Fact CheckHealthYoruba

Kòsí eri to daju pé a le fi ewe ọ̀pẹ òyìnbó dẹkùn ìgbẹ́ ọ̀rìn

Getting your Trinity Audio player ready...

Aheso: Olumulo ikanni ibaraẹnisọrẹ Facebook salaye pé a le fi omí latara ewe opeyinbo ṣe ìtọjú ààrùn ìgbẹ́ ọ̀rìn.

Kòsí eri to daju pé a le fi ewe ọ̀pẹ òyìnbó dẹkùn ìgbẹ́ ọ̀rìn

Alaye l’ẹkunrẹrẹ 

Ààrùn ìgbẹ́ ọ̀rìn máà n farayo nipasẹ ki èniyàn máà ya igbẹ gbuuru yala omodé tàbí àgbàlagbà léyìn ti wón ba jẹ ounjẹ tabi mu omí tí kò dára. Ó ṣeéṣe kí àgbàlagbà f’ori lugbadi aarun yii lẹẹkan l’ọdun, èèmejì lọdun fún ọmọde. Àjọ ti o n rísí ètò ìlera  sàlàyé pé ààrùn ìgbẹ́ ọ̀rìn yii le farahàn fẹẹrẹfẹ, ki èniyàn níí fún ojó méjì pere, o si le burú jáì débi pé ènìyàn a ya’gbe gbuuru fún ọ̀sẹ̀ mẹta. 

Laipẹ yii, olumulo kan lori ikanni ibaraẹnisọrẹ Facebook sọ pé ti a bá rin ewé opẹyinbo sinu omi, eyi le ṣẹ ìwòsàn ààrùn ìgbẹ́ ọ̀rìn, yala fún ọmọde tàbí àgbàlagbà. Olumulo naa sọ wípé ti a ba bọ ewe opẹyinbo ninu omi gbóná, leyin iṣẹju diẹ, ti omí náà ba tútù, àgbàlagbà le mu ife omí yii lẹẹkan tabi lẹmeji lojumọ fún ọ̀sẹ̀ kan, àwọn ọmọdé, bẹrẹ láti ọmọ odun márùún le mu ilaarin ife omi yìí lẹmeji lojumọ fún ọ̀sẹ̀ kan. Ṣugbọn o parowa fun wón pè ki aláboyún ati awon ọmọ ọwọ máṣe mu omi yìí.

“E je ki n ko yin ti e se le ṣẹ itoju ìgbẹ́ ọ̀rìn nínu ilẹ. Bi eniyan ba jẹ majele tabi ounjẹ ti ko dára, oun tí ẹ nilo ni ewé opeyinbo ati omi lita kan.

“E fi àwọn elo wònyí sì inu àbọ, e ṣàán daada ki e sì bọ̀ọ́ fun iseju mẹẹdogun, ti o ba tútù, e mu ife omi yii leemeji lojumọ fún ọ̀sẹ̀ kan, e o rii pe aarun ìgbẹ́ ọ̀rìn yii a d’ohun ìgbàgbé. 

“Fun ọmọdé, bèèrè láti ọmọ ọdun márùn, ni ilaarin ife omi yìí leemeji lojumo fún ọ̀sẹ̀ kan. Ẹjọwọ, e ma se je ki ọmọ ọwọ sì ọmọ odun meji mu ọmi yii, koda alaboyun o gbọdọ muu,” arabinrin náà salaye.

Ọpọlọpọ eniyan lo ri atejade naa lórí ẹrọ alatagba ti wón ṣi gbagbọ. DUBAWA pinnu láti ṣe iwadii ọrọ naa, pàápàá nitori ewu ti o le wa nínú lílo apopo yii fún iwosan ìgbẹ́ ọ̀rìn yala fún ọmọde tàbí àgbàlagbà. 

Ifidiododomule 

Nínú ìwádìí ti Dokita Farid Hossain, Shaheen Akhtar, ati Mustafa Anwa ṣe lórí ànfààní opẹyinbo, won ríi wípé eso ati gbongbo opeyinbo wúlò lọpọlọpọ. Koda, ìwádìí naa fihan pe àgbo ti wón fi gbongbo opeyinbo ṣe, lè dẹkun ààrùn ìgbẹ́ ọ̀rìn.

