni WhatsApp ṣ’atunpin atejade kan ti o so wipe lilo bébà ìgbọ̀nsẹ̀ le fa akoran si oju ara obinrin.
Wọn ṣ’atunpin atejade na lati se ikilo fun awon obinrin ki won le wa ni ailewu.
“Mọ daju pe bébà ìgbọ̀nsẹ̀ le fa akoran si oju ara obinrin. Jọ̀wọ́, fojusi ilera ara re, mo ki yin ku odun tuntun,” atejade naa wi.
Sugbon ko si oruko eni to fi oro naa sita, tabi linki awon eniyan si ti satunpin re ni opolopo igba si awon ara, ọ̀rẹ́ ati ojulumọ wọn.
Nitori pataki ọ̀rọ̀ naa si ilera àwùjọ eniyan, DUBAWA ṣe iwadii.
Ifidiododomulẹ̀
Akoran ẹ̀yà ìtọ̀ je aarun to maa n dojúkọ ọ̀nà-ìtọ̀, àpò ìtọ̀, ìfun ìtọ̀ tabi kíndìnrí. Akoran maa n saba ṣe ikọlu si àpò-ìtọ̀ àti ọ̀nà-ìtọ̀.
Ami apeere akoran naa ni ki eniyan maa ri ẹ̀jẹ̀ ninu ìtọ̀, ki ìtọ̀ bere sii gbọn eeyan ni gbogbo igba, ati òòrúùn kikan ninu ìtọ̀. O saba maa n da obinrin laamu ju okunrin lọ.
Akoran yii ma n bere ni igba ti kokoro afaisan ailefojuri ba wọ inu ọ̀nà ìtọ̀ (urethra) ti o si gba ibẹ lọ inu àpòòtọ̀ (bladder) ti o si bere sii dagba sibe. Bébà ìgbọ̀nsẹ̀ ni awon eniyan maa n saba fi n nu idi ti wọ́n ba ṣe ìgbọ̀nsẹ̀ tan.
Wọn ṣ’ẹda rẹ lati ara igi bii igi apádò, igi arère, ati awon igi miran.
Awon ti won seda bébà naa maa n lo òyì-iná (oxygen), òyì-àrá (ozone), kẹmika hydroxide tabi peroxide ki bébà naa funfun sii. Nigba ti awon oluseda miran maa n lo kẹmika chlorine dioxide.
Nibayi, ǹjẹ́ àṣepọ̀ kankan wa laarin bébà ìgbọ̀nsẹ̀ ati akoran ẹ̀ya ìtọ̀ ara?
Iwadii kan ti won gbe jade laipe yii fihan pe ti obinrin ba lo beba naa lati fi nu idi lati eyin lo si iwaju oju ara, o le ko akoran. Sugbon, ko si oun to tokasi pe bébà naa lo n fa akoran, eyi nilo iwadii.
Ekanem Eyo, ẹni ti o je ojogbon nipa ilera ọmọde, ni ilé ẹ̀kọ́ giga ti ilu Uyo salaye pe beba ìgbọ̀nsẹ̀ o le fa akoran si eya ito ara sugbon ona ti won gba lo beba naa le faa.
Ekanem so wipe, “Beba ìgbọ̀nsẹ̀ ò le fa akoran si eya ito. Nko mo ti awon kemika to le ṣe ijamba ba wa ninu beba ìgbọ̀nsẹ̀, nko le so nkankan nipa rẹ̀.”
O tunbo so siwaju si pe ti obinrin ba nu idi lati eyin lo si iwaju, eyi le mu ki kokoro afaisan ailefojuri lo lati furo wo inu ọ̀nà ìtọ̀.
Ekanem sọ pe o se pataki ki obinrin nu idi lati waju lo si eyin yala ti wọn ba yagbe tabi tọ.
Alaye re dale iriri re gegebi oludari ile iwosan fásitì Uyo, ni ibi ti o ti ṣiṣẹ́ pelu awon dokita ilera obinrin ati awon onimo miran.
Kelvin Echetabu, dokita ti o n se itoju ilera awon okunrin ni ile ìwòsàn fasiti Nsukka sọ wipe ko si kẹmika kankan ninu bébà ìgbọ̀nsẹ̀ ti o le fa akoran fun obinrin.
O salaye pe ti obinrin ba fi beba ìgbọ̀nsẹ̀ nu furo lo si oju ara, tabi lilo awon inudi miran, eyi lo le mu ki kokoro aifojuri gba furo lo si ona ito ati apooto, ti yoo si fa akoran.
Oun kan pato nipa beba ìgbọ̀nsẹ̀ ni wipe ti won ba fi nu idi tan, o le lẹ̀ mọ́ oju ara paapaa ti eeyan ba ṣẹṣẹ tọ tan tabi da omi si oju ara. Ti eyi ba wọ inu ọ̀nà-ìtọ̀ lọ, o le mu akoba ba eya ito ara, Kelvin lo salaye eyi.
Akotan
Iwadii ati awon onimo fihan pe lilo bébà ìgbọ̀nsẹ̀ kọ lo n fa akoran eya ito ara bikose bi onitoun se lo. Nitori naa, irọ́ nla ni aheso naa.