Fact CheckHealthYoruba

Kò sí ẹ̀rí tó dájú pé ènìyàn lè fi kanafuru àti ata ilẹ̀/aáyù fọ ile ọmọ

Getting your Trinity Audio player ready...

Aheso: A lè fi kanafuru àti ata ilẹ̀ fọ ilé ọmọ obinrin.

<strong>Kò sí ẹ̀rí tó dájú pé ènìyàn lè fi kanafuru àti ata ilẹ̀/aáyù fọ ile ọmọ</strong>

Àbájáde ìwádìí: Irọ́ ni! Àwọn àkọsílẹ̀ ìmọ̀ ìṣègùn òyìnbó àti àwọn onímọ̀ ṣàlàyé pé kò sí oun tó jọ bẹ́ẹ̀. 

Iroyin lẹkunrẹrẹ

Ní ayé òde òní, ọpọlọpọ ènìyàn ló n wa ọnà àdáyébá tí wọ́n lè fi ṣe ìtọ́jú ara wọn, yatọ si lilo oògùn òyìnbó. Ojú òpó kan l’órí ìkànnì ibaraẹnisọre Facebook, Fertility Guideline Group ṣàlàyé pé èèyàn lè lo kanafuru ati ata ilẹ̀/aáyù fi fọ ilé ọmọ.

Ojú òpó náà sàlàyé pé ki èèyàn kọ́kọ́ bu omi s’ínú ìgò, leyin eyi, a fi kanafuru ati ègé ata ilẹ̀/aáyù sínú ẹ̀, a ṣí gbe pámọ́ fún ọjọ́ mẹta, léyìn èyí, a gbe sí inú ẹ̀rọ amóúnjẹ tutù. O fikun wípé ki wọn gbe kanna laaro kutukutu ki wọn ṣì gbe mú kinwon to jẹ oúnjẹ aarọ. Obìnrin le mu àgbo yíì nígbà nnkan osu, sùgbón wọn kò gbọdọ mu ni asiko ti ara obìnrin ba n ye ẹyin (ovulation). Oju opo náà fikun wípé àwọn ọkùnrin ti o ni ààrùn Ibalopọ Chlamydia tàbí gonorrhea le loo.

Olumulo míràn l’ori ìkànnì ibaraẹnisọre Facebook, ẹni ti oruko re n jẹ Tomi Adenuga, náà jẹrisi oro yíi.

A ríi wípé ọpọlọpọ ènìyàn ló ti wò fónrán óún, wọn ṣì ti satunpin re laimoye ìgbà. 

Nítorí itakanle ọ̀rọ̀ náà ati pé ó ṣe pàtàkì fún ọ̀rọ̀ ìlera láwùjọ, DUBAWA fi ìdí òdodo múlẹ̀. 

Ifidiododomule

Ile-ise Healthline ṣàlàyé pé èròjà eugenol wa nínú kanafuru, èyí ti ọ máa n ṣe ìtọ́jú wàhálà tabí àníyàn. Kódà, òróró ti a gba silẹ latara kanafuru máà n pa oró kòkòrò jẹjẹrẹ ọpa ounje ti inu ofun ati awon aarun míràn. Kódà o fi múlẹ pé lóòtọ́, èròjà to ti ara kanafuru wa àti egboogi nigericin le ṣe itọju ṣuga inú ẹjẹ, mu ki eegun ènìyàn le si, ṣe itoju ọgbẹ́ inu tàbí jẹjẹrẹ ikùn. 

Àkọsílẹ Medical News Today fihàn pé èròjà ara kanafuru ti mu idinku ba èèyàn to saran lasan jù. Àkọsílẹ náà tunbo fikun wípé àwọn eku ti wọn fún ní eroja ti a mu jade lára kanafuru padanu ọra ara to pọ̀ lapọju.

Kódà àwọn àkọsílẹ Breathe Well-being, Verywell Health, MedicineNet, ati Drug.com ṣàgbékalẹ̀ orisirisi anfààní to wa lara kanafuru, kò sí ẹyi to mẹnuba fífọ ilé ọmọ.

Njẹ ata ilẹ/aáyù lè fọ ile ọmọ obìnrin?

Medical News Today sàlàyé pé ata ilẹ/aáyù máa n gbogun ti oríṣiríṣi ààrùn lago ara bii jẹjẹrẹ ẹdọfóró, jẹjẹrẹ ọpọlọ, àwòkà eégún ibadi, ààrùn ọkan, ìtọ̀ ṣuga àti ifunpa gíga. PharmEasy, Spice World, Everyday Health, Real Simple, ati Health.com gbogbo won lo tọka sí ànfààní ti ata Ile/aáyù n se laago ara. Sugbọn ko sí ẹyi to menuba iṣẹ to n se ni ile ọmọ obinrin. 

Kini onimo so?

Ninu ìfòròwánilénuwò wa pelu Dokita Victoria Shittu, onimọ náà sọ wípé kò sí ẹrí tó dájú nínú ìmọ̀ sáyẹ́nsì to le ṣe atilẹyin ahesọ náà. 

“Ile ọmọ obinrin o nilo pé wọn fọ. Sugbọn awon ẹlòmíràn maa n wa ọna ti wọn yoo fi mu idoti wọ inu re, bíi atejade ori ikanni ibaraẹnisọre yẹn,” Dokita naa ṣàlàyé. 

O fikun wipe fifọ ile ọmọ kíì sé dandan. Bi won bá tiẹ fẹ fọ ile ọmọ, ojúṣe àwọn onímọ̀ isegun òyìnbó nìyẹn, pàápàá ti awon ìdòtí keekeekee kọọkan ba ráyè wọ inu rẹ̀.

“Ile ọmọ ti kò ni idọti o nilo fifọ. Kódà, eni ti inu ile ọmọ re ba kò idoti lèyìn iṣẹyun, o ni awon nkan ti a má lo gegebi onimo isegun” dókítà náà lo sọ èyí.

Dokita Nathaniel Adewole, ẹni ti o jé onimọ nipa ìlera ara obìnrin ni ile-iwosan Yunifásítì ti Abuja sọ pé kò sí oun tó jọ bẹẹ, ati wípé oun isebẹ, ata ilẹ ati kanafuru kò le fọ ile ọmọ obinrin. 

Akotan 

Iro ni òrò náà. Kòsí ìwádìí kankan ninu ìmọ sayensi tàbi onimo nipa ìlera ara obìnrin to satileyin aheso pé ata ilẹ ati kanafuru le fọ ile ọmọ obìnrin. 

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Back to top button