Akọsilẹ ile-iṣẹ Healthline ṣ’ayẹwo èso opeyinbo ati ewé rè àti iwulo wọn ninu eto ilera ode òní. Wón fi idi re mu’le pé ewe opeyinbo le ṣẹ ànfààní fún ara, o le mu àpọ̀jù ọ̀rá inu eje wa sile, o le se iranwọ fún eto ẹ̀da oúnjẹ ati awon anfaani miran.

Ṣugbọn o se pataki ki a fì idi re mu’le pé wón ṣe àwọn ìwádìí wọnyí lórí èkúté.

Imọran àwọn onimọ 

Ninu ìfòròwánilénuwò wa pẹlú Johnson Udodi, eni ti o jẹ onisegun òyìnbó ni ile iwosan ijoba ti ilu Abuja, ó ṣàlàyé pé èèyàn to ni ààrùn ìgbé orin máà tete pàdánù omí ati iyọ ara, o si se pataki ki alaisan mu omi iyò yala ti inu ọrá, tabi eyi ti a popọ nínu ile, pẹlú òògùn. Dokita Udodi sọ wípé irufe aheso yíì le mu kí awon eniyan kọ̀ láti ṣe oun tó yẹ.

“Tí ènìyàn ba pàdánù omí ati iyọ ara lera lera, eyi le mu ikú dani, bi a ti ríi ni ti àisàn onígbàmeji to bẹ sile lorile-ede Nàìjíríà. Ṣíṣe àfikún omi ati iyọ̀ ara ṣe kókó, yala nípasẹ omi ati iyọ t’inu ọrá tàbí èyí ti a sé nínú ilè, àwọn nkan wọnyi ṣe kókó fún itọju. 

“Lilo omi iyò yìí ti ràn àwọn eniyan lọwọ ki wọn ma pàdánù ẹ̀mí wọn. Kódà àwọn dókítà máà n fun àwọn ènìyàn ni egbòogi to gbogun ti ailera yii. Kosi eri to daju pé apopọ ti arabinrin yii mẹnuba le ṣẹ itoju aiṣan. 

“Koda aheso náa le ṣẹ ìjàmbá, nípasẹ̀ pé awon eniyan le kọ̀ jalẹ láti ṣe oun to tọ bíi mímú omi iyọ̀, tabi kọ̀ lati wa sí ile iwosan fun itọju,” dokita náà lo sọ eyi. 

Bákan náà, Nneka Ogbodo, dokita agba ni ile iwosan ijoba naa, so pé oún kò tíì ri ìwádìí kankan lórí ìmúlò ewé opẹyinbo fún itọju ààrùn ìgbé orin. Dokita obirin náà salaye pé biotilẹjẹpe ó rọrun láti ṣe itọju ààrùn igbe orin, o ṣeéṣe ki èniyàn ṣe àsìse pàápàá lórí àwọn ọmọdé. Dokita sọ wípé àfikún omi sí àgọ ara ṣe pàtàkì, ki aláìsàn to ri itọju gba nílé ìwosàn.

“Mi o mọ nipa ìwádìí kankan ti wón gbè jade lórí anfaani mímú omi ewe opeyinbo. E je ka yẹra fún àwọn aheso ti ko ni ipilẹ ninu imọ sayẹnsi, nitori o le mu kí aisan náà burú si.

“Itoju ààrùn igbe orin rọrun ṣugbọn o le seku pani ti a kò bà ṣe itọju naa daada paapa fún àwọn ọmọdé. Fún àwọn ti o ni aarun yii, o se pataki ki a sè àfikún omi ara siwaju itọju nile ìwòsan.”

Akotan 

Kó si eri to daju pé ewe opẹyinbo le ṣẹ ìtọjú ààrùn ìgbé orin. Àwọn onimọ gbani nimoran pe ki aláìsàn lo omi iyò, yala t’inu ora tàbí èyí ti a popọ nínu ile, yàgò fún àwọn ounje kọọkan, ki aláìsàn sì wa itọju lọ ilé ìwòsan.

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Back to top button