Fact CheckHealthYoruba

Njẹ “oogun Brahmi” yìí jé egbòogi imularada fún àìsàn ẹjẹ riru?

Aheso: Ojú òpó kan lórí Facebook lo kéde pé àwọn n ta òògùn kiibati ti o ma mu opin ba àìsàn ẹjẹ riru, eyi ti o je oogun Brahmi.

Abajade ìwádìí: Irọ ponbele ni. Àjọ elétò ìlera lágbayé, World Health Organization (WHO) ati awọn onimọ nipa oògùn òyìnbó ti ṣàlàyé pé kò sí egbòogi imularada kankan ti o je kiibati fún àìsàn ẹjẹ riru. 

Ìròyìn lẹkunrẹrẹ 

Àjọ WHO ṣ’apejuwe àìsàn ẹjẹ ríru ti a mọ̀ sí ifunpa gíga, gẹ́gẹ́bí àìlera tó máa n jẹ́yọ ni ìgbà tí ẹ̀jẹ̀ ba rú sókè tabi ti ifunpa ènìyàn ba kọjá gbedeke tabi àlà ti imo sayensi fi sílẹ̀ (140/90mmHg). Àìsàn yi wọ́pọ̀ ṣùgbọ́n ó mú ewu dani ti a koba se itoju rẹ̀. Àwọn ẹlòmíràn le ni àìsàn ẹ̀jẹ̀ ríru ki o má sí aami àìsàn lára wọn, nítorí náà ọ̀nà kan ti awọn ènìyàn fi le mọ̀ bóyá wọ́n ní ẹjẹ ríru ni kí wọ́n ṣe àyẹwò ifunpa wọn.

Ojú òpó kan lórí ìkànnì Facebook, Life and Food fi àtẹ̀jáde kan sí ojú òpó rẹ̀, o ni o ṣe òun ní kàyéfì pé àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà gbàgbọ́ pé kò sí egbòogi imularada fún ẹ̀jẹ̀ ríru, o sì fikun wípé oògùn kan wà tó le wo àìsàn náà.

Fónrán fídíò ìṣẹ́jú àáyá merindilaadota pẹ̀lú linki kan wà lórí atẹjade náà ti o ṣàlàyé bi ẹjẹ ríru ṣe lè fa ààrùn rọpárọsẹ̀ ati ìfọ́jú. Ohùn tí a gbọ́ ninu fídíò náà ṣàlàyé pé oògùn kiibati kan wa nínú linki ti wọn fi sí atejade naa. 

Ọpọlọpọ olumulo ìkànnì Facebook lo ti ká àtẹ̀jáde náà, o sì ṣeéṣe kí ó ní ipa lórí ọrọ̀ ìlera láwùjọ, èyí ló jẹ́ kí DUBAWA ṣe ìwádìí lórí ọrọ náà.  

Ifidiododomule 

Linki ti wọn fi sí orí atẹjade náà gbé wa lọ sí ojú aaye ayelujara Healthier Living. Àkọsílẹ náà sọ ìtàn arakunrin kan to ni àìsàn ẹjẹ riru fún ọdún mẹta ki o to di pe o ṣ’abapade pẹlu eniyan kan to fi “oògùn Brahmi” hàn.

Ìwádìí DUBAWA fihan pe oògùn Brahmi ni àwọn oloyinbo n pe ni Bacopa monnieri. Àwọn onise isegun ibilẹ ti n lo òògùn naa láti ayédáyé. Wọn máa n lo lati mu ọpọlọ ṣ’iṣẹ daada, tọju èèyàn tó ní ìjaya ojiji ati ààrùn wárápá.

Botilejepe wọn lo òògùn Brahmi fún itọju àìsàn ẹjẹ ríru ni inú àwọn ẹranko, kò sí ìwádìí sáyẹnsì kankan tó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé wọn le lo òògùn yi fún ọmọ ènìyàn. 

Àjọ National Kidney Foundation ṣàlàyé pé kò sí egbòogi imularada kiibati fún àìsàn ẹjẹ riru ṣugbọn a lè se ìtọ́jú rẹ nipasẹ gbígbé ìgbé ayé tó dára.

Kini awon onimọ oògùn oyinbo sọ?  

Onímọ̀ nípa oògùn òyìnbó ni Federal Medical Center ti ìlú Jabi, Tessy Ahmadu sọ pé àìsàn ẹjẹ riru máa n tipase ọjọ orí ènìyàn, o le jẹ ajogunba tabi ki o bẹrẹ ni igba tí obinrin ba ní oyún. O ni, “Bi a ṣe n dagba sí, awọn ẹ̀yà ara to n gbe ẹjẹ máa bẹrẹ síi di aláìlágbára.

Botilejepe àwọn ìwádìí kan fi múlẹ̀ pé oògùn Brahmi ṣiṣẹ́ fun àwọn ẹranko, àwọn onímọ̀ ni lati ṣe ìwádìí miran lori oògùn naa fún àwọn ọmọ ènìyàn, ati wipe won ni lati sọ iwọn oogun ti wọn ní lati lo. 

Nígbà ti a béèrè lọwọ arábìnrin Ahmadu ti egbòogi kiibati kankan ba wa fun àìsàn ẹjẹ ríru, onimọ náà jẹ kó yẹ wa pé kò sí nkankan to jọ bẹẹ. 

Dọ́kítà Amodu Opeyemi, onímọ̀ nípa iṣegun òyìnbó ni Rufina Catholic Medical Center ni ìpínlẹ̀ Ogun sọ pé, “Ko sí òun kan taara ti máa n fa ẹjẹ riru, sugbon ọpọlọpọ nkan lo se ṣokunfa ẹjẹ riru lára ènìyàn. Ni ìgbà míràn, eniyan lè ní ẹjẹ riru torí awon obi rẹ ni àìsàn náà, o seese ki a ṣ’atunṣe sí ẹjẹ ríru yìí. Ni igba miran, ko ṣeéṣe ki ènìyàn ṣe àtúnṣe sí àwọn ẹjẹ ríru, eyi ti o máa n saba wọpọ ninu awọn ti o máa n fa sìgá tàbí àwọn ènìyàn ti ọrá po lara wọn.”

O f’ikun wípé kò sí egbòogi imularada kiibati fún àìsàn ẹ̀jẹ̀ ríru, “A o tii ri egbòogi imularada kankan fún àìsàn ẹjẹ riru. Ìwádìí n lọ lórí àìsàn náà, ṣùgbọ́n a lè se itoju rẹ̀ nipasẹ oògùn ti o máa mú ẹjẹ riru wa sílẹ̀, din jije iyọ̀ kù ati ki ènìyàn ṣe eré ìdárayá. Ẹmá jẹ ki ẹnikẹni tán yín pé oògùn imularada kiibati kankan wa fún ẹ̀jẹ̀ ríru. Itọju nikan la le ṣe.”

Àkótán

Botilejepe wọn n lo òògùn Brahmi lati se itoju àìsàn ẹjẹ riru nínú àwọn ẹranko, o ṣe pàtàkì fun awon onimọ lati ṣe ìwádìí lilo oogun naa lori ọmọ ènìyàn. Lasiko yii, ko sí oògún kiibati kankan fún itọju ifunpa gíga. 

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Back to top button